Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 10-23

Saulu gba ẹ̀mí ara rẹ̀

10 (A)Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, Àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa. Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua. Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́.

Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.

Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é; Bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e. Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Saulu ti kú, òhun pẹ̀lú ṣubú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà.

Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn.

Ní ọjọ́ kejì, Nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa. Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 10 Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni.

11 Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jabesi—Gileadi gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Filistini ṣe fún Saulu, 12 Gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jabesi. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi óákù ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.

13 Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí Olúwa: Kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà. 14 Kò sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.

Dafidi di ọba lórí Israẹli

11 (B)Gbogbo àwọn Israẹli kó ara wọn jọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa í ṣe. Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Saulu jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Israẹli ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùṣọ́ Israẹli ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”

Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú Olúwa, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa láti ọwọ́ Samuẹli.

Dafidi borí Jerusalẹmu

(C)Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀. Àwọn ará ìlú Jebusi sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wọ ìhín yìí wá.” Ṣùgbọ́n Dafidi kó ìlú odi Sioni—èyí tí í ṣe ìlú Dafidi.

Dafidi ti wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tètè kọlu àwọn ará Jebusi ni yóò di olórí àti balógun.” Joabu ọmọ Seruiah sì kọ́kọ́ gòkè lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.

Dafidi sì ń gbé inú ìlú odi, nítorí náà ni wọ́n fi ń pè é ni ìlú Dafidi. Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri; láti Millo yíkákiri; Joabu sì tún ìyókù àwọn ìlú náà ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ga, ó sì pọ̀ sí i, nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú rẹ̀.

Dafidi alágbára ọkùnrin

10 (D)Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dafidi, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fún ìjọba rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí: 11 Èyí sì ni iye àwọn akọni ọkùnrin Dafidi:

Jaṣobeamu ọmọ Hakumoni, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.

12 Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Eleasari ọmọ Dodo àwọn ará Ahohi, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára. 13 Ó sì wà pẹ̀lú Dafidi ní Pasi-Dammimu nígbà tí àwọn ará Filistini kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà barle. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Filistini. 14 Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárín pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Filistini mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.

15 Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní Àfonífojì ní orí òkè Refaimu. 16 Ní àsìkò náà Dafidi sì ń bẹ nínú ìlú odi, ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Filistini sì ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu. 17 Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu? 18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Filistini, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu ó sì gbé padà tọ Dafidi wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa. 19 “Kí Ọlọ́run dẹ́kun kí èmi ó má ṣe ṣe èyí!” ó wí pé. “Ṣé kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dafidi kò ní mu ú.

Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.

20 Abiṣai arákùnrin Joabu ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta. 21 Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.

22 Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò sno (yìnyín dídì), ó sì pa kìnnìún kan 23 Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀. 24 Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta. 25 Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò kà á láàrín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Dafidi sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́.

26 Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí:

Asaheli arákùnrin Joabu,

Elhanani ọmọ Dodo láti Bẹtilẹhẹmu,

27 Ṣamotu ará Harori,

Helesi ará Peloni

28 Ira ọmọ Ikẹsi láti Tekoa,

Abieseri láti Anatoti,

29 Sibekai ará Huṣati,

láti ará Ahohi

30 Maharai ará Netofa,

Heledi ọmọ Baanah ará Netofa,

31 Itai ọmọ Ribai láti Gibeah ní Benjamini,

Benaiah ará Piratoni,

32 Hurai láti Àfonífojì Gaaṣi,

Abieli ará Arbati,

33 Asmafeti ará Bahurimu

Eliaba ará Ṣaalboni

34 Àwọn ọmọ Haṣemu ará Gisoni

Jonatani ọmọ Ṣage ará Harari.

35 Ahiamu ọmọ Sakari ará Harari,

Elifali ọmọ Uri

36 Heferi ará Mekerati,

Ahijah ará Peloni,

37 Hesro ará Karmeli

Naarai ọmọ Esbai,

38 Joeli arákùnrin Natani

Mibari ọmọ Hagari,

39 Seleki ará Ammoni,

Naharai ará Beroti ẹni tí ó jẹ́ ẹni tí n ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah.

40 Ira ará Itri,

Garebu ará Itri,

41 Uriah ará Hiti

Sabadi ọmọ Ahlai.

42 Adina ọmọ Ṣina ará Reubeni, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Reubeni, àti pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀.

43 Hanani ọmọ Maaka.

Jehoṣafati ará Mitini.

44 Ussia ará Asiterati,

Ṣama àti Jeieli àwọn ọmọ Hotami ará Aroeri,

45 Jediaeli ọmọ Ṣimri,

àti arákùnrin Joha ará Tisi

46 Elieli ará Mahafi

Jeribai àti Joṣafia àwọn ọmọ Elnaamu,

Itimah ará Moabu,

47 Elieli, Obedi àti Jaasieli ará Mesoba.

Àwọn ọ̀gágun tí ó dúró ti Dafidi

12 Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Siklagi, nígbà tí ó sá kúrò níwájú Saulu ọmọ Kiṣi (Wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti ibi ìjà. Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Saulu láti ẹ̀yà Benjamini):

Ahieseri Olórí wọn àti Joaṣi àwọn ọmọ Ṣemaah ará Gibeah:

Jeṣieli àti Peleti ọmọ Asmafeti,

Beraka, Jehu ará Anatoti. Àti Iṣmaiah ará Gibeoni, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n;

Jeremiah, Jahasieli, Johanani, Josabadi ará Gedera, Elusai, Jerimoti, Bealiah, Ṣemariah àti Ṣefatia ará Harufiti;

Elkana, Iṣiah, Asareeli, Joeseri àti Jaṣobeamu ará Kora;

Àti Joela, àti Sebadiah àwọn ọmọ Jerohamu láti Gedori.

Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.

Eseri sì jẹ́ ìjòyè,

Ọbadiah sì jẹ́ igbákejì akọgun, Eliabu ẹlẹ́kẹta,

10 Miṣimana ẹlẹ́kẹrin, Jeremiah ẹlẹ́karùnún

11 Attai ẹlẹ́kẹfà, Elieli èkeje,

12 Johanani ẹlẹ́kẹjọ Elsabadi ẹlẹ́kẹsànán

13 Jeremiah ẹlẹ́kẹwàá àti Makbannai ẹlẹ́kọkànlá.

14 Àwọn ará Gadi wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún. 15 Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jordani ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú Àfonífojì, lọ sí ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn.

16 Ìyókù ará Benjamini àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Juda lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní ibi gíga. 17 Dafidi sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo ṣetán láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀tá mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”

18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé:

“Tìrẹ ni àwa ń ṣe, ìwọ Dafidi!
    Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jese!
Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ,
    àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́,
        nítorí Ọlọ́run rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.

19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Manase sì yà sí ọ̀dọ̀ Dafidi nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Filistini láti bá Saulu jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọn kò sì ran ará Filistini lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn tiwọn sọ̀rọ̀ papọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé, “Yóò jẹ́ ìparun fún wa tí ó bá padà tọ ọ̀gá rẹ̀ Saulu lọ.”) 20 Nígbà tí Dafidi lọ sí Siklagi, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Manase ẹni tí ó sì yà sọ́dọ̀ rẹ̀. Adina, Josabadi, Jediaeli, Mikaeli, Josabadi, Elihu àti Siletai, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹgbẹ̀rún ní Manase. 21 Wọ́n sì ran Dafidi lọ́wọ́ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run.

Àwọn tókù darapọ̀ pẹ̀lú Dafidi ní Hebroni

23 Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni láti yí ìjọba Dafidi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ:

24 Ọkùnrin Juda, tí o ń gbé asà àti ọ̀kọ̀, ẹgbàáta lé lọ́gọ́rin (6,080) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun;

25 Àwọn ọkùnrin Simeoni, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó-lé-ọgọ́rùn-ún (7,100);

26 Àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600), 27 Pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn (3,700), 28 Àti Sadoku akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn (22) méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀;

29 Àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà;

30 àwọn arákùnrin Efraimu, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàáwàá ó le ẹgbẹ̀rin (20,800).

31 Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹgbàásàn án (18,000).

32 Àti ní ti àwọn ọmọ Isakari, àwọn ẹni tí ó ní òye àkókò, láti mọ ohun tí Israẹli ìbá máa ṣe; olórí wọn jẹ́ ìgbà (200); àti gbogbo àwọn ìbátan wọn ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn.

33 Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n (50,000).

34 Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá-méjì-dínlógún (36,000). Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn.

35 Àwọn ọkùnrin Dani, tí wọ́n ṣetán fún ogun ẹgbàá-mẹ́tàlá (28,600)

36 Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì (40,000).

37 Láti ìlà-oòrùn Jordani, ọkùnrin Reubeni, Gadi, àti ìdajì ẹ̀yà Manase, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000).

38 Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ́ fún nínú ẹgbẹ́.

Wọ́n wá sí Hebroni tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dafidi jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Israẹli sì jẹ́ onínú kan láti fi Dafidi jẹ ọba 39 Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dafidi, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèsè oúnjẹ fún wọn. 40 Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí Ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.

Gbígbé padà àpótí ẹ̀rí

13 (E)Dafidi sì gbèrò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ ọgọ́rùn-ún Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Israẹli pé, Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jíjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tókù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Israẹli àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọ pọ̀ sọ́dọ̀ wa. Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Saulu. Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn.

Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu. Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù—gòkè wá.

Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Abinadabu lórí kẹ̀kẹ́ tuntun, Ussa àti Ahio ń ṣọ́ ọ. Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè.

Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọsẹ̀. 10 Ìbínú Olúwa, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

11 Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Pereṣi-Uṣa.

12 Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi? 13 Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará rẹ̀ ní ìlú ti Dafidi dípò èyí, ó sì gbé e yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. 14 Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwọn ará ilé Obedi-Edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.

Ilé àti ìdílé Dafidi

14 (F)Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un. Dafidi sì mọ Israẹli àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀.

(G)Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni, Ibhari, Eliṣua, Elifeleti, Noga, Nefegi, Jafia, Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti.

Dafidi ṣẹ́gun àwọn ará Filistini

(H)Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi ààmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn. Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti Àfonífojì Refaimu; 10 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé: “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?”

Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”

11 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Perasimu, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dafidi lórí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Perasimu. 12 Àwọn ará Filistini sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dafidi sì pa á láṣẹ láti jó wọn nínú iná.

13 (I)Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ará Filistini gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì, 14 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì tún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, Má ṣe gòkè tààrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká kí ẹ sì mú wọn níwájú igi muliberi. 15 Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró ẹsẹ̀ ní orí òkè igi muliberi, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fihàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini. 16 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini láti gbogbo ọ̀nà Gibeoni lọ sí Geseri.

17 Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dafidi tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rù rẹ̀.

Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalẹmu

15 (J)Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un. Nígbà náà Dafidi wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé.

Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀:

Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati;

Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Merari;

Asaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

Àádóje nínú àwọn ọmọ Gerṣoni;

Joeli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

Igba nínú àwọn ọmọ Elisafani;

Ṣemaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hebroni;

Elieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

10 Méjìléláàdọ́fà nínú àwọn ọmọ Usieli;

Amminadabu olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

11 Dafidi sì ránṣẹ́ pe Sadoku, Abiatari tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Urieli, Asaiah. Joeli, Ṣemaiah, Elieli àti Amminadabu tí wọ́n jẹ́ Lefi. 12 Ó sì fi fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un. 13 Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Lefi kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ ko lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀. 14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Israẹli. 15 Nígbà náà ni àwọn Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

16 Dafidi sọ fún àwọn olórí àwọn Lefi láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin olókùn, dùùrù, àti símbálì.

17 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Lefi yan Hemani ọmọ Joeli; àti nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, Asafu ọmọ Bẹrẹkiah, àti nínú àwọn ọmọ Merari arákùnrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah; 18 àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Sekariah, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Unni, Eliabu, Benaiah, Maaseiah, Mattitiah, Elifelehu, Mikimeiah, àti Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn aṣọ́bodè.

19 Àwọn akọrin sì ni Hemani, Asafu, àti Etani ti àwọn ti kimbali idẹ tí ń dún kíkan; 20 Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí alamoti, 21 Àti Mattitiah, Elifelehu, Mikneiah, Obedi-Edomu, Jeieli àti Asasiah ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn gooro, láti darí gẹ́gẹ́ bí ṣeminiti. 22 Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀.

23 Berekiah àti Elkana ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí. 24 Ṣebaniah, Jehoṣafati, Netaneli, Amasai, Sekariah, Benaiah àti Elieseri ní àwọn àlùfáà, tí o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Edomu àti Jehiah ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.

25 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn àgbàgbà Israẹli àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Edomu, pẹ̀lú inú dídùn. 26 Nítorí Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lefi ẹni tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi ṣé ìrúbọ. 27 Dafidi sì wọ efodu; aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ń ru àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn akọrin, àti Kenaniah olórí pẹ̀lú àwọn akọrin. Dafidi sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun. 28 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro.

29 Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa ti ń wọ ìlú ńlá Dafidi, Mikali ọmọbìnrin Saulu ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dafidi ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

Orin ọpẹ́ Dafidi

16 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan.

Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan. Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run.

Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí Olúwa:

(K)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ rẹ̀,
    ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe
Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i,
    Ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀
10 Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́;
    jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.
11 Ẹ wá Olúwa àti agbára rẹ̀;
    E wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

12 Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe,
    iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ.
13 A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀,
    àwọn ọmọ Jakọbu, ẹ̀yin tí ó ti yàn.
14 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa;
    ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

15 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
    ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
16 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
    ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
17 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu,
    gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
18 “Sí ọ, ni Èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani.
    Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.”

19 Nígbà tí wọn kéré ní iye,
    wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,
20 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè
    láti ìjọba kan sí èkejì.
21 Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú;
    nítorí tiwọn, ó bá àwọn ọba wí.
22 “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni ààmì òróró mi;
    Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.”

23 (L)Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé;
    ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.
24 Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.

25 Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ;
    òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ.
26 Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà,
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
27 Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀;
    agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀.

28 Fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,
    ẹ fi ògo àti ipá fún Olúwa.
29 Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;
    gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀.
Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.
30     Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
    Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i.

31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;
    Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”
32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀;
    Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀!
33 Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin,
    Wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa,
    nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé.

34 (M)Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
    ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.
35 (N)Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run Olùgbàlà a wa;
    kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,
    kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.”
36 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,
    láé àti láéláé.

Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé “Àmín,” wọ́n sì “Yin Olúwa.”

37 Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. 38 Ó fi Obedi-Edomu àti méjì-dínláàdọ́rin (68) ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.

39 Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ Olúwa ní ibi gíga ní Gibeoni. 40 Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Olúwa, tí ó ti fún Israẹli. 41 Pẹ̀lú wọn ni Hemani àti Jedutuni àti ìyókù tí a mú àti yàn nípasẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé 42 Hemani àti Jedutuni ni wọ́n dúró fún fífọn ìpè àti Kimbali àti fún lílo ohun èlò yòókù fún orin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Jedutuni wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà.

43 Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀: Dafidi yípadà láti súre fún ìdílé rẹ̀.

Ìlérí Ọlọ́run sí Dafidi

17 (O)Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani wòlíì pé, “Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpépé (igi) ààfin kedari nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wà lábẹ́ àgọ́.”

Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.”

Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé:

“Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé. Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’

“Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi mú ọ kúrò ní pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ kí ó lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi ti wà pẹ̀lú rẹ ní, ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmí sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ tí ó wà ní ayé. Èmi yóò sì pèsè ààyè kan fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, kí wọn kí ó lè ní ilé tiwọn, kí a má sì ṣe dààmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀. 10 Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi pẹ̀lú yóò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá yín.

“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín: 11 Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. 12 Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé. 13 Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀. 14 Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”

15 Natani ròyìn fún Dafidi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn yí.

Àdúrà Dafidi

16 Nígbà náà, ọba Dafidi wọlé lọ, ó sì jókòó níwájú Olúwa ó sì wí pé:

“Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí? 17 Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lójú rẹ, Ọlọ́run. Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàrín àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.

18 “Kí ni ohun tí Dafidi tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ? Nítorí tí ìwọ mọ ìránṣẹ́ rẹ, 19 Olúwa. Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìlérí ńlá yìí hàn.

20 “Kò sí ẹnìkan bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan àfi ìwọ, gẹ́gẹ́ bí à ti gbọ́ pẹ̀lú etí ara wa. 21 Pẹ̀lú ta ni ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli—orílẹ̀-èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti láti ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀, ẹni tí ó gbàlà láti Ejibiti? 22 Ìwọ ṣe àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn.

23 “Nísinsin yìí, Olúwa, Jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ àti ilé rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé. Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe ìlérí. 24 Kí ó lè di fífi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni Ọlọ́run Israẹli.’ Ilé ìránṣẹ́ rẹ Dafidi sì ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.

25 “Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ. 26 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 27 Nísinsin yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìránṣẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀síwájú ní ojú rẹ; nítorí ìwọ, Olúwa, ti bùkún un, a ó sì bùkún un títí láéláé.”

Àwọn ìṣẹ́gun Dafidi

18 (P)Ní àkókò kan, Dafidi kọlu àwọn ará Filistini, ó sì ṣẹ́gun wọn. Ó sì mú Gati àti àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Filistini.

Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.

Síbẹ̀, Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọba Ṣoba ní Hamati, bí ó ti ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Eufurate. Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá-méjì ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà.

Nígbà ti àwọn ará Siria ti Damasku wá láti ran Hadadeseri ọba Ṣoba lọ́wọ́, Dafidi lu ẹgbàá-méjì wọn bọ lẹ̀. Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.

Dafidi mú apata wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu. Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ.

Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Ṣoba. 10 Ó rán ọmọ rẹ̀ Hadoramu sí ọba Dafidi láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun lórí Hadadeseri, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tou. Hadoramu mú oríṣìíríṣìí ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti idẹ wá.

11 Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki.

12 Abiṣai ọmọ Seruiah lu méjì-dínlógojì ẹgbẹ̀rin ará Edomu bolẹ̀ ní Àfonífojì Iyọ̀. 13 Ó fi ẹgbẹ́ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sìn ní abẹ́ Dafidi. Olúwa fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

Àwọn oníṣẹ́ Dafidi

14 (Q)Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

15 Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun;

Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16 Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà;

Safsa jẹ́ akọ̀wé;

17 Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti;

àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.

Dafidi ṣẹ́gun àwọn ara Ammoni

19 (R)Ní àkókò yí, Nahaṣi ọba àwọn ará Ammoni sì kú, ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Dafidi rò wí pé èmi yóò fi inú rere hàn sí Hanuni ọmọ Nahaṣi, nítorí baba a rẹ̀ fi inú rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dafidi rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí Hanuni ní ti baba a rẹ̀.

Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dafidi wá sí ọ̀dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ Àwọn ará Ammoni láti fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí i, Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ammoni sọ fún Hanuni pé, Ṣé ìwọ rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nípa rírán àwọn olùtùnú sí ọ? Ṣé àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti rìn wò àti láti bì í ṣubú, àti láti ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà. Bẹ́ẹ̀ ni Hanuni fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dafidi, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárín ìdí rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.

Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dafidi nípa àwọn ọkùnrin rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, “Dúró ní Jeriko títí tí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ẹ padà wá”.

Nígbà tí àwọn ará Ammoni sì ri pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dafidi, Hanuni àti àwọn ará Ammoni rán ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti Aramu-Naharaimu, Siria Maaka àti Ṣoba. Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Maaka pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Medeba, nígbà tí àwọn ará Ammoni kójọpọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun.

Ní gbígbọ́ eléyìí, Dafidi rán Joabu jáde pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun ọkùnrin tí ó le jà. Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi ìlú ńlá wọn, nígbà tí àwọn ọba tí ó wá, fún rara wọn wà ni orílẹ̀-èdè tí ó ṣí sílẹ̀.

10 Joabu ri wí pé àwọn ìlà ogun wà níwájú àti ẹ̀yìn òun; Bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ogun tí ó dára ní Israẹli, o sì tẹ́ ogun wọn sí àwọn ará Siria. 11 Ó fi ìyókù àwọn ọkùnrin náà sí abẹ́ àkóso Abiṣai arákùnrin rẹ̀, a sì tẹ́ wọn kí wọn dojúkọ àwọn ará Ammoni. 12 Joabu wí pé tí àwọn ará Siria bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ammoni bá le jù fún ọ, nígbà náà èmi yóò gbà ọ́. 13 Jẹ́ alágbára kí ẹ sì jẹ́ kí a jà pẹ̀lú ìgboyà fún àwọn ènìyàn wa àti àwọn ìlú ńlá ti Ọlọ́run wa. Olúwa yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.

14 Nígbà náà Joabu àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀ lọ síwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Siria. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú rẹ̀. 15 Nígbà ti àwọn ará Ammoni ri pé àwọn ará Siria ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin rẹ̀ Abiṣai. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu padà lọ sí Jerusalẹmu.

16 Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Siria rí wí pé àwọn Israẹli ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Siria rékọjá odò Eufurate wá, pẹ̀lú Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun Hadadeseri, tí ó ń darí wọn.

17 Nígbà tí a sọ fún Dafidi nípa èyí, ó pe gbogbo Israẹli jọ wọ́n sì rékọjá Jordani; Ó lọ síwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n. Dafidi fa ìlà rẹ̀ láti bá àwọn ará Siria jagun wọ́n sì dojú ìjà kọ ọ́. 18 Ṣùgbọ́n àwọn ará Siria sálọ kúrò níwájú Israẹli, Dafidi sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ẹgbàá-mẹ́rin ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó pa Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun wọn pẹ̀lú.

19 Nígbà tí àwọn ẹrú Hadadeseri rí i wí pé Israẹli ti borí wọn, wọ́n ṣe àlàáfíà pẹ̀lú Dafidi, wọ́n sì ń sìn ní abẹ́ ẹ rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Siria kò ní ìfẹ́ sí ríran àwọn ará Ammoni lọ́wọ́ mọ́.

Dafidi ṣẹ́gun Rabba

20 (S)(T) Ní àkókò àkọ́rọ̀ òjò, ni ìgbà tí àwọn ọba lọ sí ogun, Joabu ṣamọ̀nà àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun. Ó fi ilẹ̀ àwọn ará Ammoni ṣòfò. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Rabba. Ó sì fi ogun dúró tì í. Ṣùgbọ́n Dafidi dúró sí Jerusalẹmu Joabu kọlu Rabba, ó sì fi sílẹ̀ ní ìparun. Dafidi mú adé kúrò lórí àwọn ọba wọn ìwọ̀n rẹ̀ dàbí i tálẹ́ǹtì wúrà, a sì tò ó jọ pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye. A sì gbé e ka orí Dafidi. Ó kó ọ̀pọ̀ ìkógun láti ìlú ńlá náà. Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké. Dafidi ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ammoni. Nígbà náà, Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ padà sí Jerusalẹmu.

Ogun pẹ̀lú àwọn ará Filistini

(U)Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri pẹ̀lú àwọn ará Filistini, ní àkókò yìí ni Sibekai ará Huṣati pa Sipai, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Refaimu, àti àwọn ará Filistini ni a ṣẹ́gun.

Nínú ogun mìíràn pẹ̀lú àwọn ará Filistini, Elhanani ọmọ Jairi pa Lahmi arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni ti ó ní ọ̀kọ̀ kan tí ó dàbí ọ̀pá ahunṣọ.

Síbẹ̀síbẹ̀ nínú ogun mìíràn, tí ó wáyé ní Gati, ọkùnrin títóbi kan wà tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìka mẹ́fà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rìnlélógún lápapọ̀. Òun pẹ̀lú wá láti Rafa. Nígbà tí ó fi Israẹli ṣẹ̀sín, Jonatani ọmọ Ṣimea, arákùnrin Dafidi sì pa á.

Wọ̀nyí ni ìran ọmọ Rafa ní Gati, wọ́n sì ṣubú sí ọwọ́ Dafidi àti àwọn ọkùnrin rẹ̀.

Dafidi ṣe ètò ìkànìyàn

21 Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì wí fún Joabu àti àwọn olórí àwọn ènìyàn pé, “Lọ kí o ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti Beerṣeba títí dé Dani. Kí o sì padà mú iye wọn fún mi wa, kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.”

Ṣùgbọ́n Joabu dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa kí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọba olúwa mi, gbogbo wọn kì í ha ṣe ìránṣẹ́ olúwa ni? Kí ni ó dé tí olúwa mi ṣe fẹ́ ṣè yìí? Kí ni ó de tí yóò fi mú ẹ̀bi wá sórí Israẹli?”

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí tí Joabu. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu jáde lọ, ó sì la gbogbo Israẹli já, ó sí dé Jerusalẹmu. Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún ọkùnrin tí ń kọ́ idà.

Ṣùgbọ́n Joabu kó àwọn Lefi àti Benjamini mọ́ iye wọn, nítorí àṣẹ ọba jẹ́ ìríra fún un. Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Israẹli.

Nígbà náà Dafidi sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidigidi nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà aṣiwèrè gidigidi.

Olúwa sì fi fún Gadi, aríran Dafidi pé. 10 “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ”

11 Bẹ́ẹ̀ ni Gadi tọ Dafidi wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Yan fún ara rẹ: 12 Ọdún mẹ́ta ìyàn, tàbí ìparun ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́ta idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn angẹli Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Israẹli run.’ Nísinsin yìí ǹjẹ́, rò ó wò, èsì wo ni èmi yóò mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”

13 Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa nísinsin yìí, nítorí tí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi; Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.”

14 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-ààrùn lórí Israẹli, àwọn tí ó ṣubú ní Israẹli jẹ́ ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn. 15 Ọlọ́run sì rán angẹli kan sí Jerusalẹmu láti pa wọ́n run. Ṣùgbọ́n bí angẹli ti ń pa wọ́n run, Olúwa sì wò. Ó sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì wí fún angẹli tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Angẹli Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.

16 Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.

17 Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.”

18 Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi. 19 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ Olúwa.

20 Nígbà tí Arauna sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí angẹli; àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa ará wọn mọ́. 21 Bí Dafidi sì ti dé ọ̀dọ̀ Arauna, Arauna sì wò, ó sì rí Dafidi, ó sì ti ibi ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ jáde, ó sì wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi.

22 Dafidi sì wí fún Arauna pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ìwọ ó sì fi fún mi ni iye owó rẹ̀ pípé, kí a lè dá àjàkálẹ̀-ààrùn dúró lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn.”

23 Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Mú un fún ara rẹ, sì jẹ́ kí olúwa mi ọba kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Wò ó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.”

24 Ṣùgbọ́n ọba Dafidi dá Arauna lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ ní pípé, nítorí èmi kì yóò èyí tí ó jẹ́ tìrẹ fún Olúwa, tàbí láti rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”

25 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi san ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà fún Arauna nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà. 26 Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ọpẹ́. Ó sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi iná dá a lóhùn láti òkè ọ̀run wá lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ sísun.

27 Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí angẹli, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ rẹ̀. 28 Ní àkókò náà nígbà tí Dafidi sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Arauna ará Jebusi, ó sì rú ẹbọ sísun níbẹ̀. 29 Àgọ́ Olúwa tí Mose ti ṣe ní aginjù, àti pẹpẹ ẹbọ sísun wà lórí ibi gíga ní Gibeoni ní àkókò náà. 30 Ṣùgbọ́n Dafidi kò lè lọ síwájú rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ angẹli Olúwa.

22 Nígbà náà Dafidi wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ẹbọ sísun fún Israẹli.”

Ìmúrasílẹ̀ fún ilé tí a kọ́ fún ìsìn Ọlọ́run

Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run. Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n. Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kedari tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Sidoni àti àwọn ará Tire mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari wá fún Dafidi.

Dafidi wí pé, “Ọmọ mi Solomoni ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìrírí, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un”. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.

Nígbà náà ó pe Solomoni ọmọ rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún un Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. (V)Dafidi sì wí fún Solomoni pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńláńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Solomoni, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún Israẹli lásìkò ìjọba rẹ̀. 10 Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’

11 “Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. 12 Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́. 13 Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.

14 “Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé Olúwa ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn. 15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́. 16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

17 Nígbà náà Dafidi pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli láti ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. 18 Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìṣẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú Olúwa àti níwájú àwọn ènìyàn. 19 Nísinsin yìí, ẹ ṣí ọkàn yin páyà àti àyà yín sí àti wá Olúwa Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé Olúwa tí a o kọ́ fún orúkọ Olúwa.”

Àwọn ará Lefi

23 Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli.

Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi. Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlógún (38,000) Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́. Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.

Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.

Àwọn ọmọ Gerṣoni

Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni:

Laadani àti Ṣimei.

Àwọn ọmọ Laadani

Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joeli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.

Àwọn ọmọ Ṣimei:

Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn.

Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.

10 Àti ọmọ Ṣimei:

Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.

11 Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.

Àwọn ará Kohati

12 Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.

13 (W)Àwọn ọmọ Amramu.

Aaroni àti Mose.

A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé. 14 Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.

15 Àwọn ọmọ Mose:

Gerṣomu àti Elieseri.

16 Àwọn ọmọ Gerṣomu:

Ṣubueli sì ni alákọ́kọ́.

17 Àwọn ọmọ Elieseri:

Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́.

Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.

18 Àwọn ọmọ Isari:

Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.

19 Àwọn ọmọ Hebroni:

Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì,

Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.

20 Àwọn ọmọ Usieli:

Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.

Àwọn ará Merari

21 Àwọn ọmọ Merari:

Mahili àti Muṣi.

Àwọn ọmọ Mahili:

Eleasari àti Kiṣi.

22 Eleasari sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.

23 Àwọn ọmọ Muṣi:

Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa 25 Nítorí pé Dafidi ti sọ pé Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé. 26 Àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀. 27 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa. 29 Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùwọ̀n. 30 Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́. 31 Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.

32 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.