Add parallel Print Page Options

Ẹ̀dá alààyè àti ògo Olúwa

(A)Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrín àwọn ìgbèkùn ní etí odò Kebari, àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.

Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn ọba Jehoiakini— ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Esekiẹli, ọmọ Busii wá, létí odò Kebari ni ilẹ̀ àwọn ará Babeli. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.

Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, (B)àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin. Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán. Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́, ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.

10 (C)Báyìí ni ìrísí ojú àwọn ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apá ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì. 11 Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn. 12 Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ. 13 Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná fìtílà. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrín àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀. 14 Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá.

15 (D)Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 16 Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kirisoleti, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú. 17 Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà sí ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ. 18 Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká.

19 Bí àwọn ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹ̀gbẹ́ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè. 20 Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn. 21 Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́.

22 Ohun tí ó dàbí òfúrufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù. 23 Ìyẹ́ wọn sì tọ́ lábẹ́ òfúrufú, èkínní sí èkejì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ méjì méjì tí ó bo ara wọn. 24 (E)Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀.

25 Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n. 26 (F)Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. 27 Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká. 28 Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká.

Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.

Ọlọ́run pe Esekiẹli

Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀.” Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí sì wọ inú mi ó mú mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì ń gbọ́ tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀.

Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní olónìí. Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí’ Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀—nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn. Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n. Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. (G)Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má ṣe ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.”

Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé kíká sì wà níbẹ̀, 10 ó sì tú ìwé náà fún mi. Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ìpohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí.

Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé kíká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.” Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà.

Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwé kíká tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.

Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsin yìí bá mi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ilé Israẹli. A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè Israẹli ni mo rán ọ sí kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ìbá sì fetísílẹ̀ sí ọ. Ṣùgbọ́n ilé Israẹli kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Israẹli. Ṣùgbọ́n bí i tiwọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le. Èmi yóò ṣe iwájú orí rẹ bí òkúta tó le jùlọ, ànító le ju òkúta-ìbọn lọ. Má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí jẹ́ kí wọn ó dáyà já ọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”

10 Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, kí o sì gba gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ọkàn rẹ. 11 Lọ nísinsin yìí sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ tó wà ní ìgbèkùn. Sọ fún wọn pé báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn kò gbọ́.”

12 Nígbà náà ni Ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi tó sọ pé, kí a gbé ògo Olúwa ga láti ibùgbé rẹ̀ wá! 13 Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá. 14 Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle Olúwa ni ara mi. 15 Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kebari níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Abibu. Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrín wọn pẹ̀lú ìyanu, fún ọjọ́ méje.

Ìkìlọ̀ sí Israẹli

16 (H)Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 17 “Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. 18 Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, dájúdájú, ‘Ìwọ yóò kú,’ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 19 Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí ó kọ̀ tí kò fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ọrùn tìrẹ ti mọ́.

20 “Bákan náà, bí olódodo kan bá yípadà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àìṣòdodo, tí mo sì fi ohun ìkọ̀sẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Nítorí pé ìwọ kọ̀ láti kìlọ̀ fún un, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a ó gbàgbé gbogbo ìwà rere tó ti hù tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún olódodo tó sì dáwọ́ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dúró, dájúdájú òun yóò yè nítorí pé ó ti gba ìkìlọ̀, ọrùn tìrẹ sì mọ́.”

22 Ọwọ́ Olúwa wà lára mi níbẹ̀, ó sì wí fún mi pé, “Dìde, lọ sí ibi tí ó tẹ́jú, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.” 23 Mo sì dìde, mo lọ sí ibi tí ó tẹ́jú. Ògo Olúwa dúró níbẹ̀, ó dàbí irú ògo tí mo rí létí odò Kebari, mo sì dojúbolẹ̀.

24 Nígbà náà ni Ẹ̀mí wọ inú mi, tí ó sì tún gbé mi dúró. Ó sì wí fún mi pé: “Lọ, ti ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ 25 ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, wọn yóò fi okùn dè ọ́ mọ́lẹ̀; dé ibi pé ìwọ kò ní í le rìn káàkiri láàrín àwọn ènìyàn. 26 Èmi yóò mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ àjà ẹnu rẹ, tó bẹ́ẹ̀ ti ìwọ yóò wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Ìwọ kò sì ní lè bá wọn wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ní wọn 27 Ṣùgbọ́n nígbà tí èmi bá bá ọ sọ̀rọ̀, Èmi yóò ṣí ọ lẹ́nu, ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.’ Ẹni tó bá fẹ́ kí ó gbọ́, ẹni tó bá fẹ́ kọ̀, kó kọ̀ nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.