Add parallel Print Page Options

(A)Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí
    Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde,
tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn,
    Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí
    àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:
(B)“Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo;
    Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú.
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
    láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn
    àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
(C)láti la àwọn ojú tí ó fọ́,
    láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú
àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n
    àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.

Read full chapter