Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Lefitiku 26:27 - Numeri 8:14

27 “ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi, 28 Ní ìbínú mi èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 29 Ebi náà yóò pa yín dé bi pé ẹ ó máa jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin. 30 Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn: Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kórìíra yín. 31 Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́. 32 Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà. 33 Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè: Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro: àwọn ìlú yín ni a ó sì parun. 34 Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi (tí kò ni lákòókò ìsinmi rẹ̀) fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un. 35 Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákokò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀.

36 “ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín 37 Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín. 38 Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39 Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.

40 (A)“ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi. 41 Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 42 Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà. 43 Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófo láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórìíra àwọn àṣẹ mi. 44 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá: èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Ọlọ́run wọn 45 Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”

46 Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mose ní orí òkè Sinai láàrín òun àti àwọn ọmọ Israẹli.

Ìràpadà ohun tí ó jẹ́ ti Olúwa

27 Olúwa sọ fún Mose pé. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ẹnìkan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì láti ya ènìyàn kan sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run nípa sísan iye tí ó tó, kí iye owó ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sí ọgọ́ta ọdún jẹ́ àádọ́ta òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà, gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ṣékélì ti ibi mímọ́ Olúwa; Bí ẹni náà bá jẹ obìnrin, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n òṣùwọ̀n ṣékélì. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ dé bi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá síwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́.

“ ‘Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún Olúwa, irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún Olúwa di mímọ́. 10 Ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kò gbọdọ̀ pàrọ̀ ẹran mìíràn, yálà kí ó pàrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára tàbí èyí tí kò dára sí èyí tí ó dára. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ti Olúwa ni ẹranko méjèèjì. 11 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ: èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún Olúwa. Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà. 12 Kí àlùfáà díye lé e, gẹ́gẹ́ bí ó ti dára tàbí bí ó ti bàjẹ́ sí. Iye owó náà ni kí ó jẹ́. 13 Bí ẹni náà bá fẹ́ rà á padà: ó gbọdọ̀ san iye owó rẹ̀ àti ìdá ogún iye owó náà láfikún.

14 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa: kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí: iye owó náà ni kí ó jẹ́. 15 Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà. Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn-ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀.

16 “ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n ṣètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n homeri irúgbìn barle. 17 Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó ya ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọtẹ́lẹ̀ náà ni kí o san. 18 Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tókù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù. 19 Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà: kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdámárùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀. 20 Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tà á fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́. 21 Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún Olúwa. Yóò sì di ohun ìní àlùfáà.

22 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa. 23 Kí àlùfáà sọ iye tí ó tọ títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ọkùnrin náà sì san iye owó náà ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ sí Olúwa. 24 Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni í, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á. 25 Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́, ogún gera.

26 “ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sọ́tọ̀. Èyí jẹ́ ti Olúwa nípasẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà akọ màlúù ni tàbí àgùntàn, ti Olúwa ni. 27 Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀.

28 (B)“ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátápátá láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí Olúwa tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún: òun kò gbọdọ̀ tà á kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún Olúwa.

29 “ ‘Ẹni tí ẹ bá ti yà sọ́tọ̀ fún pípa, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ rà á padà, pípa ni kí ẹ pa á.

30 (C)“ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni. Mímọ́ ni fún Olúwa. 31 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un. 32 Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa. 33 Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀: àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà.’ ”

34 Àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni Olúwa pa fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Sinai.

Ìkànìyàn

(D)Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé: “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun. Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.

“Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí:

“Láti ọ̀dọ̀ Reubeni, Elisuri ọmọ Ṣedeuri;

Láti ọ̀dọ̀ Simeoni, Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai;

Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu;

Láti ọ̀dọ̀ Isakari, Netaneli ọmọ Ṣuari;

Láti ọ̀dọ̀ Sebuluni, Eliabu ọmọ Heloni;

10 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu:

láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu;

Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri;

11 Láti ọ̀dọ̀ Benjamini, Abidani ọmọ Gideoni;

12 Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai;

13 Láti ọ̀dọ̀ Aṣeri, Pagieli ọmọ Okanri;

14 Láti ọ̀dọ̀ Gadi, Eliasafu ọmọ Deueli;

15 Láti ọ̀dọ̀ Naftali, Ahira ọmọ Enani.”

16 Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.

17 Mose àti Aaroni mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí 18 wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, 19 gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai.

20 Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 21 Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlélógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500).

22 Láti ìran Simeoni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 23 Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (59,300).

24 Láti ìran Gadi:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn. 25 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ (45,650).

26 Láti ìran Juda:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 27 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600).

28 Láti ìran Isakari:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 29 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400).

30 Láti ìran Sebuluni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 31 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400).

32 Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu:

Láti ìran Efraimu:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 33 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

34 Láti ìran Manase:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 35 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún ó-lé-igba (32,200).

36 Láti ìran Benjamini:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 37 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).

38 Láti ìran Dani:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 39 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

40 Láti ìran Aṣeri:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 41 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

42 Láti ìran Naftali:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 43 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

44 Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mose àti Aaroni kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Israẹli, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣojú fún ìdílé rẹ̀. 45 Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 46 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta, (603,550).

47 (E)A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù. 48 Nítorí Olúwa ti sọ fún Mose pé, 49 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Lefi, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli: 50 (F)Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká. 51 Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, àwọn ọmọ Lefi ni yóò tú palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Lefi náà ni yóò ṣe é. Àlejò tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á 52 kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀. 53 Àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Israẹli; kí àwọn ọmọ Lefi sì máa ṣe ìtọ́jú àgọ́ ẹ̀rí náà.”

54 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ètò ibùdó ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan

Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”

Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn:

ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600).

Ẹ̀yà Isakari ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Isakari ni Netaneli ọmọ Ṣuari. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400).

Ẹ̀yà Sebuluni ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400).

Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàléláàdọ́run ó-lé-irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.

10 Ní ìhà gúúsù:

ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 11 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlélógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (46,500).

12 Ẹ̀yà Simeoni ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Simoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. 13 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje. (59,300).

14 Ẹ̀yà Gadi ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli. 15 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,650).

16 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-márùn-dínlọ́gọ́rin ó-lé-àádọ́ta-lé-légbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.

17 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi Àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.

18 Ní ìhà ìlà-oòrùn:

ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu. 19 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (40,500).

20 Ẹ̀yà Manase ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Manase ni Gamalieli ọmọ Pedasuri. 21 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-igba (32,200).

22 Ẹ̀yà Benjamini ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni. 23 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).

24 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìnléláàdọ́ta ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.

25 Ní ìhà àríwá:

ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 26 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ̀gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700).

27 Ẹ̀yà Aṣeri ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okanri. 28 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

29 Ẹ̀yà Naftali ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Naftali ni Ahira ọmọ Enani. 30 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-egbèje (53,400).

31 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gọ̀rin ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.

32 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta (603,550). 33 Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Lefi papọ̀ mọ́ àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

34 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.

Àwọn ẹ̀yà Lefi

Ìwọ̀nyí ni ìdílé Aaroni àti Mose ní ìgbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai.

(G)Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí, Nadabu ni àkọ́bí, Abihu, Eleasari àti Itamari. Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni ni ìwọ̀nyí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sinai, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Eleasari àti Itamari ló ṣiṣẹ́ àlùfáà nígbà ayé Aaroni baba wọn.

(H)(I) Olúwa sọ fún Mose pé, “Kó ẹ̀yà Lefi wá, kí o sì fà wọ́n fún Aaroni àlùfáà láti máa ràn án lọ́wọ́. Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní àgọ́ ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́. Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Israẹli nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́. Fi ẹ̀yà Lefi jì Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Aaroni nínú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. 10 Kí o sì yan Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.”

11 (J)Olúwa tún sọ fún Mose pé, 12 “Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi, 13 nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

Kíka àwọn ọmọ Lefi

14 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose ní aginjù Sinai pé, 15 (K)“Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè” 16 Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

17 (L)Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

18 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:

Libni àti Ṣimei.

19 Àwọn ìdílé Kohati ni:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

20 Àwọn ìdílé Merari ni:

Mahili àti Muṣi.

Wọ̀nyí ni ìdílé Lefi gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

21 Ti Gerṣoni ni ìdílé Libni àti Ṣimei; àwọn ni ìdílé Gerṣoni.

22 Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500).

23 Àwọn ìdílé Gerṣoni yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀-oòrùn lẹ́yìn àgọ́.

24 Olórí àwọn ìdílé Gerṣoni ni Eliasafu ọmọ Láélì.

25 Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gerṣoni nínú àgọ́ ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26 aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

27 Ti Kohati ní ìdílé Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli, wọ̀nyí ni ìran Kohati.

28 Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rin ó-lé-ẹgbẹ̀ta (8,600),

tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́.

29 Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.

30 Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli.

31 Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

32 Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.

33 Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari.

34 Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).

35 Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili.

Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.

36 Àwọn ìran Merari ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn; 37 Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.

38 Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀-oòrùn níwájú àgọ́ ìpàdé.

Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli.

Àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á.

39 Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Lefi tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá (22,000).

40 Olúwa sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn. 41 Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.”

42 Mose sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un. 43 Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó-dínméje (22,273).

44 Olúwa tún sọ fún Mose pé, 45 (M)Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi. Èmi ni Olúwa. 46 Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Israẹli tó ju iye àwọn ọmọ Lefi lọ, 47 ìwọ yóò gba ṣékélì márùn-ún (5) lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gera. 48 Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli tó lé yìí, ni kí o kó fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀.

49 Nígbà náà ni Mose gba owó ìràpadà àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi ti ra àwọn yòókù padà. 50 Mose sì gba egbèje ṣékélì ó dín márùn-dínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli. 51 Mose sì kó owó ìràpadà yìí fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

Àwọn ọmọ Kohati

(N)Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.

“Wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kohati nínú àgọ́ àjọ, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ. Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí. Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

“Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀. Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

“Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 10 Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.

11 “Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

12 “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.

13 “Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí. 14 Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwokòtò. Kí wọn ó fi awọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

15 “Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé.

16 “Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”

17 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 18 “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi: 19 Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé. 20 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kohati kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”

Àwọn ọmọ Gerṣoni

21 Olúwa sọ fún Mose pé: 22 “Tún ka iye àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 23 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.

24 “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù: 25 Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26 Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí àgbàlá, okùn àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìsìn, àti ohun gbogbo tí à ń lò fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa sìn. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 27 Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un. 28 Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gerṣoni ni àgọ́ ìpàdé Itamari, ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn.

Àwọn ọmọ Merari

29 “Ka iye àwọn ọmọ Merari nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 30 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 31 Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábùú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀, 32 Pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un; 33 Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Merari, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.”

Àbájáde kíka àwọn ọmọ Lefi

34 Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kohati nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

35 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ ìpàdé. 36 Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó-dínàádọ́ta (2,750). 37 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

38 Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

39 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 40 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó-lé-ọgbọ̀n (2,630). 41 Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ Olúwa.

42 Wọ́n ka àwọn ọmọ Merari nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

43 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 44 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200). 45 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Merari. Mose àti Aaroni kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

46 Gbogbo àwọn tí a kà nínú àwọn ọmọ Lefi, ti Mose àti Aaroni àti àwọn olórí Israẹli kà, nípa ìdílé wọn àti gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. 47 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn ẹrù inú Àgọ́ Ìpàdé. 48 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580). 49 Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Wíwà ní mímọ́ ibùdó

Olúwa sọ fún Mose pé: (O)“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn” Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

Ìjẹ́wọ́ àti àtúnṣe

(P)Olúwa sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi. Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó súnmọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀. 10 Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ ti òun nìkan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”

Àyẹ̀wò fún aláìṣòótọ́ ìyàwó

11 Olúwa sọ fún Mose wí pé, 12 “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìṣòótọ́ sí i, 13 Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lòpọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà). 14 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ dé bi pé ó ń funra sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́, 15 nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.

16 “ ‘Àlùfáà yóò sì mú un wá síwájú Olúwa. 17 Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀, 18 Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnrarẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́. 19 Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi. 20 Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ bá ọ lòpọ̀,” 21 nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrín àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ̀ sì wú. 22 Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹrà dànù.”

“ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”

23 “ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé kíká, yóò sì sìn ín sínú omi kíkorò náà. 24 Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi. 25 Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ. 26 Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi. 27 Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 28 Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.

29 “ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe a ṣe má ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́ 30 Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó funra sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un. 31 Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’ ”

Òfin fún àwọn Nasiri

Olúwa sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ sí Olúwa nípa àìgé irun orí (Nasiri): (Q)Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ. Níwọ́n ìgbà tí ó sì jẹ́ Nasiri, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èso àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀.

“ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.

“ ‘Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn. Ìbá à ṣe òkú baba, àti ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí àbúrò rẹ̀, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí wọn, nítorí pé ààmì ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run wà ní orí rẹ̀. Ní gbogbo àsìkò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

“ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje. 10 Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 11 Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà. Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an. 12 Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.

13 (R)“ ‘Èyí ni òfin fún Nasiri nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 14 Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà, 15 pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí.

16 “ ‘Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá síwájú Olúwa, yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun. 17 Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.

18 “ ‘Nígbà náà ni Nasiri náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà.

19 “ ‘Lẹ́yìn tí Nasiri bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́. 20 Àlùfáà yóò fi gbogbo rẹ̀ níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú igẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè mu wáìnì.

21 “ ‘Èyí ni òfin Nasiri tó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ rẹ̀ sí Olúwa, yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Nasiri, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tó lágbára láti mú wá. Ó gbọdọ̀ mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Nasiri.’ ”

Ìbùkún àlùfáà

22 Olúwa sọ fún Mose pé, 23 “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé:

24 “ ‘ “Kí Olúwa bùkún un yín
    Kí ó sì pa yín mọ́.
25 Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára.
    Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
26 Olúwa bojú wò yín;
    Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’

27 “Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Israẹli, Èmi ó sì bùkún wọn.”

Ọrẹ níbi ìyàsímímọ́ àgọ́

Nígbà tí Mose ti parí gbígbé àgọ́ dúró, ó ta òróró sí i, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, Ó tún ta òróró sí pẹpẹ, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn olórí Israẹli, àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn alábojútó àwọn tí a kà náà mú ọrẹ wá. Wọ́n mú ọrẹ wọn wá síwájú Olúwa: kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà ti abo, àti akọ màlúù kan láti ọ̀dọ̀ olórí kọ̀ọ̀kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù kan láti ọ̀dọ̀ olórí méjì. Wọ́n sì kó wọn wá sí iwájú àgọ́.

Olúwa sọ fún Mose pé: “Gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n ba à lè wúlò fún iṣẹ́ inú àgọ́ ìpàdé. Kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan bá ṣe nílò rẹ̀.”

Mose sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti akọ màlúù náà fún àwọn ọmọ Lefi. Ó fún àwọn ọmọ Gerṣoni ní kẹ̀kẹ́ méjì àti akọ màlúù mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Ó fún àwọn ọmọ Merari ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Ṣùgbọ́n Mose kò fún àwọn ọmọ Kohati ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn.

10 Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá síwájú pẹpẹ. 11 Nítorí tí Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ.”

12 Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ní Nahiṣoni ọmọ Amminadabu láti inú ẹ̀yà Juda.

13 Ọrẹ rẹ̀ jẹ́:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

14 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

15 Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,

16 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,

17 Akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

18 Ní ọjọ́ kejì ni Netaneli ọmọ Ṣuari olórí àwọn ọmọ Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

19 Ọrẹ tí ó kó wá ní:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

20 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

21 Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

22 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

23 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Ṣuari.

24 Eliabu ọmọ Heloni, olórí àwọn ọmọ Sebuluni ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹta.

25 Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) àti ṣékélì fàdákà, àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì,

26 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

27 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

28 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

29 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni.

30 Elisuri ọmọ Ṣedeuri olórí àwọn ọmọ Reubeni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin.

31 Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

32 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

33 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

34 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

35 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

36 Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai, olórí àwọn ọmọ Simeoni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún.

37 Ọrẹ tí ó kó wá ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

38 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

39 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

40 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

41 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.

42 Eliasafu ọmọ Deueli olórí àwọn ọmọ Gadi ní ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹfà.

43 Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò bí ẹbọ ohun jíjẹ;

44 àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

45 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

46 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

47 màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Eliasafu ọmọ Deueli.

48 Eliṣama ọmọ Ammihudu, olórí àwọn ọmọ Efraimu ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ keje.

49 Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

50 àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

51 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

52 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

53 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Eliṣama ọmọ Ammihudu.

54 Gamalieli ọmọ Pedasuri, olórí àwọn ọmọ Manase ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹjọ.

55 Ọrẹ tirẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

56 àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

57 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

58 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

59 màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Gamalieli ọmọ Pedasuri.

60 Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ọmọ Benjamini ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹsànán.

61 Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

62 àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

63 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

64 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

65 màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Abidani ọmọ Gideoni.

66 Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olórí àwọn ọmọ Dani ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá.

67 Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo sílífà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

68 àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

69 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

70 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

71 àti fún ẹbọ ti ẹbọ àlàáfíà, akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn márùn-ún ọlọ́dún kan.

Èyí ni ọrẹ ẹbọ tí Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

72 Pagieli ọmọ Okanri, olórí àwọn ọmọ Aṣeri ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kọkànlá.

73 Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

74 àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

75 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

76 akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

77 màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Pagieli ọmọ Okanri.

78 Ahira ọmọ Enani, olórí àwọn Naftali ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kejìlá.

79 Ọrẹ rẹ̀ ni:

àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì, àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

80 àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

81 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

82 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

83 màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà.

Èyí ni ọrẹ Ahira ọmọ Enani.

84 Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí:

àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá. 85 Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. 86 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwo wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì (120).

87 Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, àgbò méjìlá, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá.

88 Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan.

Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i.

89 Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárín àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tí ó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mose sọ̀rọ̀.

Gbígbé ọ̀pá fìtílà ró

Olúwa sọ fún Mose pé: “Bá Aaroni sọ̀rọ̀ kí o wí fún un pé. ‘Nígbà tí ó bá ń to àwọn fìtílà, àwọn fìtílà méjèèje gbọdọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí àyíká níwájú ọ̀pá fìtílà.’ ”

Aaroni sì ṣe bẹ́ẹ̀; ó to àwọn fìtílà náà tí wọ́n sì fi kojú síwájú lórí ọ̀pá fìtílà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bí a ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyìí: A ṣe é láti ara wúrà lílù: láti ìsàlẹ̀ títí dé ibi ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí bátànì tí Olúwa fihan Mose.

Ìyàsọ́tọ̀ àwọn ọmọ Lefi

Olúwa sọ fún Mose pé: (S)“Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́. Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́: Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Israẹli jọ síbẹ̀ pẹ̀lú. 10 Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Israẹli yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Lefi lórí. 11 Aaroni yóò sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa.

12 “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi. 13 Mú kí àwọn ọmọ Lefi dúró níwájú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa. 14 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.