Saamu 25-32
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ti Dafidi.
25 Olúwa,
ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́
ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
ni kí ojú kí ó tì.
4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
kọ mi ní ipa tìrẹ;
5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6 Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,
fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,
dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?
Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,
nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;
nítorí pé mo dúró tì ọ́.
22 Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run,
nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!
Ti Dafidi.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.
Ti Dafidi.
27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?
2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
6 Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.
7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
8 “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
wọ́n sì mí ìmí ìkà.
13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
èmi yóò rí ìre Olúwa
ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
àní dúró de Olúwa.
Ti Dafidi.
28 Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi;
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí ibi mímọ́ rẹ jùlọ.
3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
4 San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
6 Alábùkún fún ni Olúwa!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
8 Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni ààmì òróró rẹ̀.
9 Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
Saamu ti Dafidi.
29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
2 Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
3 Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
Ọlọ́run ògo sán àrá,
Olúwa san ara.
4 Ohùn Olúwa ní agbára;
ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
5 Ohùn Olúwa fa igi kedari;
Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
6 Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
7 Ohùn Olúwa ń ya
bí ọwọ́ iná mọ̀nà
8 Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
9 Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”
10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
ìwọ sì ti wò mí sàn.
3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
31 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
gbà mí nínú òdodo rẹ.
2 Tẹ́ etí rẹ sí mi,
gbà mí kíákíá;
jẹ́ àpáta ààbò mi,
jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
3 Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
4 Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
5 Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.
6 Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;
ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
7 Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,
nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi
ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
8 Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́
ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.
9 Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,
ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;
agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,
egungun mi sì ti rún dànù.
11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,
mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;
àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
13 (A)Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,
wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi
láti gba ẹ̀mí mi.
14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa
Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
àti àwọn onínúnibíni.
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
17 Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;
nítorí pé mo ké pè ọ́;
jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;
jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.
18 Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,
wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.
19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
kúrò nínú ìjà ahọ́n.
21 Olùbùkún ni Olúwa,
nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
“A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
23 Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
Olúwa pa olódodo mọ́,
ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le
gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.
Ti Dafidi. Maskili.
32 (B)Ìbùkún ni fún àwọn
tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.
3 Nígbà tí mo dákẹ́,
egungun mi di gbígbó dànù
nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
4 Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.
5 Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.
6 Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.
8 Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
9 Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.
11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.