Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 21:8-32:19

Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

Ìrìnàjò sí Moabu

10 Àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú wọ́n sì péjọ sí Obotu. 11 Wọ́n gbéra ní Obotu wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-Abarimu, ní aginjù tí ó kọjú sí Moabu ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn. 12 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní Àfonífojì Seredi. 13 Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori. 14 Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé:

“…Wahebu ní Sufa, Òkun pupa àti
ní odò Arnoni 15     àti ní ìṣàn odò
tí ó darí sí ibùjókòó Ari
    tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.”

16 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”

17 Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé:

“Sun jáde, ìwọ kànga!
    Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,
18 nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́,
    nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ;
    tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.”

Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana, 19 láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti, 20 àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.

Ìṣẹ́gun Sihoni àti Ogu

21 (A)Israẹli rán oníṣẹ́ láti sọ fún Sihoni ọba àwọn ará Amori wí pé:

22 “Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

23 Ṣùgbọ́n Sihoni kò ní jẹ́ kí àwọn Israẹli kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí aginjù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó dé Jahasi, ó bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 24 Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi. 25 Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká. 26 Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.

27 Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé:

“Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;
    jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.

28 “Iná jáde láti Heṣboni,
    ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.
Ó jó Ari àti Moabu run,
    àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.
29 Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!
    Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!
Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá
    àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn
    fún Sihoni ọba àwọn Amori.

30 “Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú;
    A ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni.
A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa,
    tí ó sì fi dé Medeba.”

31 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.

32 Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde. 33 (B)Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìndà wọ́n sì gòkè lọ sí Baṣani, Ogu ọba ti Baṣani àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wọ́de ogun jáde láti pàdé wọn ní ojú ogun ní Edrei.

34 Olúwa sọ fún Mose pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”

35 Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọn kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè. Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀.

Balaki ránṣẹ́ sí Balaamu

22 (C)Nígbà náà àwọn ọmọ Israẹli rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani tí ó kọjá lọ sí Jeriko.

Nísinsin yìí, Balaki ọmọ Sippori rí gbogbo ohun tí àwọn Israẹli ti ṣe sí àwọn ará Amori, ẹ̀rù sì ba Moabu nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Moabu kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Israẹli.

Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.”

Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà, rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé:

“Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi. Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”

Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn.

“Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí” Balaamu sọ fún un pé, “Èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí Olúwa bá wí fún mi.” Nítorí tí àwọn ìjòyè Moabu dúró sọ́dọ̀ rẹ̀.

Ọlọ́run tọ Balaamu wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?”

10 Balaamu sọ fún Ọlọ́run pé, “Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: 11 ‘Àwọn ènìyàn kan ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá tí wọ́n bo ojú ilẹ̀. Nísinsin yìí, wá, kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá Èmi yóò lè bá wọn jà, èmi ó sì lé wọn jáde.’ ”

12 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Balaamu pé, “Má ṣe bá wọn lọ. Ìwọ kò gbọdọ̀ gé ègún lé àwọn ènìyàn náà lórí, nítorí a ti bùkún wọn.”

13 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Balaamu dìde ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Balaki pé, “Ẹ padà sí orílẹ̀-èdè yín, nítorí tí Olúwa ti kọ̀ láti jẹ́ kí n tẹ̀lé yín.”

14 Nígbà náà àwọn ìjòyè Moabu sì padà tọ Balaki lọ wọ́n sì wí pé, “Balaamu kọ̀ láti tẹ̀lé wa.”

15 Nígbà náà Balaki rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ. 16 Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu wọ́n sì sọ pé:

“Èyí ni ohun tí Balaki ọmọ Sippori sọ: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, 17 Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára, èmi yóò sì ṣe ohunkóhun tí ìwọ bá sọ. Wá, kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.”

18 Ṣùgbọ́n Balaamu dá wọn lóhùn pé, “Kódà tí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò ní ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí ó kọjá òfin Olúwa Ọlọ́run mi. 19 Nísinsin yìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí Olúwa yóò tún sọ fún mi.”

20 Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Balaamu wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Balaamu

21 Balaamu dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. 22 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, angẹli Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Balaamu ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 23 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fàyọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Balaamu sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.

24 Nígbà náà angẹli Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrín ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì. 25 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nà án, lẹ́ẹ̀kan sí i.

26 Nígbà náà angẹli Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì. 27 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó sì jókòó ní abẹ́ Balaamu, inú sì bí i tó sì nà án pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀. 28 Nígbà náà Olúwa ṣí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”

29 Balaamu sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ìbá pa ọ́ nísinsin yìí.”

30 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Balaamu pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”

“Rárá,” Ó dáhùn.

31 Nígbà náà Olúwa ṣí ojú Balaamu, ó sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ. Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba.

32 Nígbà náà angẹli Olúwa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi. 33 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí mi ó sì yà kúrò fún mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta yìí. Tí ó bá jẹ́ wí pé kò yà kúrò. Èmi kì ìbá ti pa ọ́ pátápátá nísinsin yìí, ṣùgbọ́n Èmi yóò sì dá òun sí.”

34 Balaamu sọ fún angẹli Olúwa pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, èmi kò mọ̀ pé o dúró níwájú ọ̀nà láti dojúkọ mí, Nísinsin yìí tí inú rẹ kò bá dùn, èmi ó padà.”

35 Angẹli Olúwa sọ fún Balaamu pé, “Lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin náà, ṣùgbọ́n nǹkan tí mo sọ fún ọ nìkan ni kí o sọ.” Nígbà náà Balaamu lọ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Balaki.

36 Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà ní agbègbè Arnoni, ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ̀. 37 Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Ǹjẹ́ èmi kò a ránṣẹ́ kánjúkánjú sí ọ? Kí ló dé tí ìwọ kò fi wá sí ọ̀dọ̀ mi? Ṣé èmi kò tó láti sọ ọ́ di ẹni ńlá?”

38 Balaamu sì wí fún Balaki pé “Kíyèsi, èmi tọ̀ ọ́ wá, èmi kò ha ní agbára kan nísinsin yìí rárá láti wí ohun kan? Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí Ọlọ́run fi sí mi lẹ́nu.”

39 Nígbà náà Balaamu lọ pẹ̀lú Balaki sí Kiriati-Hosotia. 40 Balaki rú ẹbọ akọ màlúù pẹ̀lú àgùntàn, ó sì fún Balaamu ní díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. 41 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Balaki gbé Balaamu lọ sí Bamoti Baali, láti ibẹ̀ ló ti rí apá kan àwọn ènìyàn.

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ Balaamu

23 Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.” Balaki ṣe bí Balaamu ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn mí, èmi yóò wí fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.

Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.”

Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Balaamu ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.”

Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu. Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé:

“Balaki mú mi láti Aramu wá,
    Ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá
Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi;
    wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’
Báwo ní èmi ó ṣe fi bú
    àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?
Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí
    àwọn tí Olúwa kò bá wí?
Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,
    láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.
Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀
    wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu
    tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli?
Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo,
    kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!”

11 Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”

12 Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ èkejì Balaamu

13 Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.” 14 Ó sì lọ sí pápá Ṣofimu ní orí òkè Pisga, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15 Balaamu ṣo fún Balaki pé, “Dúró níbí ti ẹbọ sísun rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ̀.”

16 Olúwa pàdé Balaamu ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jíṣẹ́ fún un.”

17 Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?”

18 Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ:

“Dìde, Balaki;
    kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori.
19 Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́,
    tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà.
Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é?
    Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
20 Èmi gba àṣẹ láti bùkún;
    Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.

21 “Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu,
    kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli.
Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.
    Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.
22 Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá,
    wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.
23 Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu,
    tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli.
Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu
    àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’
24 Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún;
    wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún
òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ
    títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.”

25 Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!”

26 Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí Olúwa bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹ̀kẹta Balaamu

27 Nígbà náà Balaki sọ fún Balaamu pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.” 28 Balaki gbé Balaamu wá sí orí òkè Peori, tí ó kọjú sí aginjù.

29 Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Mọ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.” 30 Balaki sì ṣe bí Balaamu ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

24 Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù. Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:

“Ó wí pé Balaamu ọmọ Beori,
    òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀,
Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
    ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
    ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:

“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu,
    àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!

“Gẹ́gẹ́ bí Àfonífojì tí ó tàn jáde,
    gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,
gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,
    gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.
Omi yóò sàn láti inú garawa:
    èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

“Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ;
    ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;
    wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.
Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,
    wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;
    wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.
(D)Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,
    bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?

“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,
    kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”

10 Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. 11 Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”

12 Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, 13 ‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? 14 Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹ̀kẹrin Balaamu

15 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe:

“Òwe Balaamu ọmọ Beori,
    òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,
16 Ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí,
    tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo,
tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
    ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí:

17 “Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí,
    Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́.
Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu;
    yóò yọ jáde láti Israẹli.
Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu,
    yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.
18 Wọn yóò borí Edomu;
    yóò ṣẹ́gun Seiri ọ̀tá rẹ̀,
    ṣùgbọ́n Israẹli yóò dàgbà nínú agbára.
19 Olórí yóò jáde láti Jakọbu
    yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”

Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ìkẹyìn Balaamu

20 Nígbà náà ni Balaamu rí Amaleki ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:

“Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
    ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”

21 Nígbà náà ní ó rí ará Keni ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe:

“Ibùgbé rẹ ní ààbò,
    ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta;
22 síbẹ̀ ẹ̀yin ará Keni ni yóò di píparun
    nígbà tí Asiria bá mú yín ní ìgbèkùn.”

23 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:

“Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?
24     Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdókọ̀ Kittimu;
wọn yóò ṣẹ́gun Asiria àti Eberi,
    ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.”

25 Nígbà náà ni Balaamu dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Balaki sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.

Moabu tan Israẹli jẹ

25 Nígbà tí àwọn Israẹli dúró ní Ṣittimu, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Moabu, tí ó pè wọ́n sí ibi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn. Báyìí ni Israẹli ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Baali-Peori. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.

Olúwa sọ fún Mose pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.”

Mose sọ fún àwọn onídàájọ́ Israẹli, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Baali-Peori.”

Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá-méjìlá. (24,000).

10 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé, 11 “Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn. 12 Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀. 13 Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”

14 Orúkọ ọmọ Israẹli tí a pa pẹ̀lú obìnrin Midiani náà ni Simri, ọmọ Salu, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Simeoni. 15 Orúkọ ọmọbìnrin Midiani náà tí a pa ní Kosbi ọmọbìnrin Suri, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Midiani.

16 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé, 17 “Ka àwọn ará Midiani sí ọ̀tá, kí o sì pa wọ́n, 18 nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Peori, àti arábìnrin wọn Kosbi ọmọbìnrin ìjòyè Midiani kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-ààrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Peori.”

Ìkànìyàn ẹlẹ́ẹ̀kejì

26 (E)Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn Olúwa sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.” Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé, “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.”

Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá:

(F)Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli,

láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá;

Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;

ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni;

ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.

Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (43,730).

Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu, àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà. 10 Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀. 11 Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

12 Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn:

ti Nemueli, ìdílé Nemueli;

ti Jamini, ìdílé Jamini;

ti Jakini, ìdílé Jakini;

13 ti Sera, ìdílé Sera;

tí Saulu, ìdílé Saulu.

14 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-igba. (22,200) ọkùnrin.

15 Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn:

ti Sefoni, ìdílé Sefoni;

ti Haggi, ìdílé Haggi;

ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;

16 ti Osni, ìdílé Osni;

ti Eri, ìdílé Eri;

17 ti Arodi, ìdílé Arodi;

ti Areli, ìdílé Areli.

18 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

19 Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.

20 Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Ṣela, ìdílé Ṣela;

ti Peresi, ìdílé Peresi;

ti Sera, ìdílé Sera.

21 Àwọn ọmọ Peresi:

ti Hesroni, ìdílé Hesroni;

ti Hamulu, ìdílé Hamulu.

22 Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlógójì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500).

23 Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Tola, ìdílé Tola;

ti Pufa, ìdílé Pufa;

24 ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu;

ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.

25 Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (64,300).

26 Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Seredi, ìdílé Seredi;

ti Eloni, ìdílé Eloni;

ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.

27 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).

28 Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu:

29 Àwọn ọmọ Manase:

ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi);

ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.

30 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi:

ti Ieseri, ìdílé Ieseri;

ti Heleki, ìdílé Heleki

31 àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli;

àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;

32 àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida;

àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.

33 (Ṣelofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).

34 Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).

35 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi;

ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri;

ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.

36 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi:

ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani;

37 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500).

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

38 Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí:

tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela;

ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli;

ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;

39 ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu;

ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.

40 Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí:

ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi;

ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.

41 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,600).

42 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu

Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: 43 Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (64,400).

44 Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina;

ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi;

ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii;

45 Ti àwọn ọmọ Beriah:

ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi;

ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli.

46 (Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.)

47 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

48 Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli:

ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni;

49 ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri;

ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.

50 Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-egbèje (45,400).

51 Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (601,730).

52 Olúwa sọ fún Mose pé, 53 “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn 54 Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ. 55 Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í. 56 Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.”

57 (G)Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni;

ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati;

ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.

58 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi;

ìdílé àwọn ọmọ Libni,

ìdílé àwọn ọmọ Hebroni,

ìdílé àwọn ọmọ Mahili,

ìdílé àwọn ọmọ Muṣi,

ìdílé àwọn ọmọ Kora.

(Kohati ni baba Amramu, 59 Orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu. 60 Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari. 61 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)

62 Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.

63 Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko. 64 (H)Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai. 65 Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.

Ọmọbìnrin Ṣelofehadi

27 (I)Ọmọbìnrin Ṣelofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa. Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé, “Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, Ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀. Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.”

Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa. Olúwa sì wí fún un pé, “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ń sọ tọ̀nà. Ogbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀. Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. 10 Tí kò bá ní arákùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀. 11 Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ”

Joṣua láti rọ́pò Mose

12 (J)Nígbà náà Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sì orí òkè Abarimu yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. 13 Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Aaroni arákùnrin rẹ ṣe ṣe, 14 nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.)

15 Mose sọ fún Olúwa wí pé, 16 “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí 17 Láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”

18 (K)Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e. 19 Jẹ́ kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Israẹli kí o sì fi àṣẹ fún un ní ojú wọn. 20 Kí ìwọ kí ó sì fi nínú ọláńlá rẹ sí i lára, kí gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kí ó lè gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. 21 Kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Urimu níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.”

22 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Joṣua ó sì mú kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ. 23 (L)Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ọrẹ ojoojúmọ́

28 Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’ (M)Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́. Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi. Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí olóòórùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná. Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́. Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ́júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn sí Olúwa.

Ẹbọ ọjọ́ ìsinmi

“ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò. 10 Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu.

Ẹbọ oṣooṣù

11 “ ‘Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún Olúwa pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù. 12 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró; 13 pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú iná. 14 Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òṣùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún. 15 Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

Àjọ ìrékọjá

16 (N)“ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé. 17 (O)Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 18 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19 Ẹ rú ẹbọ sísun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù. 20 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá; 21 pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan ìdákan nínú mẹ́wàá. 22 Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín. 23 Ṣe eléyìí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀. 24 Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu. 25 Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

Àjọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀

26 (P)“ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 27 Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa. 28 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan. 29 Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdákan nínú mẹ́wàá. 30 Ẹ fi òbúkọ kan ṣe ètùtù fún ara yín. 31 Kí ẹ̀yin kí ó rú wọn pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.

Àsè ìpè

29 (Q)“ ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfùnpè ni ó jẹ́ fún yín. Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, ẹ pèsè ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdá méjì nínú mẹ́wàá, òṣùwọ̀n fún àgbò kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn méje. Àti òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún yín. Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.

Ọjọ́ ẹbọ ètùtù

(R)“ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó sẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí Olúwa, ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín. Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ọrẹ ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan, 10 àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n. 11 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn.

Àpèjẹ Àgọ́

12 (S)“ ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje. 13 Kí ẹ sì rú ẹbọ sísun kan, ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ tí ẹgbọrọ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá tí ó jẹ́ ọdún kan, tí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù. 14 Àti ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá mẹ́ta òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, bẹ́ẹ̀ ni fún akọ màlúù mẹ́tẹ̀ẹ̀tàlá, ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì, 15 àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá. 16 Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀.

17 “ ‘Àti ní ọjọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọrọ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rú ẹbọ. 18 Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 19 Àti òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

20 “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù. 21 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 22 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu.

23 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù. 24 Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

26 “ ‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 27 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà. 28 Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

29 “ ‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 30 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 31 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

32 “ ‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù. 33 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 34 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

35 (T)“ ‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpéjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan. 36 Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù. 37 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 38 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

39 “ ‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ̀dún tí a yàn yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’ ”

40 Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

Ẹ̀jẹ́

30 Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: (U)(V)Nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ.

“Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró. Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un.

“Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè, Tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró. Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.

“Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀.

10 “Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, 11 tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. 12 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀. 13 Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀. 14 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó ṣe ìwádìí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ láìsọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀. 15 Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”

16 Èyí ni ìlànà tí Olúwa fún Mose nípa ìbátan láàrín ọkùnrin àti obìnrin àti láàrín baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.

Gbígbẹ̀san lára àwọn ọmọ Midiani

31 Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbẹ̀san lára àwọn Midiani fún àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ.”

Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wọ ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Midiani láti gba ẹ̀san Olúwa lára wọn. Rán ẹgbẹ̀rún (1,000) ọmọ-ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn Israẹli, ẹgbẹ̀rún (1,000) ènìyàn láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá-mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun. Mose rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún (1,000) láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Finehasi ọmọ Eleasari, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀.

Wọ́n dojú ìjà kọ Midiani gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, kí wọn sì pa gbogbo wọn. Wọ́n sì pa àwọn ọba Midiani pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Efi, Rekemu, Suri àti Huri, àti Reba: ọba Midiani márùn-ún, wọ́n sì fi idà pa Balaamu ọmọ Beori. Àwọn ọmọ Israẹli sì mú gbogbo obìnrin Midiani ní ìgbèkùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn. 10 Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn. 11 Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran. 12 Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Israẹli ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani létí Jeriko.

13 Mose, Eleasari àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbèríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó. 14 Inú bí Mose sí àwọn olórí ọmọ-ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ̀rún (1,000) àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún (1,000) tí wọ́n ti ogun dé.

15 Mose sì béèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí? 16 (W)Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Israẹli padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Peori, níbi tí àjàkálẹ̀-ààrùn ti kọlu ìjọ Olúwa. 17 Nísinsin yìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin, 18 Ṣùgbọ́n kí o dá obìnrin tí kò bá tí ì súnmọ́ ọkùnrin sí fún ara yín.

19 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́. 20 Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”

21 Eleasari àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mose. 22 Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, idẹ àti òjé. 23 Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ yóò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi. 24 Ní ọjọ́ keje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”

Pínpín ogún

25 Olúwa sọ fún Mose pé, 26 “Ìwọ àti Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbèkùn. 27 Pín ohun ìní àti ìkógun náà láàrín àwọn ọmọ-ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrín gbogbo ìjọ. 28 Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà: ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ènìyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran. 29 Gba ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín tiwọn, kí o sì fún Eleasari àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa. 30 Lára ààbọ̀ ti Israẹli, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Lefi, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.” 31 Nígbà náà Mose àti Eleasari àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

32 Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ-ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (675,000) ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àgùntàn. 33 Ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógójì (72,000) màlúù 34 ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, 35 Pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún, (32,000) ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.

36 Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́:

ẹgbàáméjì-dínláàdọ́san (337,500) ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ àgùntàn. 37 Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675) àgùntàn;

38 ẹgbọrọ màlúù jẹ́ ẹgbàáméjì-dínlógún, (36,000) tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàdọ́rin (72);

39 kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, (30,500) tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta; (61).

40 Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n. (32).

41 Mose fi ìdá náà fún Eleasari, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

42 Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, tí Mose yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun. 43 Ààbọ̀ tí ìjọ jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínláàdọ́sàn-án ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn, 44 pẹ̀lú ẹgbàáméjì-dínlógún (36,000) màlúù 45 tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (30,500) 46 Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́jọ; (16,000). 47 Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Israẹli, Mose yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.

48 Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wá sọ́dọ̀ Mose. 49 Wọ́n sì sọ fún un pé, “ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ-ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan tó dín. 50 Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka-àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.”

51 Mose àti Eleasari àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́. 52 Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mose àti Eleasari, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá-mẹ́jọ ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì. 53 Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀. 54 Mose àti Eleasari àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú àgọ́ ìpàdé fún ìrántí àwọn Israẹli níwájú Olúwa.

Àwọn ẹ̀yà ìkọjá odò Jordani

32 Àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilẹ̀ Jaseri àti Gileadi dára fún ohun ọ̀sìn. Àwọn ọmọ Gadi àti àwọn ọmọ Reubeni sì wá, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà àti sí olórí gbogbo ìlú, wọ́n sì wí pé, “Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni. Ni ilẹ̀ tí Olúwa ti ṣẹ́gun níwájú ìjọ Israẹli tí ó sì dára fún ohun ọ̀sìn, ṣáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ohun ọ̀sìn. Tí a bá rí ojúrere rẹ,” wọ́n wí, “jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má ṣe jẹ́ kí a rékọjá odò Jordani.”

Mose sọ fún àwọn ọmọ Gadi àti fún ọmọ Reubeni pé, “Ṣé kí àwọn arákùnrin yín lọ sí ogun, kí ẹ̀yin kí ó sì jókòó sí bí? Kí ni ó dé tí o fi mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Israẹli láti lọ sí ibi ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn? (X)Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi-Barnea láti lọ wo ilẹ̀ náà. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ sí Àfonífojì Eṣkolu tí wọ́n rí ilẹ̀ náà, wọ́n mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Israẹli láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn. 10 (Y)Ìbínú Olúwa sì dìde sí wọn ní ọjọ́ náà, ó sì búra, wí pé: 11 ‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Ejibiti ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Abrahamu, fún Isaaki àti fún Jakọbu: 12 kò sí ẹnìkankan àyàfi Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissiti àti Joṣua ọmọ Nuni, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn.’ 13 Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli ó sì mú wọn rìn ní aginjù fún ogójì (40) ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ.

14 “Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò baba yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Israẹli. 15 Tí ẹ̀yin bá yípadà ní ẹ̀yìn rẹ̀ yóò sì fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ ní aginjù, ìwọ yóò sì mú un ṣe ìparun.”

16 Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, “Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhìn-ín yìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa. 17 Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣáájú àwọn ọmọ Israẹli títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdáàbòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà. 18 A kì yóò padà sí ilẹ̀ wa láìṣe pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti gba ogún wọn. 19 A kì yóò gba ogún kankan pẹ̀lú wọn ní òdìkejì Jordani, nítorí ogún ti wa, ti wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.