Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 36:1-47:12

Àsọtẹ́lẹ̀ kan sí àwọn òkè Israẹli

36 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè gíga Israẹli kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, “Háà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa.” ’ Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdíbàjẹ́ sí, nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè: Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kéékèèkéé, fún Àfonífojì ńlá àti Àfonífojì kéékèèkéé, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà, èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’ Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kéékèèkéé, sí àwọn Àfonífojì ńlá àti sí àwọn Àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.

“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Israẹli, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí. Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́, 10 èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Israẹli. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a yóò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́. 11 Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa. 12 Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Israẹli, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́.

13 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ wọn,” 14 nítorí náà ìwọ kì yóò pa àwọn ènìyàn run tàbí mú kì orílẹ̀-èdè di aláìlọ́mọ mọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí. 15 Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀-èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

16 Síwájú sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 17 “Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli: ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi. 18 Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́. 19 Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn. 20 Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’ 21 Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Israẹli sọ di aláìmọ́ ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ.

22 “Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ. 23 Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárín wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa Olódùmarè wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.

24 “ ‘Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀-èdè náà; Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà; Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. 25 Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin. 26 Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín. 27 Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́. 28 Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. 29 Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín. 30 Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn. 31 (A)Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu. 32 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!

33 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀. 34 Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́. 35 Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.” 36 Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’

37 “Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àgùntàn, 38 Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Àfonífojì àwọn egungun gbígbẹ

37 Ọwọ́ Olúwa wà lára mi, ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, ó mú kí ń wà ní àárín àfonífojì; ti o kún fún àwọn egungun. Ó mú mi lọ síwájú àti sẹ́yìn láàrín wọn, èmi sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egungun ní orí ilẹ̀ àfonífojì, àwọn egungun tí ó gbẹ gan. Olúwa sì bi mí léèrè, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí?”

Èmi sì wí pé, “Ìwọ Olúwa Olódùmarè, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí.”

Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! (B)Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí: Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè. Èmi yóò so iṣan ara mọ́ ọn yín, èmi yóò sì mú kí ẹran-ara wá sí ara yín, èmi yóò sì fi awọ ara bò yín: Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

Nítorí náà ni mo ṣe sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń sọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun. Mo wò ó, iṣan ara àti ẹran-ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn.

Lẹ́yìn náà ni ó sọ fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí èémí; sọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ” 10 Nítorí náà, mo sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn; Wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀.

11 Lẹ́yìn náà ó sọ fún mi: “Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ni gbogbo ìdílé Israẹli. Wọ́n sọ wí pé, ‘Egungun wa ti gbẹ ìrètí wa sì ti lọ; a ti gé wa kúrò.’ 12 Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fun wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Ẹ̀yin ènìyàn mi, Èmi yóò ṣí àwọn ibojì yín, èmi yóò sì mú yín wá si ilẹ̀ Israẹli. 13 Ẹ̀yin o sì mọ̀ èmi ni Olúwa, nígbà tí èmi bá ti ṣí ibojì yín, ẹ̀yin ènìyàn mi, ti èmi bá si mú un yín dìde kúrò nínú ibojì yín 14 (C)Èmi yóò fi èémí mi sínú yín, ẹ̀yin yóò sì yè, èmi yóò sì mú kí ẹ fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi sì ti ṣe ni Olúwa wí.’ ”

Orílẹ̀-èdè kan ní abẹ́ ọba kan

15 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá: 16 “Ọmọ ènìyàn, mú igi pátákó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Juda àti ti Israẹli tí ó ní àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátákò mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Igi tí Efraimu jẹ́ ti Josẹfu àti gbogbo ilé Israẹli tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ 17 So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ.

18 “Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’ 19 Sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gba igi Josẹfu—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Efraimu—àti ti ẹ̀yà Israẹli tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Juda, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’ 20 Gbé igi pátákó tí ó kọ nǹkan sí i sókè ní iwájú wọn, 21 kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Israẹli jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn. 22 Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Israẹli, ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì. 23 Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

24 “ ‘Dafidi ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́. 25 Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, ìránṣẹ́ mi Dafidi ni yóò jẹ́ Ọmọ-aládé wọn láéláé. 26 (D)Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mú títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì sọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárín wọn títí láé. 27 (E)Ibùgbé mí yóò wà pẹ̀lú wọn, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. 28 Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé, èmi Olúwa sọ Israẹli di mímọ́, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárín wọn títí ayérayé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ kan sí Gogi

38 Ọrọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: (F)“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gogu, ti ilẹ̀ Magogu; olórí ọmọ-aládé, Meṣeki, àti Tubali sọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé, Meṣeki àti Tubali. Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ-ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹṣinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèkéé, gbogbo wọn ń fi idà wọn. Persia, Kuṣi àti Puti yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìṣíborí wọn Gomeri náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti Beti-Togarma láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀.

“ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò bẹ̀ ọ wò; ní ọdún ìkẹyìn ìwọ yóò dó ti ilẹ̀ tí a ti gbà padà lọ́wọ́ idà, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sí àwọn òkè gíga ti Israẹli, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, nísinsin yìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu. Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀síwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ mọ́lẹ̀.

10 “ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú. 11 Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé Ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká: Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò funra sí gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu-ọ̀nà òde àti àsígbè-irin. 12 Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú ẹran ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ náà.” 13 Ṣeba, Dedani àti àwọn oníṣòwò Tarṣiṣi àti gbogbo àwọn ọmọ kìnnìún wọn, yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ogun yín jọ pọ̀ fún ìkógun, láti kó fàdákà àti wúrà lọ, láti kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’

14 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì sọ fún Gogu: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Israẹli ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀? 15 Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹṣin ẹgbẹ́ ńlá, jagunjagun alágbára. 16 Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Israẹli ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gogu, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fi ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.

17 “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ha kọ́ ni mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà ìṣáájú láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ mi ti Israẹli? Ní ìgbà náà wọ́n sọtẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé èmi yóò mú ọ lòdì sí wọn. 18 Èyí ni ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà: Nígbà tí Gogu bá kọlu ilẹ̀ Israẹli, gbígbóná ìbínú mi yóò ru sókè, ni Olúwa Olódùmarè wí. 19 Ní ìtara mi àti ní gbígbóná ìbínú mi, Mo tẹnumọ́ ọn pé; ní àsìkò náà ilẹ̀ mímì tí ó lágbára ní ilẹ̀ Israẹli yóò ṣẹlẹ̀. 20 Ẹja inú Òkun, àwọn ẹyẹ òfúrufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi. A yóò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀. 21 Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gogu ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni Olúwa Olódùmarè wí. Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀. 22 (G)Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀; Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí-ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀. 23 Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’

39 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ sí Gogu, kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé ti Meṣeki àti Tubali. Èmi yóò dá ọ padà, èmi yóò sì darí rẹ. Èmi yóò mú ọ wá láti jìnnàjìnnà ìhà àríwá, Èmi yóò rán ọ lòdì sí orí àwọn òkè gíga Israẹli. Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ. (H)Ìwọ yóò sì ṣubú ní orí àwọn òkè Israẹli, ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn onírúurú ẹyẹ àti fún àwọn ẹranko igbó. Ìwọ yóò ṣubú ní gbangba pápá, nítorí tì mo ti sọ̀rọ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí. Èmi yóò fi iná sí Magogu àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

“ ‘Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrín àwọn ènìyàn mì Israẹli. Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi Olúwa, èmi ni ẹni mímọ́ ní Israẹli. Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè. Èyí yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

“ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárín àwọn ìlú tí ó wà ni Israẹli yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ̀—àpáta kéékèèkéé àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná. 10 Wọn kò ní nílò láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lo òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni Olúwa Olódùmarè.

11 “ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gogu ní Israẹli, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà oòrùn Òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn-àjò, nítorí Gogu àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a yóò pè é ní Àfonífojì tí Ammoni Gogu.

12 “ ‘Fún oṣù méje ní ilé Israẹli yóò fi máa sìn wọ́n láti ṣe àfọ̀mọ́ ilẹ̀ náà. 13 Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà yóò sìn wọ́n, ọjọ́ tí a yìn mi lógo yóò jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ní Olúwa Olódùmarè wí.

14 “ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ lóòrèkóòrè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tókù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù keje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn. 15 Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, òun yóò gbé ààmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní Àfonífojì Hamoni Gogu. 16 (Bákan náà ìlú kan tí a ń pè ni Hamona yóò wà níbẹ̀). Nítorí náà wọn yóò wẹ ilẹ̀ náà:’

17 “Ọmọ ènìyàn èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí pé: Pe gbogbo oríṣìíríṣìí ẹyẹ àti gbogbo àwọn ẹranko igbó jáde: ‘Kí wọn péjọpọ̀ láti gbogbo agbègbè sí ìrúbọ tí mó ń múra rẹ̀ fún ọ, ìrúbọ ńlá náà ní orí òkè gíga tí Israẹli. Níbẹ̀ ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀. 18 Ẹ̀yin yóò jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn ńlá, ẹ o sì mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ-aládé ayé bí ẹni pé wọn jẹ́ àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, ewúrẹ́ àti akọ màlúù gbogbo wọn jẹ́ ẹran ọlọ́ràá láti Baṣani 19 Níbi ìrúbọ tí mo ń múra kalẹ̀ fún yín, ẹ̀yin yóò jẹ ọ̀rá títí ẹ̀yin yóò fi jẹ àjẹkì, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ títí ẹ̀yin yóò fi yó. 20 Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìíríṣìí jagunjagun,’ ni Olúwa Olódùmarè wí.

21 “Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n. 22 Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Israẹli yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn. 23 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Israẹli lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ṣubú nípasẹ̀ idà. 24 Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ́ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

25 “Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Jakọbu padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní ìyọ́nú si gbogbo ènìyàn Israẹli, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi. 26 Wọn yóò gbàgbé ìtìjú wọn àti gbogbo àìṣòdodo tí wọ́n fihàn sí mi nígbà tí wọn ń gbé ni àìléwu ni ilẹ̀ wọn níbi tí kò ti sí ẹnikẹ́ni láti dẹ́rùbà wọ́n. 27 Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀. 28 Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rán wọn lọ sí ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò kó wọn jọ sí orí ilẹ̀ wọn, láìfi nǹkan kan sẹ́yìn. 29 Èmi kì yóò sì fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ nítorí èmi yóò tú èémí mi jáde sí ilé Israẹli, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Agbègbè tẹmpili tuntun

40 (I)Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí a ti wà ni oko ẹrú wa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ni oṣù kẹwàá ọdún kẹrìnlá lẹ́yìn Ìṣubú ìlú ńlá náà ní ọjọ́ náà gan an ọwọ́ Olúwa ń bẹ̀ lára mi, òun sì mú mi lọ síbẹ̀. (J)Nínú ìran Ọlọ́run, ó mú mí lọ sí ilẹ̀ Israẹli, ó sì gbé mi lọ sí orí òkè gíga fíofío. Ní ẹ̀gbẹ́ gúúsù ọ̀pọ̀ ilé tó wà níbẹ̀ dàbí ìlú ńlá. (K)Ó mú mi lọ síbẹ̀, mo sì rí ọkùnrin kan tí ìrírí rẹ̀ dàbí ìrí baba; ó dúró ni ẹnu-ọ̀nà pẹ̀lú okùn aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun àti ọ̀pá ìwọnlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, wò pẹ̀lú ojú rẹ kí o sì gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ, kí ó sì fi ara balẹ̀ sì gbogbo ohun tí mo máa fihàn ọ, nítorí ìdí nìyí tí a fi mú ọ wá síhìn-ín. Sọ gbogbo ohun tí ó bá rí fún ilé Israẹli.”

Ibi àbájáde tí apá ilà oòrùn àgbàlá ojúde

Mo rí ògiri tí ó yí agbègbè ibi mí mọ̀ po. Gígùn ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ìlàsí mẹ́rin ẹsẹ̀ bàtà. Ó wọn ògiri náà; ó jẹ́ ìwọ̀nyí ọ̀pá náà ni nínípọn, ó sì jẹ́ ọ̀pá kan ní gíga.

Lẹ́yìn náà ni ó wá lọ sí ẹnu-ọ̀nà òde tí ó kọjú sí ìlà-oòrùn. Ó gun àtẹ̀gùn rẹ̀, o sì wọn ìloro ẹnu-ọ̀nà ilé; ó jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn. Yàrá kéékèèkéé sì jẹ ọ̀pá kan ni gígùn àti ọ̀pá kan ní ibú, ìgbéró ògiri àárín yàrá kéékèèkéé náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Ìloro ẹnu-ọ̀nà náà tí ó kángun sí àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà náà tó kọjú sì tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn.

Lẹ́yìn náà, ó wọ̀n ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà: Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọn. Ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà kọjú sí tẹmpili.

10 Ní ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ni àwọn yàrá kéékèèkéé mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n. 11 Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu-ọ̀nà náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá. 12 Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèkéé kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèkéé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. 13 Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu-ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèkéé kan títí dé òkè ìdojúkọ ọ̀kan; jíjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó ṣí sílẹ̀ sí ìdojúkọ ọ̀kan. 14 Ó sí ṣe àtẹ́rígbà ọlọ́gọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àní títí dé àtẹ́rígbà ògiri àgbàlá, yí ẹnu-ọ̀nà ká. 15 Láti iwájú ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèkéé náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu-ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. 16 Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká; Àwọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé àti láti fèrèsé dé òrùlé.

Àgbàlá ojúde

17 Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà, 18 O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu-ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígùn rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀. 19 Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnnà rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu-ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti tí àríwá.

Ẹnu ọnà àríwá

20 Lẹ́yìn náà, ó wọn gígùn àti ibú ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ àríwá, à bá wọ àgbàlá. 21 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà jẹ́ bákan náà ni wíwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹnu-ọ̀nà àkọ́kọ́. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ìbú. 22 Ojú ihò rẹ̀, àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ àti igi ọ̀pẹ tí í ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni wọn kàn gẹ́gẹ́ bí tí àwọn ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìlà-oòrùn. Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà òdìkejì wọn. 23 Ẹnu-ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni ìdojúkọ ẹnu-ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà-oòrùn. Ó wọ́n láti ẹnu-ọ̀nà sí ìdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

Àbájáde sí ìhà gúúsù

24 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúúsù, mo sì rí ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ gúúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù. 25 Ẹnu-ọ̀nà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú. 26 Àtẹ̀gùn méje ní ń bẹ láti bá gun òkè rẹ̀, àti àwọn ìloro rẹ̀ sì ń bẹ níwájú wọn; Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. 27 Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu-ọ̀nà yìí sí ẹnu-ọ̀nà ìta ni ìhà gúúsù; o jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

Àbáwọlé si àgbàlá ti inú

28 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí àgbàlá ti inú láti ẹnu-ọ̀nà gúúsù, ó ní ìwọ̀n kan náà ẹnu-ọ̀nà gúúsù; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. 29 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu-ọ̀nà náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo 30 (Àwọn àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ó yí àgbàlá po jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n ni ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni jíjìn). 31 Àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i.

32 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn ẹnu-ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. 33 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu-ọ̀nà náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ihò yí po. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. 34 Àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àtẹ́rígbà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ sì lọ sókè rẹ̀.

35 Gẹ́gẹ́ bí àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ ṣe rí. Àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, ó sì ní àwọn ihò yí i po. O jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú. 36 Àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ àwọn ògiri òpó rẹ̀ àti ìloro rẹ̀, àti fèrèsé rẹ̀ yíká: gígùn rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àti ìbú rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n. 37 Àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ ògiri àgbàlá ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó so mọ́ ọn lókè.

Àwọn yàrá fún ṣíṣètò ìrúbọ

38 Yàrá kan pẹ̀lú ìlẹ̀kùn wà ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹnu-ọ̀nà inú, níbi tí wọn tí ń fọ àwọn ẹbọ sísun. 39 Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ẹnu-ọ̀nà ni tẹmpili méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, lórí èyí tí a ti ń pa ọrẹ ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. 40 Ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ìta àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà tí ẹnu-ọ̀nà, tí ó súnmọ́ àwọn àtẹ̀gùn ní àbáwọlé tí ẹnu-ọ̀nà àríwá ni tẹmpili méjì wà, ní ẹ̀gbẹ́ kejì tí àtẹ̀gùn ní tẹmpili méjì wà. 41 Nítorí náà, tẹmpili mẹ́rin ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan ẹnu-ọ̀nà, mẹ́rin sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì tẹmpili, mẹ́jọ ni gbogbo rẹ̀ lórí èyí ni a ti ń pa ohun ìrúbọ. 42 Tẹmpili mẹ́rin tí à fi òkúta ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ sì tún wà fún ẹbọ sísun, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ni gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ kan ni gíga. Ní orí rẹ̀ ni a kó àwọn ohun èlò fún pípa, ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ìrúbọ tí ó kù sí. 43 Ìlọ́po méjì ohun èlò bí àmúga tí o ní ìwọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìbú ọwọ́ ní gígùn, ni a so mọ́ ara ògiri yíká. Àwọn tẹmpili náà wa fún ẹran ohun ìrúbọ.

Àwọn yàrá fún àwọn àlùfáà

44 Lẹ́yìn náà ó wọn àgbàlá: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Pẹpẹ sì wà ní iwájú tẹmpili. 45 Ó sì wí fún mi pé, “yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà. 46 Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sadoku nínú àwọn ọmọ Lefi, tí wọ́n ń súnmọ́ Olúwa láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.”

47 Ó sì wọn àgbàlá náà, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, àti pẹpẹ ti ń bẹ níwájú ilé náà.

Tẹmpili náà

48 Ó mú mi lọ sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tẹmpili, ó sì wọn àwọn àtẹ́rígbà àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà; wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì rẹ̀. Fífẹ̀ àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá, ìgbéró àwọn ògiri náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní ìbú ní ẹ̀gbẹ́ ògiri méjèèjì. 49 Àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ìgbọ̀nwọ́ méjìlá láti iwájú dé ẹ̀yìn. Láti ara àtẹ̀gùn ní a ti ń dé ibẹ̀ àwọn òpó sì wà ni ẹ̀gbẹ́ ògiri kọ̀ọ̀kan àwọn àtẹ́rígbà náà.

41 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi lọ sí ìta ibi mímọ́, ó sì wọn àwọn àtẹ́rígbà náà; ìbú àtẹ́rígbà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ẹ̀gbẹ́ ògiri kọ̀ọ̀kan. Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú, ẹ̀gbẹ́ ògiri ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Ó sì wọn ìta ibi mímọ́ bákan náà; ó jẹ́ ogójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú.

Lẹ́yìn náà ó lọ sí inú yàrá ibi mímọ́, ó sì wọn àtẹ́rígbà àbáwọlé: ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni ìbú. Àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni ìbú, ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ni ìbú. O sì wọn gígùn inú yàrá ibi mímọ́; o sì jẹ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ títí dé ìparí ìta ibi mímọ́. O sì sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi mímọ́ jùlọ.”

Lẹ́yìn náà ó wọn ògiri ilé Ọlọ́run náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní nínípọn, yàrá kọ̀ọ̀kan tí ó wà ní ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ wà ni ipele mẹ́ta, lórí ara wọn, nígbà ọgbọ̀n lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn òpó ẹlẹ́wà wà yípo ògiri ilé Ọlọ́run náà mú kí ògiri àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ náà ní agbára, ni ọ̀nà tí àwọn ìfaratì náà kò fi wọ inú ògiri ilé Ọlọ́run náà lọ. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo tẹmpili ń fẹ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń lọ sí òkè sí i. Àwọn ilé tí a kọ́ yípo ilé Ọlọ́run ni a kọ́ sókè ní pele ní pele, èyí mú kí àwọn yàrá yìí máa fẹ̀ sí i bí ó ṣe ń gòkè sí i. Àtẹ̀gùn rẹ̀ gba ti àwùjọ ilé àárín lọ sókè láti ilé títí dé òkè pátápátá.

Mo ri i pé ilé Ọlọ́run náà ní ìgbásẹ̀ tí a mọ yí i ká, tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ilé tí a mọ yí àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ po. Ó jẹ́ ìwọ̀n ọ̀pá náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní gígùn. Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Agbègbè tí ó wà lófo ní àárín àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo. 10 Yàrá àwọn àlùfáà jẹ́ ogun ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú yípo tẹmpili náà. 11 Àwọn ojú ọ̀nà àbáwọlé wá sí àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́, ọ̀kan ní àríwá àti èkejì ní gúúsù, ojú ọ̀nà ni ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú yípo rẹ̀.

12 Ilé tí ó dojúkọ ìta gbangba ìṣeré ilé Ọlọ́run náà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ àádọ́rin ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. Ògiri ilé náà nípọn tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

13 Lẹ́yìn èyí ní ó wá wọn ilé Ọlọ́run: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ìta gbangba ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ilé àti ògiri rẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn. 14 Ibú ìta gbangba ilé Ọlọ́run ní ìhà ìlà-oòrùn, papọ̀ mọ́ iwájú ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

15 Ó wá wọn gígùn ilé tí ó dojúkọ gbangba ìta ní agbègbè ilé Ọlọ́run papọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

Ìta ibi mímọ́, inú ibi mímọ́ náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìta gbangba, 16 àti pẹ̀lú àwọn ìloro ilé àti àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè yípo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, gbogbo rẹ̀ ní ìta papọ̀ mọ́ ìloro ilé ni wọ́n fi igi bò. Ilẹ̀ ògiri sókè títí dé ojú fèrèsé ni wọ́n fi igi bò pátápátá. 17 Ní ìta gbangba lókè ìta ẹnu-ọ̀nà inú ibi mímọ́ àti lára ògiri pẹ̀lú àlàfo tí kò ju ara wọn lọ yípo inú ìta ibi mímọ́ 18 ní wọn fín àwọn kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ. Wọn fi àwọn igi ọ̀pẹ bo àárín àwọn kérúbù. Kérúbù kọ̀ọ̀kan ní ojú méjì méjì: 19 Ojú ènìyàn sí ìhà igi ọ̀pẹ ni ẹ̀gbẹ́ kan, ojú ọ̀dọ́ kìnnìún sí ìhà igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kejì. Wọn fín gbogbo rẹ̀ yípo gbogbo ilé Ọlọ́run. 20 Láti ilẹ̀ sí agbègbè òkè ẹnu-ọ̀nà, àwọn Kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ ni wọ́n fín si ara ògiri ìta ibi mímọ́.

21 Ìta ibi mímọ́ ni férémù onígun mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀kan tí ó wà ní ibi mímọ́ jùlọ rí bákan náà. 22 Pẹpẹ ìrúbọ kan tí a fi igi ṣe wà, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, àwọn igun rẹ̀, ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ògiri rẹ́ jẹ́ igi. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Èyí yìí ní tẹmpili tí ó wà ní iwájú Olúwa.” 23 Ìta ibi mímọ́ àti ibi mímọ́ jùlọ ni ìlẹ̀kùn méjì papọ̀. 24 Lẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní ewé méjì méjì, ewé méjì tí a gbe kọ́ fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan. 25 Ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ìta ibi mímọ́ ni àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ tí a fín bí ti àwọn tí a fín si àwọn ara ògiri, ìbòrí tí á fi igi ṣe wà ní iwájú ẹnu-ọ̀nà ilé ní ìta. 26 Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ògiri ẹnu-ọ̀nà ní àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú igi ọ̀pẹ tí a fín ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì wà. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà ni ìbòrí tí a fi igi ṣe.

Àwọn yàrá fún àwọn àlùfáà

42 Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ìta gbangba ni ìhà àríwá ó sì mú mi wọ àwọn yàrá ni òdìkejì ìta gbangba ilé Ọlọ́run àti ni òdìkejì ògiri ìta ní apá ìhà àríwá. Ilé tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ kọjú sí àríwá jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Méjèèjì ní ogún ìgbọ̀nwọ́ ìpín láti inú ilé ìdájọ́ àti ni ìpín tí ó dojúkọ iwájú ìta ìdájọ́, ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè kọjú sì ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ìdọ́gba mẹ́ta. Ní iwájú àwọn ọ̀nà, yàrá wà nínú tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú tí ó sì jẹ́ ọgọ́ọ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. Àwọn ìlẹ̀kùn wọn wà ní apá ìhà àríwá. Nísinsin yìí àwọn yàrá òkè ṣe tóóró, nítorí ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè dàbí ẹni pé ó ní ààyè láti ara wọn ju láti ara àwọn yàrá ti ó wà ní ìsàlẹ̀ tàbí àárín ilé. Àwọn yàrá tí ó wà ní àgbékà kẹta kò ni àwọn òpó gẹ́gẹ́ bí ilé ìdájọ́ ṣe ní; nítorí náà wọ́n kéré ní ààyè ju àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ àti àwọn àgbékà ti àárín. Ògiri kan wà ní ìta tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àwọn yàrá àti ìta ilé ìdájọ́; a fà á gùn ní iwájú àwọn yàrá ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Nígbà tí ọ̀wọ́ yàrá ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kángun sí ìta ilé ìdájọ́ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọ̀wọ́ ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ tí ó súnmọ́ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu-ọ̀nà ní ìhà ìlà-oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́.

10 Ní ìhà gúúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà. 11 Àti ọ̀nà ni iwájú wọn rí gẹ́gẹ́ bí ti ìrí àwọn yàrá tí ó wà ní ọ̀nà àríwá bí wọ́n ti gùn mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbòòrò mọ àti gbogbo ìjáde wọn sì dàbí ìṣe wọn àti bí ìlẹ̀kùn wọn 12 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní yàrá tí òun ti ìlẹ̀kùn wọn ní ọ̀nà gúúsù, ìlẹ̀kùn kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà tí ó ṣe déédé pẹ̀lú ògiri tí ó gùn dé ìhà ìlà-oòrùn tí ènìyàn ń gba wọ inú àwọn yàrá.

13 Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ Olúwa yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ; níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́ 14 Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àlùfáà bá ti wọ aṣọ funfun ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ lọ sí ìta ilé ìdájọ́ àfi tí wọ́n bá bọ àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìsin sílẹ̀ ní ibi tí wọn tí lò ó, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọn gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọn tó súnmọ́ ibi tí àwọn ènìyàn yòókù máa ń wà.”

15 Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn agbègbè náà yípo: 16 Ó wọn ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 17 Ó wọn ìhà àríwá; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan. 18 O wọn ìhà gúúsù; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan. 19 Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀-oòrùn o sì wọ̀n-ọ́n: ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n. 20 Báyìí ní ó wọ̀n-ọ́n ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi àìmọ́.

Ògo padà sí inú ilé Ọlọ́run

43 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, (L)mo sì ri ògo Ọlọ́run Israẹli ń bọ láti ìhà ìlà-oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànṣán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀. Ó sì dàbí ìran tí mo rí, gẹ́gẹ́ bí ìran tí mo rí nígbà tí mo wá láti pa ìlú náà run; ìran náà sì dà bí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari, mo sì dojú mi bolẹ̀. Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá. Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsi ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run.

Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run. Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgúnwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli títí láéláé. Ilé Israẹli kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn ní ibi gíga. Nígbà tí wọ́n ba gbé ìloro ilé wọn kángun sí ìloro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárín èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi. Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbèrè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárín wọn láéláé.

10 “Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Israẹli kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà, 11 tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.

12 “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà: Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹmpili náà.

Pẹpẹ ìrúbọ náà

13 “Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìbú, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan: Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà: 14 Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní ìbú: 15 Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná. 16 Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní ìbú. 17 Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní ìbú, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdajì ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà-oòrùn.”

18 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ̀n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán: 19 Ẹ̀yin ní láti mú ọ̀dọ́ akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrékọjá fún àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi, tí ìdílé Sadoku tí ó wá sí agbègbè láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi ní Olúwa Olódùmarè wí. 20 Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjókòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀. 21 Ìwọ gbọdọ̀ mú akọ màlúù fún ìrékọjá, ìwọ yóò sì sun ún ní apá ibi tí a sàmì sí ní agbègbè ilé Ọlọ́run ní ìta ibi mímọ́.

22 “Ní ọjọ́ kejì ìwọ yóò fi ewúrẹ́, òbúkọ aláìlábàwọ́n fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, a sì gbọdọ̀ sọ pẹpẹ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣọ́ di mímọ́ pẹ̀lú akọ màlúù. 23 Nígbà tí ìwọ bá parí ìsọdimímọ́, ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgbò aláìlábàwọ́n láti inú agbo fún ìrúbọ. 24 Ìwọ yóò mú wọn lọ sí iwájú Olúwa, àwọn àlùfáà ni yóò fi iyọ̀ wọ́n wọn, wọn yóò sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí Olúwa.

25 “Fún ọjọ́ méje, ìwọ ní láti pèsè akọ ewúrẹ́ kan lójoojúmọ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; ìwọ yóò sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò láti inú agbo, méjèèjì yóò sì jẹ́ aláìlábàwọ́n. 26 Fún ọjọ́ méje wọn yóò jẹ́ ètùtù fún pẹpẹ, wọn yóò sì sọ ọ́ di mímọ́; nípa bẹ́ẹ̀ wọn yóò yà á sọ́tọ̀. 27 Ní ìparí ọjọ́ wọ̀nyí, láti ọjọ́ mẹ́jọ síwájú, àwọn àlùfáà ni yóò gbé àwọn ẹbọ sísun rẹ àti ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, èmi yóò tẹ́wọ́gbà yín ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Àwọn ọmọ ọba, àwọn Lefi àti àwọn àlùfáà

44 Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí ibi mímọ́, èyí tí ó kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wà ní títì. Olúwa sọ fún mi, “Ẹnu-ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì. A kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀; kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé. Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí gbà ibẹ̀ wọlé. Ọmọ-aládé fúnrarẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu-ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìloro ẹnu-ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.”

(M)Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu-ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ̀.

Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáradára, fetísílẹ̀ dáradára kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa òfin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́. Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwà ìríra rẹ tí tó gẹ́ẹ́, ìwọ ilé Israẹli! Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjèjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkulò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́. Dípò kí ìwọ pa òfin mi mọ́, ìwọ fi àwọn mìíràn sí ibi mímọ́ mi. Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Àjèjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli.

10 “ ‘Àwọn Lefi tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 11 Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rú ẹbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 12 Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Israẹli ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí. 13 Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ nǹkan kan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn. 14 Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo iṣẹ́ tí a gbọdọ̀ ṣe níbẹ̀.

15 “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi àti àwọn ìran Sadoku tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí. 16 Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ súnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi.

17 “ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ ẹ̀wù ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run. 18 Wọ́n yóò sì dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò sì gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn. 19 Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ ẹ̀wù mìíràn, wọn kì yóò sì fi ẹ̀wù wọn sọ àwọn ènìyàn di mímọ́.

20 “ ‘Wọn kò gbọdọ̀ fá irun, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí irun wọn gùn, ṣùgbọ́n wọn gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn wà ní gígẹ̀. 21 Àlùfáà kankan kò gbọdọ̀ mu ọtí nígbà tí ó bá wọ àgbàlá tí inú. 22 Wọn ko gbọdọ̀ fẹ́ opó ni ìyàwó, wọn kò sì gbọdọ̀ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀; Wọ́n lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ti kò tí i mọ ọkùnrin rí, tí ó sì jẹ́ ìran àwọn ọmọ Israẹli, tàbí kí wọn fẹ́ àwọn opó àlùfáà. 23 Wọn yóò sì fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín mímọ́ àti àìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, wọn yóò sì fihàn wọ́n bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́.

24 “ ‘Nínú èyíkéyìí èdè-àìyedè, àwọn àlùfáà ní yóò dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn, wọn sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi ní mímọ́.

25 “ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ baba tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 26 Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje. 27 Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti ṣe ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí ó rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.

28 “ ‘Èmi ni yóò jẹ́ ogún kan ṣoṣo tí àwọn àlùfáà yóò ní. Ẹ kì yóò fún wọn ni ìpín kankan ní Israẹli; Èmi ni yóò jẹ́ ìní wọn. 29 Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Israẹli ni yóò jẹ́ tiwọn. 30 Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ọrẹ yín yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ó sì fi àkọ́pò ìyẹ̀fun yín fún wọn kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yín. 31 Àwọn àlùfáà kì yóò jẹ́ ohunkóhun bí i ẹyẹ tàbí ẹranko, tí ó ti kú fúnrarẹ̀ tàbí èyí ti ẹranko ńlá fàya.

Ilẹ̀ pínpín

45 “ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ibi mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú; gbogbo agbègbè rẹ̀ yíká ni yóò jẹ́ mímọ́. Lára inú èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta yóò jẹ́ ti ibi mímọ́ ní gígùn, pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní ìbú, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yíká, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún gbangba rẹ̀ yíká. Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ìbú. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ. Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa. Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.

“ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Israẹli.

“ ‘Àwọn ọmọ-aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbègbè tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn láti apá ìwọ̀-oòrùn àti si ìlà-oòrùn, láti apá ìlà-oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀-oòrùn sí ààlà ìlà-oòrùn, ti ìṣe déédé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà. Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn ọmọ-aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Israẹli gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.

“ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí. 10 Kí ẹ̀yin kì ó lo òṣùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́. 11 Efa àti bati gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bati tí ó gba ìdámẹ́wàá homeri, àti efa ìdámẹ́wàá homeri: Homeri ni kí ó jẹ́ òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin yóò lò fún méjèèjì. 12 Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì márùn-dínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ minas kan.

Ọrẹ àti àwọn ọjọ́ mímọ́

13 “ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹ gbọdọ̀ ṣe: efa kẹfà láti inú homeri ọkà kọ̀ọ̀kan àti efa kẹfà láti inú homeri barle kọ̀ọ̀kan. 14 Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bati wọ́n, ni ìdámẹ́wàá bati láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí homeri kan, fún ìdámẹ́wàá bati jẹ́ bákan náà sì homeri kan.) 15 Bákan náà ni ọ̀dọ́-àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba, láti inú pápá oko tútù Israẹli, fún ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti fún ọrẹ ẹbọ sísun, àti fún ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Olódùmarè wí. 16 Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ-aládé ni Israẹli. 17 Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ-aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àsè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ́ ìsinmi ni gbogbo àjọ̀dún tí a yàn ní ilé Israẹli. Òun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Israẹli.

18 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́. 19 Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ìlẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú. 20 Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ keje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run.

21 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà. 22 Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà. 23 Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 24 Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan.

25 “ ‘Láàrín ọjọ́ méje àsè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, òun yóò tún pèsè ohun kan náà fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ, àti fún òróró.

46 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmi àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a ṣí i. Ọmọ-aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kángun sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ìlẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́. Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù. Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan. Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n. Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan. Nígbà tí ọmọ-aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.

“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde. 10 Ọmọ-aládé gbọdọ̀ wà ní àárín wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.

11 “ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan. 12 Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.

13 “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀. 14 Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí. 15 Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

16 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ. 17 Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pamọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀; Lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ-aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; ó jẹ́ tiwọn. 18 Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’ ”

19 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bàá ẹnu-ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀-oòrùn. 20 O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má ṣe jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá, kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”

21 Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan. 22 Ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnu pọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà. 23 Ní agbègbè inú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo. 24 Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”

Odò láti inú tẹmpili náà

47 (N)Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹmpili náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹmpili náà sí apá ìhà ìlà-oòrùn (nítorí tẹmpili náà dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn) Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúúsù tẹmpili náà, ní ìhà gúúsù pẹpẹ. Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, omi náà sì ń sàn láti ìhà gúúsù wá.

Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kò jì jù kókósẹ̀ lọ. Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí ó jì ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí. Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni. Ó bi mí léèrè pé: “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”

Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò. Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá. Àwọn ohun alààyè tí ó ń rákò yóò máa gbé ní ibikíbi tí odò ti ń sàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń sàn síbẹ̀, ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń sàn, gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè. 10 Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti En-Gedi títí dé En-Eglaimu ààyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi Òkun ńlá. 11 Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀. 12 Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.