Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 1-16

Ìbẹ̀rẹ̀ dídá ayé

(A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi.

(B)Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.

(C)Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.

Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10 Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára.

11 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 12 Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. 13 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta.

14 Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún ààmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, 15 Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16 Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńláńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. 17 Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, 18 láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 19 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹrin.

20 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” 21 Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńláńlá sí inú Òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 22 Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi Òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” 23 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ karùn-ún.

24 Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 25 Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.

26 (D)Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.”

27 (E)(F) Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,
    ní àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá a,
    akọ àti abo ni Ó dá wọn.

28 Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.”

29 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín. 30 Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà: gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

31 Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀, ó jẹ́ ọjọ́ kẹfà.

(G)Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

(H)(I) Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.

Adamu àti Efa

Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run.

Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀. (J)Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.

Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. (K)Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.

10 Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. 11 Orúkọ èkínní ni Pisoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. 12 (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá (bedeliumu) àti òkúta (óníkìsì) oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). 13 Orúkọ odò kejì ni Gihoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. 14 Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi: òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate.

15 Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 16 Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; 17 ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.”

18 Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”

19 Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. 20 Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.

Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. 21 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. 22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

23 Ọkùnrin náà sì wí pé,

“Èyí ni egungun láti inú egungun mi
    àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;
‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,
    nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

24 (L)Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

25 Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

Ìṣubú ènìyàn

(M)Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”

Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwa lè jẹ lára àwọn èso igi tí ó wà nínú ọgbà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èso igi tí ó wà láàrín ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kùú.’ ”

(N)Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.” “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”

Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èso igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́. Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.

Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”

10 Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.”

11 Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”

12 Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

13 (O)Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”

Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”

14 (P)Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,

“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn
    àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ!
Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,
    ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
15 (Q)Èmi yóò sì fi ọ̀tá
    sí àárín ìwọ àti obìnrin náà,
    àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà;
òun yóò fọ́ orí rẹ,
    ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

16 Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé:

“Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ;
    ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ.
Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí,
    òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”

17 (R)Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’

“Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ;
    nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀,
    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
18 Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ,
    ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.
19 Nínú òógùn ojú rẹ
    ni ìwọ yóò máa jẹun
títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀,
    nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá;
erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ,
    ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”

20 Adamu sì sọ aya rẹ̀ ní Efa nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè.

21 Olúwa Ọlọ́run, sì dá ẹ̀wù awọ fún Adamu àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. 22 (S)Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èso igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láààyè títí láéláé.” 23 Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá. 24 Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tán, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ́ná síwájú àti sẹ́yìn láti ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè, ní ìhà ìlà-oòrùn ọgbà Edeni.

Kaini àti Abeli

Adamu sì bá aya rẹ̀ Efa lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Kaini. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọ ọkùnrin.” Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli.

Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. (T)Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro.

Nígbà náà ni Olúwa bi Kaini pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro? Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.”

(U)Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.

Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?”

Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?”

10 Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. 11 Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ. 12 Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.”

13 Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ. 14 Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.”

15 Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Kaini, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi ààmì sí ara Kaini, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á. 16 Kaini sì kúrò níwájú Ọlọ́run, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nodi ní ìhà ìlà-oòrùn Edeni.

17 Kaini sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Enoku. Kaini sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Enoku sọ ìlú náà. 18 Enoku sì bí Iradi, Iradi sì ni baba Mehujaeli, Mehujaeli sì bí Metuṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba Lameki.

19 Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla. 20 Adah sì bí Jabali: òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. 21 Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè. 22 Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama.

23 Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀,

“Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi;
    ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí,
    ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára.
24 Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje,
    ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tà-dínlọ́gọ́rin.”

25 Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.” 26 Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Enoṣi.

Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.

Ìran Adamu títí dé ìran Noa

(V)Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu.

Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.

Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti. Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.

Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùnún ọdún (105), ó bí Enoṣi. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.

Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kenani. 10 Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. 11 Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.

12 Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Mahalaleli: 13 Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 14 Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó-lé-mẹ́wàá ọdún (910), ó sì kú.

15 Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Jaredi. 16 Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 17 Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú.

18 Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Enoku. 19 Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 20 Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dínméjìdínlógójì (962), ó sì kú.

21 Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Metusela. 22 Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 23 Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irínwó-dínmárùn-dínlógójì-ọdún (365). 24 (W)Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.

25 Nígbà tí Metusela pé igba ó-dínmẹ́tàlá ọdún (187) ní o bí Lameki. 26 Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rìn-dínméjì-dínlógún ọdún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 27 Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó-dínmọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.

28 Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án (182) ni ó bí ọmọkùnrin kan. 29 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn ún.” 30 Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ó-dínmárùn-ún ọdún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 31 Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún ó-dínmẹ́tàlélógún (777), ó sì kú.

32 Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500) ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

Ìkún omi

(X)Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”

(Y)Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.

Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo. Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́. Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere Olúwa.

(Z)Wọ̀nyí ni ìtàn Noa.

Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn. 10 Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

11 Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú. 12 Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn. 13 Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. 14 Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà-ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. 15 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. 16 Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí. 17 Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun. 18 Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ. 19 Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ. 20 Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè. 21 Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀, kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.”

22 (AA)Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.

Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí. Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́. Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé. Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.”

Noa sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.

Noa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún (600) nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀. (AB)Noa àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti sá àsálà fún ìkún omi. Méjì méjì ni àwọn ẹran tí ó mọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà, akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa. 10 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.

11 (AC)Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀. 12 Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

13 Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. 14 Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. 15 Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀. 16 Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.

17 Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. 18 Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi. 19 Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. 20 Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 21 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. 22 Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. 23 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù.

24 Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́ (150).

Ìkún omi gbẹ

Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró. Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà. Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati. Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn.

Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀. Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti sẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀. Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀. 10 Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. 11 Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. 12 Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.

13 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. 14 Ní ọjọ́ kẹtà-dínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátápátá.

15 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé. 16 “Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn. 17 Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn lórí ilẹ̀.”

18 Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde. 19 Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátápátá ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn.

20 Noa sì mọ pẹpẹ fún Olúwa, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. 21 Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀: “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe.

22 “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà,
ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè
ìgbà òtútù àti ìgbà ooru,
ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò,
ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru,
yóò wà títí láé.”

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Noa

(AD)Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé. Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja Òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

(AE)“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn.

(AF)“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀,
    láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.
Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run
    ni Ọlọ́run dá ènìyàn.

(AG)Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”

Ọlọ́run sì wí fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn. 10 Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé. 11 Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”

12 Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni ààmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: 13 Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé. 14 Nígbàkúgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀. 15 Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run. 16 Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”

17 Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni ààmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.”

Àwọn ọmọ Noa

18 Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani). 19 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Noa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé.

20 Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. 21 Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. 22 Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. 23 Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn.

24 Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. 25 Ó wí pé:

“Ègún ni fún Kenaani.
    Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe
    fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

26 Ó sì tún wí pé;

“Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ṣemu
    Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu.
27 Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀,
    Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu
    Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.”

28 Noa wà láààyè fún irínwó ọdún ó-dínàádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. 29 Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.

Ìran àwọn ọmọ Noa

10 Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.

Ìran Jafeti

Àwọn ọmọ Jafeti ni:

Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.

Àwọn ọmọ Gomeri ni:

Aṣkenasi, Rifàti àti Togarma.

Àwọn ọmọ Jafani ni:

Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).

Ìran Hamu

Àwọn ọmọ Hamu ni:

Kuṣi, Misraimu, Puti àti Kenaani.

Àwọn ọmọ Kuṣi ni:

Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Ṣabteka.

Àwọn ọmọ Raama ni:

Ṣeba àti Dedani.

Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé. Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.” 10 Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari. 11 Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala, 12 àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.

13 Misraimu sì bí

Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu. 14 Patrusimu, Kasluhimu, (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.

15 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀,

àti Heti. 16 Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, 17 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, 18 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Ṣemari, àti àwọn ará Hamati.

Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀. 19 Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Ṣeboimu, títí dé Laṣa.

20 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.

Ìran Ṣemu

21 A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.

22 Àwọn ọmọ Ṣemu ni:

Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.

23 Àwọn ọmọ Aramu ni:

Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki.

24 Arfakṣadi sì bí Ṣela,

Ṣela sì bí Eberi.

25 Eberi sì bí ọmọ méjì:

ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.

26 Joktani sì bí

Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. 27 Hadoramu, Usali, Dikla, 28 Obali, Abimaeli, Ṣeba. 29 Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.

30 Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn.

31 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.

32 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Noa gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀-èdè wọn. Ní ipasẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.

Ilé ìṣọ́ Babeli

11 Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari (Babeli), wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.

Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà-ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́. Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.”

Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó. Ìdí èyí ni a fi pè é ní Babeli[a] nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.

Ìran Ṣemu tó fi dé ti Abramu

10 Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu.

Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún (100) ni ó bí Arfakṣadi. 11 Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

12 Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùn-dínlógójì (35) ni ó bí Ṣela. 13 Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

14 Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Eberi. 15 Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

16 Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pelegi. 17 Eberi sì wà láààyè fún irínwó ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

18 Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Reu. 19 Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ó-lé-mẹ́sàn án ọdún (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

20 Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni ó bí Serugu. 21 Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

22 Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Nahori. 23 Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

24 Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹra. 25 Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn-dínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

26 Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Abramu, Nahori àti Harani.

27 Wọ̀nyí ni ìran Tẹra.

Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani, Harani sì bí Lọti. 28 Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea. 29 Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska. 30 Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ.

31 Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.

32 Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ó-lé-márùn-ún ọdún (205) ni ó kú ní Harani.

Ìpè Abramu

12 (AH)Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.

(AI)“Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá
    Èmi yóò sì bùkún fún ọ.
Èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá,
    ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí.
(AJ)Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ,
    ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré;
nínú rẹ ni a ó bùkún
    gbogbo ìdílé ayé.”

Bẹ́ẹ̀ ni Abramu lọ bí Olúwa ti sọ fún un. Lọti náà sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin (75) ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani. Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀.

Abramu sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni More ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani sì wà ní ilẹ̀ náà. (AK)Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án.

Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.

Nígbà náà ni Abramu tẹ̀síwájú sí ìhà gúúsù.

Abramu ní Ejibiti

10 (AL)Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Abramu sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi. 11 Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Ejibiti, ó wí fún Sarai, aya rẹ̀ pé, “Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ, 12 nígbà tí àwọn ará Ejibiti bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí. 13 Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”

14 Nígbà tí Abramu dé Ejibiti, àwọn ará Ejibiti ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi. 15 Nígbà tí àwọn ìjòyè Farao sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú Farao, wọ́n sì mú un lọ sí ààfin, 16 Ó sì kẹ́ Abramu dáradára nítorí Sarai, Abramu sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú ìbákasẹ.

17 Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn búburú sí Farao àti ilé rẹ̀, nítorí Sarai aya Abramu. 18 Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Abramu, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe? 19 Èéṣe tí o fi wí pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya? Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí o sì máa lọ.” 20 Nígbà náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.

Ìpinyà Abramu àti Lọti

13 Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.

Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.

Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”

10 (AM)Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run). 11 Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. 12 Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè Àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa.

14 Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. 15 (AN)Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. 16 Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. 17 Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.”

18 Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.

Abramu gba Lọti là

14 Ní àsìkò yìí ni Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu àti Tidali ọba Goyimu jáde lọ láti bá Bera ọba Sodomu, Birṣa ọba Gomorra, Ṣenabu ọba Adma, Ṣemeberi ọba Ṣeboimu àti ọba Bela (èyí nì ni Soari) jagun. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí Àfonífojì Siddimu (Òkun iyọ̀). Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kedorlaomeri bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i.

Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n ṣígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ará Refaimu ní Aṣteroti-Karnaimu, àwọn ará Susimu ni Hamu, àwọn ará Emimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriataimu, àti àwọn ará Hori ní orí òkè wọ̀n-ọn-nì Seiri, títí ó fi dé Eli-Parani ní etí ijù. Wọ́n sì tún yípadà lọ sí En-Miṣpati (èyí yìí ni Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Amaleki, àti àwọn ará Amori tí ó tẹ̀dó sí Hasason Tamari pẹ̀lú.

Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Ṣeboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu, láti kojú ìjà sí Kedorlaomeri ọba Elamu, Tidali ọba Goyimu, Amrafeli ọba Ṣinari àti Arioku ọba Ellasari (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún). 10 Àfonífojì Siddimu sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Sodomu àti ọba Gomorra sì sá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà ṣubú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè. 11 Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Sodomu àti Gomorra àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ. 12 Wọ́n sì mú Lọti ọmọ arákùnrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu àti gbogbo ohun ìní rẹ̀.

13 Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Abramu, ará Heberu ni. Abramu sá ti tẹ̀dó sí ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre ará Amori, arákùnrin Eṣkolu àti Aneri: àwọn ẹni tí ó ń bá Abramu ní àṣepọ̀. 14 Nígbà tí Abramu gbọ́ wí pé, a di Lọti ní ìgbèkùn, ó kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dani. 15 Ní ọ̀gànjọ́ òru, Abramu pín àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Hoba tí ó wà ní apá òsì Damasku. 16 Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọti pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tókù.

17 (AO)Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní Àfonífojì Ṣafe (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì Ọba).

18 Melkisedeki ọba Salẹmu (Jerusalẹmu) sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo. 19 Ó sì súre fún Abramu wí pé,

“Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
20 Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
    tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.”

Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.

21 Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”

22 Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè, 23 pé, èmi kì yóò mú láti fọ́nrán òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kí yóò mú ohun kan tí ṣe tìrẹ, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.’ 24 Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Aneri, Eṣkolu àti Mamre. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Abramu

15 Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé:

“Abramu má ṣe bẹ̀rù,
    Èmi ni ààbò rẹ,
    Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”

Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

(AP)Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” (AQ)Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”

(AR)Abramu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”

Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”

Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

10 Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. 11 Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.

12 (AS)Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó. 13 (AT)(AU)Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 14 Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. 15 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. 16 Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”

17 Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. 18 (AV)Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate: 19 ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni, 20 àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu. 21 Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”

Hagari àti Iṣmaeli

16 Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari. Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”

Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya. Abramu sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún.

Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀. Nígbà náà ni Sarai wí fún Abramu pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹ mí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrín tèmi tìrẹ.”

Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ.

Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri. Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”

Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.”

Angẹli Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.” 10 Angẹli Olúwa náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.”

11 Angẹli Olúwa náà sì wí fún un pé,

“Ìwọ ti lóyún, ìwọ yóò sì bí
    ọmọkùnrin kan,
ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli,
    nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ.
12 Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyàn
    ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo,
    ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀,
yóò sì máa gbé ní ìkanra
    pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.”

13 Ó sì pe orúkọ Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.” 14 Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi: kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi.

15 (AW)Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli. 16 Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndín-láàádọ́rùn-ún (86) nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.