Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Luku 20:20 - Johanu 5:47

Sísan owó orí fún Kesari

20 (A)Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́. 21 (B)Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́. 22 Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”

23 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, 24 “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?”

Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”

25 (C)Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

26 Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.

Àjíǹde àti ìgbéyàwó

27 (D)(E) Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í, 28 (F)wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. 29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. 31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. 32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. 33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”

34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. 35 Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. 36 Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde. 37 (G)Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 38 Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.”

39 (H)Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!” 40 (I)Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.

Ọmọ ta ni Jesu n ṣe

41 (J)Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? 42 Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé:

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43 títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’

44 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

45 (K)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, 46 “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; 47 Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”

Oore opó

21 (L)Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra. Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ: Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”

Àwọn ààmì ìkẹyìn ayé

(M)Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹmpili, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, fun Ọlọ́run, Jesu wí pé (N)“Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

(O)Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti ààmì kín ni yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”

(P)Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má bá à mú yín ṣìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kristi náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”

10 (Q)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. 11 Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti ààmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.

12 (R)(S) “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi. 13 (T)Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi. 14 (U)Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. 15 Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú. 16 (V)A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; on ó sì mú kì a pa nínú yín. 17 (W)A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. 18 (X)Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé. 19 (Y)Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.

20 (Z)“Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. 21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. 22 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. 23 (AA)Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 24 (AB)Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.

25 (AC)(AD) “Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27 (AE)Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28 (AF)Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”

29 (AG)Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi; 30 Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́. 31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.

32 (AH)“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. 33 (AI)Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

34 (AJ)“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn. 35 Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé. 36 (AK)Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”

37 (AL)Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili: lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. 38 Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.

Judasi gbà láti da Jesu

22 (AM)Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́. Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn. Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá. Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́. (AN)Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó. Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.

Oúnjẹ alẹ́ Olúwa

(AO)(AP) Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ. (AQ)Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”

10 Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀, 11 kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 12 Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”

13 Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn: wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.

14 (AR)Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀. 15 (AS)Ó sì wí fún wọn pé, “Tinútinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà: 16 (AT)Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”

17 (AU)Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrín ara yín. 18 (AV)Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”

19 (AW)Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín: ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”

20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín. 21 (AX)Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì. 22 Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.” 23 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè láàrín ara wọn, ta ni nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí.

24 (AY)Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. 25 (AZ)Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. 26 (BA)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 27 Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 28 (BB)(BC)Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi. 29 (BD)Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi: 30 (BE)Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”

31 (BF)Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: 32 (BG)Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

33 (BH)Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”

34 Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Peteru, àkùkọ kì yóò kọ lónìí tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”

35 (BI)Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?”

Wọ́n sì wí pé, “Rárá!”

36 (BJ)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò-owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ọ̀kan. 37 (BK)Nítorí mo wí fún yín pé, ‘Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.”

38 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhìn-ín yìí!”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.”

Jesu gbàdúrà lórí òkè olifi

39 (BL)Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 40 (BM)(BN)Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” 41 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. 42 (BO)Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” 43 Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. 44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.

45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. 46 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”

Wọ́n mú Jesu

47 (BP)Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsi i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jesu láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 48 Jesu sì wí fún un pé, “Judasi, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?”

49 (BQ)Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwa fi idà sá wọn?” 50 Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.

51 Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé, “Ko gbọdọ̀ ṣe èyí mọ.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn.

52 Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá? 53 (BR)Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.”

Peteru sẹ́ Jesu

54 (BS)Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. 55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. 56 (BT)Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”

58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”

Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”

59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”

60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! 61 (BU)Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” 62 Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ n gan Jesu

63 (BV)Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. 64 Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” 65 Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.

Jesu níwájú Pilatu àti Herodu

66 (BW)Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, 67 (BX)“Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!”

Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́; 68 Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ). 69 Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”

70 (BY)Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.”

71 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”

23 (BZ)Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pilatu. (CA)Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.”

(CB)Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”

Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”

(CC)Pilatu sì wí fún àwọn olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọkùnrin yìí.”

Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Judea, ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili títí ó fi dé ìhín yìí!”

Nígbà tí Pilatu gbọ́ orúkọ Galili, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Galili. Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ abẹ́ àṣẹ Herodu ni, ó rán an sí Herodu, ẹni tí òun tìkára rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà.

(CD)Nígbà tí Herodu, sì rí Jesu, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ́ ó sá à ti ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ ààmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe. (CE)Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá. 10 Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn kàn án gidigidi. 11 (CF)Àti Herodu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pilatu lọ. 12 Pilatu àti Herodu di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ náà: nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.

13 Pilatu sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ. 14 (CG)Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà: sì kíyèsi i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn. 15 Àti Herodu pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsi i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀. 16 (CH)Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.” 17 (Ṣùgbọ́n kò lè ṣe àìdá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)

18 (CI)Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Baraba sílẹ̀ fún wa!” 19 Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.

20 Pilatu sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ àgbélébùú!”

22 Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kín ni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”

23 (CJ)Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélébùú, ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀. 24 Pilatu sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́. 25 Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

Wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú

26 (CK)Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Simoni ara Kirene, tí ó ń ti ìgbèríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélébùú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jesu. 27 Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún 28 (CL)Ṣùgbọ́n Jesu yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín. 29 Nítorí kíyèsi i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fún ni mu rí!’ 30 Nígbà náà ni

“ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Yí lù wá!”
    Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’

31 Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kín ni a ó ṣe sára igi gbígbẹ?”

32 Àwọn méjì mìíràn bákan náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa. 33 (CM)Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. 34 (CN)Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn.

35 (CO)Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”

36 (CP)Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. 37 Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”

38 Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe:

èyí ni ọba àwọn júù.

39 Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.”

40 Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà? 41 (CQ)Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”

42 Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.”

43 (CR)Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!”

Ikú Jesu

44 (CS)Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́. 45 (CT)Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì, 46 (CU)Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

47 Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!” 48 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé. 49 (CV)Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.

Ìsìnkú Jesu

50 (CW)Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́. 51 Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run. 52 Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu. 53 Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. 54 Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.

55 Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀. 56 (CX)Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórùn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); Wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.

Àjíǹde náà

24 (CY)Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú ìkunra olóòórùn dídùn ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá. Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì. Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jesu Olúwa. Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n: Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn angẹli náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrín àwọn òkú? (CZ)Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili. Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.’ ” Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù. 10 (DA)Maria Magdalene, àti Joanna, àti Maria ìyá Jakọbu, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn aposteli. 11 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́. 12 Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.

Ní ojú ọnà sí Emmausi

13 Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀. 14 Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. 16 (DB)Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.

17 Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”

Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro. 18 Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”

19 (DC)Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, 20 Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú. 21 Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀. 22 Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu: 23 Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè. 24 (DD)Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”

25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́: 26 Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.” 27 (DE)Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.

28 (DF)Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú. 29 Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.

30 (DG)Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn. 31 Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú 32 Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”

33 Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, 34 (DH)Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!” 35 Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.

Jesu fi ara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

36 (DI)Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jesu tìkára rẹ̀ dúró láàrín wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”

37 Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì wárìrì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan. 38 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín? 39 (DJ)Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkára mi ni! Ẹ dì mímú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”

40 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n. 41 Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhìn-ín yìí?” 42 Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè. 43 Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.

44 (DK)Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”

45 Nígbà náà ni ó ṣí wọn ní iyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn. 46 (DL)Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú: 47 (DM)Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ. 48 Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí. 49 (DN)Èmi yóò rán ohun tí Baba mi ṣe ìlérí sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerusalẹmu, títí a ó fífi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”

Ìgòkè re ọ̀run

50 Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Betani, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn. 51 (DO)Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run. 52 (DP)Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀: 53 Wọ́n sì wà ní tẹmpili nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ di ẹran-ara

(DQ)Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe. (DR)Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá. (DS)Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé, (DT)ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.

(DU)Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Johanu. Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀. Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà.

(DV)Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé. 10 Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n. 11 Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á. 12 (DW)Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi ẹ̀tọ́ fún láti di ọmọ Ọlọ́run; 13 (DX)Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.

14 (DY)Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.

15 (DZ)Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ” 16 (EA)Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún. 17 (EB)Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá. 18 (EC)Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, bí kò ṣe òun nìkan, àní ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí òun pàápàá jẹ́ Ọlọ́run, tí ó sì wà ní ìbásepọ̀ tí ó súnmọ́ jùlọ pẹ̀lú baba, òun náà ni ó sì fi í hàn.

Johanu sọ pé òun kì í ṣe Kristi

19 (ED)Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe. 20 (EE)Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kristi náà.”

21 (EF)Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta ha ni ìwọ? Elijah ni ìwọ bí?”

Ó sì wí pé, “Èmi kọ́.”

“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”

Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

22 Ní ìparí wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”

23 (EG)Johanu sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”

24 Ọ̀kan nínú àwọn Farisi tí a rán 25 bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bamitiisi nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kristi, tàbí Elijah, tàbí wòlíì náà?”

26 (EH)Johanu dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi bamitiisi: ẹnìkan dúró láàrín yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀; 27 Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”

28 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.

Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run

29 (EI)Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30 Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31 Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”

32 (EJ)Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33 Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34 Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu àkọ́kọ́

35 (EK)Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 36 Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”

37 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jesu lẹ́yìn. 38 Nígbà náà ni Jesu yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”

Wọ́n wí fún un pé, “Rabbi” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”

39 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”

Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.

40 (EL)Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn. 41 (EM)Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi). 42 (EN)Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu.

Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

Jesu pe Filipi àti Natanaeli

43 (EO)Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

44 Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida. 45 (EP)Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”

46 (EQ)Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?”

Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.”

47 Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”

48 Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”

Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.”

49 (ER)Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.”

50 Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.” 51 (ES)Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn angẹli Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”

Jesu sọ omi di ọtí wáìnì

(ET)Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀, A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà. (EU)Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”

(EV)Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”

Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”

(EW)Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá.

Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.

Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.”

Wọ́n sì gbé e lọ; alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan, 10 Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”

11 (EX)Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ ààmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

Jesu ṣe àfọ̀mọ́ tẹmpili

12 (EY)Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu, Òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

13 (EZ)Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu, 14 (FA)Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nínú tẹmpili wọ́n jókòó: 15 Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú. 16 (FB)Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.” 17 (FC)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

18 (FD)Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Ààmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

19 (FE)Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

20 Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?” 21 (FF)Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀. 22 (FG)Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.

23 Nígbà tí ó sì wà ní Jerusalẹmu, ní àjọ ìrékọjá, lákokò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì tí ó ṣe. 24 Ṣùgbọ́n Jesu kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn. 25 (FH)Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn: nítorí tí o mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.

Jesu kọ́ Nikodemu

(FI)Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisi, tí a ń pè ní Nikodemu, ìjòyè kan láàrín àwọn Júù: (FJ)Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.

(FK)Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”

Nikodemu wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i?

(FL)Jesu dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. (FM)Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni; èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti Ẹ̀mí ni. Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’ (FN)Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”

Nikodemu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”

10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? 11 (FO)Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa. 12 Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín? 13 (FP)Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run. 14 (FQ)Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú: 15 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

16 (FR)“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17 (FS)Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là. 18 Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́. 19 (FT)Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú. 20 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí. 21 (FU)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ ní í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”

Ẹ̀rí Johanu nípa Jesu

22 (FV)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni. 23 Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi. 24 (FW)Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú. 25 Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù. 26 (FX)Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”

27 (FY)Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá. 28 (FZ)Ẹ̀yin fúnrayín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’ 29 (GA)Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.

31 (GB)“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 32 (GC)Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33 Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run. 34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke. 35 Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ 36 (GD)Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”

Jesu sọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin ara Samaria

(GE)Àwọn Farisi sì gbọ́ pé, Jesu ni, ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ ju Johanu lọ, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu tìkára rẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmi bí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.

(GF)Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria. (GG)Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀. Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.

Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi: Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu. Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra oúnjẹ.

(GH)Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)

10 (GI)Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà? 12 Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”

13 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́: 14 (GJ)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

15 (GK)Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

16 Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

17 Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.”

Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: 18 (GL)Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe. 20 (GM)Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

21 (GN)Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. 22 (GO)Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. 23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24 (GP)Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25 Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

26 (GQ)Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pẹ̀lú Jesu

27 Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”

28 Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, 29 (GR)“Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?” 30 Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

31 Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”

32 (GS)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

33 Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”

34 (GT)Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀. 35 (GU)Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ Wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè. 36 Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀. 37 (GV)Nítorí nínú èyí ni ọ̀rọ̀ náà fi jẹ́ òtítọ́: Ẹnìkan ni ó fúnrúgbìn, ẹlòmíràn ni ó sì ń kórè jọ. 38 Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”

Ọ̀pọ̀ ara Samaria gbàgbọ́

39 Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.” 40 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn: ó sì dúró fún ọjọ́ méjì. 41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

42 (GW)Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́: nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”

Jesu wo ọmọkùnrin ọlọ́lá san

43 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Galili. 44 (GX)Nítorí Jesu tìkára rẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ òun tìkára rẹ̀. 45 Nítorí náà nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jerusalẹmu nígbà àjọ ìrékọjá; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.

46 (GY)Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. 47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

48 (GZ)Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”

49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”

50 Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”

Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. 52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”

53 (HA)Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.

54 (HB)Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.

Ìwòsàn ní etí odò adágún

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò; Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. (HC)Adágún omi kan sì wà ní Jerusalẹmu, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Betisaida ní èdè Heberu, tí ó ní ẹnu-ọ̀nà márùn-ún. Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dùbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti aláàrùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi. Nítorí angẹli a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú ààrùnkárùn tí ó ní. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjì-dínlógójì. Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.”

(HD)Jesu wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.” Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn.

Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi. 10 (HE)Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”

11 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”

12 Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”

13 Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jesu ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.

14 (HF)Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!” 15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jesu ni ẹni tí ó mú òun láradá.

Àṣẹ ọmọ Ọlọ́run

16 Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi. 17 (HG)Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” 18 (HH)Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.

19 (HI)Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. 20 (HJ)Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. 21 (HK)Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. 22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: 23 (HL)Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.

24 (HM)“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè. 25 (HN)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè. 26 Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; 27 Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn.

28 “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. 29 (HO)Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́. 30 (HP)Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́ ni, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

Àwọn ẹ̀rí nípa Jesu

31 (HQ)“Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́. 32 Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́.

33 (HR)“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. 34 (HS)Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ́rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là. 35 Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

36 (HT)“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi. 37 Àti Baba tìkára rẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rìí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀. 38 Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́. 39 (HU)Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi. 40 Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè.

41 “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn. 42 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnrayín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín. 43 (HV)Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà. 44 Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?

45 (HW)“Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba: ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mose, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé. 46 Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mose gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́: nítorí ó kọ ìwé nípa tèmi. 47 (HX)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.