Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 48 - Ẹkun Jeremiah 1

Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí Moabu

48 (A)Ní ti Moabu:

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí:

“Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun.
    A dójútì Kiriataimu, a sì mú un,
    ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.
Moabu kò ní ní ìyìn mọ́,
    ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,
‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’
    Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,
    a ó fi idà lé e yín.
Gbọ́ igbe ní Horonaimu,
    igbe ìrora àti ìparun ńlá.
Moabu yóò di wíwó palẹ̀;
    àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.
Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti,
    wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;
ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu
    igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.
Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín;
    kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù.
Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,
    a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,
Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn
    pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.
Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,
    ìlú kan kò sì ní le là.
Àfonífojì yóò di ahoro
    àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,
    nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
Fi iyọ̀ sí Moabu,
    nítorí yóò ṣègbé,
àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro
    láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.

10 “Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa,
    ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀.

11 “Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá
    bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,
tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì
    kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.
Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,
    òórùn rẹ̀ kò yí padà.
12 Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,”
    ni Olúwa wí,
“nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgò
    tí wọ́n ó sì dà á síta;
Wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo,
    wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.
13 Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi,
    bí ojú ti í ti ilé Israẹli
    nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli.

14 “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘ajagun ni wá,
    alágbára ní ogun jíjà’?
15 A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;
    a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”
    ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
16 “Ìṣubú Moabu súnmọ́;
    ìpọ́njú yóò dé kánkán.
17 Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i ká
    gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.
Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ
    títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’

18 “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,
    kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,
ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni,
    nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run
yóò dojúkọ ọ́
    yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.
19 Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,
    ìwọ tí ń gbé ní Aroeri.
Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà
    ‘kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’
20 Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀.
    Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe!
Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé,
    a pa Moabu run.
21 Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ
    sórí Holoni, Jahisa àti Mefaati,
22 sórí Diboni, Nebo àti Beti-Diblataimu
23 sórí Kiriataimu, Beti-Gamu àti Beti-Meoni,
24 sórí Kerioti àti Bosra,
    sórí gbogbo ìlú Moabu, nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn.
25 A gé ìwo Moabu kúrò,
    apá rẹ̀ dá,”
    ni Olúwa wí.

26 “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí
    nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa,
jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀,
    kí ó di ẹni ẹ̀gàn.
27 Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ?
    Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè
tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́
    nígbàkúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
28 Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta,
    ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu.
Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀
    sí ẹnu ihò.

29 “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu:
    àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀
    àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.
30 Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,”
    ni Olúwa wí,
    “ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan.
31 Nítorí náà, mo pohùnréré
    ẹkún lórí Moabu fún àwọn
ará Moabu ni mo kígbe lóhùn rara
    Mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
32 Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún
    ìwọ àjàrà Sibma.
Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun,
    wọn dé Òkun Jaseri.
Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ,
    ìkórè èso àjàrà rẹ.
33 Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò
    nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu.
Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí;
    kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà,
    wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.

34 “Ohùn igbe wọn gòkè
    láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi,
láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi,
    nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ
35 Ní ti Moabu ni èmi yóò ti fi òpin sí
    ẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gíga
    àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,”
    ni Olúwa wí.
36 “Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè,
ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
    Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé.
37 Gbogbo orí ni yóò pá,
    gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò,
gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́,
    àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.
38 Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé Moabu,
    àti ní ìta rẹ̀,
nítorí èmi ti fọ́ Moabu
    bí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,”
    ni Olúwa wí.
39 “Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú,
    tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún!
Báwo ni Moabu ṣe yí
    ẹ̀yìn padà ní ìtìjú!
Moabu ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti
    ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”
40 Báyìí ni Olúwa wí:
“Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀
    ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu.
41 Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà
Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu
    yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.
42 A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí
    orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa.
43 Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè
    ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,”
    Olúwa wí.
44 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún
    ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn
ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta
    nínú ọ̀fìn ní à ó mú
nínú okùn dídè nítorí tí
    èmi yóò mú wá sórí
Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,”
    Olúwa wí.

45 “Ní abẹ́ òjìji Heṣboni
    àwọn tí ó sá dúró láìní agbára,
nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni,
    àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni,
yóò sì jó iwájú orí Moabu run,
    àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.
46 Ègbé ní fún ọ Moabu!
Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Kemoṣi ṣègbé
a kó àwọn ọmọkùnrin rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjì
    àti àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ sí ìgbèkùn.

47 “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ
    Moabu padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,”
    ni Olúwa wí.

Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí Moabu.

Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí Ammoni

49 (B)Ní ti Ammoni:

Báyìí ni Olúwa wí:

“Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin?
    Israẹli kò ha ní àrólé bí?
Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi?
    Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?
Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,”
    ni Olúwa wí;
“nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun ní Rabba
    tí Ammoni yóò sì di òkìtì ahoro,
gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná.
    Nígbà náà ni Israẹli yóò
lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,”
    ni Olúwa wí.
“Hu, ìwọ Heṣboni
    nítorí Ai tí rún,
kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba!
    Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀.
Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà,
    nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn
    pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.
Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú Àfonífojì rẹ,
    ṣògo nínú Àfonífojì rẹ fún èso?
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́,
    ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé,
    ‘ta ni yóò kò mí lójú?’
Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ
    láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,”
    ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
    Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan
tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,”
    ni Olúwa wí.

Àsọtẹ́lẹ̀ Ní ti Edomu

(C)Nípa Edomu:

Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani?
    Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè?
    Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?
Yípadà kí o sálọ, sápamọ́ sínú ihò,
    ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani,
nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau,
    ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.
Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;
    ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?
Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní
    kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?
10 Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò,
    èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn,
nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́.
    Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti
àwọn ará ilé rẹ yóò parun.
    Wọn kò sì ní sí mọ́.
11 Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀
    èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn.
    Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”

12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un. 13 Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”

14 Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa:
    A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé,
    Ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun.

15 “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di
    kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo;
    ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn.
16 Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú
    ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ;
ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta,
    tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga
síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì;
    láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,”
    ni Olúwa wí.
17 “Edomu yóò di ahoro
    gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì
    fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ
18 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu
    àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú
tí ó wà ní àyíká rẹ,”
    Olúwa wí.
“Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀;
    kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

19 “Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
    Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
    Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí
    Olúwa ní fún Edomu, ohun tí
ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani.
    Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde.
    Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.
21 Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn,
    a ó gbọ́ igbe wọn
    ní Òkun pupa.
22 Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,
    yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra.
Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun
    Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Damasku

23 Nípa Damasku,

“Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,
    wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.
24 Damasku di aláìlera, ó pẹ̀yìndà
    láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a,
ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú, ìrora
    bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.
25 Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;
    ìlú tí mo dunnú sí.
26 Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ
    yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo
àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa
    ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
27 “Èmi yóò fi iná sí odi Damasku,
    yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”

Ọ̀rọ̀ nípa Kedari àti Hasori

28 Nípa Kedari àti ìjọba Hasori èyí ti Nebukadnessari ọba Babeli dojú ìjà kọ:

Èyí ni ohun tí Olúwa sọ:

“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ Kedari,
    kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn run.
29 (D)Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn ni wọn ó kó lọ;
    àgọ́ wọn yóò di ìṣínípò padà
pẹ̀lú gbogbo ẹrù àti ìbákasẹ wọn.
    Àwọn ènìyàn yóò ké sórí wọ́n pé;
    ‘Ẹ̀rù yí káàkiri!’

30 “Sálọ kíákíá!
    Fi ara pamọ́ sí ibi jíjìn, ẹ̀yin olùgbé Hasori,”
    ni Olúwa wí.
    “Nebukadnessari ọba Babeli ti dojú ìjà kọ ọ́.

31 “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ìrọ̀rùn,
èyí tí ó gbé ní àìléwu,”
    Olúwa wí.
“Orílẹ̀-èdè tí kò ní odi tàbí irin,
    àwọn ènìyàn rẹ̀ ń dágbé.
32 Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù
    àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun.
Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́.
    Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,”
    báyìí ní Olúwa wí.
33 “Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn
    akátá, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé,
    kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

Àṣọtẹ́lẹ̀ ní ti Elamu

34 Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda:

35 Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ:

“Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu,
    ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.
36 Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin
    àgbáyé lòdì sí Elamu.
Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin
    àti pé, kò sí orílẹ̀-èdè tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.
37 Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn,
    àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn;
    Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn,
àní, ìbínú gbígbóná mi,”
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
    “Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.
38 Èmi yóò sì gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu,
    èmí yóò sì pa ọba wọn àti ìjòyè wọn run,”
    báyìí ni Olúwa wí.

39 “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ
    Elamu padà láìpẹ́ ọjọ́,”
    báyìí ni Olúwa wí.

Àsọtẹ́lẹ̀ ní ti Babeli

50 (E)Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu wòlíì Jeremiah láti sọ fún ará ilẹ̀ Babeli:

“Ẹ sọ ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde,
    kí ẹ sì gbé àsíá sókè, ẹ kéde rẹ̀
    ẹ má sì ṣe bò ó, wí pé,
‘a kó Babeli,
    ojú tí Beli,
    a fọ́ Merodaki túútúú,
ojú ti àwọn ère rẹ̀,
    a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’
Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò
    sì máa gbóguntì wọ́n.
Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò
    sá kúrò ní ìlú yìí.

“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”
    ni Olúwa wí,
“Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá,
àwọn, àti àwọn ọmọ Juda,
    wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí
    Olúwa Ọlọ́run wọn
Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn
    yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a
darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé,
    tí a kì yóò gbàgbé.

“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,
    àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà,
wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè
    wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,
    wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.
Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ
    àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi
nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé
    òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

“Jáde kúrò ní Babeli,
    ẹ fi ilẹ̀ àwọn ará Kaldea sílẹ̀,
    kí ẹ sì jẹ́ bí òbúkọ níwájú agbo ẹran.
Nítorí pé èmi yóò ru,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè
ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀;
    Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò
    dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo
10 A ó dààmú Babeli, gbogbo
    àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú
ìfẹ́ wọn ṣẹ,”
    ni Olúwa wí.

11 “Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀,
    ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn
fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù,
    ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin.
12 Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ
    yóò sì gba ìtìjú.
Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
    ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá.
13 Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;
    ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.
Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò
    fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

14 “Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli
    àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà.
    Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa.
15 Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà!
    Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀,
níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa,
    gbẹ̀san lára rẹ̀.
    Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.
16 Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli,
    àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè!
Nítorí idà àwọn aninilára
    jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀,
    kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.

17 “Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri,
    kìnnìún sì ti lé e lọ.
Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ,
    àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli
    fa egungun rẹ̀ ya.”

18 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí;

“Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.
19 Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli
    padà wá pápá oko tútù rẹ̀
òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani,
    a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè
    Efraimu àti ní Gileadi
20 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”
    ni Olúwa wí,
“À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli,
ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun;
    àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan
    nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.

21 “Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn
    tí ó ń gbé ní Pekodi.
Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,”
    ni Olúwa
    “Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.
22 Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà
    ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.
23 Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó,
    lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé!
    Báwo ní Babeli ti di ahoro
    ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè.
24 Mo dẹ pàkúté sílẹ̀
    fún ọ ìwọ Babeli,
kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,
    o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.
25 Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde,
    nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun
    ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.
26 Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo,
    sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀,
    ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà,
Kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun,
    ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.
27 Pa gbogbo àwọn akọ màlúù rẹ,
    jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n!
    Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé,
    àkókò ìbẹ̀wò wọn.
28 Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá,
    sì sọ ní Sioni,
Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san,
    ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.

29 “Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli,
    ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà.
Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀
    gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe,
ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga
    Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.
30 Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀
    yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn
ológun lẹ́nu mọ́,”
    Olúwa wí.
31 “Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,”
    ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“nítorí ọjọ́ rẹ ti dé,
    àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.
32 Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò
    sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde.
Èmi yóò tan iná ní ìlú náà,
    èyí tí yóò sì jo run.”

33 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ:

“A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli
    lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú.
Gbogbo àwọn tí ó kó wọn
    nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin
    wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà.
34 Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára,
    Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀.
Yóò sì gbe ìjà wọn jà,
    kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà;
    ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli.

35 “Idà lórí àwọn Babeli!”
    ni Olúwa wí,
“lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli,
    àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.
36 Idà lórí àwọn wòlíì èké
    wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun,
    wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.
37 Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀
    àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀.
Wọn yóò di obìnrin.
    Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀!
38 Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.
    Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,
    àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

39 “Nítorí náà àwọn ẹranko ijù
    pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀,
abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀,
    a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé,
    bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.
40 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba
    Sodomu àti Gomorra
pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,”
    ni Olúwa wí,
    “kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀.

41 “Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá;
    orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń
    gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.
42 Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun,
    wọ́n burú wọn kò sì ní àánú.
Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ.
    Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli.
43 Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,
    ọwọ́ wọn sì rọ,
    ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.
44 Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani
    sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
    Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
    Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
    Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

45 Nítorí náà, gbọ́ ohun tí
    Olúwa sọ nípa Babeli
ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì
    sí Babeli; n ó sì pa
    agbo ẹran wọn run.
46 Ní ohùn igbe ńlá pé;
    a kò Babeli, ilẹ̀ ayé yóò mì tìtì,
a sì gbọ́ igbe náà
    láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

51 Ohùn ti Olúwa wí nìyìí:

“Wò ó èmi yóò ru afẹ́fẹ́ apanirun sókè
    sí Babeli àti àwọn ènìyàn Lebikamai
Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Babeli
    láti fẹ́ ẹ, tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfo;
wọn yóò takò ó ní gbogbo ọ̀nà
    ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.
Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀
    jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀;
má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
    sí, pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
Gbogbo wọn ni yóò ṣubú
    ní Babeli tí wọn yóò sì
    fi ara pa yánnayànna ní òpópónà.
Nítorí pé Juda àti Israẹli ni
    Ọlọ́run wọn tí í ṣe Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn
    kún fún kìkì ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Israẹli.

(F)“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà
    fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Àsìkò àti gbẹ̀san Ọlọ́run ni èyí,
    yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.
(G)Ife wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa;
    ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí.
Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀,
    wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.
Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́;
    Ẹ hu fun un!
Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ,
bóyá yóò le wo ọ́ sàn.

“ ‘À bá ti wo Babeli sàn,
    ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀,
kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè,
    ó ga àní títí dé òfúrufú.’

10 “ ‘Olúwa ti dá wa láre,
    wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa
    Ọlọ́run wa ti ṣe.’

11 “Ṣe ọfà rẹ ní mímú,
    mú apata!
    Olúwa ti ru ọba Media sókè,
nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run.
    Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.
12 Gbé àsíá sókè sí odi Babeli!
    Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí,
ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri,
    ẹ ṣètò àwọn tí yóò sápamọ́
Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde,
    òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.
13 (H)Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀,
    tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé,
    àní àsìkò láti ké ọ kúrò!
14 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀,
    Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú,
    wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ.

15 “Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀,
    o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,
    o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.
16 Nígbà tí ará omi ọ̀run hó
    ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé.
Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,
    ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.

17 “Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ
    tí kò sì ní ìmọ̀, olúkúlùkù
alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀.
    Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn wọn kò ní èémí nínú.
18 Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà,
    nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé.
19 Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí;
    nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo,
àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

20 “Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi,
    ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú,
    èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́.
21 Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;
    èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú
    èmi ó pa awakọ̀
22 Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,
    pẹ̀lú rẹ, mo pa
àgbàlagbà àti ọmọdé,
    Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.
23 Èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ olùṣọ́-àgùntàn,
    àti agbo àgùntàn rẹ̀ túútúú,
èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àjàgà màlúù túútúú,
    èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ túútúú.

24 “Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Babeli àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Sioni,”

    ni Olúwa wí.
25 “Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun
    ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,”
    ni Olúwa wí.
“Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ,
    èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta,
    Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.
26 A kò ní mú òkúta kankan láti
    ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí
fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di
    ahoro títí ayé,”
    Olúwa wí.

27 “Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà!
    Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!
Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀,
    pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́:
    Ararati, Minini àti Aṣkenasi.
Yan olùdarí ogun láti kọlù ú,
    rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú.
28 Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀,
    àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀,
àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.
29 Ilẹ̀ wárìrì síhìn-ín sọ́hùn-ún, nítorí pé
    ète Olúwa, sí Babeli dúró
láti ba ilẹ̀ Babeli jẹ́ lọ́nà
    tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.
30 Gbogbo àwọn jagunjagun
    Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn.
Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin.
    Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun,
    gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.
31 Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn
    láti sọ fún ọba Babeli pé
    gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn.
32 Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́
    ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”

33 Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí:

“Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”

34 “Nebukadnessari ọba Babeli tó jẹ wá run,
    ó ti mú kí ìdààmú bá wa,
ó ti sọ wá di àgbá òfìfo.
    Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì.
Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀,
    lẹ́yìn náà ni ó pọ̀ wá jáde.
35 Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,”
    èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí.
“Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,”
    ni Jerusalẹmu wí.

36 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí:

“Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí
    ohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san,
    èmi yóò mú kí omi Òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ.
37 Babeli yóò parun pátápátá,
    yóò sì di ihò àwọn akátá,
    ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.
38 Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramù
    bí ọmọ kìnnìún.
39 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè,
    èmi yóò ṣe àsè fún wọn,
èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó
    tí wọn yóò máa kọ fun ẹ̀rín,
lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun, wọn kì yóò jí,”
    ni Olúwa wí.
40 “Èmi yóò fà wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn
    tí a fẹ́ pa, gẹ́gẹ́ bí àgbò àti ewúrẹ́.

41 “Báwo ni Ṣeṣaki yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé.
    Irú ìpayà wo ni yóò bá
    Babeli láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!
42 Òkun yóò ru borí Babeli,
    gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Babeli.
43 Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro,
    ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ̀ tí ènìyàn
    kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò.
44 Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli
    àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì.
    Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́.
    Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó.

45 “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀
    ẹ̀yin ènìyàn mi!
Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ!
    Sá fún ìbínú ńlá Ọlọ́run.
46 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú
    tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí
a bá gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa;
    àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí,
òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá
    ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.
47 Nítorí ìgbà náà yóò wá
    dandan nígbà tí èmi
yóò fi ìyà jẹ àwọn
    òrìṣà Babeli, gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì
    gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.
48 Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,
    yóò sì kọrin lórí Babeli:
nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,”
    ni Olúwa wí.

49 “Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli,
    gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.
50 Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró:
    Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè,
    ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”

51 “Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn:
    ìtìjú ti bò wá lójú
    nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

52 “Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
    “tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀:
    àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀
53 Bí Babeli tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run,
    bí ó sì ṣe ìlú olódi ní òkè agbára rẹ,
síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,”
    Olúwa wí.

54 “Ìró igbe láti Babeli,
    àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea!
55 Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ,
    ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀;
    àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.
56 Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀,
    àní sórí Babeli;
a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn:
    nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa,
    yóò san án nítòótọ́.
57 Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí,
    àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀
àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀,
    wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,”
    ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

58 Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá,
    ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun:
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán,
    àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná,
    tí àárẹ̀ sì mú wọn.”

59 Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó. 60 Jeremiah sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Babeli sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sí Babeli. 61 Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 62 Kí ìwọ kí ó sì wí pé, ‘Olúwa ìwọ ti sọ̀rọ̀ sí ibí yí, láti ké e kúrò, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti ènìyàn àti ẹran, nítorí pé yóò di ahoro láéláé.’ 63 (I)Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá parí kíka ìwé yìí tán kí ìwọ kí ó di òkúta mọ́ ọn, kí ó sì sọ ọ́ sí àárín odò Eufurate. 64 Kí ìwọ sì wí pé, ‘Báyìí ní Babeli yóò rì, kí yóò sì tún dìde kúrò nínú ibi tí èmi ó mú wá sórí rẹ̀: àárẹ̀ yóò sì mú wọn.’ ”

Títí dé ìhín ni ọ̀rọ̀ Jeremiah.

Ìṣubú Jerusalẹmu

52 Sedekiah jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọ Jeremiah; láti Libina ló ti wá. (J)Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu àti Juda àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀.

Sedekiah ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.

Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ti Sedekiah tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá Nebukadnessari ọba Babeli sì lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀. Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá ọba Sedekiah.

Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ-ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrín odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Àwọn ará Babeli yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ogun Babeli lépa ọba Sedekiah wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká. Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn.

Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 10 Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda. 11 Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

12 Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàn-dínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu. 13 Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńláńlá. 14 Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 15 Nebusaradani balógun ìṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 16 Ṣùgbọ́n Nebusaradani, balógun ìṣọ́ fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti ro oko.

17 Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, Wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Babeli. 18 Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ. 19 Balógun ìṣọ́ náà kó àwokòtò wọ̀n-ọn-nì, ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti ago wáìnì wọ̀n-ọn-nì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.

20 Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ. 21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́n yìí ni ga ní ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlógún; okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá sì yí i ká. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú. 22 Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra. 23 Pomegiranate mẹ́rìn-dínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranate sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan.

24 Balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ mu Seraiah olórí àwọn àlùfáà àti Sefaniah àlùfáà kejì àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 25 Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú ìwẹ̀fà kan, tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà. 26 Nebusaradani, balógun ìṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 27 Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati.

Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

28 Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.

Ní ọdún keje ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó-lé-mẹ́tàlélógún (3,023) ará Juda.

29 Ní ọdún kejì-dínlógún Nebukadnessari

o kó ẹgbẹ̀rún ó-lé-méjì-dínlọ́gbọ̀n láti Jerusalẹmu.

30 Ní ọdún kẹtàlélógún àwọn Júù

tí Nebusaradani kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín-márùn-ún (745).

Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún.

Ìtúsílẹ̀ Jehoiakimu

31 Ní ọdún kẹtà-dínlógójì ti Jehoiakini ọba Juda ni Efili-Merodaki di ọba Babeli. Ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù kejìlá. 32 Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli. 33 Nítorí náà, Jehoiakini pàrọ̀ aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 34 Ní ojoojúmọ́ ni ọba Babeli ń fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè, títí di ọjọ́ kú rẹ̀.

Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan,
    nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn!
Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    tí ó wà ní ipò opó,
Ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú
    ni ó padà di ẹrú.

Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò
    pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.
Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
    kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀
    wọ́n ti di alátakò rẹ̀.

Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,
    Juda lọ sí àjò
Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.
Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́
    ibi tí kò ti le sá àsálà.

Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀,
    nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn.
Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro,
    àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn,
àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú,
    òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.

Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,
    nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,
Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́
    nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,
    ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.

Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé
    kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni.
    Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín
tí kò rí ewé tútù jẹ;
    nínú àárẹ̀ wọ́n sáré
níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.

Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni
    Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀
    tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.
Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,
    kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un.
Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó
    wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.

Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀
    ó sì ti di aláìmọ́.
Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,
    nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀;
ó kérora fúnrarẹ̀,
    ó sì lọ kúrò.

Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀,
Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;
    olùtùnú kò sì ṣí fún un.
“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,
    nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”

10 Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé
    gbogbo ìní rẹ;
o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè
    tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—
àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀
    láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

11 Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora
    bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;
wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ
    láti mú wọn wà láààyè.
“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó,
    nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”

12 “Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín?
    Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá,
Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà
    tí a fi fún mi, ti
Olúwa mú wá fún mi
    ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.

13 “Ó rán iná láti òkè
    sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.
Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,
    ó sì yí mi padà.
Ó ti pa mí lára
    mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.

14 “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà;
    ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀.
Wọ́n ti yí ọrùn mi ká
    Olúwa sì ti dín agbára mi kù.
Ó sì ti fi mí lé
    àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.

15 “Olúwa kọ
    àwọn akọni mi sílẹ̀,
ó rán àwọn ológun lòdì sí mi
    kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run.
Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́
    àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda.

16 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún
    tí omijé sì ń dà lójú mi,
Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi,
    kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.
Àwọn ọmọ mi di aláìní
    nítorí ọ̀tá ti borí.”

17 Sioni na ọwọ́ jáde,
    ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un.
Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu
    pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un
Jerusalẹmu ti di
    ohun aláìmọ́ láàrín wọn.

18 “Olóòtítọ́ ni Olúwa,
    ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.
Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;
    ẹ wò mí wò ìyà mi.
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi
    ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.

19 “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi
    ṣùgbọ́n wọ́n dà mí.
Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi
    ṣègbé sínú ìlú
nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ
    tí yóò mú wọn wà láààyè.

20 Olúwa, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira!
    Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,
ìdààmú dé bá ọkàn mi
    nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.
Ní gbangba ni idà ń parun;
    ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.

21 “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,
    ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.
Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;
    wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.
Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,
    kí wọ́n le dàbí tèmi.

22 “Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ;
    jẹ wọ́n ní yà
bí o ṣe jẹ mí ní yà
    nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Ìrora mi pọ̀
    ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.