Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 1-9

Ìran Adamu títí de Abrahamu

Títí dé ọmọkùnrin Noa

(A)Adamu, Seti, Enoṣi,

Kenani, Mahalaleli, Jaredi,

Enoku, Metusela, Lameki,

Noa.

Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

Àwọn Ọmọ Jafeti

Àwọn ọmọ Jafeti ni:

Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.

Àwọn ọmọ Gomeri ni:

Aṣkenasi, Rifàti àti Togarma.

Àwọn ọmọ Jafani ni:

Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.

Àwọn ọmọ Hamu

Àwọn ọmọ Hamu ni:

Kuṣi, Misraimu, Puti, àti Kenaani.

Àwọn ọmọ Kuṣi ni:

Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Ṣabteka.

Àwọn ọmọ Raama:

Ṣeba àti Dedani.

10 Kuṣi sì bí Nimrodu:

Ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.

11 Misraimu sì bí

Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu, 12 Patrusimu, Kasluhimu, (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.

13 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀,

àti Heti, 14 Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, 15 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, 16 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Ṣemari, àti àwọn ará Hamati.

Àwọn ará Ṣemu.

17 Àwọn ọmọ Ṣemu ni:

Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.

Àwọn ọmọ Aramu:

Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.

18 Arfakṣadi sì bí Ṣela,

Ṣela sì bí Eberi.

19 Eberi sì bí ọmọ méjì:

ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.

20 Joktani sì bí

Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. 21 Hadoramu, Usali, Dikla, 22 Ebali, Abimaeli, Ṣeba. 23 Ofiri, Hafila, àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.

24 Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,

25 Eberi, Pelegi. Reu,

26 Serugu, Nahori, Tẹra:

27 Àti Abramu (tí ń ṣe Abrahamu).

Ìdílé Abrahamu

28 Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli.

Àwọn ọmọ Hagari

29 Èyí ni àwọn ọmọ náà:

Nebaioti àkọ́bí Iṣmaeli: Kedari, Adbeeli, Mibsamu, 30 Miṣima, Duma, Massa, Hadadi, Tema, 31 Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Iṣmaeli.

Àwọn ọmọ Ketura

32 Àwọn ọmọ Ketura, obìnrin Abrahamu:

Simrani, Jokṣani Medani, Midiani Iṣbaki àti Ṣua.

Àwọn ọmọ Jokṣani:

Ṣeba àti Dedani.

33 Àwọn ọmọ Midiani:

Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa.

Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura.

Àwọn Ìran Sara

34 Abrahamu sì jẹ́ baba Isaaki:

Àwọn ọmọ Isaaki:

Esau àti Israẹli.

Àwọn ọmọ Esau

35 Àwọn ọmọ Esau:

Elifasi, Reueli, Jeuṣi, Jalamu, àti Kora.

36 Àwọn ọmọ Elifasi:

Temani, Omari, Sefi, Gatamu àti Kenasi;

láti Timna: Amaleki.

37 Àwọn ọmọ Reueli:

Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa.

Àwọn ènìyàn Seiri ní Edomu

38 Àwọn ọmọ Seiri:

Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri àti Diṣani.

39 Àwọn ọmọ Lotani:

Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.

40 Àwọn ọmọ Ṣobali:

Afiani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.

Àwọn ọmọ Sibeoni:

Aiah àti Ana.

41 Àwọn ọmọ Ana:

Diṣoni.

Àwọn ọmọ Diṣoni:

Hemdani, Eṣbani, Itrani, àti Kerani.

42 Àwọn ọmọ Eseri:

Bilhani, Saafani àti Akani.

Àwọn ọmọ Diṣani:

Usi àti Arani.

Àwọn alákòóso Edomu

43 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:

Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

47 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

48 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀

49 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

50 Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. 51 Hadadi sì kú pẹ̀lú.

Àwọn baálẹ̀ Edomu ni:

baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti 52 baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni. 53 baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, 54 Magdieli àti Iramu.

Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu.

Àwọn ọmọ Israẹli

(B)Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.

Juda

Àwọn ọmọ Hesroni

(C)Àwọn ọmọ Juda:

Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua.

Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.

Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.

(D)Àwọn ọmọ Peresi:

Hesroni àti Hamulu.

Àwọn ọmọ Sera:

Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.

Àwọn ọmọ Karmi:

Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.

Àwọn ọmọ Etani:

Asariah.

Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni:

Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.

Láti ọ̀dọ̀ Ramu ọmọ Hesroni

10 Ramu sì ni baba Amminadabu,

àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.

11 Nahiṣoni sì ni baba Salmoni,

Salmoni ni baba Boasi,

12 Boasi baba Obedi

àti Obedi baba Jese.

13 Jese sì ni baba

Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu,

ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea, 14 Ẹlẹ́kẹrin Netaneli,

ẹlẹ́karùnún Raddai, 15 ẹlẹ́kẹfà Osemu

àti ẹlẹ́keje Dafidi.

16 Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili.

Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli.

17 Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli.

Kalebu ọmọ Hesroni

18 Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀:

Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni.

19 Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un.

20 Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli.

21 Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu.

22 Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi.

23 (Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.)

Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri Baba Gileadi.

24 Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un.

Jerahmeeli ọmọ Hesroni

25 Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni:

Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah. 26 Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu.

27 Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli:

Maasi, Jamini àti Ekeri.

28 Àwọn ọmọ Onamu:

Ṣammai àti Jada.

Àwọn ọmọ Ṣammai:

Nadabu àti Abiṣuri. 29 Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi.

30 Àwọn ọmọ Nadabu

Ṣeledi àti Appaimu. Ṣeledi sì kú láìsí ọmọ.

31 Àwọn ọmọ Appaimu:

Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai.

32 Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai:

Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ.

33 Àwọn ọmọ Jonatani:

Peleti àti Sasa.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli.

34 Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní.

Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha. 35 Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai.

36 Attai sì jẹ́ baba fún Natani,

Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi,

37 Sabadi ni baba Eflali,

Eflali jẹ́ baba Obedi,

38 Obedi sì ni baba Jehu,

Jehu ni baba Asariah,

39 Asariah sì ni baba Helesi,

Helesi ni baba Eleasa,

40 Eleasa ni baba Sismai,

Sismai ni baba Ṣallumu,

41 Ṣallumu sì ni baba Jekamiah,

Jekamiah sì ni baba Eliṣama.

Ìdílé Kalebu

42 Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli:

Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi,

àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.

43 Àwọn ọmọ Hebroni:

Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.

44 Ṣema ni baba Rahamu,

Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu.

Rekemu sì ni baba Ṣammai.

45 Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni,

Maoni sì ni baba Beti-Suri.

46 Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá

Harani, Mosa àti Gasesi,

Harani sì ni baba Gasesi.

47 Àwọn ọmọ Jahdai:

Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafa.

48 Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá

Seberi àti Tirhana.

49 Ó sì bí Ṣaafa baba Madmana,

Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah.

ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.

50 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu.

Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata:

Ṣobali baba Kiriati-Jearimu. 51 Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.

52 Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni:

Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti. 53 Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá.

54 Àwọn ọmọ Salma:

Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori, 55 Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.

Àwọn ọmọ Dafidi

(E)Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni:

Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli;

èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;

Ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un;

ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;

Ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali;

àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.

(F)Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33). Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu:

Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.

Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti, Noga, Nefegi, Jafia, Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.

Àwọn ọba Juda

10 Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu,

Abijah ọmọ rẹ̀,

Asa ọmọ rẹ̀,

Jehoṣafati ọmọ rẹ̀,

11 Jehoramu ọmọ rẹ̀,

Ahasiah ọmọ rẹ̀,

Joaṣi ọmọ rẹ̀,

12 Amasiah ọmọ rẹ̀,

Asariah ọmọ rẹ̀,

Jotamu ọmọ rẹ̀,

13 Ahasi ọmọ rẹ̀,

Hesekiah ọmọ rẹ̀,

Manase ọmọ rẹ̀,

14 Amoni ọmọ rẹ̀,

Josiah ọmọ rẹ̀.

15 Àwọn ọmọ Josiah:

Àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani,

èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu,

ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah,

ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.

16 Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu:

Jekoniah ọmọ rẹ̀,

àti Sedekiah.

Ìdílé ọba lẹ́yìn ìgbèkùn

17 Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn:

Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, 18 Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.

19 Àwọn ọmọ Pedaiah:

Serubbabeli àti Ṣimei.

Àwọn ọmọ Serubbabeli:

Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn. 20 Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi.

21 Àwọn ọmọ Hananiah:

Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Ọbadiah àti ti Ṣekaniah.

22 Àwọn ọmọ Ṣekaniah:

Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.

23 Àwọn ọmọ Neariah:

Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24 Àwọn ọmọ Elioenai:

Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn.

Ìran Juda

Àwọn ọmọ Juda:

Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.

Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati.

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu:

Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.

Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara.

Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara.

Àwọn ọmọ Hela:

Sereti Sohari, Etani, Àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu.

Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.” 10 Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.

11 Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni. 12 Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.

13 Àwọn ọmọ Kenasi:

Otnieli àti Seraiah.

Àwọn ọmọ Otnieli:

Hatati àti Meonotai. 14 Meonotai sì ni baba Ofira.

Seraiah sì jẹ́ baba Joabu,

baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.

15 Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne:

Iru, Ela, àti Naamu.

Àwọn ọmọ Ela:

Kenasi.

16 Àwọn ọmọ Jehaleeli:

Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli.

17 Àwọn ọmọ Esra:

Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni.

Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa.

18 Aya rẹ̀ láti ẹ̀yà Juda sì bí Jaredi baba Gedori, àti Heberi baba Soko àti Jekutieli baba Sanoa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọbìnrin Farao Bitia, ẹni ti Meredi ti fẹ́.

19 Àwọn ọmọ aya Hodiah arábìnrin Nahamu:

Baba Keila ará Garimu, àti Eṣitemoa àwọn ará Maakati.

20 Àwọn ọmọ Ṣimoni:

Amnoni, Rina, Beni-Hanani àti Tiloni.

Àwọn ọmọ Iṣi:

Soheti àti Beni-Soheti.

21 Àwọn ọmọ Ṣela ọmọ Juda:

Eri baba Leka, Lada baba Meraṣa àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń hun aṣọ oníṣẹ́ ní Beti-Aṣibea.

22 Jokimu, ọkùnrin Koṣeba, àti Joaṣi àti Sarafi, olórí ní Moabu àti Jaṣubi Lehemu. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́). 23 Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Netaimu àti Gedera; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba.

Simeoni

24 (G)Àwọn Ọmọ Simeoni:

Nemueli, Jamini, Jaribi, Sera àti Saulu;

25 Ṣallumu sì jẹ́ ọmọ Saulu, Mibsamu ọmọ rẹ̀ Miṣima ọmọ rẹ̀.

26 Àwọn ọmọ Miṣima:

Hamueli ọmọ rẹ̀ Sakkuri ọmọ rẹ̀ àti Ṣimei ọmọ rẹ̀.

27 Ṣimei sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìn-dínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Juda. 28 (H)Wọ́n sì ń gbé ní Beerṣeba, Molada, Hasari-Ṣuali, 29 Àti ní Biliha, àti ní Esemu, àti ní Toladi, 30 Betueli, Horma, Siklagi, 31 Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi, 32 agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún, 33 àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn.

Àti ìtàn ìdílé wọ́n.

34 Meṣobabu àti Jamleki,

Josa ọmọ Amasiah, 35 Joeli,

Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,

36 àti pẹ̀lú Elioenai, Jaakoba, Jeṣohaiah,

Asaiah, Adieli, Jesimieli, Benaiah,

37 àti Sisa ọmọ Ṣifi ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah.

38 Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn.

Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi, 39 Wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn 40 Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

41 Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn. 42 Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri. 43 Wọ́n sì pa àwọn ará Amaleki tí ó kù, àwọn tí ó ti sálà, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

Rubeni

(I)Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí. Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu), àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:

Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi.

Àwọn ọmọ Joeli:

Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀,

Ṣimei ọmọ rẹ̀. Mika ọmọ rẹ̀,

Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀.

Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́.

Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:

Jeieli àti Sekariah ni olórí, àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli.

Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni. Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi.

10 Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi.

Ìdílé Gadi

11 Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka:

12 Joeli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ, Janai, àti Ṣafati ni Baṣani,

13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:

Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje.

14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado ọmọ Busi.

15 Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn.

16 Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn.

17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli.

18 Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà. 19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu. 20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 21 Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún. 22 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn.

Ààbọ̀ Ẹ̀yà Manase

23 Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni.

24 Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn. 25 Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn. 26 Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (ẹ̀mí Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.

Lefi

(J)Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli.

Àwọn ọmọ Amramu:

Aaroni, Mose àti Miriamu.

Àwọn ọmọkùnrin Aaroni:

Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

Eleasari jẹ́ baba Finehasi,

Finehasi baba Abiṣua

Abiṣua baba Bukki,

Bukki baba Ussi,

Ussi baba Serahiah,

Serahiah baba Meraioti,

Meraioti baba Amariah,

Amariah baba Ahitubu

Ahitubu baba Sadoku,

Sadoku baba Ahimasi,

Ahimasi baba Asariah,

Asariah baba Johanani,

10 Johanani baba Asariah.

(Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

11 Asariah baba Amariah

Amariah baba Ahitubu

12 Ahitubu baba Sadoku.

Sadoku baba Ṣallumu,

13 Ṣallumu baba Hilkiah,

Hilkiah baba Asariah,

14 Asariah baba Seraiah,

pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki

15 A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.

16 Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

17 Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:

Libni àti Ṣimei.

18 Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

19 Àwọn ọmọ Merari:

Mahili àti Muṣi.

Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn:

20 Ti Gerṣoni:

Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati

Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀, 21 Joah ọmọkùnrin rẹ̀,

Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀

àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀.

22 Àwọn ìran ọmọ Kohati:

Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀,

Asiri ọmọkùnrin rẹ̀. 23 Elkana ọmọkùnrin rẹ̀,

Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.

24 Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀,

Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.

25 Àwọn ìran ọmọ Elkana:

Amasai, Ahimoti

26 Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀

Nahati ọmọ rẹ̀, 27 Eliabu ọmọ rẹ̀,

Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀

àti Samuẹli ọmọ rẹ̀.

28 Àwọn ọmọ Samuẹli:

Joeli àkọ́bí

àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì.

29 Àwọn ìran ọmọ Merari:

Mahili, Libni ọmọ rẹ̀.

Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.

30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀

àti Asaiah ọmọ rẹ̀.

Ilé ti a kọ́ fún àwọn Olórin

31 Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀. 32 Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:

Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati:

Hemani olùkọrin,

ọmọ Joeli, ọmọ Samuẹli,

34 Ọmọ Elkana ọmọ Jerohamu,

ọmọ Elieli, ọmọ Toha

35 Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana,

ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

36 Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli,

ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah

37 Ọmọ Tahati, ọmọ Asiri,

ọmọ Ebiasafi ọmọ Kora,

38 ọmọ Isari, ọmọ Kohati

ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;

39 Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀:

Asafu ọmọ Bẹrẹkiah, ọmọ Ṣimea,

40 Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah,

ọmọ Malkiah 41 Ọmọ Etini,

ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,

42 Ọmọ Etani, ọmọ Simma,

ọmọ Ṣimei, 43 Ọmọ Jahati,

ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;

44 láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀:

Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi,

ọmọ Malluki, 45 Ọmọ Haṣabiah

ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,

46 Ọmọ Amisi ọmọ Bani,

ọmọ Ṣemeri, 47 Ọmọ Mahili,

ọmọ Muṣi, ọmọ Merari,

ọmọ Lefi.

48 Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run. 49 Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.

50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni:

Eleasari ọmọ rẹ̀. Finehasi ọmọ rẹ̀,

Abiṣua ọmọ rẹ̀, 51 Bukki ọmọ rẹ̀,

Ussi ọmọ rẹ̀. Serahiah ọmọ rẹ̀,

52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀,

Ahitubu ọmọ rẹ̀, 53 Sadoku ọmọ rẹ̀

àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.

54 (K)Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn):

55 A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀. 56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne. 57 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa, 58 Hileni, Debiri, 59 Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.

60 Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.

61 Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.

62 Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.

63 Sebuluni Àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.

64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

65 Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.

66 Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.

67 Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri 68 Jokimeamu, Beti-Horoni. 69 Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

70 Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.

71 Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;

72 Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati 73 Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

74 Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni, 75 Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

76 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

77 Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

78 Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa, 79 Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

80 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu, 81 Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

Isakari

Àwọn ọmọ Isakari:

Tola, Pua, Jaṣubu àti Ṣimroni, mẹ́rin ni gbogbo rẹ̀.

Àwọn ọmọ Tola:

Ussi, Refaiah, Jehieli, Jamai, Ibsamu àti Samuẹli olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dafidi, àwọn ìran ọmọ Tola tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-ẹgbẹ̀ta (22,600).

Àwọn ọmọ, Ussi:

Israhiah.

Àwọn ọmọ Israhiah:

Mikaeli, Ọbadiah, Joeli àti Iṣiah. Gbogbo àwọn márààrún sì jẹ́ olóyè. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá-mẹ́rìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó.

Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Isakari, bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínláàádọ́rin (87,000) ni gbogbo rẹ̀.

Benjamini

Àwọn ọmọ mẹ́ta Benjamini:

Bela, Bekeri àti Jediaeli.

Àwọn ọmọ Bela:

Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn (22,034).

Àwọn ọmọ Bekeri:

Semirahi, Joaṣi, Elieseri, Elioenai, Omri, Jeremoti, Abijah, Anatoti àti Alemeti. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Bekeri Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ó-lé-nígba (20,200) ọkùnrin alágbára.

10 Ọmọ Jediaeli:

Bilhani.

Àwọn ọmọ Bilhani:

Jeuṣi Benjamini, Ehudu, Kenaana, Setamu, Tarṣiṣi àti Ahiṣahari. 11 Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tà-dínlógún ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun.

12 Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri.

Naftali

13 Àwọn ọmọ Naftali:

Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha.

Manase

14 Àwọn ìran ọmọ Manase:

Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi. 15 Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Ṣelofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo. 16 Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu.

17 Ọmọ Ulamu:

Bedani.

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manase.

18 Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila.

19 Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́:

Ahiani, Ṣekemu, Likki àti Aniamu.

Efraimu

20 Àwọn ìran ọmọ Efraimu:

Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀,

Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀.

Tahati ọmọ rẹ̀ 21 Sabadi ọmọ, rẹ̀,

àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀.

Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn 22 Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú. 23 Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà. 24 Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú.

25 Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀,

Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀,

26 Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀,

Eliṣama ọmọ rẹ̀, 27 Nuni ọmọ rẹ̀

àti Joṣua ọmọ rẹ̀.

28 Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò. 29 Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.

Aṣeri

30 Àwọn ọmọ Aṣeri:

Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera.

31 Àwọn ọmọ Beriah:

Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti.

32 Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua.

33 Àwọn ọmọ Jafileti:

Pasaki, Bimhali àti Asifati.

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti.

34 Àwọn ọmọ Ṣomeri:

Ahi, Roga, Jahuba àti Aramu.

35 Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu

Ṣofahi, Imina, Ṣeleṣi àti Amali.

36 Àwọn ọmọ Ṣofahi:

Sua, Haniferi, Ṣuali, Beri, Imra. 37 Beseri, Hodi, Ṣama, Ṣilisa, Itrani àti Bera.

38 Àwọn ọmọ Jeteri:

Jefunne, Pisifa àti Ara.

39 Àwọn ọmọ Ulla:

Arah, Hannieli àti Reṣia.

40 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlá (26,000) ọkùnrin.

Ìtàn Ìdílé láti Ọ̀dọ̀ Baba Ńlá ti Saulu ará Benjamini

Benjamini jẹ́ baba:

Bela àkọ́bí rẹ̀,

Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,

Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀ẹ̀karùnún.

Àwọn ọmọ Bela jẹ́:

Adari, Gera, Abihudi, Abiṣua, Naamani, Ahoa, Gera, Ṣefufani àti Huramu.

Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:

Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu.

A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara. Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Ṣibia, Meṣa, Malkamu, 10 Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé. 11 Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali.

12 Àwọn ọmọ Elipali:

Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.) 13 Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò.

14 Ahio, Ṣasaki, Jeremoti, 15 Sebadiah, Aradi, Ederi 16 Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah.

17 Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi 18 Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali.

19 Jakimu, Sikri, Sabdi, 20 Elienai, Siletai, Elieli, 21 Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.

22 Iṣipani Eberi, Elieli, 23 Abdoni, Sikri, Hanani, 24 Hananiah, Elamu, Anitotijah, 25 Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki.

26 Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah 27 Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu.

28 Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.

29 Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni.

Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka, 30 Àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu, 31 Gedori Ahio, Sekeri 32 Pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.

33 Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.

34 Ọmọ Jonatani:

Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.

35 Àwọn ọmọ Mika:

Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.

36 Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa. 37 Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.

38 Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:

Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Ọbadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.

39 Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki:

Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta. 40 Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin márùn-dínlọ́gọ́jọ ní gbogbo rẹ̀.

Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini.

(L)Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn.

Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Jerusalẹmu

Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn Ìránṣẹ́ ilé Olúwa.

(M)Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́:

Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda.

Àti nínú ará Ṣilo:

Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀.

Ní ti ará Sera:

Jeueli

Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).

Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni:

Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah;

Ibinaiah ọmọ Jerohamu;

Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri;

àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah.

Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.

10 Ní ti àwọn àlùfáà:

Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini;

11 Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

12 Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah;

àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri

13 Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.

14 Ní ti àwọn ará Lefi:

Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari;

15 Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;

16 Ọbadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni;

àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa.

17 Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà:

Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn, 18 ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi.

19 Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé Olúwa.

20 Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

21 Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.

22 Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó-lé-méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn.

Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn. 23 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́. 24 Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. 25 Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje. 26 Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run. 27 Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.

28 Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde. 29 Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn. 30 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀. 31 Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín. 32 Àti nínú àwọn arákùnrin wọn, nínú àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn, láti máa pèsè rẹ̀ ní ọjọọjọ́ ìsinmi.

33 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Lefi dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa, wọn kò sì ṣe lára iṣẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà lọ́sàn, lóru.

34 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Lefi, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.

Ìdílé àti Ìrandíran Saulu

35 Jeieli baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni.

Orúkọ ìyàwó rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka, 36 Pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Abdoni, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu. 37 Gedori, Ahio, Sekariah àti Mikiloti. 38 Mikiloti jẹ́ baba Ṣimeamu, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.

39 Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba a Saulu, àti Saulu baba a Jonatani, àti Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.

40 Ọmọ Jonatani:

Meribu-Baali, tí ó jẹ́ baba Mika:

41 Àwọn ọmọ Mika:

Pitoni. Meleki, Tarea àti Ahasi.

42 Ahasi jẹ́ baba Jada, Jada jẹ́ baba Alemeti, Asmafeti, Simri, sì Simri jẹ́ baba Mosa. 43 Mosa jẹ́ baba Binea; Refaiah jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.

44 Aseli ní ọmọ mẹ́fà, pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:

Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli Ṣeariah, Ọbadiah àti Hanani, gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.