Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Onidajọ 15:13 - 1 Samuẹli 2:29

13 “Àwa gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, àwa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn tuntun méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà. 14 Bí ó ti súnmọ́ Lehi, àwọn Filistini ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. 15 Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tuntun kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.

16 Samsoni sì wí pé,

“Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan
    Mo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan
    Mo ti pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.”

17 Nígbà tí ó dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó ju egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ náà nù, wọ́n sì pe ibẹ̀ ní Ramati-Lehi (ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ pa).

18 Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe Olúwa, wí pé, “Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí. Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn?” 19 Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìsun omi tí ó wà ní Lehi, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀. Nígbà tí Samsoni mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìsun omi náà ni. Ẹni Hakkore (orísun ẹni tí ó pe Ọlọ́run) èyí tí ó sì wà ní Lehi di òní.

20 Samsoni ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ogún ọdún ní àkókò àwọn ará Filistini.

Samsoni àti Dẹlila

16 Ní ọjọ́ kan Samsoni lọ sí Gasa níbi tí ó ti rí obìnrin panṣágà kan. Ó wọlé tọ̀ ọ́ láti sun ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Àwọn ará Gasa sì gbọ́ wí pé, “Samsoni wà níbí.” Wọ́n sì yí agbègbè náà ká, wọ́n ń ṣọ́ ọ ní gbogbo òru náà ní ẹnu-bodè ìlú náà. Wọn kò mira ní gbogbo òru náà pé ní “àfẹ̀mọ́júmọ́ àwa yóò pa á.”

Ṣùgbọ́n Samsoni sùn níbẹ̀ di àárín ọ̀gànjọ́. Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábùú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hebroni.

Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó sì ní ìfẹ́ obìnrin kan ní Àfonífojì Soreki, orúkọ ẹni tí í ṣe Dẹlila. Àwọn ìjòyè Filistini sì lọ bá obìnrin náà, wọ́n sọ fún un wí pé, “Bí ìwọ bá le tàn án kí òun sì fi àṣírí agbára rẹ̀ hàn ọ́, àti bí àwa ó ti lè borí rẹ̀, kí àwa sì dè é kí àwa sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wa yóò sì fún ọ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà fàdákà.”

Torí náà Dẹlila sọ fún Samsoni pé, “Sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi àti bí wọ́n ti le dè ọ́, àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ.”

Samsoni dá a lóhùn wí pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fi okùn tútù méje tí ẹnìkan kò sá gbẹ dè mí, èmi yóò di aláìlágbára bí i gbogbo àwọn ọkùnrin yòókù.”

Àwọn olóyè Filistini sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹlila òun sì fi wọ́n dè é. Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sápamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, “Samsoni àwọn Filistini ti dé láti mú ọ.” Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná. Torí náà wọn kò mọ àṣírí agbára rẹ̀.

10 Dẹlila sì sọ fún Samsoni pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́.

11 Òun dáhùn pé, “Bí wọ́n bá lè fi okùn tuntun tí ẹnikẹ́ni kò tí ì lò rí dì mí dáradára, èmi yóò di aláìlágbára, èmi yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yòókù.”

12 Dẹlila sì mú àwọn okùn tuntun, ó fi wọ́n dì í. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Filistini ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ,” òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú.

13 Dẹlila sì tún sọ fún Samsoni pé, “Títí di ìsinsin yìí ìwọ sì ń tún tàn mí, o sì tún purọ́ fún mi. Sọ fún mi ọ̀nà tí wọ́n fi le dè ọ́.”

Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ bá hun ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí mi pẹ̀lú okùn, tí ó sì le dáradára kí o sì fi ẹ̀mú mú un mọ́lẹ̀, èmi yóò di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.” Nígbà tí òun ti sùn, Dẹlila hun àwọn ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí rẹ̀, 14 ó sì fi ìhunṣọ dè wọ́n.

Ó sì tún pè é pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.” Òun sì jí ní ojú oorun, ó sì fa ìdè ìhunṣọ náà tu pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀.

15 Dẹlila sì sọ fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wí pé, ‘Èmi fẹ́ràn rẹ,’ nígbà tí ìwọ kò fi ọkàn tán mi. Èyí ni ìgbà kẹta tí ìwọ ti tàn mí jẹ, tí ìwọ kò sì sọ àṣírí ibi tí agbára ńlá rẹ gbé wà fún mi.” 16 Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó sú dé òpin ẹ̀mí rẹ̀.

17 Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.”

18 Nígbà tí Dẹlila rí i pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹlila ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Filistini pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Filistini padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́. 19 Òun sì mú kí Samsoni sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀. Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.

20 Òun pè é wí pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.”

Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìnwá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀.

21 Nígbà náà ni àwọn Filistini mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú un lọ sí Gasa. Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú. 22 Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.

Ikú Samsoni

23 Àwọn ìjòyè, àwọn ará Filistini sì péjọpọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dagoni ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Samsoni ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́.

24 Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Samsoni wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé,

“Ọlọ́run wa ti fi ọ̀tá wa
    lé wa lọ́wọ́.
Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ wa
    ẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.”

25 Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Samsoni wá kí ó wá dá wa lára yá. Wọ́n sì pe Samsoni jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn.

Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàrín àwọn òpó. 26 Samsoni sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, “Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹmpili dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n.” 27 Ní àsìkò náà, tẹmpili yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Filistini wà níbẹ̀, ní òkè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Samsoni bí òun ti ń ṣeré. 28 Nígbà náà ni Samsoni ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.” 29 Samsoni sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàrín gbùngbùn, orí àwọn tí tẹmpili náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n, 30 Samsoni sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Filistini!” Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ.

31 Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ ní àpapọ̀ gòkè lọ wọ́n sì gbé e, wọ́n gbé e padà wá, wọ́n sì sin ín sí agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli, sínú ibojì Manoa baba rẹ̀. Òun ti ṣe àkóso Israẹli ní ogún (20) ọdún.

Ìbọ̀rìṣà Mika

17 Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika láti agbègbè òkè Efraimu sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣẹ́ èpè. Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.”

Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí Olúwa bùkún ọ ọmọ mi!”

Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí Olúwa fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.”

Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba (200) ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Mika.

Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́.

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda wá, tí í ṣe ìdílé Juda, ẹni tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, òun sì ṣe àtìpó níbẹ̀, Ọkùnrin náà sì ti ìlú Bẹtilẹhẹmu ti Juda lọ, láti ṣe àtìpó ní ibikíbi tí ó bá rí. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Mika nínú àwọn ilẹ̀ òkè Efraimu.

Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?”

Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.”

10 Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.” 11 Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 12 Nígbà náà ni Mika ya ará Lefi náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀. 13 Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.”

Àwọn ìran Dani tẹ̀dó sí Laiṣi

18 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba.

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tiwọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàrín àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Dani rán àwọn jagunjagun márùn-ún lọ láti Sora àti Eṣtaoli láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínní fínní.”

Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika, níbi tí wọ́n sùn ní òru náà. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e Mika, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, “Tá ni ó mú ọ wa sí ibi? Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín-yìí? Èéṣe tí o fi wà ní ibí?”

Ó sọ ohun tí Mika ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, “Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀.”

Wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere.”

Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Ọlọ́run pàdé.”

Àwọn ọkùnrin márààrún náà kúrò, wọ́n sì wá sí Laiṣi, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Sidoni, láìsí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Sidoni, wọn kò fi ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀.

Nígbà tí wọ́n padà sí Sora àti Eṣtaoli, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ síbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà. 10 Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ yóò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.”

11 Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dani, jáde lọ láti Sora àti Eṣtaoli ní mímú ra láti jagun. 12 Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí. 13 Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika.

14 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Laiṣi wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní ẹ̀wù efodu, àwọn yòókù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.” 15 Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà, sí ilé Mika, wọ́n sì béèrè àlàáfíà rẹ̀. 16 Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará Dani náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi. 17 Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà.

18 Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Mika lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?”

19 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?” 20 Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ. 21 Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.

22 Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Mika, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbègbè Mika kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá. 23 Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dani yípadà wọ́n sì bi Mika pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”

24 Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ”

25 Àwọn ọkùnrin Dani náà dáhùn pé, “Má ṣe bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbìínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.” 26 Àwọn ọkùnrin Dani náà sì bá ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí Mika rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀.

27 Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Mika ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Laiṣi, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run. 28 Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Sidoni, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bàá a Beti-Rehobu.

Àwọn ará Dani sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀. 29 Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dani, ẹni tí wọ́n bí fún Israẹli: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Laiṣi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí. 30 Àwọn ọmọ Dani sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jonatani ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn. 31 Wọ́n tẹ̀síwájú láti lo àwọn ère tí Mika ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣilo.

Ọmọ Lefi kan àti àlè rẹ̀

19 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Israẹli kò ní ọba.

Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Lefi tí ń gbé ibi tí ó sápamọ́ nínú àwọn agbègbè òkè Efraimu, mú àlè kan láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda. Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà sì ṣe panṣágà sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda, ó sì wà ní ibẹ̀ ní ìwọ̀n oṣù mẹ́rin, ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á. Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀.

Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.” Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn-ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun.

Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, “Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ. Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ. Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọ ilé.” 10 Ṣùgbọ́n nítorí pé òun kò fẹ́ dúró mọ́ níbẹ̀ ní òru náà ọkùnrin náà kúrò ó sì gba ọ̀nà Jebusi: ọ̀nà Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó fi dì í ní gàárì àti àlè rẹ̀.

11 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi tí ilẹ̀ ti fẹ́ ṣú tan, ìránṣẹ́ náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a dúró ní ìlú yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jebusi kí a sì sùn níbẹ̀.”

12 Ọ̀gá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Rárá o, àwa kì yóò wọ ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí olùgbé ibẹ̀ kì í ṣe ọmọ Israẹli, a yóò dé Gibeah.” 13 Ó fi kún un pé, ẹ wá ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú kí a dé Gibeah tàbí Rama kí a sùn ní ọ̀kan nínú wọn. 14 Wọ́n sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn, oòrùn wọ̀ bí wọ́n ti súnmọ́ Gibeah tí ṣe ti àwọn Benjamini. 15 Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú Gibeah láti wọ̀ síbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí.

16 Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Efraimu, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gibeah (ibẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Benjamini ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko. 17 Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìn-àjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, “Níbo ni ò ń lọ? Níbo ni o ti ń bọ̀?”

18 Ọmọ Lefi náà dá a lóhùn pé, “Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbègbè tí ó sápamọ́ ní àwọn òkè Efraimu níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹtilẹhẹmu ti Juda, èmi sì ń lọ sí ilé Olúwa nísinsin yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀. 19 Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ—èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.”

20 Ọkùnrin arúgbó náà sì wí pé. “Àlàáfíà fún ọ, bí ó ti wù kí ó rí, èmi yóò pèsè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ní ìgboro.” 21 Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹsẹ̀ wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu.

22 Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Beliali kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kùn; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.”

23 Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. 24 Kíyèsi i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúńdíá, àti àlè rẹ̀; àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí sí.”

25 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀. Nítorí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́. 26 Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀.

27 Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsi i àlè rẹ̀ wà ní ṣíṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu-ọ̀nà ibẹ̀ mú, 28 òun sì wí fún obìnrin náà pé, “Dìde jẹ́ kí a máa bá ọ̀nà wa lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni ọkùnrin náà gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì kọjá lọ sí ilé e rẹ̀.

29 Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ ó sì gé àlè rẹ̀ ní oríkeríke sí ọ̀nà méjìlá, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo agbègbè Israẹli. 30 Gbogbo ẹni tí ó rí i sì wí pé, “A kò ti rí i, bẹ́ẹ̀ a kò tí ì ṣe irú nǹkan yìí rí, kì í ṣe láti ọjọ́ tí Israẹli ti jáde tí Ejibiti wá títí di òní olónìí. Ẹ rò ó wò, ẹ gbìmọ̀ràn, kí ẹ sọ fún wa ohun tí a yóò ṣe!”

Àwọn ọmọ Israẹli bá ará Benjamini jà

20 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti Dani dé Beerṣeba, àti láti ilẹ̀ Gileadi jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ síwájú Olúwa ni Mispa. Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. (Àwọn ẹ̀yà Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Israẹli yòókù ti gòkè lọ sí Mispa.) Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.”

Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gibeah lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú. Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli. Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”

Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí Gibeah ní yìí: Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa. 10 A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.” 11 Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.

12 Àwọn ẹ̀yà Israẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Benjamini wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín? 13 Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gibeah yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Israẹli.”

Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Benjamini kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Israẹli. 14 Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gibeah láti bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 15 Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá-mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah. 16 Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé).

17 Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.

18 Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli (ilé Ọlọ́run) wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?”

Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.”

19 Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah). 20 Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah. 21 Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbàá-mọ́kànlá ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà. 22 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́. 23 Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?”

Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”

24 Àwọn ọmọ Israẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Benjamini ní ọjọ́ kejì. 25 Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Benjamini jáde sí wọn láti Gibeah, láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbẹ̀sán (18,000) ọkùnrin Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.

26 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Beteli, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà (ọrẹ ìrẹ́pọ̀) sí Olúwa. 27 Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀, 28 Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) Wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?”

Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”

29 Àwọn ọmọ Israẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sápamọ́ yí Gibeah ká. 30 Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Benjamini lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gibeah bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí. 31 Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Israẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Beteli àti èkejì sí Gibeah. 32 Nígbà tí àwọn Benjamini ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.”

33 Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Baali-Tamari, àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí wọ́n sápamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀-oòrùn Gibeah. 34 Nígbà náà ni ẹgbàá-márùn ún (10,000) àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Israẹli gbógun ti Gibeah láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Benjamini kò funra pé ìparun wà nítòsí. 35 Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá-méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,000) ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun. 36 Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn.

Àwọn ọkùnrin Israẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Benjamini nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gibeah. 37 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gibeah, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà. 38 Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní ààmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà, 39 nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli yípadà, wọ́n sá gun.

Àwọn ọmọ Benjamini sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.” 40 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Benjamini yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run. 41 Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Benjamini nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu. 42 Wọ́n sì sá níwájú àwọn ọmọ Israẹli sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀. 43 Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Benjamini ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbègbè ìlà-oòrùn Gibeah. 44 Ẹgbàá-mẹ́sàn án (18,000) àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun. 45 Bí wọ́n ṣe ṣíjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbàá (2,000) ọkùnrin ṣubú.

46 Ní ọjọ́ náà ẹgbàá-méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun. 47 Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rimoni, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin. 48 Àwọn ọkùnrin Israẹli sì padà sí àwọn ìlú Benjamini wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.

Àwọn aya fún àwọn ẹ̀yà Benjamini

21 Àwọn ọkùnrin Israẹli ti búra ní Mispa pé: “Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Benjamini ní ìyàwó.”

Àwọn ènìyàn náà lọ sí Beteli: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún kíkorò. Wọ́n sọkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Israẹli? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Israẹli lónìí?”

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà.

Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti péjọ síwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mispa pípa ni àwọn yóò pa á.

Àwọn ọmọ Israẹli sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Benjamini. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Israẹli lónìí.” Báwo ni a yóò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya. Wọ́n sì béèrè wí pé, “Èwo ni nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mispa?” Wọ́n rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wa láti Jabesi Gileadi tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà. Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkankan láti inú àwọn ará Jabesi Gileadi tí ó wà níbẹ̀.

10 Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá-mẹ́fà àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gileadi wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. 11 Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúńdíá.” 12 Wọ́n rí àwọn irínwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani.

13 Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Benjamini ní ihò àpáta Rimoni. 14 Àwọn ẹ̀yà Benjamini náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gileadi. Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn.

15 Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 16 Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Benjamini run?” 17 Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Benjamini ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Israẹli má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀. 18 Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Israẹli ti ṣe ìbúra yìí pé: ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Benjamini.’ ” 19 Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsi i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣilo ní ìhà àríwá Beteli àti ìhà ìlà-oòrùn òpópó náà tí ó gba Beteli kọjá sí Ṣekemu, àti sí ìhà gúúsù Lébónà.”

20 Wọ́n sì fi àṣẹ fún àwọn ará Benjamini pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fi ara pamọ́ nínú àwọn ọgbà àjàrà 21 kí ẹ sì wà ní ìmúrasílẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin Ṣilo bá jáde láti lọ darapọ̀ fún ijó, kí ẹ yára jáde láti inú àwọn ọgbà àjàrà wọ̀n-ọn-nì kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbé aya kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ṣilo kí ẹ padà sí ilẹ̀ Benjamini. 22 Nígbà tí àwọn baba wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá fi ẹjọ́ sùn wá, àwa yóò wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe wá ní oore nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí àwa kò rí aya fún wọn ní àkókò ogun, ẹ̀yin kò sì ní jẹ̀bi, nítorí pé ẹ̀yin kọ́ ni ó fi àwọn ọmọbìnrin yín fún wọn bí aya.’ ”

23 Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn.

24 Ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

25 Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli; olúkúlùkù sì ń ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.

Naomi àti Rutu

Ní ìgbà tí àwọn onídàájọ́ ń ṣe àkóso ilẹ̀ Israẹli, ìyàn kan mú ní ilẹ̀ náà, ọkùnrin kan láti Bẹtilẹhẹmu ti Juda, òun àti aya rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì lọ láti máa gbé ní ilẹ̀ Moabu fún ìgbà díẹ̀. Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Elimeleki, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Naomi, orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ni Maloni àti Kilioni àwọn ará Efrata, ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda. Wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń gbé níbẹ̀.

Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimeleki, ọkọ Naomi kú, ó sì ku òun pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì. Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Moabu méjì, orúkọ ọ̀kan ń jẹ́ Oripa, èkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá, Maloni àti Kilioni náà sì kú, Naomi sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún un mọ́.

Nígbà tí Naomi gbọ́ ní Moabu tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fífún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀. Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà sí ilẹ̀ Juda.

Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Naomi wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú. Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.”

Naomi sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” Wọ́n sì sọkún kíkankíkan. 10 Wọ́n sì wí fún un pé, “Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”

11 Ṣùgbọ́n Naomi dáhùn wí pé, “Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi. Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi? Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le ṣe ọkọ yin? 12 Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí èmi ti di arúgbó jù láti ní ọkọ mìíràn. Bí èmí wí pé, Èmí ní ìrètí, bí èmí tilẹ̀ ní ọkọ mìíràn ní alẹ́ yìí, tí èmí sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn, 13 ẹ̀yin ha le è dúró dìgbà tí wọ́n yóò fi dàgbà? Ẹ̀yin ó le è dúró dè wọ́n láì fẹ́ ọkọ mìíràn? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, nítorí pé inú mi bàjẹ́ gidigidi ju tiyín lọ, nítorí tí ọwọ́ Olúwa fi jáde sí mi!”

14 Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì tún sọkún. Nígbà náà ní Oripa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rutu dì mọ́ ọn síbẹ̀.

15 Naomi wí pé, “Wò ó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀.”

16 Ṣùgbọ́n Rutu dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí ìwọ bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ìwọ bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run, mi, 17 Níbi tí ìwọ bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.” 18 Nígbà tí Naomi rí i wí pé Rutu ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́.

19 Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Naomi ni èyí bí?”

20 Naomi sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Naomi. Ẹ pè mí ní Mara (Ìkorò), nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò. 21 Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kín ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”

22 Báyìí ni Naomi ṣe padà láti Moabu pẹ̀lú Rutu, ará Moabu ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹtilẹhẹmu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà barle.

Rutu pàdé Boasi

Naomi ní ìbátan kan láti ìdílé Elimeleki ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi.

Rutu ará Moabu sì wí fún Naomi pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojúrere rẹ̀ pàdé.”

Naomi sì sọ fún un pé, “Máa lọ, ọmọbìnrin mi.” Rutu sì jáde lọ láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Boasi tí ó ti ìdílé Elimeleki wá ni ó lọ láìmọ̀-ọ́n-mọ̀.

Nígbà náà ni Boasi dé láti Bẹtilẹhẹmu tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín.”

Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ.”

Boasi sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?”

Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Moabu tí ó tẹ̀lé Naomi wá láti ilẹ̀ Moabu ni. Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣá ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsin yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.”

Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi. Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkúgbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”

10 Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?”

11 Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí. 12 Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.”

13 Rutu sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ síwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”

14 Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Boasi sọ fún Rutu pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yìí kí o sì fi run wáìnì kíkan.”

Òun sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Boasi sì fún un ní ọkà yíyan. Òun sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù. 15 Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣá ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàrín oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́. 16 Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣá, kí ẹ má sì ṣe ba a wí.”

17 Rutu sì ń ṣá ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà barle tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan (lítà méjìlélógún). 18 Ó sì gbé e, ó sì lọ sí ìlú, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí ṣà bi o tí pọ̀ tó, Rutu sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀.

19 Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣá ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.”

Rutu sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi ni mo ti ṣiṣẹ́ lónìí.”

20 Naomi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.”

21 Rutu, ará Moabu sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣá ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ”

22 Naomi sì sọ fún Rutu, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”

23 Rutu sì bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin Boasi ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà barle àti ti jéró. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.

Rutu àti Boasi ní ilẹ̀ ìpakà

Ní ọjọ́ kan, Naomi, ìyá ọkọ Rutu wí fún un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ? Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí. Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán. Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”

Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe.

Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?”

Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”

10 Boasi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà. 11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́n ní obìnrin oníwà rere. 12 Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ. 13 Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”

14 Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.”

15 Ó sì tún wí fún un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rutu sì ṣe bẹ́ẹ̀, Boasi sì wọn òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìlú.

16 Nígbà tí Rutu dé ilé Naomi ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí ọmọbìnrin mi?”

Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un fún ìyá ọkọ rẹ̀. 17 Ó fi kún un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà, ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà barle mẹ́fà.’ ”

18 Naomi sì wí fún un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí, nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”

Boasi gbé Rutu ní ìyàwó

Nígbà náà ni Boasi gòkè lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó sì jókòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó súnmọ́ Elimeleki jùlọ, arákùnrin tí Boasi ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Boasi pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jókòó.” Ó sì lọ jókòó.

Boasi sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbàgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, “Arábìnrin Naomi tí ó dé láti ilẹ̀ Moabu fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin Elimeleki wa. Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jókòó sí ibi yìí. Bí ìwọ yóò bá rà á padà rà á. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀. Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀.”

Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, “Èmi yóò rà á padà.”

Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.”

Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le è rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ̀, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.”

(A)Ní ayé ìgbàanì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàṣípàrọ̀ ohun ìní fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnìkejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Israẹli fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.

Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Boasi wí pé, “Ìwọ rà á fúnrarẹ̀,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

Nígbà náà ni Boasi wí fún àwọn àgbàgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Maloni àti Kilioni lọ́wọ́ Naomi. 10 Ní àfikún, mo ra Rutu ará Moabu opó Maloni padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrín àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”

11 Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rakeli àti Lea láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Israẹli ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Efrata àti olókìkí ní ìlú Bẹtilẹhẹmu. 12 Olúwa fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Peresi ọmọkùnrin tí Tamari bí fún Juda láti ipasẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí.”

Èyí ni ìran Dafidi

13 Báyìí ni Boasi ṣe mú Rutu, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyún, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan. 14 Àwọn obìnrin sì wí fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà. Kí ọmọ náà di olókìkí ní Israẹli. 15 Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.”

16 Naomi sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. 17 Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Naomi.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Obedi. Òun sì ni baba Jese tí í ṣe baba Dafidi.

18 Èyí ni ìran Peresi:

Peresi ni baba Hesroni,

19 Hesroni ni baba Ramu,

Ramu ni baba Amminadabu

20 Amminadabu ni baba Nahiṣoni,

Nahiṣoni ni baba Salmoni,

21 Salmoni ni baba Boasi,

Boasi ni baba Obedi,

22 Obedi ní baba Jese,

Jese ni baba Dafidi.

Ìbí Samuẹli

Ọkùnrin kan wà, láti Ramataimu-Sofimu, láti ìlú olókè Efraimu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ará Efrata. Ó sì ní ìyàwó méjì: orúkọ wọn ni Hana àti Penina: Penina ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò ní.

Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa. Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú. Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú. Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hana bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín níràn títí tí yóò fi máa sọkún tí kò sì ní lè jẹun. Elkana ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hana èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?”

Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣilo, Hana dìde wá síwájú Olúwa. Nígbà náà, Eli àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó. 10 Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hana sọkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 11 Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”

12 Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa, Eli sì kíyèsi ẹnu rẹ̀. 13 Hana ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Eli rò wí pé ó ti mu ọtí yó. 14 Eli sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.”

15 Hana dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” “Èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; Èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni. 16 Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”

17 Eli dáhùn pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Israẹli fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”

18 Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà bá tirẹ̀ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.

19 Wọ́n sì dìde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rama: Elkana si mọ Hana aya rẹ̀: Olúwa sì rántí rẹ̀. 20 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hana lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Samuẹli, pé, “Nítorí tí mo béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”

A ya Samuẹli sí mímọ́ fún Olúwa

21 Ọkùnrin náà Elkana, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rú ẹbọ ọdún sí Olúwa, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀. 22 Ṣùgbọ́n Hana kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.”

23 Elkana ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa sá à mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.

24 Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun efa kan, àti ìgò ọtí wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣilo: ọmọ náà sì wà ní ọmọdé. 25 Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Eli wá. 26 Hana sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láààyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa. 27 Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi. 28 Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fi í fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa níbẹ̀.

Àdúrà Hana

Hana sì gbàdúrà pé:

“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;
    Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.
Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi,
    nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.

“Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;
    kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;
    kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

“Má ṣe halẹ̀;
    má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde
nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,
    láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.

“Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́,
    àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.
Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,
    àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní.
Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje.
    Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.

Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;
    ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.
Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;
    ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.
Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,
    ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá,
láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,
    láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo:

“Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni,
    ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,
    àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.

“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.
10     A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;
láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;
    Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.

“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,
    yóò si gbé ìwo ẹni ààmì òróró rẹ̀ sókè.”

11 Elkana sì lọ sí Rama sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà.

Àwọn ọmọ Eli búburú

12 Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa. 13 Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀. 14 Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo. 15 Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfáà; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe tútù.”

16 Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́,” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”

17 Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí àwọn ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.

18 Ṣùgbọ́n Samuẹli ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní efodu ọ̀gbọ̀. 19 Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mú wá fún un lọ́dọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún. 20 Eli súre fún Elkana àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn. 21 Olúwa si bojú wo Hana, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Samuẹli ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.

22 Eli sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Israẹli; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 23 Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. 24 Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹ̀yin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀. 25 Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa, ta ni yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n.

26 Ọmọ náà Samuẹli ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa, àti ènìyàn pẹ̀lú.

Wòlíì sọtẹ́lẹ̀ nípa ilé Eli

27 Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao. 28 Èmi sì yàn án kúrò láàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rú ẹbọ lórí pẹpẹ mi, láti fi tùràrí jóná, láti wọ efodu níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Israẹli máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀. 29 Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo pàṣẹ ní ibùjókòó mi: ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jù mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Israẹli àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.