Add parallel Print Page Options

Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó lè ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn aláìmòye, tí ó sì lé bá àwọn tí ó ti yapa kẹ́dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú. Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń ṣe fún ara rẹ̀ náà.

Read full chapter