Joṣua 7:6-15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 Joṣua sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Israẹli sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí wọn. 7 Joṣua sì wí pé, “Háà, Olúwa Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani? 8 Olúwa, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Israẹli sì ti sá níwájú ọ̀tá a rẹ̀? 9 Àwọn Kenaani àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?”
10 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀? 11 Israẹli ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. 12 Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.
13 “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.
14 “ ‘Ní òwúrọ̀, kí ẹ mú ará yín wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan. 15 Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.