Bible in 90 Days
A mú Stefanu
8 Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ ààmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn. 9 Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń ṣe ara Sinagọgu, tí a ń pè ní Libataini. Àwọn Júù Kirene àti ti Alekisandiria àti ti Kilikia, àti ti Asia wá, wọ́n ń bá Stefanu jiyàn, 10 ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.
11 Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Stefanu ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mose àti sí Ọlọ́run.”
12 Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀. 13 Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tiwọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin. 14 Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jesu ti Nasareti yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mose fi fún wa padà.”
15 Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.
Ọ̀rọ̀ Stefanu sí àwọn àjọ ìgbìmọ̀
7 Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí pé, “Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí?”
2 (A)Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani. 3 (B)Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.’
4 (C)“Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kaldea, ó sì ṣe àtìpó ni Harani. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí. 5 (D)Kò sí fún un ni ìní kan, ànító bi ìwọ̀n ààyè ẹsẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀ ìní náà fún un àti fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ. 6 (E)Ọlọ́run sì sọ báyìí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 7 (F)Ọlọ́run wí pé, Orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde kúrò, wọn ó sì wá sìn mí níhìn-ín yìí.’ 8 (G)Ó sì fún Abrahamu ni májẹ̀mú ìkọlà. Abrahamu bí Isaaki, ó kọ ọ́ ní ilà ni ọjọ́ kẹjọ tí ó bí i. Isaaki sí bí Jakọbu, Jakọbu sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.
9 (H)(I) “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Josẹfu, wọ́n sì tà á sí Ejibiti; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, 10 (J)ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Josẹfu ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Farao ọba Ejibiti; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Ejibiti àti gbogbo ilé rẹ̀.
11 (K)“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. 12 (L)Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. 13 (M)Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. 14 (N)(O)Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. 15 Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. 16 (P)A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan.
17 (Q)“Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Abrahamu ṣẹ kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbèrú si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Ejibiti. 18 Ṣùgbọ́n ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 19 (R)Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.
20 (S)“Ní àkókò náà ni a bí Mose, (ẹni tí ó dára ní ojú Ọlọ́run) ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀. 21 (T)Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀. 22 A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.
23 (U)“Nígbà tí Mose di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Israẹli ará rẹ̀ wò. 24 Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa: 25 Mose rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀. 26 Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
27 “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ ti Mose sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? 28 Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti lánàá?’ 29 (V)Mose sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Midiani, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.
30 (W)“Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, angẹli Olúwa fi ara han Mose ní ijù, ní òkè Sinai, nínú ọ̀wọ́-iná nínú igbó. 31 Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, 32 Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́.
33 “Olúwa sì wí fún un pé, ‘bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni. 34 Ní rí rí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, Mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’
35 (X)“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè. 36 (Y)Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún.
37 (Z)“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’ 38 (AA)Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.
39 (AB)“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti; 40 (AC)Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ 41 (AD)Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42 Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:
“ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi
ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?
43 Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki,
àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín,
àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n.
Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’
44 (AE)“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. 45 (AF)Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi. 46 (AG)Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu. 47 (AH)Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.
48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:
49 (AI)“ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.
Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?
ni Olúwa wí.
Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?
50 Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’
51 (AJ)“Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́! 52 Ǹjẹ́ ọ̀kan tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa. 53 Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn angẹli ti fi fún ni, tí ẹ kò sì pa á mọ́.”
A sọ Stefanu ní òkúta pa
54 Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i. 55 Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 56 Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”
57 Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, 58 wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.
59 Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60 Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.
8 (AK)Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí ìjọ, wọ́n sì túká
Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli. 2 Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
Filipi ní Samaria
4 Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. 5 Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn. 6 Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ ààmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. 7 Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá. 8 Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
Simoni onídán
9 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Simoni, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaria. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun. 10 Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bu ọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ ńlá.” 11 Wọ́n bu ọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn. 12 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Filipi gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jesu Kristi, a bamitiisi wọn. 13 Simoni tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bamitiisi rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú Filipi, ó wo iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Filipi ṣe, ẹnu sì yà á.
14 Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn. 15 Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́: 16 nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni. 17 Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.
18 Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, 19 ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”
20 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run! 21 Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run. 22 Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́. 23 (AL)Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”
24 Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”
25 Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìhìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.
Filipi àti ìwẹ̀fà Itiopia
26 Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.” 27 Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn, 28 Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah. 29 Ẹ̀mí sì wí fún Filipi pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”
30 Filipi si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah, Filipi sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”
31 Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Filipi kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.
32 (AM)Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:
“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;
àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.
33 Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún:
Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀?
Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”
34 Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?” 35 Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìhìnrere ti Jesu fún un.
36 Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitiisi?” 37 Filipi sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitiisi rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọ́run ni.” 38 Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀. 39 Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀. 40 Filipi sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Asotu, bí ó ti ń kọjá lọ, o wàásù ìhìnrere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesarea.
Ìyípadà Saulu
9 (AN)Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Saulu sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí-èémí ìhalẹ̀-mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí àlùfáà lọ, 2 ó béèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí Sinagọgu tí ń bẹ ní ìlú Damasku pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbá à ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerusalẹmu. 3 Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súnmọ́ Damasku; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí i ká. 4 Ó sì ṣubú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Saulu, Saulu, èéṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”
5 Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?”
Olúwa sì wí pé, “Èmi ni Jesu, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí; (ohùn ìrora ni fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún). 6 Ó sì ń wárìrì, ẹnu sì yà á, ó ni Olúwa, kín ní ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe? Olúwa sì wí fún pé, Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.”
7 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Saulu lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan. 8 Saulu sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Damasku. 9 Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.
10 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Damasku, tí a ń pè ni Anania! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Anania!”
Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”
11 Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Judasi ní Òpópónà Tààrà, kí ó sì béèrè ẹni tí a ń pè ni Saulu, ara Tarsu, sá wò ó, ó ń gbàdúrà. 12 Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Anania, ó wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”
13 Anania sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúròó ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búburú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerusalẹmu. 14 Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”
15 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Máa lọ; nítorí ohun èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Israẹli. 16 Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”
17 Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” 18 Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.
Saulu ní Damasku àti Jerusalẹmu
Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀ 20 Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run. 21 Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.” 22 Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà.
23 Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á 24 (AO)Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á. 25 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.
26 Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni. 27 Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu. 28 Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa. 29 Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a. 30 Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu.
31 Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.
Aenea àti Dọkasi
32 Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida. 33 Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà. 34 Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà. 35 Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.
36 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi; obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe. 37 Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè. 38 Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.”
39 Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà: gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.
40 Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó. 41 Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè. 42 Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́. 43 Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Joppa ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Simoni oníṣọ̀nà-awọ.
Àwọn ìpè Korneliu fún Peteru
10 (AP)Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. 2 Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. 3 Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”
4 Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?”
Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. 5 Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru. 6 Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”
7 Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo. 8 Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa.
Ìran Peteru
9 Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́: 10 Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran. 11 Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀: 12 Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 13 Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.”
14 Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”
15 Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”
16 Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.
Korneliu ránṣẹ́ sí Peteru
17 Bí Peteru sì ti ń dààmú nínú ara rẹ̀ bí òun bá ti mọ̀ ìran tí òun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Korneliu dé. Wọ́n ń béèrè ilé Simoni, wọ́n dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 18 Wọn nahùn béèrè bí Simoni tí a ń pè ní Peteru, wọ̀ níbẹ̀.
19 Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ. 20 Ǹjẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kó ara ró láti bá wọn lọ: nítorí èmi ni ó rán wọn.”
21 Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí rẹ̀ ti ẹ fi wá?”
22 Wọ́n sì wí pé, “Korneliu balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtítọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ angẹli mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” 23 Nígbà náà ni Peteru pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.
Peteru ní ilé Korneliu
Ní ọjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, díẹ̀ nínú àwọn ti o ti gbàgbọ́ ní Joppa sì bá a lọ pẹ̀lú. 24 Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesarea, Korneliu sì ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. 25 Ó sì ṣe bí Peteru ti ń wọlé, Korneliu pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un. 26 Ṣùgbọ́n Peteru gbé e dìde, ó ni, “Dìde ènìyàn ni èmi tìkára mi pẹ̀lú.”
27 Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ. 28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́. 29 Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo béèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”
30 Korneliu sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹsànán ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi. 31 Ó sì wí pé, ‘Korneliu, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run. 32 Ǹjẹ́ ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru; ó wọ̀ ní ilé Simoni aláwọ létí Òkun.’ 33 Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsin yìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”
34 Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 35 Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀. 36 Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo 37 Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Judea, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Galili, lẹ́yìn bamitiisi ti Johanu wàásù rẹ̀. 38 Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
39 “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 40 Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. 41 Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú. 42 Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú. 43 Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”
44 Bí Peteru sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. 45 Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti a ti kọ nílà tí wọ́n bá Peteru wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú. 46 Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo.
Nígbà náà ni Peteru dáhùn wí pé, 47 “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin pe, kí a má bamitiisi àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?” 48 Ó sì pàṣẹ kí a bamitiisi wọn ni orúkọ Jesu Kristi. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ọjọ́ mélòó kan.
Peteru ṣàlàyé nípa àwọn ìhùwàsí rẹ̀
11 Àwọn aposteli àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Judea sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 2 Nígbà tí Peteru sì gòkè wá sí Jerusalẹmu, àwọn ti ìkọlà ń bá a wíjọ́ 3 wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”
4 (AQ)Ṣùgbọ́n Peteru bẹ̀rẹ̀ sí là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé, 5 “Èmi wà ni ìlú Joppa, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi. 6 Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko igbó, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 7 Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Peteru: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’
8 “Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘rara Olúwa! Nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láéláé.’
9 “Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kejì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’ 10 Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.
11 “Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesarea sí mi. 12 Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà: 13 Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí angẹli kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Peteru; 14 ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’
15 “Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe. 16 (AR)Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’ 17 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”
18 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ògo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpìwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”
Ìjọ ní Antioku
19 (AS)Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù. 20 Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa. 21 Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.
22 Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku; 23 Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa. 24 Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
25 Barnaba sì jáde lọ sí Tarsu láti wá Saulu, 26 nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Antioku. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọpọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Antioku ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kristiani.”
27 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá sí Antioku. 28 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Agabu sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Romu. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣèjọba Kilaudiu.) 29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea. 30 Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu.
Peteru bọ́ kúrò ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìyanu
12 Ní àkókò ìgbà náà ni Herodu ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú. 2 Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu. 3 Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà. 4 Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́.
5 Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un.
6 Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. 7 Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.
8 Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” 9 Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. 10 Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
11 Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!”
12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà. 13 Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. 14 Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà.
15 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!”
16 Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n. 17 Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn.
18 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrín àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó dé bá Peteru. 19 Nígbà tí Herodu sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó pàṣẹ pé, kí a pa wọ́n.
Ikú Herodu
Herodu sì sọ̀kalẹ̀ láti Judea lọ sí Kesarea, ó sì wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 20 Herodu sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tire àti Sidoni; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ ṣọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bilasitu ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tí wọ́n ti ń gba oúnjẹ.
21 Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. 22 Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” 23 Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.
24 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.
25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.
A rán Barnaba àti Paulu fún iṣẹ́ ìránṣẹ́
13 Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu. 2 Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Barnaba àti Saulu sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!” 3 Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.
Ní Saipurọsi
4 Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn méjèèjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Seleusia; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Saipurọsi. 5 Nígbà ti wọ́n sì wà ni Salami, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Sinagọgu àwọn Júù. Johanu náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn.
6 Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Pafosi, wọ́n rí ọkùnrin oṣó àti wòlíì èké kan ti i ṣe Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Bar-Jesu. 7 Ó wà lọ́dọ̀ Segiu Paulusi baálẹ̀ ìlú náà tí í ṣe amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Barnaba àti Saulu, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 8 Ṣùgbọ́n Elimu oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa baálẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́. 9 Ṣùgbọ́n Saulu ti a ń pè ni Paulu, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Elimu, ó sì wí pé, 10 (AT)“Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ èṣù, ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po? 11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí oòrùn ní sá à kan!”
Lójúkan náà, ìkùùkuu àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ. 12 Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.
Ní Pisidia ti Antioku
13 Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu. 14 Nígbà ti wọ́n sì là Perga kọjá, wọ́n wá sí Pisidia ní Antioku. Wọ́n sì wọ inú Sinagọgu ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó. 15 Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí Sinagọgu ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”
16 Paulu sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Israẹli, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi! 17 (AU)Ọlọ́run àwọn ènìyàn Israẹli yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ejibiti, pẹ̀lú agbára ńlá ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀, 18 (AV)ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù, 19 (AW)nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kenaani, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní. 20 Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) ọdún.
“Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídàájọ́ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samuẹli wòlíì. 21 Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún. 22 (AX)Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’
23 “Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí. 24 (AY)Ṣáájú wíwá Jesu ni Johanu ti wàásù bamitiisi ìrònúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Israẹli. 25 (AZ)Bí Johanu sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣe bí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’
26 (BA)“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. 27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. 28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. 29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. 30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, 31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.
32 “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, 33 (BB)èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé:
“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;
lónìí ni mo bí ọ.’
34 (BC)Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé:
“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
35 (BD)Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé:
“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’
36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.
38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín. 39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose. 40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:
41 (BE)“ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;
nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín,
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”
42 Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀. 43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
44 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 45 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ.
46 Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. 47 (BF)Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé:
“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,
kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”
48 Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.
49 A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà. 50 Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn. 51 Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikoniomu. 52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.
Ní Ikoniomu
14 Ó sí ṣe, ni Ikoniomu, Paulu àti Barnaba jùmọ̀ wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn Helleni gbàgbọ́, 2 Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà. 3 Nítorí náà Paulu àti Barnaba gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì mu kí iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe. 4 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apá kan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apá kan pẹ̀lú àwọn aposteli. 5 Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta, 6 wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lysra, àti Dabe, àwọn ìlú Likaonia àti sí agbègbè àyíká. 7 Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere.
Ní Lysra àti Dabe
8 Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí. 9 Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. 10 Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.
11 Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!” 12 Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ. 13 Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí.
14 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: 15 (BG)“Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 16 Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn. 17 Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.” 18 Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.
19 (BH)Àwọn Júù kan sì ti Antioku àti Ikoniomu wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì sọ Paulu ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣe bí ó ti kú. 20 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Barnaba lọ sí Dabe.
Ìpadàbọ̀ sí Antioku ti Siria
21 Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìhìnrere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lysra, àti Ikoniomu, àti Antioku, 22 wọn sì ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró nínú ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ́njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run. 23 Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́. 24 Nígbà tí wọn sí la Pisidia já, wọ́n wá sí pamfilia. 25 Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Perga, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Atalia:
26 Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Antioku ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí 27 Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ìlẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà. 28 Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.
Àjọ ìgbìmọ̀ ní Jerusalẹmu
15 (BI)Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.” 2 Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí. 3 Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin. 4 Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.
5 Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”
6 Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí. 7 Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́. 8 Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa. 9 Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́. 10 Ǹjẹ́ nítorí náà èéṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù? 11 Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jesu àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”
12 Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà. 13 Lẹ́yìn tí wọn sì dákẹ́, Jakọbu dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi: 14 Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀. 15 Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe déédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
16 (BJ)“ ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà,
èmi ó sì tún àgọ́ Dafidi pa tí ó ti wó lulẹ̀:
èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́,
èmi ó sì gbé e ró.
17 Kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa,
àti gbogbo àwọn kèfèrí, lára ẹni tí a ń pe orúkọ mi,’
ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí,
18 ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá.
19 “Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu. 20 Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ́hìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀. 21 Nítorí òfin Mose nígbà àtijọ́ ṣá ní a ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú Sinagọgu ni ọjọọjọ́ ìsinmi.”
Ìwé tí àwọn àjọ ìgbìmọ̀ kọ sí àwọn onígbàgbọ́ aláìkọlà
22 Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin. 23 Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé:
Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà,
Tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria: àti ní Kilikia.
24 Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà, (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́) ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ: 25 Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa. 26 Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi. 27 Nítorí náà àwa rán Judasi àti Sila àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín. 28 Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù le é yin lórí, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì; 29 í ẹ̀yin fàsẹ́yìn kúrò nínú ẹran ti à pa bọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti nínú àgbèrè. Bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere.
Àlàáfíà.
30 Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Antioku. Nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ papọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn. 31 Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà. 32 Bí Judasi àti Sila tìkára wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le. 33 Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. 34 (Ṣùgbọ́n ó wu Sila láti gbé ibẹ̀.) 35 Paulu àti Barnaba sì dúró díẹ̀ ni Antioku, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.
Ìjà láàrín Paulu àti Barnaba
36 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòókan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.” 37 Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku. 38 Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà. 39 Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi. 40 Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin. 41 Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.
Timotiu darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila
16 Ó sì wá sí Dabe àti Lysra: sí kíyèsi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Timotiu, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Giriki ní baba rẹ̀. 2 Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lysra àti Ikoniomu. 3 Òun ni Paulu fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbègbè wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Giriki ni baba rẹ̀. 4 Bí wọn sì ti ń la àwọn ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerusalẹmu, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́. 5 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹ̀múlẹ̀ ní ìgbàgbọ́, wọn sí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojúmọ́.
Ìran Paulu nípa arákùnrin Makedonia
6 Wọ́n sì la agbègbè Frigia já, àti Galatia, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Asia. 7 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn. 8 Nígbà tí wọ́n sì kọjá lẹ́bàá Misia, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Troasi. 9 Ìran kan si hàn sì Paulu ni òru: Ọkùnrin kan ará Makedonia dúró, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Rékọjá wá sí Makedonia, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!” 10 Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedonia, a ka á sí pé, Ọlọ́run tí pè wá láti wàásù ìhìnrere fún wọn.
Ìyípadà Lidia ní Filipi
11 Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Troasi a ba ọ̀nà tààrà lọ sí Samotrakea, ni ọjọ́ kejì a sì dé Neapoli; 12 Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Filipi, tí í ṣe ìlú Makedonia, olú ìlú ìhà ibẹ̀, ìlú lábẹ́ Romu, àwa sì jókòó ní ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókan.
13 Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀. 14 Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lidia, elése àlùkò, ará ìlú Tiatira, ẹni tí ó sin Ọlọ́run, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísí ohun tí a tí ẹnu Paulu sọ. 15 Nígbà tí a sí bamitiisi rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtítọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá.
Paulu àti Sila nínú túbú
16 Bí àwa tí n lọ sí ibi àdúrà náà, ọmọbìnrin kan tí o ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ, pàdé wa, ẹni tí ó fi àfọ̀ṣẹ mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀: 17 Òun náà ni ó ń tọ Paulu àti àwa lẹ́hìn, ó sì ń kígbe, pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yin!” 18 Ó sì ń ṣe èyí lọ́jọ́ púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí inú Paulu bàjẹ́, tí ó sì yípadà, ó wí fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu Kristi kí o jáde kúrò lára rẹ̀!” Ó sí jáde ni wákàtí kan náà.
19 Nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé, ìgbẹ́kẹ̀lé èrè wọn pin, wọ́n mú Paulu àti Sila, wọn sì wọ́ wọn lọ sí ọjà tọ àwọn aláṣẹ lọ; 20 Nígbà tí wọ́n sì mú wọn tọ àwọn onídàájọ́ lọ, wọ́n wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí í ṣe Júù, wọ́n ń yọ ìlú wa lẹ́nu jọjọ; 21 Wọ́n sì ń kọ́ni ní àṣà tí kò yẹ fún wa, àwa ẹni tí í ṣe ara Romu, láti gbà àti láti tẹ̀lé.”
22 (BK)Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì Paulu àti Sila. Àwọn olórí sí fà wọ́n ní aṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fi ọ̀gọ̀ lù wọ́n. 23 Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára: 24 Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀.
25 Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. 26 Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀. 27 Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣe bí àwọn ara túbú ti sálọ. 28 Ṣùgbọ́n Paulu gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má ṣe pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn-ín yìí!”
29 Nígbà tí ó sì béèrè iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Paulu àti Sila. 30 Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”
31 Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jesu Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.” 32 Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. 33 Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a sì bamitiisi rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà. 34 Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.
35 Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídàájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀.” 36 Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Paulu, wí pé, “Àwọn onídàájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da ìwọ àti Sila sílẹ̀. Ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”
37 Ṣùgbọ́n Paulu wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bi, àwa ẹni tí ì ṣe ara Romu. Ṣe nísinsin yìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀? Rara! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkára wọn wá mú wa jáde!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.