Add parallel Print Page Options

Obìnrin kan àti Dragoni

12 Ààmì ńlá kan sì hàn ni ọ̀run; obìnrin kan tí a fi oòrùn wọ̀ ní aṣọ, òṣùpá sì ń bẹ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ lórí rẹ̀: (A)Ó sì lóyún, ó sì kígbe ni ìrọbí, ó sì wà ni ìrora àti bímọ. (B)Ààmì mìíràn sì hàn ní ọ̀run; sì kíyèsi i, dragoni pupa ńlá kan, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, àti adé méje ní orí rẹ̀. (C)Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dragoni náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ. (D)Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè: a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀. Obìnrin náà sì sálọ sí aginjù, níbi tí a gbé ti pèsè ààyè sílẹ̀ dè é láti ọwọ́ Ọlọ́run wá, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta.

(E)Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mikaeli àti àwọn angẹli rẹ̀ bá dragoni náà jagun; dragoni sì jagun àti àwọn angẹli rẹ̀. Wọ́n kò sì lè ṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọ̀run. (F)A sì lé dragoni ńlá náà jáde, ejò láéláé nì, tí a ń pè ni Èṣù, àti Satani, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.

10 (G)Mo sì gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run, wí pè:

“Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá,
    àti ọlá àti Kristi rẹ̀.
Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arákùnrin wa jáde,
    tí o ń fi wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn án àti lóru.
11 Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀
    nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà,
    àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn,
wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn
    àní títí dé ikú.
12 (H)Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run,
    àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn.
Ègbé ni fún ayé àti Òkun;
    nítorí èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá,
nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú sá ni òun ní.”

13 Nígbà tí dragoni náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà. 14 (I)A sì fi apá ìyẹ́ méjì tí idì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí aginjù, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà. 15 Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ. 16 Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dragoni náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá. 17 Dragoni náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú, Ó sì dúró lórí iyanrìn Òkun.

Ẹranko kan tí n ti inú okun jáde wá

13 (J)Mo sì rí ẹranko kan ń ti inú Òkun jáde wá, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, lórí àwọn ìwo náà ni adé méje wà, ni orí kọ̀ọ̀kan ni orúkọ ọ̀rọ̀-òdì wà. Ẹranko tí mo rí náà sì dàbí ẹkùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí tí beari ẹnu rẹ̀ sì dàbí tí kìnnìún: dragoni náà sì fún un ni agbára rẹ̀, àti ìtẹ́ rẹ̀, àti àṣẹ ńlá. Mo sì rí ọ̀kan nínú àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a sá a pa, a sì tí wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ náà sàn, gbogbo ayé sì fi ìyanu tẹ̀lé ẹranko náà. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dragoni náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?”

(K)A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀-òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì. Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run. (L)A sì fún un láti máa bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn: a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlùkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

(M)Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́.

10 (N)Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbèkùn,
    ìgbèkùn ni yóò lọ;
ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà,
    ni a ó sì fi idà pa.

Níhìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà.

Ẹranko jáde nínú ilẹ̀

11 Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́-àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dragoni. 12 Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn. 13 Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn. 14 (O)Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti ya àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè. 15 (P)A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà. 16 Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba ààmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn; 17 àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní ààmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí ààmì orúkọ rẹ̀.

18 Níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka òǹkà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà: nítorí pé òǹkà ènìyàn ni, òǹkà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ọgọ́ta-ẹẹ́fà. (666).

Ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000)

14 (Q)Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù. Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nnì àti àwọn àgbà náà: kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá. Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà. A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.

Àwọn angẹli mẹ́ta

Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”

(R)Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”

Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba ààmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. 10 (S)Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn: 11 (T)Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba ààmì orúkọ rẹ̀.” 12 Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.

13 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”

Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

Ìkórè ayé

14 (U)Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o “dàbí Ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀. 15 (V)Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.” 16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.

17 Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan. 18 Angẹli mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ́ àwọn ìdì àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.” 19 Angẹli náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ̀ ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntí, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run. 20 (W)A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.

Angẹli méje pẹ̀lú ìyọnu méje

15 (X)Mo sì rí ààmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn angẹli méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹyìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin. Mo sì rí bí ẹni pé, Òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí Òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n ṣẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti ààmì rẹ̀ àti nọ́mbà orúkọ rẹ̀, wọn ní ohun èlò orin Ọlọ́run. (Y)Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:

“Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,
    Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;
òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,
    ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.
(Z)Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,
    tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?
Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,
    ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,
nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”