1 Ọba 10:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ayaba Ṣeba bẹ Solomoni wò
10 (A)Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle.
Read full chapter
1 Ọba 10:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńláńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.
Read full chapter
2 Kronika 9:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ọbabìnrin Ṣeba bẹ Solomoni wò
9 (A)Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.