Bible in 90 Days
11 “Báyìí ni Olúwa wí, Kíyèsi i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládùúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrùn yìí. 12 Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀: Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Israẹli, àti níwájú òòrùn.’ ”
13 Dafidi sì wí fún Natani pé, “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa!”
Natani sì wí fún Dafidi pé, “Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú. 14 Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀-òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.”
Ọmọ náà kú
15 Natani sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi ààrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Uriah bí fún Dafidi, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀. 16 Dafidi sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dafidi sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lórí ilé ni òru náà. 17 Àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.
18 Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní èṣe tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”
19 Nígbà tí Dafidi sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dafidi sì kíyèsi i, pé ọmọ náà kú: Dafidi sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”
20 Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin: ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.
21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láààyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sọkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”
22 Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sọkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’ 23 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”
Batṣeba sì tún bí ọmọ mìíràn tí a pè ní Solomoni
24 Dafidi sì ṣìpẹ̀ fún Batṣeba aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀: òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dafidi sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Solomoni: Olúwa sì fẹ́ ẹ. 25 Ó sì rán Natani wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidiah, nítorí Olúwa.
Ìṣẹ́gun Dafidi lórí àwọn Ammoni
26 (A)Joabu sì bá Rabba ti àwọn ọmọ Ammoni jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn. 27 Joabu sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rabba jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olómi. 28 Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má bá à gba ìlú náà kí a má ba à pè é ní orúkọ mi.”
29 Dafidi sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rabba, ó sì bá a jà, ó sì gbà á. 30 Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ tálẹ́ǹtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dafidi lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀. 31 Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtulẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe: bẹ́ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ammoni. Dafidi àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jerusalẹmu.
Amnoni àti Tamari
13 Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀.
2 Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀.
3 Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi: Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi. 4 Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?”
Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.”
5 Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn: baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”
6 Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”
7 Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.” 8 Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà. 9 Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ.
Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá. 11 Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.”
12 Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. 13 Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” 14 Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀.
15 Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!”
16 Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.”
Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. 17 Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” 18 Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. 19 Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.
Absalomu kọlu Amnoni
20 Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
21 Ṣùgbọ́n nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi. 22 Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú: nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.
23 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu: Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. 24 Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”
25 Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.
26 Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.”
Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” 27 Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.
28 Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” 29 Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.
30 Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” 31 Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.
32 Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. 33 Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.”
Absalomu sálọ sí Geṣuri
34 Absalomu sì sá.
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”
35 Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”
36 Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.
37 Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́.
38 Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta. 39 Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.
Absalomu padà si Jerusalẹmu
14 Joabu ọmọ Seruiah sì kíyèsi i, pé ọkàn ọba sì fà sí Absalomu. 2 Joabu sì ránṣẹ́ sí Tekoa, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀. 3 Kí o sì tọ ọba wá, kí o sọ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.” Joabu sì fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu.
4 Nígbà tí obìnrin àrá Tekoa sì ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún ọba, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, o sí bu ọlá fún un, o sì wí pé, “ọba, gbà mi.”
5 Ọba sì bi í léèrè pé, “Kín ni o ṣe ọ́?”
Òun sì dáhùn wí pé, “Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú. 6 Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á. 7 Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú: wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú sílẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé.”
8 Ọba sì wí fún obìnrin náà pé, “Lọ sí ilé rẹ̀, èmi ó sì kìlọ̀ nítorí rẹ.”
9 Obìnrin ará Tekoa náà sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lórí ìdílé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.”
10 Ọba sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ sí ọ, mú ẹni náà tọ̀ mí wá, òun kì yóò sì tọ́ ọ mọ́.”
11 Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe ìparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!”
Òun sì wí pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.”
Ẹ̀bẹ̀ ní ti Absalomu
12 Obìnrin náà sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi ọba.”
Òun si wí pé, “Máa wí.”
13 Obìnrin náà sì wí pé, “Nítorí kín ni ìwọ sì ṣe ro irú nǹkan yìí sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run? Nítorí pé ní sísọ nǹkan yìí ọba ní ẹ̀bi, nítorí pé ọba kò mú ìsáǹsá rẹ̀ bọ̀ wá ilé. 14 Nítorí pé àwa ó sá à kú, a ó sì dàbí omi tí a tú sílẹ̀ tí a kò sì lè ṣàjọ mọ́; nítorí bí Ọlọ́run kò ti gbà ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ti ṣe ọ̀nà kí a má bá a lé ìsáǹsá rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
15 “Ǹjẹ́ nítorí náà ni èmi sì ṣe wá sọ nǹkan yìí fún olúwa mi ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti dẹ́rùbà mí; ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ èmi ó sọ fún ọba; ó lè rí bẹ́ẹ̀ pé ọba yóò ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un. 16 Nítorí pé ọba ò gbọ́, láti gbà ìránṣẹ́bìnrin rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà tí ó ń fẹ́ gé èmi àti ọmọ mi pẹ̀lú kúrò nínú ilẹ̀ ìní Ọlọ́run.’
17 “Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú; nítorí bí angẹli Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú: Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’ ”
Dafidi mọ̀ pé Joabu ni ó ṣe èyí
18 Ọba sì dáhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, “Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́.”
Obìnrin náà wí pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba máa wí?”
19 Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?”
Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láààyè, olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti wí: nítorí pé Joabu ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu. 20 Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Joabu ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n angẹli Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.”
Absalomu padà wá sí ilé
21 Ọba sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Absalomu padà wá.”
22 Joabu sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Joabu sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.”
23 Joabu sì dìde, ó sì lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu wá sí Jerusalẹmu. 24 Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Absalomu sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.
Ẹwà Absalomu àti àwọn ọmọ rẹ̀
25 Kó sì sí arẹwà kan ní gbogbo Israẹli tí à bá yìn bí Absalomu: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀. 26 Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣékélì nínú òṣùwọ̀n ọba.
27 A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Absalomu àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú.
Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Absalomu
28 Absalomu sì gbé ni ọdún méjì ní Jerusalẹmu kò sì rí ojú ọba. 29 Absalomu sì ránṣẹ́ sí Joabu, láti rán an sí ọba: ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá. 30 Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, oko Joabu gbé ti èmi, ó sì ní ọkà barle níbẹ̀; ẹ lọ kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́.” Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tiná bọ oko náà.
31 Joabu sì dìde, ó sì tọ Absalomu wá ní ilé, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi tiná bọ oko mi?”
32 Absalomu sì dá Joabu lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Geṣuri wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn ún síbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.”
33 Joabu sì tọ ọba wá, ó sì rò fún un: ó sì ránṣẹ́ pe Absalomu, òun sì wá sọ́dọ̀ ọba, ó tẹríba fún un, ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀ níwájú ọba, ọba sì fi ẹnu ko Absalomu lẹ́nu.
Absalomu dìtẹ̀ sí Dafidi baba rẹ̀
15 Lẹ́yìn èyí náà, Absalomu sì pèsè kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin fún ara rẹ̀, àti àádọ́ta ọmọkùnrin tí yóò máa sáré níwájú rẹ̀. 2 Absalomu sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apá kan ọ̀nà ẹnu ibodè: bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli wá.” 3 Absalomu yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ ṣá dára, ó sì tọ́: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.” 4 Absalomu a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan bá à lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”
5 Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ láti tẹríba fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dìímú, a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 6 Irú ìwà báyìí ni Absalomu a máa hù sí gbogbo Israẹli tí ó tọ́ ọba wá nítorí ìdájọ́: Absalomu sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Israẹli sọ́dọ̀ rẹ̀.
7 Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Absalomu sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hebroni. 8 Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Geṣuri ní Siria pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jerusalẹmu, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”
9 Ọba sì wí fún un pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hebroni.
10 Ṣùgbọ́n Absalomu rán ààmì sáàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Absalomu jẹ ọba ní Hebroni.’ ” 11 Igba ọkùnrin sì bá Absalomu ti Jerusalẹmu jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkan kan. 12 Absalomu sì ránṣẹ́ pe Ahitofeli ará Giloni, ìgbìmọ̀ Dafidi, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Giloni, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Absalomu.
Dafidi sálọ kúrò lórí oyè
13 Ẹnìkan sì wá rò fún Dafidi pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Israẹli ṣí sí Absalomu.”
14 Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sálọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Absalomu; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má bá à yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.”
15 Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ti murá.”
16 Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé. 17 Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà. 18 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí iwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kereti, àti gbogbo àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ará Gitti, ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gati wá, sì kọjá níwájú ọba.
Ìwà òótọ́ Itai ará Gitti
19 Ọba sì wí fún Ittai ará Gitti pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó; nítorí pé àlejò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀. 20 Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ káàkiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arákùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
21 Ittai sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láààyè, àti bí olúwa mi ọba ti ń bẹ láààyè, nítòótọ́ níbikíbi tí olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbá à ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.”
22 Dafidi sì wí fún Ittai pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ittai ará Gitti náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kéékèèkéé tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
23 Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sọkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá Àfonífojì Kidironi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù.
A gbé àpótí ẹ̀rí padà sí ìlú Jerusalẹmu
24 Sì wò ó, Sadoku pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Abiatari sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá.
25 Ọba sì wí fún Sadoku pé, “Sì tún gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú: bí èmi bá rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa, yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀. 26 Ṣùgbọ́n bí òun bá sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí ọ,’ wò ó, èmi nìyìí, jẹ́ kí òun ó ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ̀.”
27 Ọba sì wí fún Sadoku àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Ahimasi ọmọ rẹ, àti Jonatani ọmọ Abiatari. 28 Wò ó, èmi ó dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà, títí ọ̀rọ̀ ó fi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá láti sọ fún mi.” 29 Sadoku àti Abiatari sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà sí Jerusalẹmu: wọ́n sì gbé ibẹ̀.
Ahitofeli lọ́wọ́ sí ìdìtẹ̀ náà
30 Dafidi sì ń gòkè lọ ní òkè igi olifi, o sì ń sọkún bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹsẹ̀: gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ. 31 Ẹnìkan sì sọ fún Dafidi pé, “Ahitofeli wà nínú àwọn aṣọ̀tẹ̀ pẹ̀lú Absalomu.” Dafidi sì wí pé, “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Ahitofeli di asán.”
Huṣai padà sí Jerusalẹmu
32 Ó sì ṣe, Dafidi dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Huṣai ará Arki sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀. 33 Dafidi sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá bá mi kọjá, ìwọ ó sì jẹ́ ìdíwọ́ fún mi. 34 Bí ìwọ bá sì padà sí ìlú, tí o sì wí fún Absalomu pé, ‘Èmi ó ṣe ìránṣẹ́ rẹ ọba, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ṣe ìránṣẹ́ baba rẹ nígbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nísinsin yìí,’ kí ìwọ sì bá ìmọ̀ Ahitofeli jẹ́. 35 Ṣé Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀? Yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ìwọ bá gbọ́ láti ilé ọba wá, ìwọ ó sì sọ fún Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà. 36 Wò ó, àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Ahimasi ọmọ Sadoku, àti Jonatani ọmọ Abiatari; láti ọwọ́ wọn ni ẹ̀yin ó sì rán ohunkóhun tí ẹ̀yin bá gbọ́ sí mi.”
37 Huṣai ọ̀rẹ́ Dafidi sì wá sí ìlú, Absalomu sì wá sí Jerusalẹmu.
Dafidi àti Ṣiba
16 Nígbà tí Dafidi sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣiba ìránṣẹ́ Mefiboṣeti sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún síírí àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn-ún èso ẹ̀rún, àti ìgò ọtí wáìnì kan.
2 Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Kí ni wọ̀nyí?”
Ṣiba sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.”
3 Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?”
Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jerusalẹmu; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Israẹli yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ”
4 Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefiboṣeti jẹ́ tìrẹ.”
Ṣiba sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, olúwa mi ọba.”
Ṣimei Bú Dafidi
5 Dafidi ọba sì dé Bahurimu, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Saulu wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera: ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀. 6 Ó sì sọ òkúta sí Dafidi, àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dafidi ọba, àti sí gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 7 Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. 8 Olúwa mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; Olúwa ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.”
9 Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.”
10 Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé: ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”
11 Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un. 12 Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, Olúwa yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”
13 Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣimei sì ń rìn òdìkejì òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókùúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀. 14 Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jordani, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀.
Huṣai farahàn Absalomu bí ẹni tí ó ní ìfẹ́ sí i
15 Absalomu àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Israẹli sì wá sí Jerusalẹmu, Ahitofeli sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16 Ó sì ṣe, nígbà tí Huṣai ará Arki, ọ̀rẹ́ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”
17 Absalomu sì wí fún Huṣai pé, “Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí? Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?”
18 Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí Olúwa, àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó. 19 Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn? Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ.”
Absalomu wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀
20 Absalomu sì wí fún Ahitofeli pé, “Ẹ bá ará yín gbìmọ̀ ohun tí àwa ó ṣe.”
21 Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ yóò sì le.” 22 Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Absalomu ní òrùlé; Absalomu sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Israẹli.
23 Ìmọ̀ Ahitofeli tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run: bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Ahitofeli fún Dafidi àti fún Absalomu sì rí.
Ahitofeli gbìmọ̀ pé kí a lépa Dafidi
17 Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Èmi ó yan ẹgbàafà ọkùnrin èmi ó sì dìde, èmi ó sì lépa Dafidi lóru yìí. 2 Èmi ó sì yọ sí i nígbà tí àárẹ̀ bá mú un tí ọwọ́ rẹ̀ sì ṣe aláìle, èmi ó sì dá a ní ìjì: gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì sá, èmi ó sì kọlu ọba nìkan ṣoṣo. 3 Èmi ó sì mú gbogbo àwọn ènìyàn padà sọ́dọ̀ rẹ bi ìgbà tí ìyàwó bá padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Ọkàn ẹnìkan ṣoṣo tí ìwọ ń wá yìí ni ó túmọ̀ sí ìpadàbọ̀ gbogbo wọn; gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àlàáfíà.” 4 Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú Absalomu, àti lójú gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli.
Huṣai fi ọgbọ́n yí ìmọ̀ náà po
5 Absalomu sì wí pé, “Ǹjẹ́ pe Huṣai ará Arki, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú.” 6 Huṣai sì dé ọ̀dọ̀ Absalomu, Absalomu sì wí fún un pé, “Báyìí ni Ahitofeli wí, kí àwa ṣe bí ọ̀rọ̀ rẹ bí? Bí ko bá sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ wí.”
7 Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Ìmọ̀ tí Ahitofeli gbà yìí, kò dára nísinsin yìí.” 8 Huṣai sì wí pé, “Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá: baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru. 9 Kíyèsi i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn: yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, ‘Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Absalomu lẹ́yìn.’ 10 Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìún, yóò sì rẹ̀ ẹ́: nítorí gbogbo Israẹli ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára.
11 “Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé: Kí gbogbo Israẹli wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dani títí dé Beerṣeba, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí Òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkára rẹ̀ ó lọ sí ogun náà. 12 Àwa ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 13 Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Israẹli yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odò, títí a kì yóò fi rí òkúta kéékèèkéé kan níbẹ̀.”
14 Absalomu àti gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wí pé, “Ìmọ̀ Huṣai ará Arki sàn ju ìmọ̀ Ahitofeli lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Ahitofeli po.” Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Absalomu.
Huṣai ránṣẹ́ sí Dafidi nípa ìmọ̀ náà
15 Huṣai sì wí fún Sadoku àti fún Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Báyìí ni Ahitofeli ti bá Absalomu àti àwọn àgbàgbà Israẹli dámọ̀ràn: báyìí lèmi sì bá a dámọ̀ràn. 16 Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dafidi pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má bá a gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ”
17 Jonatani àti Ahimasi sì dúró ní En-Rogeli ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dafidi ọba nítorí pé kí a má bá à rí wọn pé wọ́n wọ ìlú. 18 Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Absalomu: ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Bahurimu, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀. 19 Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkan ó fi bo kànga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀.
20 Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?”
Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu.
21 Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dafidi ọba. Wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Dìde kí o sì gòkè odò kánkán: nítorí pé báyìí ni Ahitofeli gbìmọ̀ sí ọ.” 22 Dafidi sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jordani: kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jordani.
Ahitofeli pokùnso
23 Nígbà tí Ahitofeli sì rí i pé wọn kò fi ìmọ̀ tirẹ̀ ṣe, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni gàárì, ó sì dìde, ó lọ ilé rẹ̀, ó sì palẹ̀ ilé rẹ̀ mọ̀, ó sì so, ó sì kú, a sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀. Absalomu gbógun ti Dafidi.
24 Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Absalomu sì gòkè odò Jordani, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli pẹ̀lú rẹ̀. 25 Absalomu sì fi Amasa ṣe olórí ogun ní ipò Joabu: Amasa ẹni tí í ṣe ọmọ ẹnìkan, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Itira, ará Israẹli, tí ó wọlé tọ Abigaili ọmọbìnrin Nahaṣi, arábìnrin Seruiah, ìyá Joabu. 26 Israẹli àti Absalomu sì dó ní ilẹ̀ Gileadi.
27 Nígbà tí Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba tí àwọn ọmọ Ammoni, àti Makiri ọmọ Ammieli ti Lo-Debari, àti Barsillai ará Gileadi ti Rogelimu. 28 Mú àwọn àkéte, àti àwọn àwo, àti ìkòkò amọ̀, àti alikama, àti ọkà barle, àti ìyẹ̀fun, àti àgbàdo díndín, àti ẹ̀wà, àti erèé, àti lẹntili. 29 Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàṣì màlúù, wá fún Dafidi àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ: nítorí tí wọ́n wí pé, “Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.”
Wọ́n pàdé ogun ní igbó Efraimu
18 Dafidi sì ka àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì mú wọn jẹ balógun ẹgbẹgbẹ̀rún, àti balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún lórí wọn. 2 Dafidi sì fi ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn náà lé Joabu lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ, àti ìdámẹ́ta lé Abiṣai ọmọ Seruiah àbúrò Joabu lọ́wọ́ àti ìdámẹ́ta lè Ittai ará Gitti lọ́wọ́, ọba sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Nítòótọ́ èmi tìkára mi yóò sì bá yín lọ pẹ̀lú.”
3 Àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ìwọ kì yóò bá wa lọ: nítorí pé bí àwa bá sá, wọn kì yóò náání wa, tàbí bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìdajì wa kú, wọn kì yóò náání wa, nítorí pé ìwọ nìkan tó ẹgbàárùn-ún wa: nítorí náà, ó sì dára kí ìwọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti ìlú wá.”
4 Ọba sì wí fún wọn pé, “Èyí tí ó bá tọ́ lójú yin ni èmi ó ṣe.”
Ọba sì dúró ní apá kan ẹnu odi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 5 Ọba sì pàṣẹ fún Joabu àti Abiṣai àti Ittai pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Absalomu.
6 Àwọn ènìyàn náà sì jáde láti pàdé Israẹli ní pápá; ní igbó Efraimu ni wọ́n gbé pàdé ìjà náà. 7 Níbẹ̀ ni a gbé pa àwọn ènìyàn Israẹli níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ṣubú lọ́jọ́ náà, àní ẹgbàáwàá ènìyàn. 8 Ogun náà sì fọ́n káàkiri lórí gbogbo ilẹ̀ náà: igbó náà sì pa ọ̀pọ̀ ènìyàn ju èyí tí idà pa lọ lọ́jọ́ náà.
Joabu sì kọlu Absalomu
9 Absalomu sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. Absalomu sì gun orí ìbáaka kan, ìbáaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbáaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò.
10 Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi rí Absalomu so rọ̀ láàrín igi óákù kan.”
11 Joabu sì wí fún ọkùnrin náà tí ó sọ fún un pé, “Sá wò ó, ìwọ rí i, èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi lù ú bolẹ̀ níbẹ̀? Èmi ìbá sì fún ọ ní ṣékélì fàdákà mẹ́wàá, àti àmùrè kan.”
12 Ọkùnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Abiṣai, àti Ittai, pé, ‘Ẹ kíyèsi i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu.’ 13 Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ èmi ìbá ṣe sí ara mi: nítorí pé kò sí ọ̀ràn kan tí ó pamọ́ fún ọba, ìwọ tìkára rẹ̀ ìbá sì kọjú ìjà sí mi pẹ̀lú.”
14 Joabu sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Absalomu ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láààyè ní agbede-méjì igi óákù náà. 15 Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Joabu sì yí Absalomu ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á.
16 Joabu sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Israẹli: nítorí Joabu ti pe àwọn ènìyàn náà padà. 17 Wọ́n sì gbé Absalomu, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Israẹli sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀.
18 Absalomu ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ́n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní Àfonífojì Ọba: nítorí tí ó wí pé, Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí: òun sì pe ọ̀wọ́n náà nípa orúkọ rẹ̀: a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Absalomu.
Dafidi ṣọ̀fọ̀
19 Ahimasi ọmọ Sadoku sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìròyìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.”
20 Joabu sì wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò mù ìròyìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ọjọ́ mìíràn: ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìròyìn kan lọ, nítorí tí ọmọ ọba ṣe aláìsí.”
21 Joabu sì wí fún Kuṣi pé, “Lọ, kí ìwọ ro ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Kuṣi sì wólẹ̀ fún Joabu ó sì sáré.
22 Ahimasi ọmọ Sadoku sì tún wí fún Joabu pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tọ Kuṣi lẹ́yìn.”
Joabu sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìròyìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.”
23 Ó sì wí pé, “Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré.”
Ó sì wí fún un pé, “Sáré!” Ahimasi sì sáré ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì sáré kọjá Kuṣi.
24 Dafidi sì jókòó lẹ́nu odi láàrín ìlẹ̀kùn méjì: Alóre sì gòkè òrùlé bodè lórí odi, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wò, wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan. 25 Alóre náà sì kígbe, ó sì wí fún ọba.
Ọba sì wí pé, “Bí ó bá ṣe òun nìkan ni, ìròyìn rere ń bẹ lẹ́nu rẹ̀.” Òun sì ń súnmọ́ tòsí.
26 Alóre náà sì rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré: Alóre sì kọ sí ẹni tí ń ṣọ́ bodè, ó sì wí pe, “Wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.”
Ọba sì wí pé, “Èyí náà pẹ̀lú ń mú ìròyìn rere wá.”
27 Alóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáré ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Ahimasi ọmọ Sadoku.”
Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìhìnrere wá!”
28 Ahimasi sì dé, ó sì wí fún ọba pé, “Àlàáfíà!” Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́.”
29 Ọba sì béèrè pé, “Àlàáfíà ha wà fún Absalomu, ọmọdékùnrin náà bí?”
Ahimasi sì dáhùn pé, “Nígbà tí Joabu rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀.”
30 Ọba sì wí fún un pé, “Yípadà kí o sì dúró níhìn-ín.” Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́.
31 Sì wò ó, Kuṣi sì wí pé, “Ìhìnrere fún olúwa mi ọba: nítorí tí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ lónìí lára gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ.”
32 Ọba sì bi Kuṣi pé, “Àlàáfíà kọ́ Absalomu ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí?”
Kuṣi sì dáhùn pe, “Kí àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà.”
33 Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sọkún; báyìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Absalomu! Ọmọ mi! Ọmọ mí Absalomu! Á à! Ìbá ṣe pé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”
Joabu bá Dafidi wí gidigidi
19 A sì rò fún Joabu pe, “Wò ó, ọba ń sọkún, ó sì ń gbààwẹ̀ fún Absalomu.” 2 Ìṣẹ́gun ọjọ́ náà sì di àwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ọjọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀. 3 Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà. 4 Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Á à! Ọmọ mi Absalomu! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!”
5 Joabu sì wọ inú ilé tọ ọba lọ, ó sì wí pé, “Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ. 6 Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kórìíra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbá ṣe pé Absalomu wà láààyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi. 7 Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ: nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí: èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsin yìí.”
8 Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu-ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó ní ẹnu-ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú ọba.
Nítorí pé, Israẹli ti sá, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀.
Àwọn àgbà mú Dafidi ọba padà
9 Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, pé, “ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Absalomu. 10 Absalomu, tí àwa fi jẹ ọba lórí wa sì kú ní ogun: ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yin fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?”
11 Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀. 12 Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran-ara mi: èéṣì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’ 13 Kí ẹ̀yin sì wí fún Amasa pé, ‘Egungun àti ẹran-ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Joabu.’ ”
14 Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Juda lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.” 15 Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jordani.
Juda sì wá sí Gilgali láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jordani.
Ọba dáríjì Ṣimei
16 Ṣimei ọmọ Gera, ará Benjamini ti Bahurimu, ó yára ó sì bá àwọn ọkùnrin Juda sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Dafidi ọba. 17 Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Benjamini, Ṣiba ìránṣẹ́ ilé Saulu, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jordani ṣáájú ọba. 18 Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀.
Ṣimei ọmọ Gera wólẹ̀. Ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ọba, bí ó tí gòkè odò Jordani. 19 Ó sì wí fún ọba pé, “Kí olúwa mi ó má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mi lọ́rùn, má sì ṣe rántí àfojúdi tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ni ọjọ́ tí olúwa mi ọba jáde ní Jerusalẹmu, kí ọba má sì fi sí inú. 20 Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wò ó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Josẹfu tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé olúwa mi ọba.”
21 Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah dáhùn ó sì wí pé, “Kò ha tọ́ kí a pa Ṣimei nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni ààmì òróró Olúwa.”
22 Dafidi sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah tí ẹ dàbí ọ̀tá fún mi lónìí? A ha lè pa ènìyàn kan lónìí ní Israẹli? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Israẹli.” 23 Ọba sì wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ kì yóò kú!” Ọba sì búra fún un.
Mefiboṣeti ṣe àlàyé fún Dafidi
24 Mefiboṣeti ọmọ Saulu sì sọ̀kalẹ̀ láti wá pàdé ọba, kò wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, kò sí tọ́ irùngbọ̀n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti jáde títí ó fi di ọjọ́ tí ó fi padà ní àlàáfíà. 25 Nígbà tí òun sì wá sí Jerusalẹmu láti pàdé ọba, ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ kò fi bá mi lọ, Mefiboṣeti?”
26 Òun sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ.’ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ. 27 Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run ni olúwa mi ọba rí: nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ. 28 Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sá à rí níwájú olúwa mi ọba: ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrín àwọn tí ó ń jẹun ní ibi oúnjẹ. Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀.”
29 Ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sá à ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣiba pín ilẹ̀ náà.”
30 Mefiboṣeti sì wí fún ọba pé, “Jẹ́ kí ó mú gbogbo rẹ̀, kí olúwa mi ọba sá à ti padà bọ̀ wá ilé rẹ̀ ni àlàáfíà.”
Dafidi súre fún Barsillai
31 Barsillai ará Gileadi sì sọ̀kalẹ̀ láti Rogelimu wá, ó sì bá ọba gòkè odò Jordani, láti ṣe ìkẹ́ rẹ̀ sí ìkọjá odò Jordani. 32 Barsillai sì jẹ́ arúgbó ọkùnrin gidigidi, ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sì ni: ó sì pèsè ohun jíjẹ fún ọba nígbà tí ó ti wà ní Mahanaimu; nítorí pé ọkùnrin ọlọ́lá ni òun ń ṣe. 33 Ọba sì wí fún Barsillai pé, “Ìwọ wá bá mi gòkè odò, èmi ó sì máa pèsè fún ọ ní Jerusalẹmu.”
34 Barsillai sì wí fún ọba pé, “Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jerusalẹmu 35 Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sá à ni èmi lónìí: ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ le mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọrin bí, ǹjẹ́ nítorí kín ni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún olúwa mi ọba. 36 Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jordani; èéṣì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi. 37 Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhamu ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá olúwa mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.”
38 Ọba sì dáhùn wí pé, “Kimhamu yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣe é fún ọ.”
39 Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jordani ọba sì gòkè; ọba sì fi ẹnu ko Barsillai lẹ́nu, ó sì súre fún un; òun sì padà sí ilé rẹ̀.
40 Ọba sì ń lọ́ sí Gilgali, Kimhamu sì ń bà a lọ, gbogbo àwọn ènìyàn Juda sì ń ṣe ìkẹ́ ọba, àti ààbọ̀ àwọn ènìyàn Israẹli.
Israẹli ń jowú
41 Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Juda fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jordani, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dafidi pẹ̀lú rẹ?”
42 Gbogbo ọkùnrin Juda sì dá àwọn ọkùnrin Israẹli lóhùn pé, “Nítorí pé ọba bá wa tan ni; èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí? Àwa jẹ nínú oúnjẹ ọba rárá bí? Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí?”
43 Àwọn ọkùnrin Israẹli náà sì dá àwọn ọkùnrin Juda lóhùn pé, “Àwa ní ipá mẹ́wàá nínú ọba, àwa sì ní nínú Dafidi jù yín lọ, èéṣì ṣe tí ẹ̀yin kò fi kà wá sí, tí ìmọ̀ wa kò fi ṣáájú láti mú ọba wa padà?”
Ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Juda sì le ju ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Israẹli.
Ṣeba ṣọ̀tẹ̀ sí Dafidi
20 Ọkùnrin Beliali kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri ará Benjamini; ó sì fún ìpè ó sì wí pé,
“Àwa kò ní ipa nínú Dafidi,
bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jese!
Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Israẹli!”
2 Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì lọ kúrò lẹ́yìn Dafidi, wọ́n sì ń tọ́ Ṣeba ọmọ Bikri lẹ́yìn: ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Juda sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jordani wá títí ó fi dé Jerusalẹmu.
3 Dafidi sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì sé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó.
Joabu fi idà gún Amasa, ó sì kú
4 Ọba sì wí fún Amasa pé, “Pe àwọn ọkùnrin Juda fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.” 5 Amasa sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Juda; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un.
6 Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Nísinsin yìí Ṣeba ọmọ Bikri yóò ṣe wá ní ibi ju ti Absalomu lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má ba à rí ìlú olódi wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.” 7 Àwọn ọmọkùnrin Joabu sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kereti, àti àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára: wọ́n sì ti Jerusalẹmu jáde lọ, láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
8 Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní Gibeoni, Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.
9 Joabu sì bi Amasa léèrè pé, “Àlàáfíà ha kọ́ ni bí, ìwọ arákùnrin mi?” Joabu sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Amasa ní irùngbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 10 Ṣùgbọ́n Amasa kò sì kíyèsi idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Joabu: bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́: Amasa sì kú. Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
Joabu lépa Seba
11 Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Joabu sì dúró tì Amasa, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Joabu? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dafidi, kí ó máa tọ Joabu lẹ́yìn.” 12 Amasa sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrín ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì rí i pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú igbó, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnikẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró. 13 Nígbà tí ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Joabu lẹ́yìn láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
Wọ́n gé Ṣeba lórí
14 Ṣeba kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli sí Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo àwọn ará Beri; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú. 15 Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì Ṣeba ní Abeli-Beti-Maaka, wọ́n sì mọ odi ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Joabu sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀. 16 Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹ sọ fún Joabu pé: Súnmọ́ ìhín yìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.” 17 Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Joabu bí?”
Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.”
Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”
Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.”
18 Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Gba ìdáhùn rẹ ní Abeli’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà. 19 Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti olóòtítọ́ ní Israẹli: ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli: èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.”
20 Joabu sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun. 21 Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Efraimu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikri, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba, àní sí Dafidi: fi òun nìkan ṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.”
Obìnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odi wá.”
22 Obìnrin náà sì mú ìmọ́ràn rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣeba ọmọ Bikri lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Joabu. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká ní ìlú náà, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. Joabu sí padà lọ sí Jerusalẹmu àti sọ́dọ̀ ọba.
Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi
23 (B)Joabu sì ni olórí gbogbo ogun Israẹli;
Benaiah ọmọ Jehoiada sì jẹ́ olórí àwọn Kereti, àti ti àwọn Peleti.
24 Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde;
Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.
25 Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé;
Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.
26 Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi.
Àwọn ará Gibeoni gba ẹ̀san
21 Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dafidi ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí pé, Nítorí ti Saulu ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.
2 Ọba sì pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Israẹli, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Amori; àwọn ọmọ Israẹli sì ti búra fún wọn: Saulu sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli àti Juda. 3 Dafidi sì bi àwọn ará Gibeoni léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kín ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa?”
4 Àwọn ará Gibeoni sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrín wa àti Saulu tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Israẹli.”
Dafidi sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?”
5 Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbègbè Israẹli. 6 Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gibeah ti Saulu ẹni tí Olúwa ti yàn.”
Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.”
Síso Àwọn Ènìyàn Saulu Méje Rọ̀
7 Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu. 8 Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola. 9 Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gibeah lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà barle.
10 Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru. 11 A sì ro èyí, tí Rispa ọmọbìnrin Aiah obìnrin Saulu ṣe, fún Dafidi. 12 Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa. 13 Ó sì mú egungun Saulu àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ.
14 Wọ́n sì sin egungun Saulu àti ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ní ilé Benjamini, ní Ṣela, nínú ibojì Kiṣi baba rẹ̀: wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ: lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà.
Ìṣẹ́gun lórí Filistini
15 Ogun sì tún wà láàrín àwọn Filistini àti Israẹli; Dafidi sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Filistini jà: ó sì rẹ Dafidi. 16 Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi. 17 Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á, Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.”
18 (C)Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini ní Gobu: nígbà náà ni Sibekai ará Huṣati pa Safu, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn Rafa.
19 Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ.
20 Ìjà kan sì tún wà ní Gati, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní Rafa. 21 Nígbà tí òun sì pe Israẹli ní ìjà. Jonatani ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì pa á.
22 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni ìran Rafa ní Gati, wọ́n sì ti ọwọ́ Dafidi ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
Orin ìyìn Dafidi
22 Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. 2 (D)Ó sì wí pé:
“Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;
3 Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,
àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi.
Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;
ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.
4 “Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,
ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
5 Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;
tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
6 Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri;
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
7 “Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa,
èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi.
Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀
igbe mí wọ etí rẹ̀.
8 Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì;
ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì,
ó sì mì, nítorí tí ó bínú.
9 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
10 Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;
òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.
11 Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò:
a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
12 Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi,
àní ìṣúdudu ìkùùkuu àwọ̀ sánmọ̀.
13 Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀
ẹ̀yín iná ràn.
14 Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá,
Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.
15 Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;
ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.
16 Ìṣàn ibú Òkun sì fi ara hàn,
ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,
nípa ìbáwí Olúwa,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.
17 “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;
ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.