Add parallel Print Page Options

13 (A)Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́. 14 Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí angẹli Ọlọ́run, àní bí Kristi Jesu. 15 Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà ha dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, bi o bá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi.

Read full chapter