Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Bible in 90 Days

An intensive Bible reading plan that walks through the entire Bible in 90 days.
Duration: 88 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Ìṣe àwọn Aposteli 16:38-28:16

38 Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàájọ́: ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Romu ni Paulu àti Sila. 39 Wọ́n sì wá, wọ́n ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà. 40 Paulu àti Sila sì jáde nínú túbú, wọ́n sì wọ ilé Lidia lọ: nígbà tí wọn sì tí rí àwọn arákùnrin, wọ́n tù wọ́n nínú, wọn sì jáde kúrò.

Ní Tẹsalonika

17 Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà: Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.

Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.

Ní Berea

10 Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ. 11 Àwọn Júù Berea sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalonika lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé mímọ́ lójoojúmọ́ bí nǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀. 12 Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Giriki ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin ti kì í ṣe díẹ̀.

13 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalonika mọ̀ pé, Paulu ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Berea, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè. 14 Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun: ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea. 15 Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

Ní Ateni

16 Nígbà tí Paulu dúró dè wọ́n ni Ateni, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà. 17 Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sinagọgu, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́. 18 Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Epikure ni àti tí àwọn Stoiki kó tì í. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí oníwàásù àjèjì òrìṣà, Wọ́n sọ èyí nítorí Paulu ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu àti àjíǹde fún wọn.” 19 Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Areopagu, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ tuntun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? 20 Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá sí etí wa: àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.” 21 Nítorí gbogbo àwọn ará Ateni, àti àwọn àjèjì tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí kí a máa gbọ́ ohun tuntun lọ.

22 Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọpọ̀. 23 Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí:

fún ọlọ́run àìmọ̀.

Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.

24 (A)“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́; 25 Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn. 26 Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn; 27 Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa: 28 Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’

29 “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀. 30 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà; 31 Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”

32 Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, “Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀.” 33 Bẹ́ẹ̀ ni Paulu sì jáde kúrò láàrín wọn. 34 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́: nínú àwọn ẹni tí Dionisiu ara Areopagu wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Damari àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn.

Ní Kọrinti

18 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Paulu jáde kúrò ni Ateni lọ sí Kọrinti. Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Akuila, tí a bí ni Pọntu, tí ó ti Itali dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Priskilla aya rẹ̀; nítorí tí Kilaudiu pàṣẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Romu. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn. Nítorí tí òun náà jẹ́ oníṣẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì ń ṣiṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ó sì ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nínú Sinagọgu lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Giriki lọ́kàn padà.

Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà. Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn mi mọ́: láti ìsinsin yìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.”

Ó sì lọ kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ọkùnrin kan tí a ń pé ní Titu Justu, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sinagọgu tímọ́tímọ́. Krisipu, olórí Sinagọgu, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀: àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọrinti, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitiisi wọn.

(B)Olúwa sì sọ fún Paulu lóru ni ojúran pé, “Má bẹ̀rù, ṣá máa sọ, má sì ṣe pa ẹnu rẹ̀ mọ́: 10 Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.” 11 Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdún kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrín wọn.

12 Nígbà tí Gallioni sì jẹ baálẹ̀ Akaia, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dìde sí Paulu wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́. 13 Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.”

14 Nígbà tí Paulu ń fẹ́ dáhùn, Gallioni wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹ̀yin Júù; 15 Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnrayín; nítorí tí èmi kò fẹ́ ṣe onídàájọ́ nǹkan báwọ̀nyí.” 16 Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́. 17 Gbogbo àwọn Giriki sì mú Sostene, olórí Sinagọgu, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gallioni kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí.

Priskilla, Akuila àti Apollo

18 Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea: nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́. 19 Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Efesu, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀. 20 Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀. 21 Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì lọ kúrò láti Efesu. 22 Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Kesarea, ó gòkè lọ si Jerusalẹmu láti kí ìjọ, lẹ́yìn náà ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Antioku.

23 Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀, ó n lọ, láti káàkiri ni agbègbè Galatia àti Frigia, o ń mu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le.

24 Júù kan sì wà tí a ń pè ni Apollo, tí a bí ni Alekisandiria, ó wá sí Efesu. Ó ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀; 25 Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu dáradára; kìkì bamitiisi tí Johanu ní ó mọ̀. 26 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sinagọgu. Nígbà tí Akuila àti Priskilla gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀, wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.

27 Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Akaia, àwọn arákùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kí wọ́n gbà á: nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ púpọ̀. 28 Nítorí tí o sọ àsọyé fún àwọn Júù ní gbangba, ó ń fi í hàn nínú ìwé mímọ́ pé, Jesu ni Kristi.

Paulu ní Efesu

19 Nígbà ti Apollo wà ni Kọrinti, ti Paulu kọjá lọ sí apá òkè ìlú, ó sì wá sí Efesu: o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan; o wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mí Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.”

Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamitiisi wo ni a bamitiisi yín sí?”

Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitiisi tí Johanu.”

Paulu sí wí pé, “Nítòótọ́, ní Johanu fi bamitiisi tí ìrònúpìwàdà bamitiisi, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kristi Jesu.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa. Nígbà tí Paulu sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá.

Nígbà tí ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi. 10 Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki.

11 Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu, 12 tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.

13 Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.” 14 Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù. 15 Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?” 16 Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.

17 Ìròyìn yìí sì di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Giriki pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Efesu; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jesu Olúwa ga. 18 Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn. 19 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń ṣe alálúpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣírò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n ìwọ̀n fàdákà. 20 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbèrú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi.

21 Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.” 22 Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia.

Ìrúkèrúdò ní Efesu

23 Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà. 24 Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà; 25 Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa. 26 Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run. 27 Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.”

28 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi ti ará Efesu!” 29 Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ọkàn kan rọ́ wọn sí inú ilé ìṣeré, wọ́n sì mú Gaiu àti Aristarku ara Makedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu nínú ìrìnàjò. 30 Nígbà ti Paulu sì ń fẹ́ wọ àárín àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un. 31 Àwọn olórí kan ara Asia, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ìṣeré náà.

32 Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíràn: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọpọ̀. 33 Àwọn kan nínú àwùjọ Júù ti Aleksanderu síwájú, wọn si pàṣẹ fun láti sọ̀rọ̀. Ó juwọ́ sí wọn láti dákẹ́ kí ó ba lè wí tẹnu rẹ̀ fun àwọn ènìyàn. 34 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi tí ará Efesu!”

35 Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú Efesu ní í ṣe olùsìn Artemisi òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Jupiteri bọ́ sílẹ̀? 36 Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìkanra ṣe ohunkóhun. 37 Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀-òdì sí òrìṣà wa. 38 Ǹjẹ́ nítorí náà tí Demetriusi, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn asọ̀ kan sí ẹnikẹ́ni, ilé ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídàájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn. 39 Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́. 40 Nítorí àwa ṣa wà nínú ewu, nítorí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lónìí yìí; kò ṣáá ní ìdí kan tí rògbòdìyàn yìí fi bẹ́ sílẹ̀, nítorí èyí àwa kì yóò lè dáhùn fún ìwọ́jọ yìí.” 41 Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.

Paulu kọjá ní Makedonia àti Giriki

20 Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí Makedonia. Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Giriki. Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ. Sopateru ará Berea ọmọ Pirusi sì bá a lọ dé Asia, àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti Sekundu, àti Gaiu ará Dabe, àti Timotiu; Tikiku àti Tirofimu ará Asia.

A jí Eutiku dìde nínú òkú ní Troasi

Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Troasi. Àwa sì ṣíkọ̀ láti Filipi lọ lẹ́yìn àjọ àìwúkàrà, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Troasi ni ọjọ́ méje.

Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́. Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú. 10 Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.” 11 Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. 12 Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ìdágbére Paulu sí àwọn Alàgbà Efesu

13 Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Asosi, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Paulu sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ. 14 Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Asosi, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Miletu. 15 Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu. 16 Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti.

17 Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 18 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà. 19 Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù: 20 Bí èmí kò ti fàsẹ́yìn láti sọ ohunkóhun tí ó ṣàǹfààní fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. 21 Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Giriki pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi Olúwa wa.

22 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerusalẹmu, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀: 23 Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi. 24 Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

25 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrín ẹni tí èmi tí ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́. 26 Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo. 27 Nítorí tí èmi kò fàsẹ́yìn láti sọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin. 28 Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábojútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà. 29 Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárín yín, yóò sì tú agbo ká. 30 Láàrín ẹ̀yin tìkára yín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn. 31 Nítorí náà ẹ máa ṣọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.

32 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́. 33 Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni. 34 Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi. 35 Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”

36 Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà. 37 Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 38 Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.

Sí Jerusalẹmu

21 Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, àti gba ibẹ̀ lọ sí Patara: A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀. Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀. Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà. Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn.

Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan. Ní ọjọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesarea; nígbà tí á sì wọ ilé Filipi efangelisti tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀.

10 Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Agabu. 11 Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”

12 Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 13 Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” 14 Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”

15 Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 16 Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kesarea bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Munasoni ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Saipurọsi, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa yóò dé sí.

Dídé Paulu sí Jerusalẹmu

17 Nígbà tí a sì dé Jerusalẹmu, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá, 18 Ní ọjọ́ kejì, a bá Paulu lọ sọ́dọ̀ Jakọbu; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrín àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.

20 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. 21 Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. 22 Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. 23 Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe: Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́; 24 Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́. 25 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti àgbèrè.”

26 Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn.

A mú Paulu

27 Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un. 28 Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ̀lú ó sì mú àwọn ará Giriki wá sínú tẹmpili, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.” 29 Nítorí wọ́n tí rí Tirofimu ará Efesu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Paulu mú wá sínú tẹmpili.

30 Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. 31 Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. 32 Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu.

33 Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. 34 Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. 35 Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. 36 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”

Ọ̀rọ̀ Paulu níwájú àwọn ènìyàn

37 Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Paulu wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?”

Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Giriki bí? 38 Ìwọ ha kọ ní ara Ejibiti náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ sí ijù?”

39 Ṣùgbọ́n Paulu sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tarsu ìlú Kilikia, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi síbẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”

40 Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́ rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wí pé: 22 “Ẹ̀yin ará àti baba, ẹ gbọ́ tí ẹnu mi nísinsin yìí.”

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Aramaiki, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́.

Nígbà náà ni ó wí pé: “Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tarsu ìlú kan ní Kilikia, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì ní ìtara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní. (C)Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin tobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú, àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Damasku láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerusalẹmu, láti jẹ wọ́n ní yà.

“Bí èmi tí súnmọ́ etí Damasku níwọ̀n ọjọ́-kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká. Mo sì ṣubú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún mi pé, ‘Saulu, Saulu èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’

“Mo sì béèrè pé, ‘Ta ni ìwọ, Olúwa?’

“Ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Èmi ni Jesu tí Nasareti, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.’ Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà nítòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.

10 “Mo sí béèrè pé, ‘Kín ni kí èmí kí ó ṣe, Olúwa?’

“Olúwa sì wí fún mi pé, ‘Dìde, kí o sì lọ sí Damasku; níbẹ̀ ni a ó sì ti sọ ohun gbogbo fún ọ tí a yàn fún ọ láti ṣe.’ 11 Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Damasku lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú.

12 “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Anania tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀. 13 Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Saulu, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì ṣí ojú sí òkè mo sì lè rí i.

14 “Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni Òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀. 15 Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́. 16 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè? Dìde, kí a sì bamitiisi rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pe orúkọ rẹ̀.’

17 “Nígbà tí mo padà wá sí Jerusalẹmu tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹmpili, mo bọ́ sí ojúran, 18 mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerusalẹmu kánkán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’

19 “Èmi sì wí pé, ‘Olúwa, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá mọ̀ pé èmi ti lọ láti inú Sinagọgu kan sí èkejì láti máa sọ wọ́n sínú túbú àti láti máa lu àwọn tí ó gbà ọ́ gbọ́. 20 Nígbà tí a sì ta ẹ̀jẹ̀ Stefanu ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, èmi náà pẹ̀lú dúró níbẹ̀, mo sì ní ohùn sí ikú rẹ̀, mo sì ń ṣe ìtọ́jú aṣọ àwọn ẹni tí ó pa á.’

21 “Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, ‘Máa lọ: nítorí èmi ó rán ọ sí àwọn aláìkọlà lókèèrè réré.’ ”

Paulu ọmọ ìbílẹ̀ Romu

22 Wọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Paulu títí tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà yìí ni wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì kígbe wí pé, “Ẹ mu ẹni yìí kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láààyè!”

23 Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run, 24 olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Paulu wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun ba à lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀. 25 Bí wọ́n sí tí fi ọṣán dè é, Paulu bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Romu ni àìdálẹ́bi bí?”

26 Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Romu ní i ṣe?”

27 Alábojútó-ogun sì dé, ó sì bí Paulu pé, “Sọ fún mi, ará Romu ni ìwọ jẹ́ bí?”

Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

28 Alábojútó-ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.”

Paulu wí pé, “Ṣùgbọ́n a bí mi sínú rẹ̀ ni.”

29 Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fàsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: lójúkan náà. Olórí ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Romu ní Paulu i ṣe, àti nítorí ó tí dè é.

Níwájú àwọn ìgbìmọ̀

30 Ní ọjọ́ kejì, nítorí tí olórí ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Paulu sùn sí, ó tú u sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Paulu sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró níwájú wọn.

23 Paulu tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fi di òní yìí.” Nígbà yìí ni Anania olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Paulu pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu. Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”

Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”

(D)Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”

Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.” Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrín àwọn Farisi àti àwọn Sadusi: àjọ sì pín sì méjì. Nítorí tí àwọn Sadusi wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí angẹli, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisi jẹ́wọ́ méjèèjì:

Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisi dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí angẹli kan tàbí ẹ̀mí kan ń ba à sọ̀rọ̀?” 10 Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Paulu má ba à di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrín wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

11 Ní òru ọjọ́ náà Olúwa dúró tì Paulu, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Romu pẹ̀lú.”

Ìdìtẹ̀ láti pa Paulu

12 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Paulu: 13 Àwọn tí ó dìtẹ̀ yìí sì ju ogójì ènìyàn lọ. 14 Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Paulu. 15 Ǹjẹ́ nísinsin yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”

16 Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu.

17 Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ: nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.” 18 Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun.

Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”

19 Alábojútó-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”

20 Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀. 21 Nítorí náà má ṣe gbọ́ tiwọn: nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsin yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”

22 Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”

A gbé Paulu lọ Kesarea

23 Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru. 24 Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.”

25 Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé:

26 Kilaudiu Lisia,

Sí Feliksi baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ:

Àlàáfíà.

27 Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á: nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Romu ni í ṣe. 28 Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn. 29 Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fi sùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n. 30 Nígbà tí a sì tí jí i sọ fún mi pé, wọn yóò dènà de ọkùnrin náà, mo rán an sí ọ lọ́gán, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sọ ohun tí wọ́n bá rí wí sí i níwájú rẹ̀.

31 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gbe Paulu, wọ́n sì mú un lóru lọ si Antipatrisi, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn. 32 Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun. 33 Nígbà tí wọ́n dé Kesarea, tí wọ́n sí fi ìwé fún baálẹ̀, wọ́n mú Paulu pẹ̀lú wá síwájú rẹ̀. 34 Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó béèrè pé agbègbè ìlú wo ni tirẹ̀. Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kilikia ni; 35 Ó wí pé, “Èmi yóò gbọ́ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfisùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì pàṣẹ pé kí wọn pa Paulu mọ́ ní abẹ́ àbojútó àwọn olùṣọ́ ní gbọ̀ngàn ìdájọ́ ààfin Herodu.

Ìpèlẹ́jọ́ níwájú Feliksi

24 Lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún Anania olórí àlùfáà náà sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn alàgbà àti ẹnìkan, Tertulu agbẹjọ́rò, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ẹjọ́ Paulu fún baálẹ̀. Nígbà tí a sí tí pè Paulu jáde, Tertulu gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ níwájú Feliksi ó wí pé: “Àwa ti wà ní àlàáfíà ní abẹ́ ìjọba rẹ láti ìgbà pípẹ́ wá, àti pé ìfojúsùn rẹ ti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí. Ní ibi gbogbo àti ní ọ̀nà gbogbo, Feliksi ọlọ́lá jùlọ, ní àwa ń tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọpẹ́ gbogbo. Ṣùgbọ́n kí èmi má ba á dá ọ dúró pẹ́ títí, mo bẹ̀ ọ́ kí o fi ìyọ́nú rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lẹ́nu wa.

“Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrín gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Nasarene: Ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹmpili jẹ́: ṣùgbọ́n àwa gbá a mú àwa sí fẹ́ bá a ṣe ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin wa. Ṣùgbọ́n Lisia olórí ogun dé, ó fì agbára ńlá gbà á lọ́wọ́ wa: Nígbà tí ìwọ fúnrarẹ̀ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínní lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀sùn rẹ̀ kàn án.”

Àwọn Júù pẹ̀lú sì fi ohùn sí i wí pé, ní òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.

10 Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Paulu sì dáhùn wí pe: “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀tayọ̀ wí tí ẹnu mi. 11 Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerusalẹmu láti lọ jọ́sìn. 12 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn nínú tẹmpili, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú Sinagọgu tàbí ní ibikíbi nínú ìlú: 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsin yìí. 14 Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀lé ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì, 15 mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkára wọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtítọ́, àti tí aláìṣòótọ́. 16 Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí ọkàn tí kò lẹ́sẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo.

17 “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún púpọ̀, mo wá sí Jerusalẹmu láti mu ẹ̀bùn wá fún àwọn ènìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀. 18 Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú ìyẹ̀wù tẹmpili, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ̀nù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárín àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo. 19 Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Asia wà níbẹ̀, àwọn tí ìbá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkóhun sí mi. 20 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tìkára wọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀. 21 Bí kò ṣe tí gbólóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ síta nígbà tí mo dúró láàrín wọn: ‘Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín ló ni yìí!’ ”

22 Nígbà tí Feliksi gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, òye sá à ye é ní àyétán nípa ọ̀nà náà; ó tú wọn ká ná, ó ní, “Nígbà tí Lisia olórí ogun bá sọ̀kalẹ̀ wá, èmi ó wádìí ọ̀ràn yín dájú.” 23 Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó máa ṣe ìtọ́jú Paulu, kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kun láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.

24 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Feliksi pẹ̀lú Drusilla ìyàwó rẹ̀ dé, obìnrin tí í ṣe Júù. Ó ránṣẹ́ pé Paulu, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 25 Bí Paulu sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Feliksi, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsin yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.” 26 Ní àkókò yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Paulu yóò mú owó ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun ba à lè dá a sílẹ̀: nítorí náà, a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkúgbà, a máa bá a sọ̀rọ̀.

27 Lẹ́yìn ọdún méjì, Porkiu Festu rọ́pò Feliksi: Feliksi sì ń fẹ́ ṣe ojúrere fún àwọn Júù, ó fi Paulu sílẹ̀ nínú túbú.

Ìjẹ́jọ́ níwájú Festu

25 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Festu gòkè láti Kesarea lọ sì Jerusalẹmu, ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Paulu wá, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́. Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Festu, kí ó bá le ṣe ojúrere fún wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Paulu wá sí Jerusalẹmu, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà. Ṣùgbọ́n Festu dáhùn pé, “A pa Paulu mọ́ ní Kesarea, àti pé òun tìkára òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”

Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesarea, ni ọjọ́ kejì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Paulu wá síwájú òun. Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Paulu si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹmpili, tàbí sí Kesari.”

Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”

10 Paulu sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kesari níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú. 11 Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí ó ṣe pe mo sì ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú: ṣùgbọ́n bí kò bá sí òtítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fi ọ̀ràn mi lọ Kesari.”

12 Lẹ́yìn tí Festu ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pe, “Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Kesari. Ní ọ̀dọ̀ Kesari ni ìwọ ó lọ!”

Festu wádìí ọ̀rọ̀ níwájú ọba Agrippa

13 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Agrippa ọba, àti Bernike sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesarea láti kí Festu. 14 Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú. 15 Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú.

16 “Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi, kí ẹni tí a fi sùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri ààyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn, 17 Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kejì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá. 18 Nígbà tí àwọn olùfisùn náà dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn. 19 Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jesu kan tí o tí kú, tí Paulu tẹnumọ́ pé ó wà láààyè. 20 Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń ṣe ìwádìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lérè pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu fi ọ̀ràn rẹ lọ Augustu, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pe kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Kesari.”

22 Agrippa wí fún Festu pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkára mi,”

Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.”

Paulu níwájú Agrippa

23 Ní ọjọ́ kejì, tí Agrippa àti Bernike wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀ṣọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Festu pàṣẹ, wọ́n sì mú Paulu jáde. 24 Festu sì wí pé, “Agrippa ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ béèrè lọ́wọ́ mi ni Jerusalẹmu àti Kesarea níhìn-ín yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láààyè mọ́. 25 Ṣùgbọ́n èmi rí i pe, kò ṣe ohun kan tí ó yẹ sí ikú, bí òun tìkára rẹ̀ sí tí fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Augustu, mo tí pinnu láti rán an lọ. 26 Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá síwájú yín, àní síwájú rẹ ọba Agrippa, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí ṣe ìwádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ. 27 Nítorí tí kò tọ́ ní ojú mi láti rán òǹdè, kí a má sì sọ ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn.”

26 Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.”

Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé: “Agrippa ọba, inú èmi tìkára mi dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi kan mi, pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrín àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fi sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.

“Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerusalẹmu. Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi. Nísinsin yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́. Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn. Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde?

(E)“Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti. 10 Èyí ni mo sì ṣe ni Jerusalẹmu. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i. 11 Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú Sinagọgu dé inú Sinagọgu, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn.

12 “Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Damasku pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 13 Ni ọ̀sán gangan, ìwọ ọba Agrippa, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò. 14 Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’

15 “Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’

“Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. 16 (F)Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ: 17 Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí 18 (G)láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

19 “Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà. 20 Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà. 21 Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹmpili, tí wọ́n sì ń fẹ́ pa mí. 22 Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fi di òní, mo ń jẹ́rìí fún èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Mose tí wí pé, yóò ṣẹ: 23 Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

24 Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”

25 Paulu dalóhùn wí pé, “Orí mi kò dàrú, Festu ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde. 26 Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń sọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀. 27 Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

28 Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

29 Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

30 Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Bernike, àti àwọn tí o bá wọn jókòó; 31 Nígbà tí wọn wọ ìyẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n.”

32 Agrippa sì wí fún Festu pé, “A bà dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ bí ó bá ṣe pe kò ì tí ì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Kesari.”

Paulu wọ ọkọ ojú omi lọ sí Romu

27 Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Itali, wọn fi Paulu àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Juliusi, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Augustu. Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa.

Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí a sì kúrò níbẹ̀, a lọ lẹ́bàá Saipurọsi, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì. Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia. Níbẹ̀ ni balógun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-òkun Alekisandiria kan, ti ń lọ sí Itali; ó sì fi wa sínú rẹ̀. Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọ̀kánkán Knidu, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láààyè, a ba ẹ̀bá Krete lọ, lọ́kankán Salmoni; Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Lasea.

Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn. 10 Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.” 11 Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ̀ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Paulu wí lọ. 12 Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fonike, tí i ṣe èbúté Krete ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oòrùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oòrùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.

Ìjì ojú omi

13 Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣe bí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń gba ẹ̀bá Krete lọ. 14 Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà. 15 Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ. 16 Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùṣù kan tí a ń pè Kauda, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjá ààbò. 17 Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri. 18 Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀; 19 Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù. 20 Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

21 Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Paulu dìde láàrín wọn, o wí pé “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Krete, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa. 22 Ǹjẹ́ nísinsin yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí òfò ẹ̀mí nínú yín, bí kò ṣe ti ọkọ̀. 23 Nítorí angẹli Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná. 24 Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Paulu; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Kesari: Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’ 25 Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá: nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi. 26 Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan.”

Rírì ọkọ̀

27 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrín Òkun Adria, láàrín ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ funra pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan: 28 Nígbà tí wọ́n sì wọn Òkun, wọ́n rí i ó jì ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn Òkun, wọn rí i pé ó jì ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 29 Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí ọkọ̀, wọ́n ń retí ojúmọ́. 30 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèkéé kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀. 31 Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!” 32 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gé okùn àwọn ọkọ̀ kéékèèkéé, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣubú sọ́hùn-ún.

33 Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Paulu bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń retí, ti ẹ kò dẹ́kun gbígbààwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun. 34 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín: nítorí irun kan kí yóò gé kúrò lórí ẹnìkan nínú yín.” 35 Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ. 36 Nígbà náà ni gbogbo wọ́n sì dárayá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ, 37 Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-òkun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó-dínmẹ́rin (276). 38 Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-òkun náà fúyẹ́, nípa kíkó alikama dà sí omi.

39 Nígbà tí ilẹ̀ sí mọ́, wọn kò mọ́ ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n wọn rí apá odò kan tí ó ní èbúté, níbẹ̀ ni wọ́n gbèrò, bóyá ó le ṣe é ṣe láti mu ọkọ̀ gúnlẹ̀. 40 Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú Òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbokùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí Òkun. 41 Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí Òkun méjì pàdé, wọn fi orí ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà.

42 Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pa àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sálọ. 43 Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Paulu là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí Òkun lọ sì ilẹ̀. 44 Àti àwọn ìyókù, òmíràn lórí pátákó, àti òmíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ̀.

Erékùṣù ni Mẹlita

28 Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà. Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù. Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́. Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.” Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é. Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.

Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọbiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Ó sì ṣe, baba Pọbiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá. 10 Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.

Paulu dé sí Romu

11 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan èyí tí ó lo àkókò òtútù ní erékùṣù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú omi ti Alekisandiria, èyí tí ààmì rẹ̀ jẹ́ tí òrìṣà ìbejì ti Kasitoru òun Polukisu. 12 Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sirakusi, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 13 Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Regiomu: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Puteoli. 14 A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Romu. 15 Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígba tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le. 16 Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.