Isaiah 43-45
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Olùgbàlà Israẹli kan ṣoṣo
43 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí
ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu
ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli:
“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
kò ní jó ọ;
ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá
èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
6 Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’
Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’
Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7 ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
tí mo dá fún ògo mi,
tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
8 Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,
tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
9 Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ
àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.
Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí
tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?
Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá
láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí
wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,
“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
11 Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,
yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12 Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde
Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13 Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
Àánú Ọlọ́run àti àìṣòdodo Israẹli
14 Èyí ni ohun tí Olúwa wí
olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli;
“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli
láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,
gbogbo ará Babeli
nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15 Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,
Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”
16 Èyí ni ohun tí Olúwa wí
Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun,
ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,
17 ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,
àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,
wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,
wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:
18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;
má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!
Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?
Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi
kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
22 “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,
ìwọ Jakọbu,
àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi
ìwọ Israẹli.
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,
tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.
Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun
tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24 Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.
25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ
àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,
tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,
jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;
ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
27 Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;
àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
28 Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún
àti Israẹli fún ẹ̀gàn.
Israẹli tí a yàn
44 “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi
àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.
2 Ohun tí Olúwa wí nìyìí
ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n
láti inú ìyá rẹ wá,
àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:
Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi,
Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
3 Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ
àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ;
Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,
àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
4 Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,
àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.
5 Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;
òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu;
bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’
yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.
Olúwa ni, kì í ṣe ère òrìṣà
6 (A)“Ohun tí Olúwa wí nìyìí
ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní
Olúwa àwọn ọmọ-ogun:
Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,
lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
7 Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.
Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi
Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí
àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,
àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀
bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
8 Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.
Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ
àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́?
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan
ha ń bẹ lẹ́yìn mi?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,
àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́
kò jámọ́ nǹkan kan.
Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;
wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.
10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,
tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;
àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.
Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì
fi ìdúró wọn hàn;
gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù.
12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,
ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;
ó fi òòlù ya ère kan,
ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,
Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;
kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.
13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n
ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe ààmì sí ara rẹ̀,
Ó tún fi ìfà fá a jáde
ó tún fi òṣùwọ̀n ṣe ààmì sí i.
Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,
kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.
14 Ó gé igi kedari lulẹ̀,
tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù.
Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó,
ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;
díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí
ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,
ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.
Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín;
ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.
16 Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;
lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,
ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.
Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,
“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
17 Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;
ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.
Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,
“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”
18 Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;
a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;
bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.
19 Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,
kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye
láti sọ wí pé,
“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;
Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,
Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.
Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan
nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?
Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”
20 Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà;
òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé
“Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”
21 “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu
nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli.
Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,
ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.
22 Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru,
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀.
Padà sọ́dọ̀ mi,
nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
23 (B)Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí;
kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.
Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,
ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,
nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà,
ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.
A ó tún máa gbé Jerusalẹmu
24 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí
Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́
láti inú ìyá rẹ wá:
“Èmi ni Olúwa
tí ó ti ṣe ohun gbogbo
tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run
tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
25 (C)ta ni ó ba ààmì àwọn wòlíì èké jẹ́
tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀,
tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀
tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
26 ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde
tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,
“ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘a ó máa gbé inú rẹ̀,’
àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’
àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’
27 ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,
èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
28 ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi
àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;
òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,”
àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”
45 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀,
sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú
láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀
àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,
láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀
tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.
2 Èmi yóò lọ síwájú rẹ
èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ
Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ
èmi ó sì gé ọ̀pá irin.
3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin,
Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni Olúwa,
Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
4 Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi
àti Israẹli ẹni tí mo yàn
Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,
mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
5 Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn;
yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,
Èmi yóò fún ọ ní okun,
bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn
títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀
kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn
mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù;
Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;
jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,
jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,
jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;
Èmi Olúwa ni ó ti dá a.
9 (D)“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
‘Òun kò ní ọwọ́?’
10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,
‘Kí ni o bí?’
tàbí sí ìyá rẹ̀,
‘Kí ni ìwọ ti bí?’
11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí
Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀:
Nípa ohun tí ó ń bọ̀,
ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,
tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé
tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.
Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run
mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta
13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi:
Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.
Òun yóò tún ìlú mi kọ́
yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
14 (E)Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi,
àti àwọn Sabeani—
wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;
wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,
wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.
Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,
wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,
‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn;
kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,
Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli
16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì
wọn yóò sì kan àbùkù;
gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
17 (F)Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa
pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;
a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín,
títí ayé àìnípẹ̀kun.
18 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí—
ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,
Òun ni Ọlọ́run;
ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,
Òun ló ṣe é;
Òun kò dá a láti wà lófo,
ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀—
Òun wí pé:
“Èmi ni Olúwa,
kò sì ṣí ẹlòmíràn.
19 Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin,
láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn;
Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé
‘Ẹ wá mi lórí asán.’
Èmi Olúwa sọ òtítọ́;
Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
20 “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;
ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn
orílẹ̀-èdè wá.
Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,
tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
21 (G)Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá
jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.
Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,
ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?
Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa?
Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,
Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;
kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.
22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,
ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;
nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
23 (H)Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,
ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,
ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́:
Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;
nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni
òdodo àti agbára wà.’ ”
Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;
yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
25 Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli
ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.