Bible in 90 Days
Níwájú Sahẹndiri
57 (A)Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí. 58 Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu.
59 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù péjọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jesu, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un. 60 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.
Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde. 61 (B)Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Èmi lágbára láti wó tẹmpili Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”
62 Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jesu pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?” 63 (C)Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́.
Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”
64 (D)Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”
65 (E)Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?” 66 Ki ni ẹ ti rò èyí sí.
Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”
67 Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú. 68 Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kristi, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”
Peteru sẹ́ Jesu
69 Lákòókò yìí, bí Peteru ti ń jókòó ní àgbàlá, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jesu ti Galili.”
70 Ṣùgbọ́n Peteru sẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”
71 Lẹ́yìn èyí, ní ìta ní ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jesu ti Nasareti.”
72 Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”
73 Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa ààmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”
74 Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.”
Lójúkan náà àkùkọ sì kọ. 75 (F)Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.
Judasi lọ pokùnso
27 (G)Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tún padà láti gbìmọ̀ bí wọn yóò ti ṣe pa Jesu. 2 Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pilatu tí i ṣe gómìnà.
3 (H)(I) Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. 4 Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”
Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”
5 Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.
6 (J)Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7 Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. 8 Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní. 9 (K)Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e. 10 Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.”
Jesu níwájú Pilatu
11 (L)Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”
Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan. 13 Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?” 14 (M)Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu.
15 Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni. 16 Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Jesu Baraba. 17 Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ síwájú ilé Pilatu lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Baraba tàbí Jesu, ẹni tí ń jẹ́ Kristi?” 18 Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́.
19 (N)Bí Pilatu sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu.
21 (O)Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”
Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!”
22 Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?”
Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
23 Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”
Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
24 (P)Nígbà tí Pilatu sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnrayín, ẹ bojútó o!”
25 (Q)Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!”
26 Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.
Àwọn ọmọ-ogun na Jesu
27 (R)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í 28 Wọ́n tú Jesu sì ìhòhò, wọ́n sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ òdòdó, 29 Wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” 30 Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí. 31 Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
A kan Jesu mọ́ àgbélébùú
32 (S)Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kirene tí à ń pè ní Simoni. Wọ́n sì mú ọkùnrin náà ní túláàsì láti ru àgbélébùú Jesu. 33 (T)Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọlgọta, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.) 34 Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 (U)Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. 36 Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀. 37 Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé:
“èyí ni jesu, ọba àwọn júù”
síbẹ̀. 38 Wọ́n kan àwọn olè méjì pẹ̀lú rẹ̀ ní òwúrọ̀ náà. Ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ̀. 39 (V)Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: 40 (W)“Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”
41 Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. 42 Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. 43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?” 44 Bákan náà, àwọn olè tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ fi í ṣe ẹlẹ́yà.
Ikú Jesu
45 (X)Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsànán ọjọ́ 46 (Y)Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, Lama Sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
47 Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yé díẹ̀ nínú àwọn ẹni tí ń wòran, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, Wọ́n wí pé ọkùnrin yìí ń pe Elijah.
48 (Z)Lẹ́sẹ̀kan náà, ọ̀kan nínú wọn sáré, ó mú kànìnkànìn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ inú ọtí kíkan. Ó fi lé orí ọ̀pá, ó gbé e sókè láti fi fún un mu. 49 Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Elijah yóò sọ̀kalẹ̀ láti gbà á là.”
50 Nígbà tí Jesu sì kígbe ní ohùn rara lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀, ó sì kú.
51 (AA)Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán. 52 Àwọn isà òkú sì ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí ó ti sùn sì tún jíǹde. 53 Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jesu, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.
54 (AB)Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sọ Jesu rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe!”
55 Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Galili pẹ̀lú Jesu láti tọ́jú rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè. 56 (AC)Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Maria Magdalene, àti Maria ìyá Jakọbu àti Josẹfu, àti ìyá àwọn ọmọ Sebede méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
A tẹ́ Jesu sínú ibojì
57 (AD)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, 58 lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. 59 Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. 60 Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnrarẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ. 61 Maria Magdalene àti Maria kejì wà níbẹ̀, wọn jókòó òdìkejì ibojì náà.
Àwọn olùṣọ́ ní ibojì
62 Lọ́jọ́ kejì tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ sọ́dọ̀ Pilatu. 63 (AE)Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà àwa rántí pé ẹlẹ́tàn nnì wí nígbà tí ó wà láyé pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’ 64 Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọningbọnin títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe wá jí gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
65 Pilatu sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.” 66 (AF)Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.
Àjíǹde rẹ̀
28 (AG)(AH) Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì.
2 (AI)Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí angẹli Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí. 3 Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. 4 (AJ)Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú.
5 Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 6 Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí. 7 (AK)Nísinsin yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.”
8 Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn. 9 (AL)Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. 10 Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ”
Àwọn olùṣọ́ ròyìn
11 (AM)Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 12 Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. 13 Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ 14 Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.” 15 Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.
Jesu pín iṣẹ́ ńlá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀
16 (AN)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. 17 Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. 18 (AO)Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19 Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. 20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”
Johanu onítẹ̀bọmi tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀
1 Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.
2 (AP)(AQ) Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé:
“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ,
Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
3 (AR)“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
4 (AS)Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. 5 Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 6 Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. 7 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. 8 Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”
Ìtẹ̀bọmi àti ìdánwò Jesu
9 (AT)Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. 11 (AU)Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
12 (AV)Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13 Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
14 (AW)Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. 15 Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.”
16 (AX)Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. 17 Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18 Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
19 Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. 20 Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Jesu lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde
21 (AY)Lẹ́yìn náà, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni. 22 Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn. 23 (AZ)Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, 24 (BA)“Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”
25 Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.” 26 Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.
27 Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrín ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ tuntun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.” 28 Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili.
Jesu mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá
29 (BB)Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. 30 Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. 31 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
32 (BC)Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. 33 Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. 34 Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.
Jesu ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti gbàdúrà
35 (BD)Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu nìkan jáde lọ sí aginjù kan, láti lọ gbàdúrà. 36 Simoni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a. 37 Nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”
38 Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.” 39 (BE)Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
Ọkùnrin tí o ní ààrùn ẹ̀tẹ̀
40 (BF)Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”
41 Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.” 42 Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
43 Jesu sì kìlọ̀ fún un gidigidi 44 (BG)Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.” 45 Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jesu kò sì le wọ ìlú ní gbangba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní aginjù. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.
Jesu wo aláàrùn ẹ̀gbà sàn
2 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jesu tún padà wọ Kapernaumu, òkìkí kàn pé ó ti wà nínú ilé. 2 Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn. 3 (BH)Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé. 4 Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. 5 Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
6 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé, 7 “Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”
8 Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? 9 Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?’ 10 Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé, 11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé àkéte rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.” 12 (BI)Lójúkan náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé àkéte rẹ̀. Ó sì jáde lọ lójú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”
Ìpè Lefi
13 Nígbà náà, Jesu tún jáde lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn. 14 (BJ)Bí ó ti ń rin etí Òkun lọ sókè, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,” Lefi dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.
15 Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e. 16 (BK)Nígbà tí àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èétirí tí ó fi ń bá àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”
17 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Ìbéèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu
18 (BL)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”
19 Jesu dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò ṣe máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó ṣì wà lọ́dọ̀ wọn? 20 (BM)Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.”
21 “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, bí ó ba ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tuntun tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fàya kúrò lára ògbólógbòó, yíya rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù. 22 Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì tuntun sínú ìgò wáìnì ògbólógbòó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a sì dàànù, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”
Olúwa ọjọ́ ìsinmi
23 (BN)(BO) Ó sì ṣe ni ọjọ́ ìsinmi, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrín oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọkà. 24 Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”
25 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò ti ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀? 26 (BP)Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Abiatari olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ àkàrà ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”
27 (BQ)Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, “Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ́ ìsinmi. 28 Nítorí náà Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú.”
3 (BR)Nígbà tí Jesu wá sí Sinagọgu. Sì kíyèsi i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. 2 (BS)Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi. 3 Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”
4 Nígbà náà ni Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.
5 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá. 6 (BT)Lójúkan náà, àwọn Farisi jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jesu.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ̀lé Jesu
7 (BU)Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 8 (BV)Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni. 9 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn èrò sẹ́yìn. 10 (BW)Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló bí ara wọn lù ú láti fi ọwọ́ kàn án. 11 Ìgbàkúgbà tí àwọn tí ó ni ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú ri, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.” 12 (BX)Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.
Jesu yan àwọn aposteli méjìlá
13 (BY)Jesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá. 14 Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù 15 àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.
16 (BZ)Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:
Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)
17 Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).
18 Àti Anderu,
Filipi,
Bartolomeu,
Matiu,
Tomasi,
Jakọbu ọmọ Alfeu,
Taddeu,
Simoni tí ń jẹ́ Sealoti (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù).
19 (CA)Àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.
Jesu àti Beelsebulu
20 (CB)Nígbà náà ni Jesu sì wọ inú ilé kan, àwọn èrò sì tún kórajọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò rí ààyè láti jẹun. 21 (CC)Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mú un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”
22 (CD)(CE) Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”
23 Jesu pè wọ́n, ó sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èṣù ṣe lè lé èṣù jáde? 24 Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀. 25 Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò le è dúró. 26 Bí Èṣù bá sì dìde sí ara rẹ̀, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé. 27 (CF)Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní ẹrù lọ, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀. 28 (CG)Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dáríjì àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀-òdì. 29 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú ewu ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”
30 Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí àìmọ́ ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”
Ìyá àti àwọn Arákùnrin Jesu
31 (CH)Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìyá wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n ń pè é. 32 Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”
33 Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”
34 Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi: 35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”
Òwe afúnrúgbìn
4 (CI)Jesu sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí Òkun Àwọn ìjọ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí Òkun. 2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: 3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. 4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. 5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. 7 Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. 8 Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
9 Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
10 (CJ)Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?” 11 (CK)Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà. 12 (CL)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé,
“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.
Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”
13 (CM)Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín? 14 Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. 15 Àwọn èso tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, ni àwọn ọlọ́kàn líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́. 16 Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 17 Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀. 18 Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. 19 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. 20 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
Àtùpà lórí ọ̀pá fìtílà
21 (CN)Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òṣùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? 22 (CO)Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23 (CP)Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
24 (CQ)Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. 25 (CR)Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún sí i àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”
Òwe irúgbìn tó ń dàgbà
26 (CS)Ó sì tún sọ èyí pé, “Èyí ni a lè fi ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. 27 Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. 28 Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ní orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó. 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”
Òwe musitadi
30 (CT)Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”
33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. 34 (CU)Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.
Jesu mú afẹ́fẹ́ okun dákẹ́ jẹ́ẹ́
35 (CV)Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apá kejì.” 36 Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n sì gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 37 Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì. 38 Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”
39 Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́! Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.
40 Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀?”
41 Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti Òkun ń gbọ́ tirẹ̀!”
Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù
5 (CW)Wọ́n lọ sí apá kejì adágún ní ẹ̀bá ilẹ̀ àwọn ará Gadara. 2 Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. 3 Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. 4 Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. 5 Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
6 Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 7 (CX)Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” 8 Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”
9 Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”
Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” 10 Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.
11 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè. 12 Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jesu pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀n-ọn-nì kí àwa le è wọ inú wọn lọ.” 13 Jesu fún wọn láààyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé.
14 Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sálọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù, tí ó jókòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ ìyè rẹ sì bọ̀ sípò, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 16 Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́, wọ́n si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú. 17 Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jesu pé kí ó fi agbègbè àwọn sílẹ̀.
18 Bí Jesu ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ. 19 Jesu kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.” 20 (CY)Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapoli nípa ohun ńlá tí Jesu ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.
Òkú ọmọbìnrin kan àti obìnrin aláìsàn
21 (CZ)Nígbà tí Jesu sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì Òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí Òkun. 22 (DA)Ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu tí à ń pè ni Jairu wá sọ́dọ̀ Jesu, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 23 (DB)Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.” 24 Jesu sì ń bá a lọ.
Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. 25 Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. 26 Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. 27 Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. 28 Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” 29 Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà.
30 (DC)Lọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?”
31 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”
32 Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun. 33 Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ fún un. 34 (DD)Jesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá: Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.”
35 Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.
36 Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”
37 (DE)Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. 38 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. 39 Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” 40 Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín.
Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. 41 (DF)Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). 42 Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. 43 (DG)Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.
Wòlíì tí kò ní ọlá
6 (DH)Jesu fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ 2 (DI)Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí Sinagọgu láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì ya àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́.
Wọ́n wí pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, tí irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? 3 (DJ)Gbẹ́nàgbẹ́nà náà kọ́ yìí? Ọmọ Maria àti arákùnrin Jakọbu àti Josẹfu, Judasi àti Simoni? Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí?” Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀.
4 Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrín àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá.” 5 (DK)Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrín wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn.
Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá jáde
6 (DL)Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jesu lọ sí àárín àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn. 7 (DM)(DN)Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.
8 O sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò ìgbànú, tàbí owó lọ́wọ́. 9 Wọn kò tilẹ̀ gbọdọ̀ mú ìpààrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́. 10 Jesu wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe sípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà. 11 (DO)Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.”
12 (DP)Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn. 13 (DQ)Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.
A bẹ́ Johanu onítẹ̀bọmi lórí
14 (DR)Láìpẹ́, ọba Herodu gbọ́ nípa Jesu, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi jíǹde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ.”
15 Àwọn mìíràn wí pé, “Elijah ní.”
Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.”
16 Ṣùgbọ́n nígbà tí Herodu gbọ́ èyí, ó wí pé “Johanu tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.”
17 (DS)Herodu fúnrarẹ̀ sá ti ránṣẹ́ mú Johanu, tìkára rẹ̀ sínú túbú nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya. 18 Johanu sì ti wí fún Herodu pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.” 19 (DT)Nítorí náà ni Herodia ṣe ní sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le ṣe é. 20 (DU)Nítorí Herodu bẹ̀rù Johanu, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòtítọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Herodu ba gbọ́rọ̀ Johanu, ó máa ń dààmú síbẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀.
21 Níkẹyìn Herodia rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Herodu, òun sì pèsè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn ènìyàn pàtàkì ní Galili. 22 Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Herodia wọlé láti jó. Inú Herodu àti àwọn àlejò rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀.
Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.” 23 (DV)Ó sì búra fún un wí pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ.”
24 Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé “Kí ní kí ń béèrè?”
Ó dáhùn pé, “Orí Johanu Onítẹ̀bọmi.”
25 Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Herodu ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Johanu Onítẹ̀bọmi nísinsin yìí nínú àwopọ̀kọ́.”
26 Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìbúra rẹ, àti nítorí àwọn tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un. 27 Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Johanu wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Johanu lórí nínú túbú. 28 Ó sì gbé orí Johanu wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 29 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.
Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn
30 (DW)Àwọn aposteli kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni. 31 Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”
32 (DX)Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́. 33 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tún wá láti ìlú ńlá gbogbo wọn sáré gba etí Òkun, wọ́n ṣáájú wọn gúnlẹ̀ ní èbúté. 34 (DY)Bí Jesu ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.
35 Nígbà tí ọjọ́ sì ti bù lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán. 36 “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”
37 (DZ)Ṣùgbọ́n Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Èyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ ọya oṣù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra àkàrà fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”
38 Jesu tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.”
Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì.”
39 Nígbà náà ni Jesu sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ lórí koríko. 40 Lẹ́sẹ̀kan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọọgọ́rùn-ún. 41 (EA)Nígbà tí ó sì mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ síwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn. 42 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. 43 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú. 44 Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin.
Jesu rìn lórí omi
45 (EB)Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Betisaida. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn. 46 Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà.
47 Nígbà tí ó di alẹ́, ọkọ̀ wà láàrín Òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀. 48 (EC)Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá, 49 ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé iwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lóhùn rara, 50 (ED)nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.
Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” 51 Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n. 52 (EE)Wọn kò sá tó ni òye iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.
53 (EF)Lẹ́yìn tí wọ́n la Òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté. 54 Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀. Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jesu, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n. 55 Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn lórí àkéte wọn wá pàdé rẹ̀. 56 (EG)Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ń ṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárín ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.
Mímọ́ àti àìmọ́
7 (EH)Àwọn Farisi sì péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé, tí ó wá láti Jerusalẹmu, 2 wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́. 3 (Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́. 4 (EI)Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)
5 (EJ)Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun.”
6 (EK)Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:
“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.
7 Ìsìn wọn jẹ́ lásán,
ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’
8 Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.”
9 Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ. 10 (EL)Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’ 11 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí ìyá rẹ̀ mọ́. 13 Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”
14 Lẹ́yìn náà, Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín. 15 Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. 16 Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”
17 (EM)Nígbà tí Jesu sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa. 18 (EN)Jesu béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́? 19 Nítorí tí kò lọ sínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n sínú ara, a sì yà á jáde, a sì gbá gbogbo oúnjẹ dànù.” (Nípa sísọ èyí, Jesu fihàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)
20 (EO)Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọ ni di aláìmọ́. 21 Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, 22 (EP)ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọtaraẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. 23 Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”
Ìgbàgbọ́ obìnrin ará Kenaani
24 (EQ)Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri. 25 Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. 26 Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
27 Jesu sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
28 Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ èérún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì.”
29 “Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”
30 Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
Ìwòsàn ọkùnrin odi àti afọ́jú
31 (ER)Nígbà náà ni Jesu fi agbègbè Tire àti Sidoni sílẹ̀, ó wá si Òkun Galili láàrín agbègbè Dekapoli. 32 (ES)Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, àwọn ènìyàn sì bẹ Jesu pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e.
33 (ET)Jesu sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ́ ṣọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀. 34 Nígbà náà ni Jesu wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Efata!” (èyí ni, “Ìwọ ṣí!”). 35 Lójúkan náà, etí rẹ̀ sì ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ketekete.
36 (EU)Jesu pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó. 37 Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́rọ̀, odi sì sọ̀rọ̀.”
Jesu bọ́ ẹgbàajì ènìyàn
8 (EV)Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 2 Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ. 3 Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”
4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?”
5 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?”
Wọ́n fèsì pé, “ìṣù àkàrà méje.”
6 Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 7 Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà. 8 Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún. 9 Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì (4,000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jesu wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dalmanuta.
11 (EW)Àwọn Farisi tọ Jesu wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ́n béèrè fún ààmì láti ọ̀run. 12 Jesu mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá ààmì? Lóòótọ́ ni mo sọ fún un yín kò si ààmì tí a ó fi fún ìran yín.” 13 (EX)Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà.
Ìwúkàrà àwọn Farisi àti Herodu
14 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú àkàrà tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù àkàrà kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn. 15 (EY)Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi àti ìwúkàrà Herodu.”
16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrín ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni?”
17 (EZ)Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni. 18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí? 19 (FA)Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?”
Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”
20 (FB)“Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì (4,000) pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?”
Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”
21 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéha ti ṣe tí kò fi yé yin?”
Ìwòsàn ọkùnrin afọ́jú ní Betisaida
22 (FC)(FD) Nígbà tí wọ́n dé Betisaida, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn. 23 (FE)Jesu fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsin yìí?”
24 Ọkùnrin náà wo àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”
25 Nígbà náà, Jesu tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere. 26 Jesu sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹ́ni ní ìlú.”
Peteru jẹ́wọ́ ẹni tí Kristi jẹ́
27 (FF)Nísinsin yìí, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Galili. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Kesarea-Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”
28 (FG)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Elijah tàbí àwọn wòlíì mìíràn ni ó tún padà wá sáyé.”
29 Ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mí pè?”
Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.”
30 (FH)Ṣùgbọ́n Jesu kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni.
Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀
31 (FI)Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde. 32 Jesu bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Peteru pe Jesu sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.
33 (FJ)Jesu yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Peteru pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Satani, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”
Ọ̀nà sí àgbélébùú
34 (FK)Nígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn. 35 (FL)Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là. 36 Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? 37 Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? 38 (FM)Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”
9 (FN)Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títí yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”
Ìparadà
2 (FO)(FP) Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn. 3 (FQ)Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan ní ayé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀. 4 Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu.
5 Peteru sì wí fún Jesu pé, “Rabbi, ó dára fún wa láti máa gbé níhìn-ín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” 6 Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìbá sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
7 (FR)Ìkùùkuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”
8 Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkankan mọ́, bí kò ṣe Jesu nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.
9 (FS)(FT) Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú. 10 Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí.
11 (FU)Nísinsin yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin ń sọ wí pé, “Elijah ní yóò kọ́kọ́ dé.”
12 (FV)Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Elijah yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 13 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Elijah ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.