Print Page Options Listen to Reading
Previous Prev Day Next DayNext

The Daily Audio Bible

This reading plan is provided by Brian Hardin from Daily Audio Bible.
Duration: 731 days

Today's audio is from the GNT. Switch to the GNT to read along with the audio.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Kronika 1-3

Solomoni béèrè fún ọgbọ́n

Solomoni ọmọ Dafidi fìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí ìjọba rẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú u rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ó ga lọ́pọ̀lọpọ̀.

Nígbà náà, Solomoni bá gbogbo Israẹli sọ̀rọ̀ sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, sí àwọn adájọ́ àti sí gbogbo àwọn olórí Israẹli, àwọn olórí ìdílé (A)Pẹ̀lú Solomoni, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gibeoni, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pa ní aginjù. Nísinsin yìí, Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jearimu sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jerusalẹmu. Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe wà ní Gibeoni níwájú àgọ́ Olúwa: Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni àti gbogbo àpéjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀. Solomoni gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú Olúwa ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀rún ẹbọ sísun lórí rẹ̀.

Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Solomoni, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.”

Solomoni dá Ọlọ́run lóhùn pé, “Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dafidi baba mi, ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dafidi wá sí ìmúṣẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. 10 Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè máa wọ ilé kí ń sì máa jáde níwájú ènìyàn wọ̀nyí, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí?”

11 Ọlọ́run wí fún Solomoni pé, “Níwọ́n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí, 12 Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”

13 Nígbà náà ni Solomoni sì ti ibi gíga Gibeoni lọ sí Jerusalẹmu láti iwájú àgọ́ ìpàdé. Ó sì jẹ ọba lórí Israẹli.

14 (B)Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàafà ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu 15 Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè. 16 Àwọn ẹṣin Solomoni ní a gbà láti ìlú òkèrè Ejibiti àti láti kún ọ̀gbọ̀ oníṣòwò ti ọba ni gba okun náà ní iye kan. 17 Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Ejibiti. Fún ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ṣékélì (6,000) fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin-méjì ó-dínláàdọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hiti àti ti àwọn ará Aramu.

Àwọn ètò fún kíkọ́ ilé Olúwa

Solomoni pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀ Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn (70,000) ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn (80,000) ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìn-dínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.

(C)Solomoni rán iṣẹ́ yìí sí Hiramu ọba Tire:

“Rán àwọn igi kedari sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dafidi. Nígbà tí ó fi igi kedari ránṣẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé. Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé.

“Ilé Olúwa tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn lọ. Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run tó ga jùlọ, kò le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún Olúwa, bí kò ṣe kìkì àti sun ẹbọ sun ẹbọ níwájú rẹ̀?

“Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní àwọ̀ ojú ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú iṣẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Juda àti Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí baba à mi Dafidi pèsè.

“Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ. Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nítorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀. 10 Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ẹgbàáwàá (20,000), alikama ilẹ̀ àti ẹgbàáwàá (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ẹgbàáwàá (20,000), bati ọtí wáìnì àti ẹgbàáwàá (20,000) bati òróró olifi.”

11 Hiramu ọba Tire fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Solomoni:

“Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti ṣe ọ́ ní ọba wọn.”

12 Hiramu fi kún un pe:

“Ìyìn ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye, tí yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti ààfin fún ara rẹ̀.

13 “Èmi ń rán Huramu-Abi, ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye sí ọ. 14 Ọmọbìnrin kan nínú àwọn ọmọbìnrin Dani àti tí baba a rẹ̀ wá láti Tire tí ó gbọ́ngbọ́n àti ṣiṣẹ́ ní wúrà àti ní fàdákà, ní idẹ, ní irin, ní òkúta àti ní ìtì igi, ní èse-àlùkò, ní aláró, àti ní ọ̀gbọ̀ tí ó dára, àti òdòdó, láti gbẹ́ onírúurú ohun gbígbẹ́ pẹ̀lú, àti láti ṣe àwárí ìmọ̀ ẹ̀rọ irú ẹ̀yàkẹ́yà tí a ó fún un ṣe. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n olúwa mi, Dafidi baba a rẹ.

15 “Nísinsin yìí, jẹ́ kí olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní alikama àti barle àti òróró Olifi náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí. 16 Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lebanoni tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi Òkun lọ sí Joppa. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu.”

17 Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbèjì-lélọ́gbọ̀n (153,600). 18 Ó sì yan ẹgbàá-márùn-dínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbèjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́.

Solomoni kọ́ ilé Olúwa

(D)Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moriah, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.

Ìpìlẹ̀ tí Solomoni gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́.

Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà. Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n. Ó ṣe ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu. Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa Pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.

Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rin mẹ́fà tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára. Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.

10 Ní ibi mímọ́ jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà. 11 Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn. 12 Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́. 13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá naà.

14 (E)Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a ṣe sórí i rẹ̀.

15 (F)Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn-ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 16 Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rin pomegiranate (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà 17 Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi.

Romu 6

Ikú sí ẹsẹ̀, iyè nínú Kristi

(A)Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jókòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i? (B)Kí a má ri! Àwa ẹni tí ó ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa ó ha ṣe wà láààyè nínú rẹ̀ mọ́? (C)Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. (D)Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun.

(E)Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. (F)Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. (G)Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́.

(H)Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. (I)Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. 10 Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

11 (J)Nítorí náà, ẹ ka ara yín bí òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí alààyè sí Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. 12 Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 13 (K)Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ohun búburú, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ fi wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára. 14 (L)Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.

Ẹrú sí ìṣòdodo

15 (M)Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsin yìí, a lè tẹ̀síwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láìbìkítà, nítorí ìgbàlà wa kò dúró nípa òfin mọ́, bí kò ṣe nípa gbígba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run! 16 (N)Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀. 17 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ̀yin jẹ́ olùgbọ́ran láti ọkàn wá sí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́. 18 (O)Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.

19 (P)Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn nítorí àìlera yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ bí ẹrú fún ìwà èérí àti ẹ̀ṣẹ̀ dé inú ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin kí ó jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ nísinsin yìí bí ẹrú fún òdodo sí ìwà mímọ́. 20 (Q)Nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin wà ní òmìnira sí òdodo. 21 (R)Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé. 22 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun. 23 (S)Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.

Saamu 16

Miktamu ti Dafidi.

16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Olúwa mi,
    lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
    àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
    Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
    ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
    nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
    ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
(A)Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 (B)nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
    Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
    pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Òwe 19:20-21

20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́
    ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.