Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 2:30-15:35

30 “Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí. 31 Kíyèsi i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ. 32 Ìwọ yóò rí wàhálà ti Àgọ́, nínú gbogbo ọlá tí Ọlọ́run yóò fi fún Israẹli; kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ láéláé. 33 Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ní ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sọkún yọ lójú àti láti banújẹ́: Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

34 “ ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, yóò jẹ́ ààmì fún ọ—àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà. 35 Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi: Èmi yóò fi ẹsẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo. 36 Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”

Olúwa pe Samuẹli

Samuẹli ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Eli. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan Eli ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáradára, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìnwá. Nígbà tí iná kò tí ì kú Samuẹli dùbúlẹ̀ nínú tẹmpili Olúwa, níbi tí àpótí Olúwa gbé wà. Nígbà náà ni Olúwa pe Samuẹli.

Samuẹli sì dáhùn “Èmi nìyí” Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.”

Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀.

Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.”

“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”

Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.

Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.”

Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà. Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

10 Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!”

Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”

11 Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. 12 Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 13 Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. 14 Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

15 Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli. 16 Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.”

Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”

17 Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.” 18 Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni Olúwa; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”

19 Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà. 20 Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa. 21 Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn án ní Ṣilo, nítorí Olúwa ti fi ará hàn án fún Samuẹli ní Ṣilo nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

Ọ̀rọ̀ Samuẹli tọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá.

Àwọn Filistini gba àpótí ẹ̀rí

Nísinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli jáde láti lọ bá àwọn Filistini jà. Àwọn ọmọ Israẹli sì pàgọ́ sí Ebeneseri àti àwọn Filistini ní Afeki. Àwọn Filistini mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Israẹli, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Filistini ṣẹ́gun Israẹli wọ́n pa ẹgbàajì ọkùnrin nínú ogun náà (4,000). Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”

Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣilo, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, ẹni tí ń wà láàrín àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Eli méjèèjì Hofini àti Finehasi wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.

Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì. Ní ìgbà tí àwọn Filistini gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, “Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Heberu?”

Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí Olúwa ti wá sí ibùdó, Àwọn Filistini sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, “A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí. Àwa gbé! Ta ni yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run alágbára yìí? Àwọn ni Ọlọ́run tí ó fi ìpọ́njú pa àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo àjàkálẹ̀-ààrùn ní aginjù. Ẹ jẹ́ alágbára Filistini, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Heberu, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín: Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun!”

10 Nígbà náà àwọn Filistini jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Israẹli olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn; Àwọn ará Israẹli tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dógún àwọn ọmọ-ogun orí ilẹ̀ (30,000). 11 Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Olúwa, àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì sì kú, Hofini àti Finehasi.

Ikú Eli

12 Lọ́jọ́ kan náà tí ará Benjamini kan sá wá láti ojú ogun tí ó sì lọ sí Ṣilo, aṣọ rẹ̀ sì fàya pẹ̀lú eruku lórí rẹ̀. 13 Nígbà tí ó sì dé, Eli sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

14 Eli gbọ́ ìró ohùn ẹkún náà ó sì béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ ariwo yìí?”

Ọkùnrin náà sì sáré tọ Eli wá 15 Eli sì di ẹni méjì-dínlọ́gọ́run ọdún, tí ojú rẹ̀ di bàìbàì, kò sì ríran mọ́. 16 Ọkùnrin náà sọ fún Eli, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi ogun náà ni: mo sá láti ibi ogun náà wá lónìí.”

Eli sì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ọmọ mi?”

17 Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn Filistini, ìṣubú àwọn ọmọ-ogun náà sì pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ.”

18 Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí Olúwa, Eli sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Israẹli fún ogójì ọdún.

19 Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Finehasi, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà. 20 Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i.

21 Ó sì pe ọmọ náà ní Ikabodu, wí pé, “Kò sí ògo fún Israẹli mọ́” nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀. 22 Ó si wí pé, “Ògo kò sí fún Israẹli mọ́, nítorí ti a ti gbá àpótí Ọlọ́run.”

Àpótí ẹ̀rí Olúwa ní Aṣdodu àti Ekroni

Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Filistini ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebeneseri sí Aṣdodu. Nígbà tí àwọn Filistini gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili Dagoni, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá Dagoni. Nígbà tí àwọn ará Aṣdodu jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dagoni ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dagoni, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dagoni ṣì wá, ó ṣubú ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu-ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù. Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dagoni tàbí àwọn mìíràn tí ó wọ inú tẹmpili Dagoni ní Aṣdodu fi ń tẹ orí ìloro ẹnu-ọ̀nà.

Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Aṣdodu àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Aṣdodu rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti Israẹli kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dagoni ọlọ́run wá.” Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Filistini jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ sí Gati.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli.

Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn oníkókó. 10 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni.

Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” 11 Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Filistini jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí ààyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú: ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn. 12 Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.

Àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sí Israẹli

Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Filistini fún oṣù méje, àwọn ará Filistini pe àwọn àlùfáà, àti àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí ààyè rẹ̀.”

Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti àwọn ọmọ Israẹli padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”

Àwọn ará Filistini béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?”

Wọ́n dáhùn, “Wúrà oníkókó márùn-ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn aláṣẹ Filistini, nítorí àjàkálẹ̀-ààrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín. Mọ àwòrán ààrùn oníkókó àti ti eku ẹ̀lírí yin tí ó ń ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Israẹli, Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín. Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn?

“Nísinsin yìí ẹ pèsè kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fi ọmú fún ọmọ, èyí tí a kò tí ì gba àjàgà sí ọrùn rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so. Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ, ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ. Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà ni Olúwa mú àjálù ńlá yìí bá wa. Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọlù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni.”

10 Nígbà náà ni wọ́n ṣe èyí. Wọ́n mú abo màlúù méjì, tí ń fi ọmú fún ọmọ, wọn mọ́ ara, wọ́n sì dè é ni ilé kẹ̀kẹ́ ẹrù, wọn sì so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ ni ilé. 11 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé orí kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àpótí tí eku ẹ̀lírí wúrà àti àwòrán ààrùn oníkókó wà níbẹ̀. 12 Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Beti-Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Filistini tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Beti-Ṣemeṣi.

13 Nísinsin yìí, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀. 14 Kẹ̀kẹ́ ẹrù wá sí pápá Joṣua ti Beti-Ṣemeṣi, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 15 Àwọn ará Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí Olúwa. 16 Àwọn aláṣẹ Filistini márààrún rí gbogbo èyí, wọ́n sì padà ní ọjọ́ náà sí Ekroni.

17 Èyí ni kókó wúrà tí àwọn Filistini fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Aṣdodu, ọ̀kan ti Gasa, ọ̀kan ti Aṣkeloni, ọ̀kan ti Gati, ọ̀kan ti Ekroni. 18 Wúrà eku ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Filistini márààrún ti wá, ìlú olódi pẹ̀lú ìletò wọn. Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Joṣua ará Beti-Ṣemeṣi.

19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọlu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Beti-Ṣemeṣi, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí Olúwa fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà. 20 Àwọn ọkùnrin ará Beti-Ṣemeṣi béèrè pé, “Ta ni ó le è dúró ní iwájú Olúwa Ọlọ́run mímọ́ yìí? Ọ̀dọ̀ ta ni àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò gbà gòkè lọ láti ibí yìí?”

21 Nígbà náà, wọ́n rán àwọn ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí Kiriati-Jearimu wí pé, “àwọn Filistini ti dá àpótí ẹ̀rí Olúwa padà. Ẹ sọ̀kalẹ̀ wá, kí ẹ gbé e gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ yín.” Nígbà náà àwọn ará Kiriati-Jearimu wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Abinadabu lórí òkè, wọ́n sì ya Eleasari ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.

Samuẹli ṣẹ́gun àwọn ará Filistini ní Mispa

Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati-Jearimu. Gbogbo ilé Israẹli ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùnréré ẹkún sí Olúwa. Samuẹli sọ fún gbogbo ilé Israẹli pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì àti Aṣtoreti kí ẹ sì fi ara yín jì fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini” Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli yẹra fún Baali àti Aṣtoreti, wọ́n sì sin Olúwa nìkan ṣoṣo.

Nígbà náà ni, Samuẹli wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ sí Mispa, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa.” Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mispa, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa.” Samuẹli sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Israẹli ní Mispa.

Nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé àwọn Israẹli ti péjọ ní Mispa, àwọn aláṣẹ Filistini gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, Ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Filistini. Wọ́n sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ọ̀dọ́-àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí ké pe Olúwa nítorí ilé Israẹli, Olúwa sì dá a lóhùn.

10 Nígbà tí Samuẹli ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Filistini súnmọ́ tòsí láti bá Israẹli ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Filistini, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 11 Àwọn ọkùnrin Israẹli tú jáde láti Mispa. Wọ́n sì ń lépa àwọn Filistini, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Beti-Kari.

12 Samuẹli mú òkúta kan ó sì fi lélẹ̀ láàrín Mispa àti Ṣeni, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ebeneseri, wí pé, “Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Filistini, wọn kò sì wá sí agbègbè àwọn ọmọ Israẹli mọ́.

Ní gbogbo ìgbésí ayé Samuẹli, ọwọ́ Olúwa lòdì sí àwọn Filistini. 14 Àwọn ìlú láti Ekroni dé Gati tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ Israẹli ni ó ti gbà padà fún Israẹli, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Filistini. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàrín Israẹli àti àwọn Amori.

15 Samuẹli tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Israẹli. Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀. 16 Láti ọdún dé ọdún, ó lọ yíká láti Beteli dé Gilgali dé Mispa, ó sì ń ṣe ìdájọ́ Israẹli ní gbogbo ibi wọ̀nyí. 17 Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rama, níbí tí ilé rẹ̀ wà, ó sì túnṣe ìdájọ́ Israẹli níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa.

Israẹli béèrè fún ọba

Nígbà tí Samuẹli di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Israẹli. Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Joeli àti orúkọ èkejì a máa jẹ́ Abijah, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Beerṣeba. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.

Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama. Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.”

Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Samuẹli lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. Olúwa sì sọ fún Samuẹli pé: “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ. Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”

10 Samuẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀. 11 Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́ṣin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 12 Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 13 Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà. 14 Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi olifi yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 15 Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 16 Àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀. 17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa ṣe ẹrú u rẹ̀. 18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”

19 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Samuẹli wọ́n wí pé, “Rárá! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ ọba lórí i wa? 20 Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”

21 Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa. 22 Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.”

Nígbà náà, Samuẹli sọ fún àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”

Samuẹli fi òróró yan Saulu

Ará Benjamini kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afiah ti Benjamini. Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Saulu, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàrín gbogbo àwọn ọmọ Israẹli—láti èjìká rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn tókù lọ.

Nísinsin yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kiṣi baba Saulu sì sọnù. Nígbà náà, Kiṣi sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrín àwọn ìlú olókè Efraimu, ó sì kọjá ní àyíká ilẹ̀ Ṣaliṣa, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Ṣaalimu, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Benjamini, wọn kò sì rí wọn.

Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”

Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ síbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a yóò gbà.”

Saulu sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, “Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà? Oúnjẹ inú àpò wa ti tán. A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Kí ni a ní?”

Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.” (Tẹ́lẹ̀ ní Israẹli tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìsinsin yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì).

10 Saulu sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára “Jẹ́ kí a lọ” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé.

11 Bí wọ́n ṣe ń lọ ní orí òkè sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ń jáde í bọ̀ láti wá pọn omí. Wọ́n sì bi wọ́n, “Ṣé wòlíì náà wà níbí?”

12 “Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsin yìí, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga. 13 Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbọdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsin yìí: ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”

14 Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Samuẹli, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.

15 Olúwa ti sọ létí Samuẹli ní ọjọ́ kan kí Saulu ó tó dé pé, 16 “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

17 Nígbà tí Samuẹli fojúrí Saulu, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

18 Saulu sì súnmọ́ Samuẹli ní ẹnu-ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”

19 Samuẹli dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ. 20 Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dààmú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Israẹli wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.”

21 Saulu dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há ṣe ẹ̀yà Benjamini? Kékeré nínú ẹ̀yà Israẹli: Ìdílé mi kò ha rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹ̀yà Benjamini? Èéṣì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”

22 Nígbà náà ni Samuẹli mú Saulu pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngán, ó sì mú wọn jókòó sí iwájú àwọn tí a pè—tí wọn tó ọgbọ̀n. 23 Samuẹli sọ fún alásè pé, “Mú ìpín ẹran tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé kí o yà sọ́tọ̀.”

24 Alásè náà sì gbé ẹsẹ̀ náà pẹ̀lú ohun tí ó wà lórí i rẹ̀, ó sì gbé e síwájú Saulu. Samuẹli wí pé, “Èyí ni ohun tí a fi pamọ́ fún ọ. Jẹ, nítorí a yà á sọ́tọ̀ fún ọ, fún ìdí yìí, láti ìgbà tí mo ti wí pé, ‘Mo ní àlejò tí a pè.’ ” Saulu sì jẹun pẹ̀lú Samuẹli ní ọjọ́ náà.

25 Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti sọ̀kalẹ̀ láti ibí gíga náà wá sí inú ìlú, Samuẹli sì bá Saulu sọ̀rọ̀ lórí òrùlé ilé e rẹ̀. 26 Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, ó pe Saulu sórí òrùlé pé, “Múra, èmi yóò rán ọ lọ.” Nígbà tí Saulu múra tán òun àti Samuẹli jọ jáde lọ síta. 27 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, “ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”

10 Samuẹli sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Saulu. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olórí lórí ohun ìní rẹ̀? Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Ṣelṣa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’

“Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi ńlá Tabori. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Beteli yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, ìṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹta yóò mú ìgò wáìnì. Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ wọn.

“Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀. Bí ìwọ bá ti rí ààmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.

“Lọ ṣáájú mi sí Gilgali. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.”

A fi Saulu jẹ ọba

Bí Saulu ti yípadà láti fi Samuẹli sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Saulu padà àti pé gbogbo ààmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà. 10 Nígbà tí wọ́n dé òkè Gibeah náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀. 11 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi yìí. Ṣé Saulu wà lára àwọn wòlíì ni?”

12 Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń pa òwe pé, ǹjẹ́ Saulu náà wà lára àwọn wòlíì bí? 13 Lẹ́yìn tí Saulu dákẹ́ sísọ àsọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga.

14 Nísinsin yìí, arákùnrin baba Saulu béèrè lọ́wọ́ Saulu àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?”

Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli.

15 Arákùnrin baba Saulu wí pé, “Sọ fún mi ohun tí Samuẹli wí fún un yín.”

16 Saulu dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Samuẹli sọ nípa ọba jíjẹ.

17 Samuẹli pé àwọn ọmọ Israẹli jọ sí iwájú Olúwa ní Mispa. 18 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ: ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’ 19 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

20 Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini. 21 Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i, 22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?”

Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.”

23 Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè. 24 Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.”

Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”

25 Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.

26 Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín. 27 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Beliali wí pé, “Báwo ni ọkùnrin yìí yóò ti ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Saulu fọwọ́ lérán.

Saulu gba ìlú Jabesi sílẹ̀

11 Nahaṣi ará Ammoni gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi Gileadi, gbogbo ọkùnrin Jabesi sì wí fún Nahaṣi pé, “Bá wa dá májẹ̀mú, àwa yóò sì máa sìn ọ́.”

Ṣùgbọ́n Nahaṣi ará Ammoni sì wí fún un pé, “Nípa èyí ni èmi yóò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọ̀tún yín kúrò, èmi yóò ṣì fi yín ṣe ẹlẹ́yà lójú gbogbo Israẹli.”

Àwọn àgbàgbà Jabesi sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Israẹli; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.”

Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gibeah tí ó jẹ́ ìlú Saulu, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún. Nígbà náà gan an ni Saulu padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sọkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi.

Nígbà tí Saulu sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè. Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyẹẹyọ sí gbogbo Israẹli nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Saulu àti Samuẹli lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo. Nígbà tí Saulu sì kó wọn jọ ní Beseki, àwọn ọkùnrin Israẹli tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. (300,000) àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000).

Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jabesi, inú wọn sì dùn. 10 Wọ́n sọ fún àwọn ará Jabesi pé, “Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa.”

11 Ní ọjọ́ kejì Saulu pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ammoni ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóoru ọjọ́. Àwọn tókù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan.

Wọ́n fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba

12 Àwọn ènìyàn sọ fún Samuẹli pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Saulu yóò ha jẹ ọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.”

13 Ṣùgbọ́n Saulu wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa ṣiṣẹ́ ìgbàlà ní Israẹli.”

14 Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gilgali, kí a lè fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba.” 15 Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gilgali, wọn sí fi Saulu jẹ ọba ní iwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní iwájú Olúwa, Saulu àti gbogbo Israẹli ṣe àjọyọ̀ ńlá.

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Samuẹli

12 Samuẹli sì wí fún gbogbo Israẹli pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín. Nísinsin yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn-ín yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí. Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni ààmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”

Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”

Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni ààmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”

Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”

Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mose àti Aaroni àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Ejibiti. Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.

“Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu wọ Ejibiti, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mose àti Aaroni, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Ejibiti láti mú wọn jókòó níbí yìí.

“Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sisera, olórí ogun Hasori, àti sí ọwọ́ àwọn Filistini àti sí ọwọ́ ọba Moabu, tí ó bá wọn jà. 10 Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Baali, àti Aṣtoreti. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’ 11 Nígbà náà ni Olúwa rán Jerubbaali, Bedani, Jefta àti Samuẹli, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà.

12 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Nahaṣi ọba àwọn Ammoni dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín. 13 Nísinsin yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún; wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín. 14 Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára 15 ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín.

16 “Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín! 17 Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”

18 Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀.

19 Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”

20 Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa. 21 Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà. Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n. 22 Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀. 23 Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín. Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́. 24 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín; Ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín. 25 Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”

Samuẹli fi Saulu bú

13 Saulu sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjìlélógójì.

Saulu yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.

Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli sì gbọ́ ìròyìn pé, “Saulu ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini, Israẹli sì di òórùn búburú fún àwọn Filistini.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti darapọ̀ mọ́ Saulu ní Gilgali.

Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́dógún kẹ̀kẹ́, (3,000) ẹgbẹ̀ta (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ. Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi.

Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù. Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Samuẹli dá; ṣùgbọ́n Samuẹli kò wá sí Gilgali, àwọn ènìyàn Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká. Saulu sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Saulu sì rú ẹbọ sísun náà. 10 Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ sísun náà, Samuẹli sì dé, Saulu sì jáde láti lọ kí i.

11 Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”

Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi, 12 mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.”

13 Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. 14 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”

15 Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta.

Israẹli láìní ohun ìjà

16 Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gibeah ti Benjamini, nígbà tí àwọn Filistini dó ní Mikmasi. 17 Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Filistini ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ofira ní agbègbè ìlú Ṣuali, 18 òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí Àfonífojì Ṣeboimu tí ó kọjú sí ijù.

19 A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!” 20 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli tọ àwọn Filistini lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ́ wọn. 21 Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdámẹ́ta ṣékélì, àti ìdámẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n òòyà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù.

Jonatani kọlu àwọn ará Filistini

22 Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani ni wọ́n ni wọ́n.

23 Àwọn ẹgbẹ́ ogun Filistini sì ti jáde lọ sí ìkọjá Mikmasi. 14 Ní ọjọ́ kan, Jonatani ọmọ Saulu wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Filistini tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀.

Saulu sì dúró ní ìhà etí ìpínlẹ̀ Gibeah lábẹ́ igi pomegiranate èyí tí ó wà ní Migroni. Àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin (600) sì wà pẹ̀lú rẹ̀, lára wọn ni Ahijah, tí ó wọ efodu. Òun ni ọmọ arákùnrin Ikabodu Ahitubu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, àlùfáà Olúwa ní Ṣilo kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jonatani ti lọ.

Ní ọ̀nà tí Jonatani ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Filistini, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkínní sì ń jẹ́ Bosesi, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sene. Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Mikmasi, èkejì sì wà ní gúúsù ní ìhà Gibeah.

Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.”

Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀síwájú; Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.”

Jonatani sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa. Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró sí ibi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ. 10 Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.”

11 Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Filistini. Àwọn Filistini sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.” 12 Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.”

Jonatani sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; Olúwa ti fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́.”

13 Jonatani lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Filistini sì ṣubú níwájú Jonatani ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. 14 Ní ìkọlù èkínní yìí, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbègbè tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sáré ilẹ̀.

15 Nígbà náà ni ìbẹ̀rùbojo bá àwọn ọmọ-ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

Àwọn ogun Filistini sá àsálà

16 Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Saulu ní Gibeah ti Benjamini sì rí àwọn ọmọ-ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà. 17 Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wò ó, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀.

18 Saulu sì wí fún Ahijah pé, “Gbé àpótí Ọlọ́run wá.” Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbà náà. 19 Nígbà tí Saulu sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Filistini sì ń pọ̀ síwájú sí. Saulu sì wí fún àlùfáà pé, “Dá ọwọ́ rẹ dúró.”

20 Saulu àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà. Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Filistini ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkejì rẹ̀. 21 Àwọn Heberu tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Filistini tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani. 22 Nígbà tí gbogbo àwọn Israẹli tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Efraimu gbọ́ pé àwọn Filistini sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná. 23 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Israẹli ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Beti-Afeni.

Jonatani jẹ oyin

24 Gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Saulu ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.

25 Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà. 26 Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ síbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré. 27 Ṣùgbọ́n Jonatani kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ìfibú kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán. 28 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun sọ fún un pé, “Baba rẹ fi ìfibú kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní!’ Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn.”

29 Jonatani sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdààmú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí. 30 Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀tá wọn lónìí, pípa àwọn Filistini ìbá ti pọ̀ tó?”

31 Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti pa nínú àwọn Filistini láti Mikmasi dé Aijaloni, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà. 32 Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀. 33 Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Saulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.”

Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá sí ibi nísinsin yìí.” 34 Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ”

Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀. 35 Nígbà náà Saulu kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.

36 Saulu sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Filistini lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má ṣì ṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.”

Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.”

Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn-ín.”

37 Nígbà náà ni Saulu béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Filistini lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

38 Saulu sì wí pé, “Ẹ wá síhìn-ín ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí. 39 Olúwa tí ó gba Israẹli là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jonatani ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.

40 Nígbà náà ni Saulu wí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jonatani ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.”

Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.”

41 Nígbà náà ni Saulu gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jonatani àti Saulu nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege. 42 Saulu sì wí pé, “Ẹ dìbò láàrín èmi àti Jonatani ọmọ mi.” Ìbò náà sì mú Jonatani.

43 Saulu sì wí fún Jonatani pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.”

Jonatani sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsin yìí ṣé mo ní láti kú?”

44 Saulu sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, nítorí pé ìwọ Jonatani yóò sá à kú dandan.”

45 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Saulu pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jonatani kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Israẹli? Kí a má rí í! Bí Olúwa ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.” Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jonatani sílẹ̀, kò sì kú.

46 Nígbà náà ni Saulu sì dẹ́kun lílépa àwọn Filistini, àwọn Filistini sì padà sí ìlú wọn.

47 Lẹ́yìn ìgbà tí Saulu ti jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká: Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni; Edomu, àti àwọn ọba Ṣoba, àti àwọn Filistini. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n. 48 Ó sì jà tagbára tagbára, ó ṣẹ́gun àwọn Amaleki, ó sì ń gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ń kọlù wọ́n.

Ìdílé Saulu

49 (A)Àwọn ọmọ Saulu sì ni Jonatani, Iṣifi àti Malikiṣua. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Merabu àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Mikali. 50 Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Ahinoamu ọmọbìnrin Ahimasi. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arákùnrin baba Saulu. 51 Kiṣi baba Saulu àti Neri baba Abneri wọ́n sì jẹ́ ọmọ Abieli.

52 Ní gbogbo ọjọ́ Saulu, ogun náà sì gbóná sí àwọn Filistini, níbikíbi tí Saulu bá sì ti rí alágbára tàbí akíkanjú ọkùnrin, a sì mú u láti máa bá a ṣiṣẹ́.

Olúwa kọ Saulu ní ọba

15 Samuẹli wí fún Saulu pé, “Èmi ni Olúwa rán láti fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli; fetísílẹ̀ láti gbọ́ Iṣẹ́ tí Olúwa rán mi sí ọ́. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi yóò jẹ àwọn Amaleki ní yà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ejibiti. Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọlu Amaleki, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tiwọn ní à parun. Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.’ ”

Bẹ́ẹ̀ ni Saulu kó àwọn ènìyàn jọ, ó sì ka iye wọn ní Talaemu, wọ́n sì jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (200,000) àwọn ológun ẹlẹ́ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹgbàárùn-ún àwọn ọkùnrin Juda (10,000). Saulu sì lọ sí ìlú Amaleki ó sì gọ dè wọ́n ní Àfonífojì kan. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ará Keni pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Amaleki kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè ti Ejibiti wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kenaiti lọ kúrò láàrín àwọn Amaleki.

Nígbà náà ni Saulu kọlu àwọn Amaleki láti Hafila dé Ṣuri, tí ó fi dé ìlà-oòrùn Ejibiti. Ó sì mú Agagi ọba Amaleki láààyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlù gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n Saulu àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ dá Agagi sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátápátá ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì níláárí ni wọ́n parun pátápátá.

10 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Samuẹli wá pé: 11 “Èmi káàánú gidigidi pé mo fi Saulu jẹ ọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Samuẹli sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì ké pe Olúwa ní gbogbo òru náà.

12 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Samuẹli sì dìde láti lọ pàdé Saulu, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Saulu ti wá sí Karmeli. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gilgali.”

13 Nígbà tí Samuẹli sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Saulu sì wí fún un pé, “Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ.”

14 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi? Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí?”

15 Saulu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ní o mú wọn láti Amaleki wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tókù run pátápátá.”

16 Samuẹli sí wí fún Saulu pé, “Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí Olúwa wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.”

Saulu sì wí pé, “Sọ fún mi.”

17 Samuẹli sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Israẹli? Olúwa fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli. 18 Olúwa sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Amaleki run pátápátá; gbóguntì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ 19 Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti Olúwa? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú Olúwa?”

20 Saulu sì wí fún Samuẹli pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí Olúwa rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Amaleki run pátápátá, mo sì ti mú Agagi ọba wọn padà wá. 21 Àwọn ọmọ-ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógun èyí tí ó dára láti fi fún Olúwa láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Gilgali.”

22 (B)Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé,

Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ
    ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́?
Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ,
    ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.
23 Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ,
    àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà.
Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,
    Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”

24 Nígbà náà ni Saulu wí fún Samuẹli pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́. 25 Mo bẹ̀ ọ́ nísinsin yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin Olúwa.”

26 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí fún un pé, “Èmi kò ní bá ọ padà. Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa sílẹ̀, Olúwa sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli!”

27 Bí Samuẹli sì ti fẹ́ yípadà láti lọ, Saulu sì di ẹ̀wù ìlekè rẹ̀ mú, ó sì fàya; 28 Samuẹli sì wí fún un pé, “Olúwa ti fa ìjọba Israẹli ya kúrò lọ́wọ́ ọ̀ rẹ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ kan tí ó sàn jù ọ́ lọ. 29 Ẹni tí ó ń ṣe ògo Israẹli, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”

30 Saulu sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbàgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Israẹli, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.” 31 Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli sì yípadà pẹ̀lú Saulu, Saulu sì sin Olúwa.

32 Nígbà náà ni Samuẹli wí pé, “Mú Agagi ọba àwọn ará Amaleki wá fún mi.”

Agagi sì tọ̀ ọ́ wá ní ìgboyà pẹ̀lú èrò pé, “Nítòótọ́ ìkorò ikú ti kọjá.”

33 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé,

“Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọ
    bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàrín obìnrin.”

Samuẹli sì pa Agagi níwájú Olúwa ni Gilgali.

34 Nígbà náà ni Samuẹli lọ sí Rama, Saulu sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah tí Saulu. 35 Samuẹli kò sì padà wá mọ́ láti wo Saulu títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Samuẹli káàánú fún Saulu. Ó sì dun Olúwa pé ó fi Saulu jẹ ọba lórí Israẹli.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.