Bible in 90 Days
Àdúrà Daniẹli
9 Ní ọdún kìn-ín-ní Dariusi ọmọ Ahaswerusi, ẹni tí a bí ní Media, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Babeli. 2 Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, èmi Daniẹli fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremiah, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jerusalẹmu yóò fi wà ní ahoro. 3 Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú àwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
4 Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé:
“Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. 5 Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀. 6 Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.
7 “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ. 8 Háà! Olúwa, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ. 9 Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí i; 10 Àwa kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀. 11 Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ.
“Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ. 12 Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí. 13 Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mose bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, síbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ rẹ. 14 Olúwa kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí Olódodo ni Olúwa Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe; síbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ràn sí i.
15 “Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. 16 Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.
17 “Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ Olúwa, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro. 18 Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ. 19 Olúwa, fetísílẹ̀! Olúwa, Dáríjì! Olúwa, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”
Àádọ́rin ọ̀sẹ̀
20 Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Israẹli ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ Olúwa Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ. 21 Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gebrieli ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣálẹ́. 22 Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Daniẹli, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye. 23 Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nígbà àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò kí ìran náà sì yé ọ:
24 “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan ẹni mímọ́ jùlọ.
25 “Nítorí náà, mọ èyí pé: Láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé Ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni. 26 Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké Ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn ọmọ-aládé náà tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi: ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro. 27 (A)Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”
Daniẹli rí ìran ọkùnrin kan
10 Ní ọdún kẹta Kirusi ọba Persia, a fi ìran kan hàn Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belteṣassari). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.
2 Ní àsìkò náà, èmi Daniẹli ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. 3 Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.
4 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù àkọ́kọ́, bí mo ti dúró sí etí i bèbè odò ńlá Tigirisi, 5 (B)Mo wo òkè, mo rí ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ àlà, ẹ̀gbẹ́ ẹni tí a fi wúrà Upasi dáradára dì ní àmùrè. 6 Ara rẹ̀ dàbí berili, ojú u rẹ̀ dàbí mọ̀nàmọ́ná, ẹyin ojú u rẹ̀ dàbí iná àtẹ̀tàn, apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ìtànná ìmọ́lẹ̀ tí o kún fún idẹ, àti ohùn rẹ̀ dàbí i ti ìjọ ènìyàn púpọ̀.
7 Èmi Daniẹli, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́. 8 Ó sì ku èmi nìkan, tí mo rí ìran ńlá yìí, kò sì ku okun kankan fún mi, ojú u mi sì rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, n kò sì ní agbára mọ́. 9 Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí i, mo sùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀.
10 Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi. 11 Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì.
12 Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Daniẹli. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà. 13 (C)Ṣùgbọ́n ọmọ-aládé ìjọba Persia dá mi dúró fún ọjọ́mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Mikaeli, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ-aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Persia. 14 Ní ìsinsin yìí mo wá láti ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú, nítorí ìran náà ń sọ nípa ọjọ́ iwájú.”
15 Bí ó sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún mi, mo sì dorí kodò mo sì dákẹ́. 16 Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, olúwa mi, n kò sì ní okun. 17 Ǹjẹ́ báwo ni èmi ìránṣẹ́ ẹ̀ rẹ ṣe lè bá ọ sọ̀rọ̀, olúwa mi? Agbára mi ti lọ, agbára káká ni mo fi ń mí.”
18 Ẹ̀wẹ̀, ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní agbára. 19 Ó sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ ọkùnrin olùfẹ́ gidigidi. Àlàáfíà ni fún ọ, mú ara le, àní mú ara le.”
Nígbà tí ohun bá mi sọ̀rọ̀, a sì mú mi lára le. “Mo sì wí pé, kí olúwa mi kí ó máa sọ̀rọ̀, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ ti mú mi ní ara le.”
20 Nígbà náà, ni ó wí pé, “Ṣé o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Láìpẹ́ èmi yóò yípadà lọ bá àwọn ọmọ-aládé Persia jà, nígbà tí mo bá lọ àwọn ọmọ-aládé Giriki yóò wá; 21 ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́, èmi yóò sọ ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ. (Kò sí ẹni tí ó kún mi lọ́wọ́ fún nǹkan wọ̀nyí bí kò ṣe Mikaeli, ọmọ-aládé e yín. 11 1 Ní ọdún kìn-ín-ní Dariusi ará Media, mo dúró láti tì í lẹ́yìn àti láti dáàbò bò ó.)
Àwọn ọba gúúsù àti àríwá
2 “Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki. 3 Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fi ara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú. 4 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì ṣọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn.
5 “Ọba ìhà gúúsù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jù ú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá. 6 Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dádúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí.
7 “Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọlu ogun ọba àríwá, yóò sì wó odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí. 8 Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Ejibiti. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀. 9 Nígbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, gúúsù, ṣùgbọ́n yóò padà sí orílẹ̀-èdè Òun fúnrarẹ̀ 10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀.
11 “Nígbà náà ni ọba gúúsù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ-ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba gúúsù yóò borí i wọn. 12 Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba gúúsù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa síbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun. 13 Nítorí ọba àríwá yóò lọ kó ogun mìíràn jọ, tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, yóò jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó ti dira ogun fún dáradára.
14 “Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba gúúsù. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí. 15 Nígbà náà ni ọba àríwá yóò wá yóò sì gbé ogun tì í, yóò sì kó ìlú olódi. Ogun ọba gúúsù kò ní ní agbára láti kọjú ìjà sí i; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀wọ́ ogun tó dára jù kò ní ní agbára láti dúró. 16 Ẹni tí ó gbóguntì í yóò máa ṣe bí ó ti wù ú, kò sì ṣí ẹni tí yóò le è dojúkọ ọ́. Yóò sì fún ara rẹ̀ ní ibùjókòó ní ilẹ̀ tí ó dára, yóò sì ní agbára láti bà á jẹ́. 17 Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba gúúsù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò dúró tàbí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. 18 Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí Òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí rẹ̀. 19 Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fúnrarẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì ṣubú, a kì yóò sì rí i mọ́.
20 “Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun.
21 “Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè. 22 Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ-aládé ti májẹ̀mú náà ni a ó parun. 23 Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú ìwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba. 24 Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbóguntì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógun ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.
25 “Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ sókè sí ọba gúúsù. Ọba gúúsù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní le è dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbèrò sí i. 26 Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun: a ó gbá ogun rẹ̀ dànù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun. 27 Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn. 28 Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè òun fúnrarẹ̀.
29 “Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí gúúsù lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọríṣí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú. 30 Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò takò ó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pami. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojúrere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà.
31 (D)“Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀. 32 Pẹ̀lú irú àwọn tí ń ṣe búburú sí májẹ̀mú ní yóò fi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni mú ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò mú ọkàn le. Wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ agbára.
33 “Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógun. 34 Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìṣòótọ́ yóò sì darapọ̀ mọ́ wọn. 35 Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a ba à tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn.
Ọba tí ó gbé ara rẹ̀ ga
36 “Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀. 37 Òun kò ní ka òrìṣà àwọn baba rẹ̀ sí tàbí èyí tí àwọn fẹ́, òun kò ní ka nǹkan kan sí, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ. 38 Ṣùgbọ́n dípò wọn, yóò bu ọlá fún òrìṣà àwọn ìlú olódi: òrìṣà tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni yóò bu ọlá fún pẹ̀lú wúrà àti fàdákà, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti ẹ̀bùn tí ó lówó lórí. 39 Yóò kọlu àwọn ìlú olódi tí ó lágbára pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òrìṣà àjèjì, yóò sì bu ọláńlá fún ẹni tí ó jẹ́wọ́ rẹ̀. Yóò mú wọn ṣe alákòóso lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí èrè.
40 “Ní ìgbà ìkẹyìn, ọba gúúsù yóò gbé ogun de sí i, ọba àríwá yóò sì jáde bí ìjì láti kọlù ú pẹ̀lú u kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ojú omi. Yóò gbógun wọ orílẹ̀-èdè púpọ̀, yóò sì bo wọn mọ́lẹ̀ bí ìkún omi. 41 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún gbógun ti ilẹ̀ ológo náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò ṣubú, ṣùgbọ́n Edomu, Moabu àti àwọn olórí Ammoni yóò bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. 42 Yóò lo agbára rẹ̀ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè; Ejibiti kì yóò là. 43 Yóò gba àkóso ìṣúra wúrà àti fàdákà àti gbogbo ọrọ̀ Ejibiti, pẹ̀lú ti Libia àti Kuṣi nígbà tí ó mú wọn tẹríba. 44 Ṣùgbọ́n ìròyìn láti ìlà-oòrùn àti láti ìwọ̀-oòrùn yóò mú ìdáríjì bá a, yóò sì fi ìbínú ńlá jáde lọ láti parun, àti láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run pátápátá. 45 Yóò sì pàgọ́ ọ rẹ̀ láàrín Òkun kọjú sí àárín òkè mímọ́ ológo Síbẹ̀ yóò wá sí òpin rẹ̀, ẹnìkan kò ní ràn án lọ́wọ́.
Ìgbà ìkẹyìn
12 (E)“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. 2 (F)Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. 3 (G)Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. 4 (H)Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”
5 Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè. 6 Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”
7 (I)Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”
8 Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”
9 Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn. 10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.
11 (J)“Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290). 12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ (1,335).
13 “Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli:
Ìdílé Hosea
2 Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.” 3 Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.
4 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin. 5 Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní Àfonífojì Jesreeli.”
6 (K)Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà, nítorí pé Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n. 7 Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”
8 Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-rúhámà, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni 9 Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.
10 “Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ 11 Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.
2 “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘àyànfẹ́ mi.’
Ẹ̀sùn tí a fi kan ìyàwó aláìṣòótọ́
2 “Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí,
nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,
Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀
àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.
3 Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò
Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i.
Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀
Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.
4 Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀
nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́
5 Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè,
ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.
Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn,
tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,
ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi,
òróró mi àti ohun mímu mi.’
6 Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà
Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
7 Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;
Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.
Nígbà náà ni yóò sọ pé,
‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́
nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’
8 Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni
àti ẹni tó fún un ní ọkà,
ọtí wáìnì tuntun àti òróró
ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Baali.
9 “Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n,
èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀.
Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà
ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.
10 Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn
lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi
11 Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin:
àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀,
ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn.
12 Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run,
èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀,
Èmi yóò sọ wọ́n di igbó,
àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.
13 Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀
nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali;
tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,
tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ.
Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,”
ni Olúwa wí.
14 “Nítorí náà, èmi yóò tàn án
Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀
Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀
15 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,
Èmi yóò fi Àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.
Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.
16 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,
Ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’;
Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’
ni Olúwa wí.
17 Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀;
ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́
18 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú
fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti
àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.
Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́
Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà
kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
19 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé.
Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti
òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.
20 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́
ìwọ yóò sì mọ Olúwa.
21 “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà”
ni Olúwa wí.
“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn
àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
22 Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,
wáìnì tuntun àti òróró lóhùn
Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.
23 Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà
Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àánú Gbà.’
Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’
‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”
Hosea bá ìyàwó rẹ làjà
3 Olúwa sì wí fún mi pé, “Tun lọ fẹ́ obìnrin kan tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Olúwasì àwọn ọmọ Israẹli tí ń wo àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì ń fẹ́ àkàrà èso àjàrà.”
2 Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan. 3 Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú rẹ.”
4 Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan. 5 Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan Israẹli
4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli,
nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn
kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà.
“Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́
Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà
2 Àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn
olè jíjà àti panṣágà.
Wọ́n rú gbogbo òfin,
ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
3 Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo
olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.
Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run
àti ẹja inú omi ló ń kú.
4 “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,
kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì
nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí
àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà
5 Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru
àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín
Èmi ó pa ìyá rẹ run
6 Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀.
“Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀.
Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi;
nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀
Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
7 Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.
Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
8 wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi
Wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
9 Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí
Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn.
Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
10 “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;
wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,
nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa
sílẹ̀ 11 ‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè,
wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́
àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù 12 Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi
ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn.
Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà
wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
13 Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá,
Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré
Lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari
àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára
Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè
àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.
14 “Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín
ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè
tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín,
nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè
nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́.
Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!
15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli
Ìdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi.
“Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali.
Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni
ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
16 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí
bí alágídí ọmọ màlúù
Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn
bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
17 Efraimu ti darapọ̀ mọ́
òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀!
18 Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán
wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè
Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
19 Ìjì ni yóò gbá wọn lọ.
Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.
Ìdájọ́ n bọ̀ lórí Israẹli àti Juda
5 “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!
Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!
Ìdájọ́ yìí kàn yín:
Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa
àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori
2 Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn
gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
3 Mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu
Israẹli kò sì pamọ́ fún mi
Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè
Israẹli sì ti díbàjẹ́.
4 “Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè
láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.
Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,
wọn kò sì mọ Olúwa.
5 Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;
Àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
6 Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran
àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,
wọn kò ní rí i,
ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
7 Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa
wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.
Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,
ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.
8 “Fọn fèrè ní Gibeah,
kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni
máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
9 Efraimu yóò di ahoro
ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli
Mo sọ ohun tí ó dájú.
10 Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
wọn lórí bí ìkún omi.
11 A ni Efraimu lára,
A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́
nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà
12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu
Mo sì dàbí ìdin ara Juda.
13 “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,
tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀
ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,
ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́
Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn
bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná
14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,
bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.
Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;
Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi
títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi
wọn yóò sì wá ojú mi
nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”
Àìronúpìwàdà Israẹli
6 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
2 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
3 Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa
Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
Yóò jáde;
Yóò tọ̀ wá wá bí òjò
bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”
4 “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
5 Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.
Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi
Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
6 (L)Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.
7 Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú
wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
8 Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú
tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.
9 Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;
tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu,
tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.
10 Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù
ní ilé Israẹli.
Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè
Israẹli sì di aláìmọ́.
11 “Àti fún ìwọ, Juda
A ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.
“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,
7 nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá.
Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn
ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta.
Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn,
àwọn olè ń fọ́ ilé;
àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;
2 Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé
mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn:
Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá;
wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.
3 “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,
àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn
4 Alágbèrè ni gbogbo wọn
wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà
tí a dáwọ́ kíkoná dúró,
lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
5 Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa
wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná
ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
6 Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò
wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí,
ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru
ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀.
7 Gbogbo wọn gbóná bí ààrò
wọ́n pa gbogbo olórí wọn run,
gbogbo ọba wọn si ṣubú
kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.
8 “Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;
Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà
9 Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run
ṣùgbọ́n kò sì mọ̀,
Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri
bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i
10 Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i
ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí
kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa
Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.
11 “Efraimu dàbí àdàbà
tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n
tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí
tó sì tún ń padà lọ si Asiria.
12 Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn
Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run
Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀
Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.
13 Ègbé ní fún wọn,
nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ìparun wà lórí wọn,
nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!
Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà.
Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi
14 Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,
Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn.
Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì
ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
15 Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára,
síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
16 Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo;
wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́
Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú
nítorí ìrunú ahọ́n wọn.
Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe
ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.
Israẹli yípadà kúrò ní ọnà
8 “Fi ìpè sí ẹnu rẹ!
Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa
nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,
wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
2 Israẹli kígbe pè mí
‘Háà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
3 Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀
ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀
4 Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi
wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀.
Wọ́n fi fàdákà àti wúrà
ṣe ère fún ara wọn,
si ìparun ara wọn.
5 Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria!
Ìbínú mi ń ru sí wọn:
yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
6 Israẹli ni wọ́n ti wá!
Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe é
Àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
7 “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́
wọ́n sì ká ìjì
Igi ọkà kò lórí,
kò sì ní mú oúnjẹ wá.
Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà
àwọn àjèjì ni yóò jẹ.
8 A ti gbé Israẹli mì,
báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
bí ohun èlò tí kò wúlò.
9 Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri.
Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín orílẹ̀-èdè
Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí
Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù
lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀
gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn.
Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì
13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,
wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀
Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.
Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Wọn yóò padà sí Ejibiti
14 (M)Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀
Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀
Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀
ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan
sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”
Ìdájọ́ fún ẹsẹ̀ Israẹli
9 Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli;
má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín.
Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè
ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.
2 Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ
wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀
3 Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa
Efraimu yóò padà sí Ejibiti
Yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.
4 Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.
Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.
Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.
Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.
Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnrawọn
kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.
5 Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn
ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?
6 Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun
Ejibiti yóò kó wọn jọ,
Memfisi yóò sì sin wọ́n.
Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún,
Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.
Ẹ̀gún yóò sì bo
gbogbo àgọ́ wọn.
7 (N)Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;
àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé
Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí
Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀
ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.
A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀
A ka ẹni ìmísí sí asínwín.
8 Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,
ni olùṣọ́ ọ Efraimu.
Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀
9 Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́
gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah
Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
10 “Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù.
Mo rí àwọn baba yín,
bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀.
Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ,
wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni,
ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. 11 Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ
kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.
12 Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà.
Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn
Ègbé ni fún wọn,
nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!
13 Mo rí Efraimu bí ìlú Tire
tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára
ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn
ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”
14 Fún wọn, Olúwa!
Kí ni ìwọ yóò fún wọn?
Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́
àti ọyàn gbígbẹ.
15 “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali
Mo kórìíra wọn níbẹ̀,
nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi
Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́
ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.
16 Efraimu ti rẹ̀ dànù
gbogbo rẹ̀ sì ti rọ,
kò sì so èso,
Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.
Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”
17 Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀
nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i;
wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀
ó ń so èso fún ara rẹ̀
Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i
bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere
o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.
2 Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ
báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn.
Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀
yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.
3 Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba
nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa
ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba,
kí ni yóò ṣe fún wa?”
4 Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀,
wọ́n ṣe ìbúra èké,
wọ́n da májẹ̀mú;
báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko,
bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro.
5 Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù
nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni
Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀
Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀,
nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.
6 A ó gbé lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá
a ó dójútì Efraimu;
ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀
7 Bí igi tó léfòó lórí omi ni
Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.
8 (O)Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun—
èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli.
Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde,
yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn.
Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!”
àti fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Ṣubú lù wá!”
9 “Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli
ìwọ sì tún wà níbẹ̀.
Ǹjẹ́ ogun kò lé
ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí?
10 Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n;
orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ wọ́n ó sì dojúkọ wọn
Láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
11 Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́,
to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà;
lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni
èmi ó dí ẹrù wúwo lé.
Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin
Juda yóò tú ilẹ̀,
Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀.
12 (P)Ẹ gbin òdòdó fún ara yín,
kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin,
Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro,
nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa,
títí tí yóò fi dé,
tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.
13 Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi,
Ẹ ti jẹ èso èké
nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín
àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín
14 Ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín
kí gbogbo odi agbára yín ba le parun.
Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun,
nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn
15 Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli,
nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù.
Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà,
a o pa ọba Israẹli run pátápátá.
Ìfẹ́ Ọlọ́run sí Israẹli
11 (Q)“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀,
mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.
2 Bí a ti ń pe wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi,
wọn rú ẹbọ sí Baali,
wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.
3 Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn
mo di wọ́n mú ní apá,
ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀
pé mo ti mú wọn láradá.
4 Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n
àti ìdè ìfẹ́.
Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn
Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.
5 “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí
Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí
nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?
6 Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn
yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́
yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn.
7 Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi
bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ,
kò ní gbé wọn ga rárá.
8 “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu?
Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma?
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣeboimu?
Ọkàn mi yípadà nínú mi
àánú mi sì ru sókè
9 Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ,
tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro.
Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn
Ẹni mímọ́ láàrín yín,
Èmi kò ní í wá nínú ìbínú
10 Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;
òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún
Nígbà tó bá bú
àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.
11 Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù
bí i ẹyẹ láti Ejibiti
bí i àdàbà láti Asiria
Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,”
ni Olúwa wí.
Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli
12 Efraimu tí fi irọ́ yí mi ká
ilé Israẹli pẹ̀lú ẹ̀tàn.
Ṣùgbọ́n Juda sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run
Ó sì ṣe olóòtítọ́ sí Ẹni mímọ́ Israẹli.
12 Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́;
o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́.
O sì ń gbèrú nínú irọ́
o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria
o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti.
2 Olúwa ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò,
yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.
3 Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀,
àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
4 Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀
o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀
Ó bá Olúwa ní Beteli
Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
5 àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun;
Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀
6 Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;
di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú
kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
7 Oníṣòwò ń lo òṣùwọ̀n èké
o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ.
8 (R)Efraimu gbéraga,
“Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,
pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé
tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”
9 “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ;
ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti;
èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́
bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì
10 Mo sọ fún àwọn wòlíì,
mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n
mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”
11 Gileadi ha burú bí?
Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán.
Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali?
Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè
nínú aporo oko.
12 Jakọbu sálọ si orílẹ̀-èdè Aramu;
Israẹli sìn kí o tó fẹ́ ìyàwó
ó ṣe ìtọ́jú ẹran láti fi san owó ìyàwó.
13 Olúwa lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti,
nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
14 Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi;
Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀
òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.
Ìbínú Olúwa sí Israẹli
13 Nígbà ti Efraimu bá ń sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì,
a gbé e ga ní Israẹli
ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó ń sin òrìṣà Baali, ó sì kú.
2 Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀
wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnrawọn
ère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sí
gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà
Wọn ń sọ nípa àwọn ènìyàn
wọ̀nyí. Pé, Jẹ́ kí àwọn
“Ènìyàn tí ń rú ẹbọ fi ẹnu
ko àwọn ẹgbọrọ màlúù ni ẹnu.”
3 Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀,
bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́,
bí i èèpo ìyẹ̀fun tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà
bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé.
4 “Ṣùgbọ́n Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ̀,
ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.
Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi
kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi
5 Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù
ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi
6 Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ
Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga
Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.