Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Ọba 7:38-16:20

38 (A)Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n bati, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà. 39 Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn-ún sí apá ọ̀tún ìhà gúúsù ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà-oòrùn sí ìdojúkọ gúúsù ilé náà. 40 Ó sì túnṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwokòtò.

Bẹ́ẹ̀ ni Huramu sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Solomoni ọba:

41 Àwọn ọ̀wọ́n méjì;

Ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́;

àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;

42 Irínwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn méjì, ọ̀wọ́ méjì pomegiranate fún iṣẹ́ àwọn kan láti bo àwọn ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;

43 Ẹsẹ̀ mẹ́wàá pẹ̀lú agbádá mẹ́wàá wọn;

44 Agbada ńlá náà, àti màlúù méjìlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀;

45 Ìkòkò, ọkọ́ àti àwokòtò.

Gbogbo ohun èlò wọ̀nyí tí Hiramu ṣe fún Solomoni ọba nítorí iṣẹ́ Olúwa sì jẹ́ idẹ dídán. 46 Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani lágbedeméjì Sukkoti àti Saretani. 47 Solomoni sì jọ̀wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí láìwọ́n, nítorí tí wọ́n pọ̀jù; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ìwọ̀n idẹ.

48 Solomoni sì túnṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú:

pẹpẹ wúrà;

tábìlì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà;

49 Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn-ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko;

fìtílà àti ẹ̀mú wúrà;

50 Ọpọ́n kìkì wúrà, alumagaji fìtílà, àti àwokòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára;

àti àgbékọ́ wúrà fún ìlẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ìlẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹmpili.

51 Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa.

A gbé àpótí ẹ̀rí wá sí inú tẹmpili

(B)Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Israẹli jọ papọ̀, níwájú Solomoni ọba ní Jerusalẹmu, láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá láti ìlú Dafidi, tí ń ṣe Sioni. Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì pe ara wọn jọ sọ́dọ̀ Solomoni ọba ní àkókò àjọ ọdún ní oṣù Etanimu tí í ṣe oṣù keje.

Nígbà tí gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli dé, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àgọ́ àjọ ènìyàn àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi sì gbé wọn gòkè wá, Àti Solomoni ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rú ẹbọ.

Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù. Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e. Àwọn ọ̀pá yìí ga tó bẹ́ẹ̀ tí a fi le rí orí wọn láti ibi mímọ́ níwájú ibi tí a yà sí mímọ́, ṣùgbọ́n a kò sì rí wọn lóde ibi mímọ́, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. Kò sí ohun kankan nínú àpótí ẹ̀rí bí kò ṣe wàláà òkúta méjì tí Mose ti fi sí ibẹ̀ ní Horebu, níbi tí Olúwa ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.

10 (C)Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́, àwọsánmọ̀ sì kún ilé Olúwa. 11 Àwọn àlùfáà kò sì le ṣiṣẹ́ wọn nítorí àwọsánmọ̀ náà, nítorí ògo Olúwa kún ilé náà.

12 (D)Nígbà náà ni Solomoni sì wí pé, “Olúwa ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri; 13 Nítòótọ́, èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé.”

14 Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn. 15 Nígbà náà ni ó wí pé:

“Ìbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, 16 ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dafidi láti ṣàkóso àwọn Israẹli ènìyàn mi.’

17 “Dafidi baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 18 Ṣùgbọ́n Olúwa sì wí fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ. 19 Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde; òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’

20 Olúwa sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́: Èmi sì ti rọ́pò Dafidi baba mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli báyìí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 21 Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú Olúwa tí ó ti bá àwọn baba wa dá, nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.”

Àdúrà Solomoni fún ìyàsímímọ́

22 Solomoni sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run. 23 Ó sì wí pé:

Olúwa Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ. 24 O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí.

25 “Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, ìwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsi ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn. 26 Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi wá sí ìmúṣẹ.

27 “Ṣùgbọ́n nítòótọ́, Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ! 28 Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí. 29 Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ilé yìí ní òru àti ní ọ̀sán, ibí yìí tí ìwọ ti wí pé, orúkọ mi yóò wà níbẹ̀, nítorí ìwọ yóò gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ gbà sí ibí yìí. 30 Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì.

31 “Nígbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì fi wá lé e láti mú un búra, bí ìbúra náà bá sì dé iwájú pẹpẹ rẹ ní ilé yìí, 32 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtítọ́ láre, kí a sì fi ẹsẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀.

33 “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Israẹli, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí 34 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ènìyàn rẹ̀ jì í, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn.

35 “Nígbà tí ọ̀run bá sé mọ́, tí kò sí òjò, nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, 36 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, à ní Israẹli, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní.

37 “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹ ni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí ààrùnkárùn tó lè wá, 38 nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Israẹli wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí, 39 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjì, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, 40 Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa.

41 “Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ, 42 nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí, 43 nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.

44 “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ, 45 nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.

46 “Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jíjìnnà tàbí nítòsí; 47 bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú’; 48 bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ; 49 Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró. 50 Kí o sì dáríjì àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn; 51 nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Ejibiti jáde wá, láti inú irin ìléru.

52 “Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Israẹli, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ. 53 Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ Olúwa Olódùmarè, mú àwọn baba wa ti Ejibiti jáde wá.”

54 Nígbà tí Solomoni ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run 55 Ó sì dìde dúró ó sì fi ohùn rara súre fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli wí pé:

56 “Ìbùkún ni fún Olúwa tí ó ti fi ìsinmi fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ wá. 57 Olúwa Ọlọ́run wa kí ó wà pẹ̀lú wa bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn baba wa; kí ó má sì ṣe fi wá sílẹ̀ tàbí kọ̀ wá sílẹ̀. 58 Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa. 59 Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa, kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Israẹli ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́, 60 kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn. 61 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí.”

Ìyàsímímọ́ ilé náà

62 (E)Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Israẹli rú ẹbọ níwájú Olúwa. 63 Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbàá-mọ́kànlá (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́.

64 Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárín tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.

65 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àpéjọ nígbà náà, àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńláńlá ni, láti ìwọ Hamati títí dé odò Ejibiti. Wọ́n sì ṣàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀. 66 Ní ọjọ́ kẹjọ ó rán àwọn ènìyàn lọ. Wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn fún gbogbo ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, àti fún Israẹli ènìyàn rẹ̀.

Olúwa farahan Solomoni

(F)Nígbà tí Solomoni sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe, Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni. Olúwa sì wí fún un pé:

“Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.

“Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́, Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’

“Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, nígbà náà ni èmi yóò ké Israẹli kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Israẹli yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè. Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’ Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn baba wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti gbá ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ”

Ojúṣe Solomoni mìíràn

10 Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba. 11 Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀. 12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn. 13 Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nìwọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ Kabulu títí fi di òní yìí. 14 Hiramu sì ti fi ọgọ́fà (120) tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.

15 Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri. 16 Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ. 17 Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀, 18 Àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀, 19 Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.

20 Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Amori ará Hiti, Peresi, Hifi àti Jebusi, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Israẹli, 21 ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò le parun pátápátá, àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ẹrú fún títí di òní yìí. 22 Ṣùgbọ́n, Solomoni kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Israẹli; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. 23 Àwọn sì tún ni àwọn olórí olùtọ́jú tí wọ́n wà lórí iṣẹ́ Solomoni, àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀ta (550), ní ń ṣe àkóso lórí àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ náà.

24 Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Farao ti gòkè láti ìlú Dafidi wá sí ààfin tí Solomoni kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Millo.

25 Nígbà mẹ́ta lọ́dún ni Solomoni ń rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà lórí pẹpẹ tí ó tẹ́ fún Olúwa, ó sì sun tùràrí níwájú Olúwa pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó parí ilé náà.

26 Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa. 27 Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. 28 Wọ́n sì dé ofiri, wọ́n sì mú irínwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.

Ayaba Ṣeba bẹ Solomoni wò

10 (G)Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle. Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńláńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀. Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un. Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!

Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀-èdè mi ní ti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ. Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsi i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́. Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ! Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Israẹli. Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Israẹli títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jẹ ọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.”

10 Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ǹtì wúrà, tùràrí olóòórùn dídùn lọ́pọ̀lọpọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dàbí irú èyí tí ayaba Ṣeba fi fún Solomoni ọba.

11 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hiramu tí ó mú wúrà láti Ofiri wá, wọ́n mú igi algumu, (igi sandali) lọ́pọ̀lọpọ̀ àti òkúta oníyebíye láti Ofiri wá. 12 Ọba sì fi igi algumu náà ṣe òpó fún ilé Olúwa àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Irú igi algumu bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí.

13 Solomoni ọba sì fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Solomoni ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Solomoni

14 Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta (666) ó-lé-mẹ́fà tálẹ́ǹtì wúrà, 15 Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Arabia, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.

16 Solomoni ọba sì ṣe igba (200) asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan. 17 Ó sì túnṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) asà wúrà lílù, pẹ̀lú òṣùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí asà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lebanoni.

18 Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ eyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó. 19 Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni ìrọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. 20 Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí. 21 Gbogbo ohun èlò mímu Solomoni ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lebanoni sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí nǹkan kan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. 22 Ọba sì ní ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hiramu ní Òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tarṣiṣi ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá.

23 Solomoni ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ. 24 Gbogbo ayé sì ń wá ojú Solomoni láti gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sí i ní ọkàn. 25 Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún olúkúlùkù àwọn tí ń wá sì ń mú ẹ̀bùn tirẹ̀ wá, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò wúrà àti ẹ̀wù, àti tùràrí olóòórùn dídùn, ẹṣin àti ìbáaka.

26 Solomoni sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ; ó sì ní egbèje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàata (13,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú ọba ní Jerusalẹmu. 27 Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti igi kedari ni ó ṣe kí ó dàbí igi sikamore tí ń bẹ ní Àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. 28 A mú àwọn ẹṣin wá fún Solomoni láti Ejibiti àti láti Kue, oníṣòwò ọba rà wọ́n láti Kue fún owó. 29 Wọ́n ń mú kẹ̀kẹ́ kan gòkè láti Ejibiti wá fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹṣin kan fún àádọ́jọ (150). Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún mú wọn wá fún ọba àwọn ọmọ Hiti àti ọba àwọn ọmọ Aramu.

Àwọn ìyàwó Solomoni

11 Solomoni ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Farao, àwọn ọmọbìnrin Moabu, àti ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni àti ti àwọn ọmọ Hiti. Wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀síbẹ̀ Solomoni fàmọ́ wọn ní ìfẹ́. Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrún (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà. Bí Solomoni sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Solomoni tọ Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni lẹ́yìn, àti Moleki òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe búburú níwájú Olúwa; kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jerusalẹmu, Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, òrìṣà ìríra Moabu, àti fún Moleki, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ fún òrìṣà wọn.

Olúwa bínú sí Solomoni nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì. 10 Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Solomoni kí ó má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Solomoni kò pa àṣẹ Olúwa mọ́. 11 Nítorí náà Olúwa wí fún Solomoni pé, “Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pàṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmíràn. 12 Ṣùgbọ́n, nítorí Dafidi baba rẹ, Èmi kì yóò ṣe é ní ọjọ́ rẹ. Èmi yóò fà á ya kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ. 13 Síbẹ̀ èmi kì yóò fa gbogbo ìjọba náà ya, ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi, àti nítorí Jerusalẹmu tí èmi ti yàn.”

Àwọn ọ̀tá Solomoni

14 Nígbà náà ni Olúwa gbé ọ̀tá kan dìde sí Solomoni, Hadadi ará Edomu ìdílé ọba ni ó ti wá ní Edomu. 15 Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi wà ní Edomu, Joabu olórí ogun sì gòkè lọ láti sin àwọn ọmọ-ogun Israẹli ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Edomu. 16 Nítorí Joabu àti gbogbo Israẹli sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, títí wọ́n fi pa gbogbo ọkùnrin Edomu run. 17 Ṣùgbọ́n Hadadi sálọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ará Edomu tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ baba rẹ̀. Hadadi sì wà ní ọmọdé nígbà náà. 18 Wọ́n sì dìde kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Parani wá, wọ́n sì lọ sí Ejibiti, sọ́dọ̀ Farao ọba Ejibiti ẹni tí ó fún Hadadi ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ.

19 Inú Farao sì dùn sí Hadadi púpọ̀ tí ó fi fún un ní arábìnrin aya rẹ̀ ní aya, arábìnrin Tapenesi, ayaba. 20 Arábìnrin Tapenesi bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Genubati, ẹni tí Tapenesi tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Genubati ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Farao fúnrarẹ̀.

21 Nígbà tí ó sì wà ní Ejibiti, Hadadi sì gbọ́ pé Dafidi ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Joabu olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú. Nígbà náà ni Hadadi wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi.”

22 Farao sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?”

Hadadi sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!”

23 Ọlọ́run sì gbé ọ̀tá mìíràn dìde sí Solomoni, Resoni ọmọ Eliada, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri olúwa rẹ̀, ọba Ṣoba. 24 Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dafidi fi pa ogun Ṣoba run; wọ́n sì lọ sí Damasku, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jẹ ọba ní Damasku. 25 Resoni sì jẹ́ ọ̀tá Israẹli ní gbogbo ọjọ́ Solomoni, ó ń pa kún ibi ti Hadadi ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Resoni jẹ ọba ní Siria, ó sì ṣòdì sí Israẹli.

Jeroboamu ṣọ̀tẹ̀ sí Solomoni

26 Bákan náà Jeroboamu ọmọ Nebati sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Solomoni, ará Efraimu ti Sereda, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Serua.

27 Èyí sì ni ìdí tí ó fi ṣọ̀tẹ̀ sí ọba: Solomoni kọ́ Millo, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dafidi baba rẹ̀. 28 Jeroboamu jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Solomoni sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Josẹfu.

29 Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jeroboamu ń jáde kúrò ní Jerusalẹmu. Wòlíì Ahijah ti Ṣilo sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá tuntun. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko, 30 Ahijah sì gbá agbádá tuntun tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá 31 Nígbà náà ni ó sọ fún Jeroboamu pé, “Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Solomoni, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ. 32 Ṣùgbọ́n nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, òun yóò ní ẹ̀yà kan. 33 Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni, Kemoṣi òrìṣà àwọn ará Moabu, àti Moleki òrìṣà àwọn ọmọ Ammoni, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dafidi baba Solomoni ti ṣe.

34 “ ‘Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Solomoni; èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́. 35 Èmi yóò gba ìjọba náà ní ọwọ́ ọmọ rẹ̀, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ. 36 Èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ kí Dafidi ìránṣẹ́ mi lè máa ní ìmọ́lẹ̀ níwájú mi nígbà gbogbo ní Jerusalẹmu, ìlú tí mo ti yàn láti fi orúkọ mi síbẹ̀. 37 Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, Èmi yóò mú ọ, ìwọ yóò sì jẹ ọba lórí ohun gbogbo tí ọkàn rẹ ń fẹ́; ìwọ yóò jẹ ọba lórí Israẹli. 38 Bí ìwọ bá ṣe gbogbo èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú mi nípa pípa òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí i Dafidi ìránṣẹ́ mi ti ṣe, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò kọ́ ilé òtítọ́ fún ọ bí èyí tí mo kọ́ fún Dafidi, èmi yóò sì fi Israẹli fún ọ. 39 Èmi yóò sì rẹ irú-ọmọ Dafidi sílẹ̀ nítorí èyí, ṣùgbọ́n kì í ṣe títí láé.’ ”

40 Solomoni wá ọ̀nà láti pa Jeroboamu, ṣùgbọ́n Jeroboamu sálọ sí Ejibiti, sọ́dọ̀ Ṣiṣaki ọba Ejibiti, ó sì wà níbẹ̀ títí Solomoni fi kú.

Ikú Solomoni

41 Ìyókù iṣẹ́ Solomoni àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìṣe Solomoni bí? 42 (H)Solomoni sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli ní ogójì ọdún. 43 Nígbà náà ni Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Rehoboamu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí Rehoboamu

12 (I)Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu, nítorí gbogbo Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó wà ní Ejibiti síbẹ̀ gbọ́, nítorí tí ó ti sá kúrò níwájú Solomoni ọba, ó sì wà ní Ejibiti. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jeroboamu, òun àti gbogbo ìjọ Israẹli sì lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n sì wí fún un pé: “Baba rẹ sọ àjàgà wa di wúwo, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú kí ìsìn baba rẹ̀ tí ó le, àti àjàgà rẹ̀ tí ó wúwo, tí ó fi sí wa ní ọrùn kí ó fẹ́rẹ̀ díẹ̀, àwa yóò sì sìn ọ́.”

Rehoboamu sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ná títí di ọjọ́ mẹ́ta, nígbà náà ni kí ẹ padà tọ̀ mí wá.” Àwọn ènìyàn náà sì lọ.

Nígbà náà ni Rehoboamu ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbàgbà tí ń dúró níwájú Solomoni baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láààyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”

Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”

Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín. Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀?”

10 Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ. 11 Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”

12 Jeroboamu àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.” 13 Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, 14 Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo; Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i; Baba mi fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.” 15 Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ Olúwa wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati láti ẹnu Ahijah ará Ṣilo ṣẹ.

16 Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé:

Ìpín wo ni àwa ní nínú Dafidi,
    ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jese?
Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Israẹli!
    Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dafidi!

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli padà sí ilé wọn. 17 Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé nínú ìlú Juda, Rehoboamu jẹ ọba lórí wọn síbẹ̀.

18 Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu. 19 Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dafidi títí di òní yìí.

20 Nígbà tí gbogbo Israẹli sì gbọ́ pé Jeroboamu ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dafidi lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Juda nìkan.

21 Nígbà tí Rehoboamu sì dé sí Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ilé Juda jọ, àti ẹ̀yà Benjamini; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Israẹli jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.

22 (J)Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé: 23 “Sọ fún Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda àti fún gbogbo ilé Juda àti ti Benjamini, àti fún àwọn ènìyàn tókù wí pé, 24 ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Israẹli. Ẹ padà, olúkúlùkù yín sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

Ẹgbọrọ màlúù wúrà ní Beteli àti Dani

25 Nígbà náà ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu ní òkè Efraimu, ó sì ń gbé inú rẹ̀. Láti ibẹ̀ ó sì jáde lọ, ó sì kọ́ Penieli.

26 Jeroboamu rò nínú ara rẹ̀ pé, “Ìjọba náà yóò padà nísinsin yìí sí ilé Dafidi. 27 Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún Olúwa wọn, Rehoboamu ọba Juda. Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Rehoboamu ọba Juda lọ.”

28 Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọrọ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Israẹli, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Ejibiti wá.” 29 Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Beteli, àti èkejì ní Dani. 30 Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dani láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀.

31 Jeroboamu sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Lefi. 32 Jeroboamu sì dá àsè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àsè tí ó wà ní Juda, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Beteli, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Beteli. 33 Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Beteli. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.

Ènìyàn Ọlọ́run kan láti Juda

13 Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ” Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní ààmì kan wí pé: “Èyí ni ààmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”

Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́. Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ààmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.”

Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, Èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí. Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’ ” 10 Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Beteli.

11 Wòlíì àgbà kan wà tí ń gbé Beteli, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé, tí ó sì ròyìn gbogbo ohun tí ènìyàn Ọlọ́run náà ti ṣe ní Beteli ní ọjọ́ náà fún un. Wọ́n sì tún sọ fún baba wọn ohun tí ó sọ fún ọba. 12 Baba wọn sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ọ̀nà wo ni ó gbà?” Àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi ọ̀nà tí ènìyàn Ọlọ́run láti Juda gbà hàn án. 13 Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un tán, ó sì gùn ún. 14 Ó sì tẹ̀lé ènìyàn Ọlọ́run náà lẹ́yìn. Ó sì rí i tí ó jókòó lábẹ́ igi óákù kan, ó sì wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá bí?”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.”

15 Nígbà náà ni wòlíì náà sì wí fún un pé, “Bá mi lọ ilé, kí o sì jẹun.”

16 Ènìyàn Ọlọ́run náà sì wí pé, “Èmi kò le padà sẹ́yìn tàbí bá ọ lọ ilé, tàbí kí èmi kí ó jẹ oúnjẹ tàbí mu omi pẹ̀lú rẹ níhìn-ín. 17 A ti sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi níhìn-ín tàbí kí o padà lọ nípa ọ̀nà tí ìwọ bá wá.’ ”

18 Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, “Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Angẹli sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé: ‘Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi.’ ” (Ṣùgbọ́n ó purọ́ fún un ni.) 19 Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀.

20 Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé; 21 Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́. 22 Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ”

23 Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un. 24 Bí ó sì ti ń lọ ní ọ̀nà rẹ̀, kìnnìún kan pàdé rẹ̀ ní ọ̀nà, ó sì pa á, a sì gbé òkú rẹ̀ sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́. 25 Àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá sì rí pé ó gbé òkú náà sọ sí ojú ọ̀nà, kìnnìún náà sì dúró ti òkú náà; wọ́n sì wá, wọ́n sì sọ ọ́ ní ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé.

26 Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́. Olúwa sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti kìlọ̀ fún un.”

27 Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi,” wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 28 Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya. 29 Nígbà náà ni wòlíì náà gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì gbé e padà wá sí ìlú ara rẹ̀ láti ṣọ̀fọ̀ fún un àti láti sin ín. 30 Nígbà náà ni ó gbé òkú náà sínú ibojì ara rẹ̀, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe, arákùnrin mi!”

31 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú rẹ̀ tán, ó sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo bá kú, ẹ sin mí ní ibojì níbi tí a sin ènìyàn Ọlọ́run sí; ẹ tẹ́ egungun mi lẹ́bàá egungun rẹ̀. 32 Nítorí iṣẹ́ tí ó jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Olúwa sí pẹpẹ tí ó wà ní Beteli àti sí gbogbo ojúbọ lórí ibi gíga tí ń bẹ ní àwọn ìlú Samaria yóò wá sí ìmúṣẹ dájúdájú.”

33 Lẹ́yìn nǹkan yìí, Jeroboamu kò padà kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún yan àwọn àlùfáà sí i fún àwọn ibi gíga nínú gbogbo àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di àlùfáà, a yà á sọ́tọ̀ fún ibi gíga wọ̀nyí. 34 Èyí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó yọrí sí ìṣubú rẹ̀, a sì pa á run kúrò lórí ilẹ̀.

Ahijah sọtẹ́lẹ̀ fún Jeroboamu

14 Ní àkókò náà Abijah ọmọ Jeroboamu sì ṣàìsàn, Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí. Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.” Bẹ́ẹ̀ ni aya Jeroboamu sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Ahijah ní Ṣilo.

Ahijah kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Ahijah pé, “Kíyèsi i, aya Jeroboamu ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”

Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Ahijah sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jeroboamu. Kí ló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ. Lọ, sọ fún Jeroboamu pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dafidi, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, ìwọ kò dàbí Dafidi ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi. Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbé mi sọ sí ẹ̀yìn rẹ.

10 “ ‘Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jeroboamu. Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jeroboamu, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Israẹli. Èmi yóò mú ilé Jeroboamu kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán. 11 Ajá yóò jẹ ẹni Jeroboamu tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní igbó ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. Olúwa ti sọ ọ́!’

12 “Ní ti ìwọ, padà lọ ilé, nígbà tí o bá sì fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ ìlú, ọmọ náà yóò kú. 13 Gbogbo Israẹli yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín. Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jeroboamu, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ní ilé Jeroboamu.

14 Olúwa yóò gbé ọba kan dìde fúnrarẹ̀ lórí Israẹli tí yóò ké ilé Jeroboamu kúrò. Ọjọ́ náà nìyìí! Kí ni? Àní nísinsin yìí. 15 Olúwa yóò kọlu Israẹli, yóò sì dàbí koríko ti ń mì nínú omi. Yóò sì fa Israẹli tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò Eufurate, nítorí wọ́n ti rú ìbínú Olúwa nípa ṣíṣe ère Aṣerah. 16 Yóò sì kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Israẹli ṣẹ̀.”

17 Nígbà náà ni aya Jeroboamu sì dìde, ó sì lọ, ó sì lọ sí Tirsa. Bí ó sì ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìloro ilé, ọmọdé náà sì kú. 18 Wọ́n sì sin ín, gbogbo Israẹli sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ahijah wòlíì.

19 Ìyókù ìṣe Jeroboamu, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jẹ ọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli. 20 Jeroboamu sì jẹ ọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Rehoboamu ọba Juda

21 Rehoboamu ọmọ Solomoni sì jẹ ọba ní Juda. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jerusalẹmu, ìlú tí Olúwa ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama, ará Ammoni.

22 Juda sì ṣe búburú níwájú Olúwa nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ. 23 Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère òkúta àti òpó Aṣerah lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. 24 Àwọn tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà wà ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

25 (K)Ó sì ṣe ní ọdún karùn-ún Rehoboamu, Ṣiṣaki ọba Ejibiti kọlu Jerusalẹmu. 26 Ó sì kó ìṣúra ilé Olúwa lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú asà wúrà tí Solomoni ti ṣe. 27 Rehoboamu ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlẹ̀kùn ilé ọba. 28 Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé Olúwa Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́.

29 Ní ti ìyókù ìṣe Rehoboamu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda bí? 30 Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní ọjọ́ wọn gbogbo. 31 Rehoboamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dafidi. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama; ará Ammoni. Abijah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Abijah ọba Juda

15 (L)Ní ọdún kejì-dínlógún ìjọba Jeroboamu ọmọ Nebati, Abijah jẹ ọba lórí Juda, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́ta ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu.

Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀; ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. Ṣùgbọ́n, nítorí i Dafidi Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jerusalẹmu nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jẹ ọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀. Nítorí tí Dafidi ṣe èyí tí ó dára ní ojú Olúwa, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí Olúwa pàṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Uriah ará Hiti.

Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní gbogbo ọjọ́ ayé Abijah. Ní ti ìyókù ìṣe Abijah, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ogun sì wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. (M)Abijah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Asa ọba Juda

Ní ogún ọdún Jeroboamu ọba Israẹli, Asa jẹ ọba lórí Juda, 10 Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ńlá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu.

11 Asa sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. 12 Ó sì mú àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò. 13 (N)Ó sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní Àfonífojì Kidironi. 14 Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Asa pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo. 15 Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa.

16 Ogun sì wà láàrín Asa àti Baaṣa ọba Israẹli ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. 17 Baaṣa, ọba Israẹli sì gòkè lọ sí Juda, ó sì kọ́ Rama láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba lọ.

18 Nígbà náà ni Asa mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Beni-Hadadi ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni ọba Siria tí ó ń gbé ní Damasku. 19 Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrín èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Baaṣa, ọba Israẹli, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”

20 Beni-Hadadi gba ti Asa ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Israẹli. Ó sì ṣẹ́gun Ijoni, Dani àti Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo Kinnereti pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. 21 Nígbà tí Baaṣa sì gbọ́ èyí, ó sì ṣíwọ́ kíkọ́ Rama, ó sì lọ kúrò sí Tirsa. 22 Nígbà náà ni Asa ọba kéde ká gbogbo Juda, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta Rama kúrò àti igi rẹ̀, tí Baaṣa fi kọ́lé. Asa ọba sì fi wọ́n kọ́ Geba ti Benjamini àti Mispa.

23 (O)Ní ti ìyókù gbogbo ìṣe Asa, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, ààrùn ṣe é ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 24 (P)Asa sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Nadabu ọba Israẹli

25 Nadabu ọmọ Jeroboamu sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún kejì Asa ọba Juda, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjì. 26 Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà baba rẹ̀ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó mú Israẹli dá.

27 Baaṣa ọmọ Ahijah ti ilé Isakari sì dìtẹ̀ sí i, Baaṣa sì kọlù ú ní Gibetoni, ìlú àwọn ará Filistini, nígbà tí Nadabu àti gbogbo Israẹli dó ti Gibetoni. 28 Baaṣa sì pa Nadabu ní ọdún kẹta Asa ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

29 Ó sì ṣe, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba ó pa gbogbo ilé Jeroboamu, kò sì ku ẹnìkan tí ń mí fún Jeroboamu, ṣùgbọ́n ó run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ó sọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Ahijah ará Ṣilo: 30 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, àti nítorí tí ó ti mú Olúwa Ọlọ́run Israẹli bínú.

31 Ní ti ìyókù ìṣe Nadabu àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? 32 Ogun sì wà láàrín Asa àti Baaṣa ọba Israẹli ní gbogbo ọjọ́ wọn.

Baaṣa ọba Israẹli

33 Ní ọdún kẹta Asa ọba Juda, Baaṣa ọmọ Ahijah sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli ní Tirsa, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́rìnlélógún. 34 Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Jeroboamu àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀.

16 Ó sì ṣe, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jehu ọmọ Hanani wá sí Baaṣa pé: “Èmi ti gbé ọ ga láti inú erùpẹ̀ wá, mo sì fi ọ́ ṣe olórí Israẹli ènìyàn mi, ṣùgbọ́n ìwọ sì rìn ní ọ̀nà Jeroboamu, ó sì mú kí Israẹli ènìyàn mi dẹ́ṣẹ̀, láti mú mi bínú nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, èmi yóò mú Baaṣa àti ilé rẹ̀ kúrò, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jeroboamu ọmọ Nebati. Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Baaṣa tí ó bá kú ní ìlú, ẹyẹ ojú ọ̀run yóò sì jẹ àwọn tí ó kú ní oko.”

Àti ìyókù ìṣe Baaṣa, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Baaṣa sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní Tirsa. Ela ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì wá nípa ọwọ́ Jehu wòlíì ọmọ Hanani pẹ̀lú sí Baaṣa àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo búburú tí ó ti ṣe níwájú Olúwa, ní mímú un bínú nípa ohun tó ti ṣe àti wíwà bí ilé Jeroboamu: àti nítorí tí ó pa á run pẹ̀lú.

Ela ọba Israẹli

Ní ọdún kẹrìn-dínlọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, Ela ọmọ Baaṣa bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba ní Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Tirsa ní ọdún méjì.

Simri, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i. Ela sì wà ní Tirsa nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Arsa, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tirsa. 10 Simri sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n Asa, ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

11 Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Baaṣa pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́. 12 Bẹ́ẹ̀ ni Simri pa gbogbo ilé Baaṣa run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ sí Baaṣa nípa ọwọ́ Jehu wòlíì: 13 nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa àti Ela ọmọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ àti tí wọ́n ti mú Israẹli ṣẹ̀, tí wọ́n fi mú Olúwa Ọlọ́run Israẹli bínú, wọ́n mú u bínú nípa òrìṣà asán wọn.

14 Ìyókù ìṣe Ela àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli?

Simri ọba Israẹli

15 Ní ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, ni Simri jẹ ọba ọjọ́ méje ní Tirsa. Àwọn ọmọ-ogun sì dó ti Gibetoni, ìlú àwọn ará Filistini. 16 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí ó dó tì gbọ́ wí pé Simri ti dìtẹ̀ sí ọba, ó sì ti pa á, wọ́n kéde Omri, olórí ogun, bí ọba lórí Israẹli ní ọjọ́ náà ní ibùdó. 17 Nígbà náà ni Omri àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gibetoni, wọ́n sì dó ti Tirsa. 18 Nígbà tí Simri sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú, 19 nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú Olúwa àti ní rírìn ní ọ̀nà Jeroboamu àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀.

20 Ní ti ìyókù ìṣe Simri, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli?

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.