Bible in 90 Days
1 Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.
Ìráhùn Habakuku
2 (A)Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,
Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?
Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”
ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
3 Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé
Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?
Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;
ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
4 Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.
Ìdáhùn Olúwa
5 (B)“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,
Kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.
6 (C)Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,
àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn
tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já
láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.
7 Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,
ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,
Yóò máa ti inú wọn jáde.
8 Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,
wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ
àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;
wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun
9 Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá
ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;
wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.
10 Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín
wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.
Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín;
Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á
11 Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,
yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”
Ìráhùn lẹ́ẹ̀kejì Habakuku
12 Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?
Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú
Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;
Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí
13 Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;
ìwọ kò le gbà ìwà ìkà
nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?
Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa
ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?
14 Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,
bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso
15 Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè
ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;
nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
16 Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀
nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn
tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
17 Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,
tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn wòlíì Habakuku
2 (D)Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye
Èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre
Èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi
àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.
Ìdáhùn Olúwa
2 Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé:
“Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀
kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà
kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
3 (E)Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn
kí yóò sìsọ èké.
Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;
nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”
4 (F)“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga;
Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.
5 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi
ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú,
ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,
ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀
ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
7 Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
8 Nítorí ìwọ ti kó orílẹ̀-èdè púpọ̀,
àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀
Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
9 “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,
kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!
10 Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ
11 Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.
12 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,
tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
13 Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé
làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná
kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?
14 Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,
bí omi ti bo Òkun.
15 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,
tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,
kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn”
16 Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú
kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn,
ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,
ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
17 Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́,
àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀
Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;
ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
18 “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,
ère dídá ti ń kọ ni èké?
Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá;
ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
19 Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘di alààyè?’
Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’
Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?
Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká;
kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”
20 (G)Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.
Àdúrà Habakuku
3 Àdúrà wòlíì Habakuku gẹ́gẹ́ bí sígónótì. Ohun èlò orin.
2 Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ;
ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa
sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa,
ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀;
ni ìbínú, rántí àánú.
3 Ọlọ́run yóò wa láti Temani,
ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Parani
ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run,
ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ
4 Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn
ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ,
níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
5 Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ;
ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.
6 Ó dúró, ó sì mi ayé;
ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì
a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká,
àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba:
ọ̀nà rẹ ayérayé ni.
7 Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú
àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora.
8 Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, Olúwa?
Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí?
Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun
tí ìwọ fi ń gun ẹṣin,
àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?
9 A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ,
ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé.
10 Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì
àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ;
ibú ń ké ramúramù
ó sì gbé irú omi sókè.
11 Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn,
pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ,
àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.
12 Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,
ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.
13 Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
àti láti gba ẹni ààmì òróró rẹ là;
Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀
14 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ
nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀
jáde láti tú wá ká:
ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.
15 Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,
ó sì da àwọn omi ńlá ru.
16 Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,
ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;
ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,
ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,
mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú
láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
17 Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,
tí èso kò sí nínú àjàrà;
tí igi olifi ko le so,
àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;
tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,
tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,
18 síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa,
èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.
19 Olúwa Olódùmarè ni agbára mi,
òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín,
yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga.
Sí olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda.
Ìkìlọ̀ fún ìparun tí ń bọ̀
2 “Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò
lórí ilẹ̀ náà pátápátá,”
ni Olúwa wí.
3 “Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko
kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú
ọ̀run kúrò àti ẹja inú Òkun, àti
ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn
ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,”
ni Olúwa wí.
Ìlòdì sí Juda
4 “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda
àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu.
Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà
pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,
5 àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé,
àwọn tí ń sin ogun ọ̀run,
àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,
tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.
6 Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;
Àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.”
7 (H)Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Olódùmarè,
nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.
Olúwa ti pèsè ẹbọ kan sílẹ̀,
ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.
8 “Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa,
Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọn
ọmọ ọba ọkùnrin,
pẹ̀lú gbogbo
àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.
9 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹ
gbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu-ọ̀nà,
tí wọ́n sì kún tẹmpili àwọn ọlọ́run wọn
pẹ̀lú ìwà ipá àti ẹ̀tàn.
10 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja,
híhu láti ìhà kejì wá àti
ariwo ńlá láti òkè kékeré wá.
11 Ẹ hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní (Maktẹsi) agbègbè ọjà,
gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò,
gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun.
12 Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà,
èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,
tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,
àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan
tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’
13 Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun,
àti ilé wọn yóò sì run.
Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n
wọn kì yóò gbé nínú ilé náà,
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,
ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí
wáìnì láti inú rẹ̀.”
Ọjọ́ ńlá Olúwa
14 “Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,
ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀
kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún
àwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,
15 Ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,
ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,
ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro
ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,
ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri,
16 ọjọ́ ìpè àti ìpè ogun
sí àwọn ìlú olódi
àti sí àwọn ilé ìṣọ́ gíga.
17 “Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí
ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú,
nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa.
Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku
àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.
18 Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn
kì yóò sì le gbà wọ́n là
ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.”
Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná
ìjowú rẹ̀ parun,
nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí
gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé.
Ìpè si Ìrònúpìwàdà
2 Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọ pọ̀
orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú,
2 kí a tó pa àṣẹ náà, kí ọjọ́ náà tó kọjá bí ìyàngbò ọkà,
kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín,
kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín.
3 Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà,
ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pàṣẹ.
Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú,
bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.
Ìlòdì sí Filistia
4 (I)Nítorí pé, a ó kọ Gasa sílẹ̀,
Aṣkeloni yóò sì dahoro.
Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Aṣdodu jáde,
a ó sì fa Ekroni tu kúrò.
5 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun,
ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti;
Ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani,
ilẹ̀ àwọn ara Filistini.
“Èmi yóò pa yín run,
ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.”
6 Ilẹ̀ náà ní etí Òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kereti,
ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn.
7 Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda,
níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran,
Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò
dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́.
Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò,
yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà.
Ìlòdì sí Moabu àti Ammoni
8 (J)“Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu,
àti ẹlẹ́yà àwọn Ammoni,
àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi,
tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn.
9 Nítorí náà, bí Èmi tí wà,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí,
“nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu
àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra,
ibi tí ó kún fún yèrèpè
àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé.
Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn;
àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni
yóò jogún ilẹ̀ wọn.”
10 Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn,
nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà.
11 Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn;
nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run.
Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn,
olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.
12 “Ẹ̀yin Etiopia pẹ̀lú,
a ó fi idà mi pa yín.”
Asiria
13 Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá,
yóò sì pa Asiria run,
yóò sì sọ Ninefe di ahoro,
àti di gbígbẹ bí aginjù.
14 Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ni àárín rẹ̀,
àti gbogbo ẹranko àwọn orílẹ̀-èdè.
Òwìwí aginjù àti ti n kígbe ẹyẹ òwìwí
yóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ́n rẹ̀.
Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé,
ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu-ọ̀nà,
òun yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá kedari sílẹ̀.
15 Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu.
Ó sì sọ fun ara rẹ̀ pé,
“Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi.”
Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́,
ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó!
Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀
yóò fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà,
wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn.
Ọjọ́ iwájú Jerusalẹmu
3 Ègbé ni fún ìlú aninilára,
ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́.
2 Òun kò gbọ́rọ̀ sí ẹnikẹ́ni,
òun kò gba ìtọ́ni,
òun kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa,
bẹ́ẹ̀ ni òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀.
3 Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tí ń ké ramúramù,
àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkookò àṣálẹ́ ni wọn,
wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀.
4 Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga,
wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn.
Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́,
wọ́n sì rú òfin.
5 Olúwa ni àárín rẹ̀ jẹ́ olódodo;
kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà.
Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀,
kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun,
síbẹ̀ àwọn aláìṣòótọ́ kò mọ ìtìjú.
6 “Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́.
Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀.
Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí
ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù,
kò sì ní sí ẹnìkan rárá.
7 Èmi wí fún ìlú náà wí pé
‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi,
ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’
Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò
bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó.
Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara
láti ṣe ìbàjẹ́.
8 Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí,
“títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin;
nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ
kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ
àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn,
àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi.
Nítorí, gbogbo ayé
ni a ó fi iná owú mi jẹ run.
9 “Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́,
nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa,
láti fi ọkàn kan sìn ín.
10 Láti òkè odò Etiopia,
àwọn olùjọsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká,
yóò mú ọrẹ wá fún mi.
11 Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì
nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi,
nígbà náà ni èmi yóò mu
kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn.
Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́
ní òkè mímọ́ mi.
12 Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù
àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀,
wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.
13 Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà
ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké,
bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní
ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.”
14 Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
kígbe sókè, ìwọ Israẹli!
Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,
ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
15 Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì
kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn.
Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ,
Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.
16 Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé,
“Má ṣe bẹ̀rù Sioni;
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
17 Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,
Ó ní agbára láti gbà ọ là.
Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;
Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,
Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”
18 “Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ,
àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀;
àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.
19 Ní àkókò náà
ni èmi yóò dojúkọ àwọn
tí ń ni yín lára,
èmi yóò gba àtiro là,
èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ,
èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní
gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.
20 Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ;
Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé.
Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín
láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé,
nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín
padà bọ sípò ní ojú ara yín,”
ni Olúwa wí.
Ìpè láti tún ilé Olúwa kọ́
1 Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà.
2 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé Olúwa.’ ”
3 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé: 4 “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnrayín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”
5 Ní ṣinṣin yìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. 6 Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”
7 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. 8 Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí. 9 “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀. 10 Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde. 11 Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”
12 Nígbà náà ni Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hagai, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa.
13 Nígbà náà ni Hagai ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni Olúwa wí. 14 Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn, 15 ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dariusi.
Ẹwà Tẹmpili tuntun náà
2 Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai wí pé: 2 “Sọ fún Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 3 ‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín? 4 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni Olúwa wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà;’ ni Olúwa wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 5 ‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’
6 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. 7 Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 8 ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 9 ‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
Ìbùkún fún àwọn ènìyàn tí a sọ di àìmọ́
10 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hagai wá pé: 11 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé: 12 Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan àkàrà tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ”
Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
13 Nígbà náà ni Hagai wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?”
Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”
14 Nígbà náà ni Hagai dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni Olúwa wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olúkúlùkù iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rú ẹbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.
15 “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili Olúwa. 16 Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òṣùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀. 17 Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí. 18 ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa lélẹ̀, rò ó dáradára: 19 Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan.
“ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ”
Serubbabeli òrùka èdìdì Olúwa
20 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé: 21 “Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé. 22 Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run; Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”
23 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
Ìpè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
1 Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé:
2 “Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. 3 Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn: Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí Ọ̀dọ̀ mi,’ Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 4 Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé: Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí. 5 Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọ́n ha wà títí ayé? 6 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?
“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”
Ènìyàn láàrín àwọn igi miritili
7 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Bẹrẹkiah ọmọ Iddo wá, pé.
8 Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà.
9 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?”
Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”
10 Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”
11 Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”
12 Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?” 13 Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.
14 Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. 15 Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’
16 “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’
17 “Máa ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”
Ìwo mẹ́rin àti alágbẹ̀dẹ mẹ́rin
18 Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin. 19 Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”
Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.”
20 Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí. 21 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?”
O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Juda ká, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sókè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orílẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sórí ilẹ̀ Juda láti tú ènìyàn rẹ̀ ká.”
Okùn ìwọ̀n ti Jerusalẹmu
2 Mó si tún gbé ojú mi, sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀. 2 Mo sí wí pé, “Níbo ni ìwọ ń lọ?”
O sí wí fún mí pé, “Láti wọn Jerusalẹmu, láti rí iye ìbú rẹ̀, àti iye gígùn rẹ̀.”
3 Sì kíyèsi i, angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, angẹli mìíràn si jáde lọ pàdé rẹ̀. 4 Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú Jerusalẹmu bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun ọ̀sìn inú rẹ̀. 5 Olúwa wí pé, Èmí ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrín rẹ̀.’
6 “Wá! Wá! Sá kúrò ni ilẹ̀ àríwá, ni Olúwa wí; nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín káàkiri,” ni Olúwa wí.
7 “Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, ìwọ Sioni, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Babeli gbé.” 8 Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀. 9 Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.
10 “Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni: Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 11 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi: èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ. 12 Olúwa yóò sì jogún Juda ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jerusalẹmu. 13 (K)Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”
Aṣọ mímọ́ fún olórí àlùfáà
3 Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i. 2 (L)Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”
3 A sì wọ Joṣua ni aṣọ èérí, ó sì dúró níwájú angẹli náà. 4 Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.”
Ó sì wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo mú kí àìṣedéédéé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”
5 Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn sì fi gèlè mímọ́ wé e lórí, wọn sì fi aṣọ wọ̀ ọ́. Angẹli Olúwa sì dúró tì í.
6 Angẹli Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Joṣua pé: 7 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní ààyè láti rìn láàrín àwọn tí ó dúró yìí.
8 “ (M)‘Gbọ́, ìwọ Joṣua olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jókòó níwájú rẹ: nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n: nítorí kíyèsi i, èmi yóò mú ìránṣẹ́ mi, Ẹ̀ka náà wá. 9 Nítorí kíyèsi i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Joṣua; lórí òkúta kan ni ojú méje wà: kíyèsi i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.
10 (N)“ ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’ ”
Ọ̀pá fìtílà wúrà àti àwọn igi olifi méjì
4 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, 2 Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”
Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀: 3 (O)Igi olifi méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.”
4 Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?”
5 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”
6 Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
7 “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 9 “Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.
10 (P)“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli.
“(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síhìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”
11 Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”
12 Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”
13 Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.”
14 Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”
Ìwé kíkà ti n fò
5 Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò.
2 Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”
Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”
3 Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé: nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀. 4 ‘Èmi yóò mú un jáde,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké: yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”
Obìnrin nínú agbọ̀n
5 Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wo nǹkan tí yóò jáde lọ.”
6 Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?”
Ó sì wí pé, “Èyí ni òṣùwọ̀n tí ó jáde lọ.” Ó sì wí pé, “Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”
7 Sì kíyèsi i, a gbé tálẹ́ǹtì òjé sókè: obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárín àpẹẹrẹ òṣùwọ̀n. 8 Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà búburú.” Ó sì ti sí àárín òṣùwọ̀n: ó sì ju ìdérí òjé sí ẹnu rẹ̀.
9 Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, obìnrin méjì jáde wá, ẹ̀fúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀: Wọ́n sì gbé àpẹẹrẹ òṣùwọ̀n náà dé àárín méjì ayé àti ọ̀run.
10 Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n náà lọ.”
11 Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀-èdè Babeli láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣetán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”
Kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́rin tí ìdájọ́ Ọlọ́run
6 (Q)Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárín òkè ńlá méjì, àwọn òkè-ńlá náà sì jẹ́ òkè-ńlá idẹ. 2 Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní; àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì. 3 Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin. 4 Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni ìwọ̀nyí, olúwa mi.”
5 (R)Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé. 6 Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde lọ si ìwọ̀-oòrùn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúúsù.”
7 Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn bá a lè rìn síhìn-ín sọ́hùn-ún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé!” Wọ́n sì rín síhìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé.
8 Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá.”
Adé fún Joṣua
9 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 10 “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Heldai, tí Tobiah, àti ti Jedaiah, tí ó ti Babeli dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Josiah ọmọ Sefaniah lọ. 11 Kí o sì mú fàdákà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. 12 (S)Sì sọ fún un pé: ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹmpili Olúwa wa. 13 Òun ni yóò sì kọ́ tẹmpili Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jẹ ọba lórí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrín àwọn méjèèjì.’ 14 Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Helemu àti fún Tobiah, àti fún Jedaiah, àti fún Heni ọmọ Sefaniah fún ìrántí ni tẹmpili Olúwa. 15 Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹmpili Olúwa, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yin yóò bá gbà ohùn Olúwa, Ọlọ́run yín gbọ́ nítòótọ́.”
Òdodo àti àánú, kì í ṣe àwẹ̀
7 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán. 2 Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere Olúwa. 3 Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”
4 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, 5 “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún? 6 Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí? 7 Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ”
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekariah wá, wí pé: 9 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀. 10 Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’
11 “Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́. 12 Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
13 “ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 14 ‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dahoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjá tàbí kí ó padà bọ̀: wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dahoro.’ ”
Ọlọ́run ṣe ìpinnu láti bùkún Jerusalẹmu
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá.
2 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńláńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńláńlá ni mo fi jowú fún un.”
3 Báyìí ni Olúwa wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”
4 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. 5 Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”
6 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
7 Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. 8 Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”
9 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili. 10 Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
12 “Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò ṣo èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí. 13 Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”
14 Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà. 15 “Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù. 16 (T)Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.
18 Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.
19 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”
20 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀. 21 Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’ 22 Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere Olúwa.”
23 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”
Ìdájọ́ lórí àwọn ọ̀tá Israẹli
9 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀:
Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hadiraki,
Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀;
nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn,
àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli.
2 Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀
Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi.
3 Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀,
ó sì kó fàdákà jọ bí eruku,
àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro.
4 Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ,
yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun,
a ó sì fi iná jó o run.
5 Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;
Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi,
àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í.
Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀,
Aṣkeloni yóò sì di ahoro.
6 Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu,
Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò.
7 Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀,
àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀:
ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa,
wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda,
àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi.
8 Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká
nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri,
kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́:
nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.
Ọba sioni ń bọ̀
9 (U)Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
Wo ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ:
òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà;
ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
10 Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu,
àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu,
a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun.
Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí.
Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun,
àti láti odò títí de òpin ayé.
11 Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ,
Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.
12 Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí:
àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì.
13 Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le,
mo sì fi Efraimu kún un,
Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni,
sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki,
mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.
Olúwa yóò farahàn
14 Olúwa yóò sì fi ara hàn ní orí wọn;
ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná.
Olúwa Olódùmarè yóò sì fọn ìpè,
Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù.
15 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n;
wọn ó sì jẹ ni run,
wọn ó sì tẹ òkúta kànnàkànnà mọ́lẹ̀;
wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì,
wọn ó sì kún bí ọpọ́n,
wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ.
16 Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà
bí agbo ènìyàn rẹ̀:
nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé,
tí a gbé sókè bí ààmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.
17 Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀!
Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá,
àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
Olúwa yóò gba Juda
10 Ẹ béèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa;
Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná,
tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn,
fún olúkúlùkù koríko ní pápá.
2 Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán,
àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké,
wọn sì tí rọ àlá èké;
wọ́n ń tu ni nínú lásán,
nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn,
a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́-àgùntàn kò sí.
3 “Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran,
èmi o sì jẹ àwọn olórí ní yà
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀,
ilé Juda wò,
yóò sì fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.
4 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni èèkàn àgọ́ tí wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.
5 Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin
alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun,
nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn,
wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.
6 “Èmi o sì mú ilé Juda ní agbára,
èmi o sì gba ilé Josẹfu là,
èmi ó sì tún mú wọn padà
nítorí mo tí ṣàánú fún wọn,
ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tì í ta wọ́n nù;
nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn,
èmi o sì gbọ́ tiwọn
7 Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára,
ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì:
àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í,
wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.
8 Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ;
nítorí èmi tí rà wọ́n padà;
wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí
wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.
9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè:
síbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jíjìn;
wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn,
wọn ó sì tún padà.
10 Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti
pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Asiria:
èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi àti Lebanoni; a
a kì yóò sì rí ààyè fún wọn bí ó ti yẹ.
11 Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já,
yóò sì bori rírú omi nínú Òkun,
gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ,
a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀,
ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò.
12 Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa;
wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.